Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan ìwé méjì kan, ìyẹn “ìwé Jáṣárì” àti “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà.” (Jóṣ. 10:13; Núm. 21:14) Àwọn ìwé wọ̀nyẹn kò sí lára àwọn ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin tó para pọ̀ di Bíbélì. Ṣé àwọn ìwé míì tí Ọlọ́run mí sí àmọ́ tó ti sọ nù ni wọ́n ni?

Kò sí ẹ̀rí kankan tó lè mú ká gbà pé àwọn ìwé méjì yẹn jẹ́ ara àwọn ìwé tí wọ́n kọ nípasẹ̀ ìmísí Ọlọ́run ṣùgbọ́n tó sọ nù nígbà tó yá. Àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì mẹ́nu kan àwọn àkọsílẹ̀ mélòó kan míì. Àwọn kan lára àwọn àkọsílẹ̀ náà lè wà nínú Bíbélì, àmọ́ kó jẹ́ pé àwa tá à ń kà wọ́n lóde òní kò fi àwọn orúkọ tí wọ́n ń pè wọ́n láyé ìgbà yẹn mọ̀ wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, 1 Kíróníkà 29:29 mẹ́nu kan “àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì aríran,” “àwọn ọ̀rọ̀ Nátánì wòlíì,” àti “àwọn ọ̀rọ̀ Gádì olùríran.” Ó lè jẹ́ pé àwọn ìwé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ló para pọ̀ di ìwé tá a mọ̀ sí Sámúẹ́lì Kìíní àti Ìkejì tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ ìwé Àwọn Onídàájọ́.

Ohun míì tún ni pé Bíbélì máa ń dárúkọ àwọn ìwé kan tí kò sí lára àwọn ìwé inú Bíbélì, àmọ́ tí orúkọ wọn jọ ti àwọn ìwé inú Bíbélì. Àpẹẹrẹ irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ni “ìwé àwọn àlámọ̀rí àkókò àwọn ọba Júdà,” “Ìwé Àwọn Ọba Júdà àti ti Ísírẹ́lì,” “Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì” àti “Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ àwọn ìwé wọ̀nyí lè jọ orúkọ àwọn ìwé inú Bíbélì tá a mọ̀ sí Àwọn Ọba Kìíní àti Àwọn Ọba Kejì, àwọn ìwé mẹ́rin náà kò ní ìmísí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sí lára àwọn ìwé inú Bíbélì. (1 Ọba 14:29; 2 Kíró. 16:11; 20:34; 27:7) Wọ́n kàn lè jẹ́ ìwé ìtàn tó wà nígbà tí wòlíì Jeremáyà àti Ẹ́sírà ń kọ àwọn ìwé inú Bíbélì tí wọ́n kọ.

Láìsí àní-àní, àwọn kan lára àwọn tó kọ Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ìwé ìtàn tàbí àkọ́sílẹ̀ míì tó wà nígbà yẹn àmọ́ tí kò ní ìmísí Ọlọ́run. Àwọn míì lára àwọn òǹkọ̀wé yìí sì lọ ṣèwádìí nínú irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́sítérì 10:2 mẹ́nu kan “Ìwé àlámọ̀rí àwọn àkókò ti àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà.” Bákan náà, nígbà tí Lúùkù ń múra àtikọ àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere rẹ̀, ó “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Lúùkù ní lọ́kàn ni pé òun lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé kan tóun rí nígbà tóun fẹ́ ṣàkọsílẹ̀ ìtàn ìran Jésù tá à ń kà nínú Ìhìn Rere rẹ̀ lónìí. (Lúùkù 1:3; 3:23-38) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé tí Lúùkù lọ ṣèwádìí nínú wọn kò ní ìmísí Ọlọ́run, síbẹ̀ ó dájú pé ìwé Ìhìn Rere tó kọ ní ìmísí Ọlọ́run. Ìwé Ìhìn Rere náà sì wúlò fún wa títí di òní olónìí.

Ní ti ìwé méjì tí ìbéèrè wa dá lé lórí, ìyẹn “ìwé Jáṣárì” àti “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà,” ó jọ pé àwọn ìwé tó wà nígbà yẹn, àmọ́ tí kò ní ìmísí Ọlọ́run ni wọ́n. Nítorí ìyẹn ni Jèhófà kò ṣe pa wọ́n mọ́ bíi ti àwọn ìwé inú Bíbélì. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwé méjì yẹn ló mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì gbà pé àwọn ìwé méjì náà jẹ́ ewì tàbí orin tó ń sọ nípa àwọn ìjà tó wáyé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọ̀tá wọn. (2 Sám. 1:17-27) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “àkójọ àwọn ewì àti orin táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, èyí táwọn olórin ní Ísírẹ́lì àtijọ́ tọ́jú pa mọ́ ló wà nínú ìwé méjì yẹn.” Àwọn èèyàn kan tí Ọlọ́run lò láwọn ìgbà kan gẹ́gẹ́ bíi wòlíì tàbí aríran tiẹ̀ kọ àwọn àkọsílẹ̀ kan tí Jèhófà kò mí sí, tàbí tí kò gbà pé kí wọ́n jẹ́ ara Ìwé Mímọ́ tó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́,” lóde òní.—2 Tím. 3:16; 2 Kíró. 9:29; 12:15; 13:22.

Kò yẹ ká torí pé Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ìwé kan tàbí pé wọ́n jẹ́ ìwé tó wúlò fún ṣíṣèwádìí, ká wá sọ pé Ọlọ́run mí sí wọn. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run ti pa gbogbo ìwé tí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa” ń bẹ nínú rẹ̀ mọ́, wọn yóò sì “wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísá. 40:8) Ó dájú pé àwọn ìwé tí Jèhófà jẹ́ kó wà lára ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] inú Bíbélì tá a ní lọ́wọ́ yìí ni ohun tá a nílò láti lè jẹ́ ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tím. 3:16, 17.