Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Rin Kinkin Mọ́ Ohun Tó Bá Ṣáà Ti Wù Ọ́?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Rin Kinkin Mọ́ Ohun Tó Bá Ṣáà Ti Wù Ọ́?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Rin Kinkin Mọ́ Ohun Tó Bá Ṣáà Ti Wù Ọ́?

ÀWỌN ọmọdé méjì jọ ń ṣeré. Ọ̀kan nínú wọn já ohun ìṣeré tó wù ú gbà lọ́wọ́ èkejì rẹ̀, ó ní, “Tèmi ni!” Èyí fi hàn pé àtikékeré ni ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ti máa ń wà nínú ọkàn àwa ẹ̀dá aláìpé. (Jẹ́n. 8:21; Róòmù 3:23) Yàtọ̀ síyẹn, ohun tó gbayé kan ni pé àwọn èèyàn kì í sábà ro tẹlòmíì mọ́ tiwọn. Àfi ká sa gbogbo ipá wa láti dènà ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, tá ò bá fẹ́ kírú ìwà yẹn ràn wá. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè máa mú àwọn èèyàn kọsẹ̀, ká sì ṣàkóbá fún àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà.—Róòmù 7:21-23.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká máa ro ipa tí ìwà wa máa ní lórí àwọn èèyàn, ó ní: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní. Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró.” Ó tún sọ pé: “Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀.” (1 Kọ́r. 10:23, 32) Tí ọ̀ràn èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ bá délẹ̀, ó yẹ ká máa bi ara wa pé: ‘Ṣé mo lè yááfì àwọn ohun tí mo lẹ́tọ̀ọ́ sí, tó bá di pé ọ̀ràn náà fẹ́ di wàhálà nínú ìjọ? Ṣé màá fẹ́ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tó bá tiẹ̀ nira fún mi láti tẹ̀ lé e?’

Tó Bá Dọ̀ràn Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn fúnra wọn ló yẹ kó ṣèpinnu lórí ọ̀ràn iṣẹ́ tó yẹ káwọn ṣe, pé tó bá tiẹ̀ máa wá kan ẹnikẹ́ni, ìwọ̀nba ni. Ṣùgbọ́n wo ìrírí ọ̀gbẹ́ni oníṣòwò kan tó fìdí kalẹ̀ sí ìlú kékeré kan ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Ògbólógbòó atatẹ́tẹ́ àti ọ̀mùtí paraku ni. Àmọ́ báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń fohun tó ń kọ́ ṣèwà hù, ìgbésí ayé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. (2 Kọ́r. 7:1) Nígbà tó sọ pé òun fẹ́ máa bá àwọn ará ìjọ jáde lọ wàásù, alàgbà kan fi ọgbọ́n sọ fún un pé kó ronú nípa irú iṣẹ́ tó ń ṣe. Ní gbogbo ìgbà yẹn, òun ni alágbàtà tó ń kó ògidì ògógóró tí wọ́n ń fi ìrèké ṣe wá sí ìlú yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n máa ń fi ògógóró yìí ṣe, àmọ́ lágbègbè yẹn, wọ́n sábàá máa ń fi í lú ọtí ẹlẹ́rìndòdò kí wọ́n tó mu ún kó bàa lè wọ̀ wọ́n lára dáadáa.

Ọ̀gbẹ́ni yẹn wòye pé tóun bá ń wàásù fáwọn èèyàn tóun sì tún ń ta irú ọjà yìí, ó máa ba orúkọ ìjọ tóun ń dara pọ̀ mọ́ jẹ́, kò sì ní jẹ́ kóun lájọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bùkátà ìdílé pọ̀ lọ́rùn rẹ̀, ó pa òwò ògógóró tó ń ṣe tì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta àwọn ohun tí wọ́n ń fi bébà ṣe. Ibẹ̀ ló sì ti ń rí ìwọ̀nba owó tó fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Ní báyìí, ọkùnrin yìí àtìyàwó rẹ̀, tó fi mọ́ méjì nínú àwọn ọmọ márùn-ún tó bí ló ti ṣèrìbọmi, wọ́n sì ti ń fìtara wàásù ìhìn rere pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.

Tó Bá Dọ̀ràn Yíyan Alábàákẹ́gbẹ́

Ṣé ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-kò-wù-ọ́ náà lọ̀rọ̀ yíyan ẹni téèyàn á máa bá rìn, àbí ó láwọn ìlànà Bíbélì kan tó yẹ kéèyàn tẹ̀ lé? Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan fẹ́ bá ọmọkùnrin kan tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ lọ sóde àríyá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kìlọ̀ fún un pé ó léwu, àmọ́ ó rò pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti bá ẹni tó wu òun lọ síbi tó bá wu òun, torí náà ó lọ sóde yẹn. Kò pẹ́ tó débẹ̀ ni wọ́n fún un ní ọtí tí wọ́n ti po oògùn oorun tó lágbára mọ́. Ló bá sùn lọ fọnfọn, nígbà tó sì fi máa jí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí, ó rí i pé ẹni tóun ń pè lọ́rẹ̀ẹ́ òun yìí ti bá òun lò pọ̀.—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 34:2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, èèyàn lè má kàgbákò bí irú tọmọbìnrin yẹn téèyàn bá ń bá àwọn aláìgbàgbọ́ rìn, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Láìsí àní-àní, ńṣe lẹni tó bá ń kó ẹgbẹ́ búburú ń rìn ní bèbè àgbákò! Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” Irú àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè ṣàkóbá fún wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 15:33; Ják. 4:4.

Tó Bá Dọ̀ràn Ìwọṣọ àti Ìmúra

Àṣà ìwọṣọ àti ìmúra máa ń bá ìgbà yí ni, àmọ́ ìyẹn ò ní kí ìlànà Bíbélì nípa ìwọṣọ àti ìmúra yí pa dà. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” Bí ìlànà yìí sì ṣe kan àwọn obìnrin ló ṣe kan àwọn ọkùnrin. (1 Tím. 2:9) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kò fi hàn pé ṣe ló yẹ káwa Kristẹni máa múra ṣákálá, tàbí kí gbogbo wa máa múra lọ́nà kan náà. Kí wá ni ìtumọ̀ ìmẹ̀tọ́mọ̀wà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí? Ohun tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà yẹn túmọ̀ sí ni pé kéèyàn mọ ohun tó tọ́ àti ìwà tó yẹ kó máa hù, ó tún kan pé kéèyàn máa wọṣọ, kó máa sọ̀rọ̀, kó sì máa hùwà lọ́nà tó bójú mu.

Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo lè fi gbogbo ọkàn mi sọ pé amẹ̀tọ́mọ̀wà ni mí tí mo bá ń rin kinkin pé mo lẹ́tọ̀ọ́ láti máa múra lọ́nà tó wù mí, bí ìmúra mi bá tiẹ̀ ń jẹ́ káwọn èèyàn máa fi mí ṣèran wò? Ṣé ọ̀nà tí mo gbà ń múra kì í jẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé oníwàkiwà ni mí, pé ìwà mi kò dáa?’ Tá ò bá fẹ́ “jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀” lórí ọ̀ràn yìí, kò yẹ ká máa ‘mójú tó ire wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’—2 Kọ́r. 6:3; Fílí. 2:4.

Tó Bá Dọ̀ràn Ìṣòwò

Nígbà tí ọ̀ràn ńlá kan tó jẹ mọ́ ṣíṣe èrú tàbí lílu jìbìtì ń jà ràn-ìn nínú ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín? Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a lu ẹ̀yin fúnra yín ní jìbìtì?” Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n múra tán láti yááfì nǹkan kan dípò kí wọ́n máa gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́. (1 Kọ́r. 6:1-7) Arákùnrin kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ̀ràn yìí. Ó bá arákùnrin kan ṣiṣẹ́, àwọn méjèèjì sì wá ní èrò tó yàtọ̀ lórí iye owó tó yẹ kó gbà. Àwọn méjèèjì tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ lórí ọ̀ràn yẹn, wọ́n bá ara wọn sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́pọ̀ ìgbà àmọ́ wọn ò rójútùú ẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n gbé e lọ sínú “ìjọ,” ìyẹn níwájú àwọn alàgbà.—Mát. 18:15-17.

Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀ràn yẹn ò mà lójútùú o. Lẹ́yìn tí arákùnrin tó gbà pé wọ́n jẹ òun lówó yìí ti gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà, ó yááfì èyí tó pọ̀ jù lára owó yẹn. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó sọ ìdí rẹ̀ nígbà tó yá, ó ní: “Ọ̀rọ̀ tá à ń fà mọ́ ara wa lọ́wọ́ yìí ti fẹ́ ba ayọ̀ mi jẹ́, ó sì ń gba àkókò tó yẹ kí n fi máa sin Ọlọ́run mọ́ mi lọ́wọ́.” Lẹ́yìn tí arákùnrin yẹn ti mójú kúrò nínú ọ̀ràn yẹn, ó rí i pé òun tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ àti pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìsìn òun.

Àní Lórí Ọ̀ràn Kéékèèké Pàápàá

Tá ò bá máa rin kinkin mọ́ ohun tó bá ṣáà ti wù wá, ó tún máa ń ṣàǹfààní fún wa lórí àwọn ọ̀ràn kéékèèké. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ àgbègbè kan, tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ti tètè dé, wọ́n sì ti jókòó síbi tó wù wọ́n. Bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀, ìdílé ńlá kan dé sínú gbọ̀ngàn ńlá tí wọ́n ti ń ṣe àpéjọ yẹn, lẹ́yìn tí èrò ti kún ibẹ̀. Bí tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yẹn ṣe rí i pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí ń wá àyè ìjókòó táá gbà wọ́n tọmọtọmọ, wọ́n dìde fún wọn. Èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo ìdílé yẹn láti jókòó pa pọ̀. Ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn àpéjọ yẹn, tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yẹn gba lẹ́tà ìdúpẹ́ kan látọ̀dọ̀ ìdílé tí wọ́n fún láyè ìjókòó. Wọ́n ṣàlàyé nínú lẹ́tà náà pé ó dun àwọn báwọn ṣe pẹ́ dé sí àpéjọ náà, àti pé ẹ̀dùn ọkàn àwọn dayọ̀ nígbà tí tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà yìí dìde fáwọn lórí ìjókòó, àwọn sì mọrírì rẹ̀ gan-an ni.

Nígbà táwa náà bá láǹfààní láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi tinútinú yọ̀ǹda ohun tó wù wá fún àwọn ẹlòmíì. Tá a bá ń lo ìfẹ́ tí “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan,” a ó lè jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìjọ àti láàárín àwa àtàwọn tó sún mọ́ wa. (1 Kọ́r. 13:5) Àmọ́, pabanbarì rẹ̀ ni pé a ó lè máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà nìṣó.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ṣé o ṣe tán láti yááfì ohun tó wù ọ́ tó bá dọ̀ràn ìmúra rẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Ṣé o ṣe tán láti dìde fáwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ kí wọ́n lè ráyè jókòó?