Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Máa Ń Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jésù Tó O Bá Ń Gbàdúrà?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jésù Tó O Bá Ń Gbàdúrà?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jésù Tó O Bá Ń Gbàdúrà?

“Nígbà tí Jésù parí àwọn àsọjáde wọ̀nyí, ìyọrísí rẹ̀ ni pé háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.”—MÁT. 7:28.

1, 2. Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni fi ya àwọn èèyàn lẹ́nu?

 Ó YẸ ká gba ọ̀rọ̀ Jésù Kristi, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run gbọ́, ká sì máa tẹ̀ lé e. Kò sẹ́ni tó mọ̀rọ̀ọ́ sọ tó o láyé. Àní, ọ̀nà tó gbà kọ́ni nígbà tó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè ya àwọn èèyàn lẹnu gan-an!—Ka Mátíù 7:28, 29.

2 Kristi Ọmọ Jèhófà kò kọ́ni bíi tàwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n máa ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ èèyàn aláìpé kọ́ni. Ńṣe ló ń kọ́ni “bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ” torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti gbọ́ àwọn ohun tó ń sọ. (Jòh. 12:50) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ míì tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè nígbà tá a bá ń gbàdúrà.

Má Ṣe Gbàdúrà Bíi Tàwọn Alágàbàgebè

3. Sọ kókó inú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 6:5.

3 Nǹkan pàtàkì ni àdúrà jẹ́ nínú ìjọsìn tòótọ́, ó sì yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Ṣùgbọ́n ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìlànà àdúrà gbígbà tí Jésù fi lélẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè. Ó ní: “Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn alágàbàgebè; nítorí wọ́n fẹ́ láti máa gbàdúrà ní dídúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní àwọn igun oríta, kí àwọn ènìyàn bàa lè rí wọn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún.”Mát. 6:5.

4-6. (a) Kí nìdí táwọn Farisí fi fẹ́ràn kí wọ́n máa gbàdúrà “ní dídúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní àwọn igun oríta”? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé irú àwọn alágàbàgebè bẹ́ẹ̀ “ń gba èrè wọn ní kíkún”?

4 Bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bá ń gbàdúrà, wọn kò gbọ́dọ̀ fara wé àwọn Farisí “alágàbàgebè” tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn, tí wọ́n máa ń ṣe bí ẹni mímọ́, tó sì jẹ́ pé ojú ayé lásán ni wọ́n ń ṣe. (Mát. 23:13-32) Àwọn alágàbàgebè yẹn fẹ́ràn kí wọ́n máa gbàdúrà “ní dídúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní àwọn igun oríta.” Nítorí kí ni? “Kí àwọn ènìyàn bàa lè rí wọn” ni. Ṣé ẹ rí i, àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní sábà máa ń gbàdúrà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ lákòókò ẹbọ sísun ní tẹ́ńpìlì (ìyẹn ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀ àti aago mẹ́tà ọ̀sán). Ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù máa ń gbàdúrà pọ̀ pẹ̀lú àwùjọ àwọn olùjọsìn ní àyíká tẹ́ńpìlì lákòókò náà. Àmọ́ àwọn Júù olùfọkànsìn yòókù tí kò sí ní Jerúsálẹ́mù sábà máa ń gbàdúrà lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́ ‘lórí ìdúró nínú àwọn sínágọ́gù.’—Fi wé Lúùkù 18:11, 13.

5 Níwọ̀n bí àkókò àdúrà yìí kì í ti í bá ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn nítòsí tẹ́ńpìlì tàbí nítòsí sínágọ́gù, wọ́n sábà máa ń gbàdúrà níbikíbi tí àkókò àdúrà bá ti bá wọn. Àwọn kan máa ń mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kí àkókò àdúrà bá àwọn “ní àwọn igun oríta,” nítorí “kí àwọn ènìyàn” tó ń kọjá ní oríta wọ̀nyẹn “bàa lè rí wọn.” Àwọn alágàbàgebè tó máa ń ṣe bí ẹni mímọ́ yìí á wá máa “gba àdúrà gígùn fún bojúbojú” kí àwọn tó ń rí wọn bàa lè máa kan sáárá sí wọn. (Lúùkù 20:47) Kò yẹ káwa máa ṣe bíi tàwọn alágàbàgebè yẹn.

6 Jésù sọ pé irú àwọn alágàbàgebè bẹ́ẹ̀ “ń gba èrè wọn ní kíkún.” Ohun tó ń wù wọ́n ṣáá ni pé káwọn èèyàn máa yìn wọ́n, kí wọ́n sì máa kan sáárá sí wọn. Èrè wọn ò sì ní jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè wọn nìyẹn, torí Jèhófà kò ní gbọ́ àdúrà àgàbàgebè wọn. Àmọ́ Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ síwájú sí i nípa àdúrà gbígbà ló fi hàn bẹ́ẹ̀.

7. Kí ni ìtọ́ni tí Jésù fún wa pé ká “lọ sínú yàrá àdáni” wa tá a bá fẹ́ gbàdúrà, túmọ̀ sí?

7 Jésù sọ pé: “Ìwọ, bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.” (Mát. 6:6) Ìtọ́ni tí Jésù fún wa pé ká lọ sínú yàrá àdáni ká sì tilẹ̀kùn tá a bá fẹ́ gbàdúrà, kò fi hàn pé èèyàn ò lè ṣojú fún ìjọ láti gbàdúrà. Ńṣe ni Jésù fún wa ní ìtọ́ni yìí láti fi kọ́ wa pé, tá a bá ń gbàdúrà láwùjọ kò tọ̀nà láti máa gbà á lọ́nà tí a ó fi pàfiyèsí sára wa tàbí ká máa gbà á lọ́nà tá a ó fi gba ìyìn lọ́dọ̀ àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká máa fi èyí sọ́kàn nígbà tá a bá láǹfààní àtiṣojú fún àwùjọ èèyàn Ọlọ́run láti gbàdúrà. Ẹ sì jẹ́ ká tẹ̀ lé ìtọ́ni míì tí Jésù tún fún wa lórí ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà.

8. Kí ni Mátíù 6:7 fi hàn pé kò tọ́ láti máa ṣe tá a bá ń gbàdúrà?

8 Jésù tún sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.” (Mát. 6:7) Jésù tipa báyìí tọ́ka sí nǹkan míì tí kò tọ́ láti máa ṣe tá a bá ń gbàdúrà, ìyẹn sísọ àsọtúnsọ. Kò sọ pé ká má máa tún ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá àti ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ sọ nínú àdúrà wa o. Jésù alára tún “ọ̀rọ̀ kan náà” sọ ní ẹ̀ẹ̀melòó kan nígbà tó ń gbàdúrà nínú ọgbà Gẹtisémánì lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la tó máa kú.—Máàkù 14:32-39.

9, 10. Irú àwọn àdúrà wo ni kò yẹ ká máa gbà?

9 Kò tọ̀nà pé ká máa gbàdúrà alásọtúnsọ bíi ti “àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè.” Ní tiwọn, ńṣe ni wọ́n máa ń sọ ohun kan náà tí wọ́n ti há sórí “ní àsọtúnsọ,” tòun ti ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tí kò wúlò. Àwọn olùjọsìn Báálì kò rí ohunkóhun gbà pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń ké pe òrìṣà yẹn “láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan, pé: ‘Báálì, dá wa lóhùn!’” (1 Ọba 18:26) Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lónìí ló ń gbàdúrà alásọtúnsọ tó gùn jàn-ànràn jan-anran ní èrò pé “a óò gbọ́ tiwọn,” tó sì jẹ́ pé lórí asán ni. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e, ó jẹ́ kó yé wa pé téèyàn bá ń ‘lo ọ̀rọ̀ púpọ̀’ láti fi gbàdúrà alásọtúnsọ tó gùn, Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ sí i.

10 Jésù sọ pé: “Nítorí náà, ẹ má ṣe dà bí wọn, nítorí Ọlọ́run tí í ṣe Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” (Mát. 6:8) Ọ̀pọ̀ aṣáájú ìsìn àwọn Júù máa ń sọ ọ̀rọ̀ gígùn jàn-ànràn jan-anran tí wọ́n bá ń gbàdúrà, èyí tó mú kí wọ́n dà bí àwọn Kèfèrí. Àdúrà ìyìn, ìdúpẹ́, àti ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́. (Fílí. 4:6) Síbẹ̀, kò tọ́ ká máa sọ ohun kan náà léraléra ní èrò pé àsọtúnsọ la máa fi tẹ ohun tá à ń fẹ́ mọ́ Ọlọ́run létí, kó má bàa gbàgbé wa. Nígbà tá a bá ń gbàdúrà, a ní láti máa rántí pé Ẹni tó ‘mọ àwọn ohun tí a ṣe aláìní kí a tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá’ là ń bá sọ̀rọ̀.

11. Kí la ní láti máa fi sọ́kàn tá a bá láǹfààní láti ṣojú fún àwùjọ láti gbàdúrà?

11 Ó yẹ kí ohun tí Jésù sọ nípa irú àdúrà tí Ọlọ́run kì í gbọ́ jẹ́ ká máa rántí pé lílo ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tàbí àsọrégèé ọ̀rọ̀ kì í jọ Ọlọ́run lójú. A tún ní láti máa fi sọ́kàn pé tá a bá ń ṣojú fún àwùjọ láti gbàdúrà, kò yẹ ká máa wá bá a ṣe máa fi àdúrà wú wọn lórí, kò sì yẹ kí àdúrà wa gùn débi pé agara á ti dá wọn, tí wọ́n á máa retí ìgbà tá a máa ṣe “Àmín.” Lójú ohun tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè, ó lòdì láti máa fi àdúrà ṣèfilọ̀, láti máa fi báni wí tàbí láti máa fi gbani nímọ̀ràn.

Jésù Kọ́ Wa Bá A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà

12. Ṣàlàyé ohun tí gbólóhùn náà, “kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́” túmọ̀ sí.

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣèkìlọ̀ nípa ṣíṣi àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti máa gbàdúrà lò, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè máa gbàdúrà. (Ka Mátíù 6:9-13.) Kì í ṣe pé ká wá há àdúrà àwòkọ́ṣe yẹn sórí ká lè máa kà á lákàtúnkà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa gbàdúrà tiwa. Bí àpẹẹrẹ, ti Ọlọ́run ni Jésù fi ṣáájú nínú àdúrà yẹn. Ó bẹ̀rẹ̀ báyìí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Ó tọ́ tá a bá pe Jèhófà ní “Baba wa” torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, tó ń gbé lókè “ọ̀run” lọ́hùn-ún. (Diu. 32:6; 2 Kíró. 6:21; Ìṣe 17:24, 28) Pípè tá à ń pe Ọlọ́run ní Baba “wa” yìí yẹ kó máa mú wa rántí pé bá a ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run làwọn ará wa yòókù náà ní in. Gbólóhùn náà, “kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́” jẹ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà sọ ara rẹ̀ di mímọ́ nípa wíwẹ gbogbo ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ rẹ̀ látìgbà ìṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì kúrò. Bí Jèhófà yóò ṣe dáhùn àdúrà yẹn ni pé yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò láyé, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di mímọ́.—Ìsík. 36:23.

13. (a) Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa dáhùn àdúrà náà “kí ìjọba rẹ dé”? (b) Tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá máa di ṣíṣe ní ayé, àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀?

13 Jésù tẹ̀ síwájú pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:10) Ó yẹ ká fi ohun kan sọ́kàn nípa gbólóhùn yìí nínú àdúrà àwòkọ́ṣe náà. Ohun náà ni pé, ìjọba tí Jèhófà gbé fún Jésù tó jẹ́ Mèsáyà àti “àwọn ẹni mímọ́” tó máa wà pẹ̀lú rẹ̀ láti máa ṣàkóso látọ̀runwá ni “ìjọba” tí ibí yìí ń wí. (Dán. 7:13, 14, 18; Aísá. 9:6, 7) Nígbà tá a bá ń gbàdúrà pé kí ó “dé,” ńṣe là ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ìjọba Ọlọ́run wá ṣèdájọ́ gbogbo àwọn alátakò ìṣàkóso Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Ìyẹn sì máa tó ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn náà, gbogbo ayé á wá di Párádísè níbi tí òdodo, àlàáfíà àti aásìkí yóò wà. (Sm. 72:1-15; Dán. 2:44; 2 Pét. 3:13) Ìfẹ́ Jèhófà ti di ṣíṣe ní ọ̀run báyìí. Nítorí náà, bá a ṣe ń gbàdúrà pé kí ó di ṣíṣe ní ayé, ńṣe là ń bẹ Ọlọ́run pé kí ó mú ìfẹ́ rẹ̀ fún ilé ayé wa yìí ṣẹ, kó sì pa àwọn alátakò rẹ̀ òde òní run bó ṣe ṣe nígbà àtijọ́.—Ka Sáàmù 83:1, 2, 13-18.

14. Kí nìdí tó fi bá a mu pé ká máa gbàdúrà fún “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní”?

14 Jésù ní: “Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” (Mát. 6:11; Lúùkù 11:3) Bá a ṣe ń tọrọ èyí nínú àdúrà, ńṣe là ń bẹ Ọlọ́run pé kó pèsè oúnjẹ tá a nílò “fún ọjọ́ òní.” Èyí fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti máa pèsè ohun tá a máa nílò lóòjọ́ fún wa. Àdúrà yìí kì í ṣe àdúrà pé ká ní ọ̀pọ̀ yanturu o. Àdúrà yìí pé kí Ọlọ́run máa pèsè ohun tá a nílò lóòjọ́ fún wa ń jẹ́ ká rántí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí olúkúlùkù wọn máa kó “iye tirẹ̀ ti òòjọ́ fún òòjọ́.”—Ẹ́kís. 16:4.

15. Ṣàlàyé ìtumọ̀ gbólóhùn náà “dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.”

15 Ohun tó kàn nínú àdúrà àwòkọ́ṣe yìí pàfiyèsí wa sí ohun kan tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe. Jésù sọ ọ́ báyìí pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” (Mát. 6:12) Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù fi hàn pé “àwọn ẹ̀ṣẹ̀” wa ni “àwọn gbèsè” tí ibí yìí ń wí. (Lúùkù 11:4) Ìgbà tí a bá “ti dárí ji” àwọn tó ṣẹ̀ wá la tó lè máa retí pé kí Jèhófà dárí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà jì wá. (Ka Mátíù 6:14, 15.) A gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn èèyàn fàlàlà.—Éfé. 4:32; Kól. 3:13.

16. Báwo ló ṣe yẹ ká lóye ẹ̀bẹ̀ nípa ìdẹwò àti ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà?

16 Jésù tún sọ pé: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mát. 6:13) Kí ni ẹ̀bẹ̀ méjì tó tan mọ́ra yìí nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù kọ́ wa túmọ̀ sí? Ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà kì í fi ẹ̀ṣẹ̀ dán wa wò. (Ka Jákọ́bù 1:13.) Ẹni tó jẹ́ “Adẹniwò” gan-an ni Sátánì, “ẹni burúkú náà.” (Mát. 4:3) Àmọ́ ṣá, nígbà míì, Bíbélì máa ń sọ pé Ọlọ́run ṣe ohun kan, tó sì jẹ́ pé ńṣe ló kàn fàyè gbà á. (Rúùtù 1:20, 21; Oníw. 11:5) Nítorí náà, gbólóhùn yìí “má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,” jẹ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà má ṣe jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀ tó bá di pé ohun kan ń dẹ wá wò láti ṣàìgbọràn sí i. Gbólóhùn tó gbẹ̀yìn àdúrà náà, ìyẹn “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” jẹ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà má ṣe jẹ́ kí Sátánì borí wa. Ó sì dá wa lójú pé ‘Ọlọ́run kì yóò jẹ́ kí a dẹ wá wò ré kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra.’—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13.

‘Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Bíbéèrè, ní Wíwá Kiri, ní Kíkànkùn’

17, 18. Kí ni ìmọ̀ràn náà pé ká ‘máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, ní wíwá kiri àti ní kíkànkùn’ túmọ̀ sí?

17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì ni Jésù ti sọ fún wa ṣáájú nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà, àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún.” (Mát. 7:7, 8) Ó tọ́ pé ká “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè” fún ohunkóhun tó bá ti bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ọ̀rọ̀ kan tó kín ọ̀rọ̀ Jésù lẹ́yìn, ó ní: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí [Ọlọ́run], pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”—1 Jòh. 5:14.

18 Ìmọ̀ràn Jésù pé ká ‘máa bá a nìṣó ní bíbéèrè àti ní wíwá kiri’ túmọ̀ sí pé ká máa fi tọkàntara gbàdúrà láìdabọ̀. Ó sì tún ṣe pàtàkì pé ká “máa bá a nìṣó ní kíkànkùn” ká lè wọ Ìjọba Ọlọ́run láti lè fi àwọn ìbùkún àti àǹfààní rẹ̀ ṣèrè jẹ. Ǹjẹ́ ó sì dá wa lójú pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa? Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá ti lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ohun tí Kristi sọ ni pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún.” Ọ̀pọ̀ ìrírí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ní sì fi hàn lóòótọ́ pé “Olùgbọ́ àdúrà” ni Ọlọ́run.—Sm. 65:2.

19, 20. Pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 7:9-11, báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ baba onífẹ̀ẹ́?

19 Jésù fi Ọlọ́run wé baba onífẹ̀ẹ́ kan tó máa ń pèsè ohun rere fáwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ fojú inú wò ó pé o wà níbi Ìwàásù Lórí Òkè yẹn, tó ò ń gbọ́ bí Jésù ṣe ń sọ pé: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dìòun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹjaòun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”Mát. 7:9-11.

20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá mú kó dà bíi pé àwọn baba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn “jẹ́ ẹni burúkú,” síbẹ̀ ìfẹ́ ọmọ wọn ṣì máa ń wà lọ́kàn wọn. Irú baba bẹ́ẹ̀ kì í tan ọmọ rẹ̀ jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa rí i pé òun pèsè “àwọn ẹ̀bùn rere” fọ́mọ òun. Bákan náà, nítorí pé Baba wa ọ̀run jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ó máa ń pèsè “àwọn ẹ̀bùn rere,” irú bí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, fún àwa ọmọ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí mímọ́ yìí lè fún wa lágbára tá a ó fi máa ṣe iṣẹ́ ìsìn tó ṣètẹ́wọ́gbà fún Jèhófà, Olùpèsè “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.”—Ják. 1:17.

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Jésù Máa Ṣe Ọ́ Láǹfààní Nìṣó

21, 22. Kí ló mú kí Ìwàásù Lórí Òkè ta yọ, báwo sì ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣe rí lọ́kàn rẹ?

21 Àsọyé tó fakíki jù láyé ńbí ni Ìwàásù Lórí Òkè lóòótọ́. Ìwàásù náà ta yọ ní ti ohun tó kọ́ni nípa Ọlọ́run àti bó ṣe ṣe kedere tó. Bí àwọn kókó inú rẹ̀ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe fi hàn, tá a bá tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni inú ìwàásù náà, a ó jàǹfààní tó pọ̀ jọjọ. Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù yìí lè mú kí ayé wa túbọ̀ dáa nísinsìnyí, ká sì tún máa retí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀.

22 Nínú àpilẹ̀kọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, ìwọ̀nba díẹ̀ la gbé yẹ̀ wò lára àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó wà nínú Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù ṣe. Abájọ tí ‘háà fi ń ṣe àwọn tó gbọ́ àsọyé náà sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.’ (Mát. 7:28) Ó dájú pé bó ṣe máa ṣe àwa náà nìyẹn, tá a bá ń ka ọ̀rọ̀ inú àsọyé yìí àtàwọn ọ̀rọ̀ tó fakíki yòókù tí Jésù Kristi Olùkọ́ Ńlá sọ, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Kí ni Jésù sọ nípa gbígba àdúrà àgàbàgebè?

• Kí nìdí tá a fi ní láti yẹra fún sísọ àsọtúnsọ nígbà tá a bá ń gbàdúrà?

• Àwọn ẹ̀bẹ̀ wo ló wà nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù kọ́ wa?

• Báwo la ṣe lè ‘máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, ní wíwá kiri àti ní kíkànkùn’?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn alágàbàgebè tí wọ́n ń gbàdúrà tìtorí káwọn èèyàn lè rí wọn kí wọ́n sì gbọ́ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi tọ́ pé ká máa gbàdúrà fún oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní?