Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Títọ́ Rẹ Ń mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Ìwà Títọ́ Rẹ Ń mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Ìwà Títọ́ Rẹ Ń mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

“Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”—ÒWE 27:11.

1, 2. (a) Ẹ̀sùn wo ni ìwé Jóòbù sọ pé Sátánì fi ń kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí ló fi hàn pé Sátánì ṣì ń ṣáátá Jèhófà nìṣó lẹ́yìn ìgbà ayé Jóòbù?

 JÈHÓFÀ fàyè gba Sátánì láti dán ìwà títọ́ Jóòbù, ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin wò. Látàrí èyí, Jóòbù pàdánù àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ṣán kú, àrùn sì tún dá a gúnlẹ̀. Àmọ́ nígbà tí Sátánì ń fẹ̀sùn kan Jóòbù lórí ìwà títọ́ rẹ̀, kì í ṣe Jóòbù nìkan ló ní lọ́kàn. Sátánì sọ pé: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” Ẹ̀sùn tí Sátánì gbé kalẹ̀ yìí kọjá ọ̀rọ̀ Jóòbù nìkan, fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Jóòbù ló ṣì ń fẹ̀sùn yìí kan gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun.—Jóòbù 2:4.

2 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lẹ́yìn ìdánwò Jóòbù, Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Ó ṣe kedere pé títí di àkókò yẹn, Sátánì ṣì ń ta ko Jèhófà. Bákan náà, nínú ìran kan tí Ọlọ́run fi han àpọ́sítélì Jòhánù, ó rí Sátánì gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣì ń fẹ̀sùn kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn tí wọ́n ti lé e kúrò lọ́run ní àkókò kan lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Kódà títí dòní pàápàá, tó ti pẹ́ tá a ti wà ní ọjọ́ ìkẹyìn ètò búburú yìí, Sátánì ṣì ń fẹ̀sùn kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ìṣòtítọ́ wọn!—Ìṣí. 12:10.

3. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ látinú ìwé Jóòbù?

3 Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́ta tá a lè rí kọ́ látinú ìwé Jóòbù. Àkọ́kọ́ ni pé ìdánwò Jóòbù jẹ́ ká rí ẹni náà gan-an tó jẹ́ ọ̀tá aráyé tó sì tún wà lẹ́yìn àtakò tí wọ́n ń ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run. Sátánì Èṣù ni ọ̀tá yẹn. Èkejì ni pé àdánwò èyíkéyìí tó wù kó dojú kọ wá, àá lè dúró lórí ìṣòtítọ́ wa tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀kẹta ni pé nígbà tí ìṣòro bá dé tí á sì dán ìgbàgbọ́ wa wò, Ọlọ́run á ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á gẹ́gẹ́ bó ṣe ran Jóòbù lọ́wọ́. Ohun tí Jèhófà ń lò láti ràn wá lọ́wọ́ lónìí ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ètò rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.

Máa Rántí Ẹni Náà Tó Jẹ́ Ọ̀tá Wa

4. Ta ló yẹ ká dá lẹ́bi gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí?

4 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbà gbọ́ pé ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Sátánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò wàhálà táyé wà lè máa mú kí wọ́n dáàmù, wọn ò mọ̀ pé Sátánì Èṣù ló dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ làásìgbò tó ń bá àwọn èèyàn ló jẹ́ àfọwọ́fà ara wọn. Ńṣe ni Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ òbí wa àkọ́kọ́ fẹ́ wà lómìnira kúrò lábẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn. Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ látìgbà náà ni pé àwọn nǹkan tí kò mọ́gbọ́n dání làwọn àtọmọdọ́mọ wọn ń ṣe. Àmọ́ Èṣù náà ló jẹ̀bi ọ̀ràn ọ̀hún, torí pé òun ló tan Éfà pé kó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Òun lẹni tó gbé ètò nǹkan ayé yìí kalẹ̀ tó sì ń darí rẹ̀ láàárín àwọn èèyàn aláìpé tí ikú ń pa. Nítorí pé Sátánì ni “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” irú àwọn ìwà tí Èṣù ń hù ló wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn, ìyẹn àwọn ìwà bí ìgbéraga, asọ̀, owú, ìwọra, ẹ̀tàn àti ìṣọ̀tẹ̀. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Tím. 2:14; 3:6; ka Jákọ́bù 3:14, 15.) Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ló ṣokùnfà ìforígbárí láàárín àwọn olóṣèlú àti láàárín àwọn onísìn, ìkórìíra, ìwà jẹgúdújẹrá àti ìdàrúdàpọ̀ tó ń pa kún ìyà tó ń jẹ ọmọ èèyàn.

5. Báwo la ṣe fẹ́ lo ìmọ̀ ṣíṣeyebíye tá a ní?

5 Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ ṣíṣeyebíye làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní yìí! Àwa ti mọ ẹni tó yẹ ká dá lẹ́bi fún gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí. Ṣé kò wá yẹ kóhun tá a mọ̀ yìí mú ká gbéra ká lọ sóde ẹ̀rí láti lọ máa sọ fún àwọn èèyàn pé Èṣù ni ọ̀tá burúkú tó ń fa gbogbo yánpọnyánrin yìí? Ṣé kì í sì í ṣe dídùn inú wa ló jẹ́ láti dúró gbọn-in sọ́dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ká sì tún máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí yóò ṣe mú Sátánì àtàwọn àjálù tó ń bá aráyé kúrò?

6, 7. (a) Ta ló wà nídìí àtakò tó ń dojú kọ àwa olùjọsìn Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Élíhù?

6 Kì í ṣe àwọn ohun ìbànújẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí nìkan ni Sátánì ń fà, òun ló tún wà nídìí àtakò tó ń dojú kọ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ó ti pinnu láti máa dán wa wò dandan. Jésù Kristi sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì ti fi dandan béèrè láti gbà yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà.” (Lúùkù 22:31) Bákan náà, gbogbo ẹni tó bá fẹ́ máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù ló máa rí àdánwò lọ́nà kan tàbí òmíràn. Pétérù sọ pé Èṣù dà bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” Pọ́ọ̀lù sì sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.”—1 Pét. 5:8; 2 Tím. 3:12.

7 Nígbà tí àjálù bá dé bá ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọ ọ̀tá tó wà nídìí ìṣòro náà? Dípò ká ta kété sí ẹni náà kó máa dá ìṣòro rẹ̀ rán, ńṣe ló yẹ ká ṣe bíi ti Élíhù tó bá Jóòbù sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ tòótọ́. A ní láti kọ́wọ́ ti Kristẹni bíi tiwa lẹ́yìn, ká jọ dojú ìjà kọ Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá gbogbo wa. (Òwe 3:27; 1 Tẹs. 5:25) Ohun tó yẹ kó gbà wá lọ́kàn ni bá a ṣe máa ran ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà lọ́wọ́ kó lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, láì kọ ohunkóhun tó lè ná wa, kẹ́ni náà lè tipa bẹ́ẹ̀ mú ọkàn Jèhófà yọ̀.

8. Kí nìdí tí ìsapá Sátánì láti mú kí Jóòbù má lè bọlá fún Jèhófà fi já sí pàbó?

8 Ohun tí Sátánì kọ́kọ́ fi dá Jóòbù lóró ni pé ó mú kó pàdánù àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀. Dúkìá iyebíye làwọn ẹran ọ̀sìn yẹn jẹ́ fún Jóòbù, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ara wọn gan-an ló ti ń rí ohun tó fi ń gbọ́ bùkátà. Àmọ́ Jóòbù tún ń lò wọ́n fún ìjọsìn. Lẹ́yìn tí Jóòbù bá ti sọ àwọn ọmọ rẹ̀ di mímọ́, yóò “dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, a sì rú àwọn ẹbọ sísun ní ìbámu pẹ̀lú iye gbogbo wọn; nítorí, Jóòbù a sọ pé, ‘bóyá àwọn ọmọ mi ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti bú Ọlọ́run nínú ọkàn-àyà wọn.’ Bí Jóòbù ti ń ṣe nìyí nígbà gbogbo.” (Jóòbù 1:4, 5) Èyí fi hàn pé Jóòbù máa ń fi ẹran ọ̀sìn rúbọ sí Jèhófà déédéé. Àmọ́ nígbà tí àdánwò wá bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ò lè ṣeé ṣe mọ́ nítorí pé Jóòbù kò ní ‘ohun ìní tí ó níye lórí’ tó lè fi bọlá fún Jèhófà mọ́. (Òwe 3:9) Síbẹ̀ ó ṣì ní ohun kan tó fi ń lè bọlá fún Jèhófà, ìyẹn ni ètè rẹ̀!

Jẹ́ Kí Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Wà Láàárín Ìwọ àti Jèhófà

9. Kí lohun tá a ní tó ṣeyebíye jù lọ nígbèésí ayé wa?

9 Ipò yòówù ká wà, yálà a jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì, a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, ara wa le tàbí kò le, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Àdánwò èyíkéyìí tí ì báà dé bá wa, tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà yóò ṣeé ṣe fún wa láti di ìṣòtítọ́ wa mú ká sì mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. Kódà àwọn tí ìmọ̀ òtítọ́ tí wọ́n ní kò pọ̀ ń mú ìdúró wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì ń di ìṣòtítọ́ wọn mú.

10, 11. (a) Báwo ni ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wa ṣe ṣe nígbà tó ń rí ìdánwò ìṣòtítọ́? (b) Èsì tó rinlẹ̀ wo ni arábìnrin yìí fún Sátánì?

10 Wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Valentina Garnovskaya, tó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Rọ́ṣíà tó dúró ṣinṣin lójú ọ̀pọ̀ àdánwò, bíi ti Jóòbù. Lọ́dún 1945 nígbà tó wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, arákùnrin kan wàásù fún un. Ẹ̀ẹ̀méjì péré ni arákùnrin náà pa dà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti wá bá a jíròrò Bíbélì tó fi di pé kò rí arákùnrin náà mọ́. Síbẹ̀ náà, Arábìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn tó wà ládùúgbò rẹ̀. Nítorí èyí, wọ́n mú un, wọ́n ní kó lọ lo ọdún mẹ́jọ nínú àgọ́ ìfìyàjẹni. Wọ́n fi í sílẹ̀ lọ́dún 1953 ó sì tún pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Ni wọ́n bá tún mú un lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ni wọ́n sọ ọ́ sí lọ́tẹ̀ yìí. Lẹ́yìn tó lo ọdún mélòó kan nínú àgọ́ kan, wọ́n mú un lọ sí àgọ́ míì. Àwọn arábìnrin kan wà nínú àgọ́ tí wọ́n mú un lọ yìí tí wọ́n ní ẹyọ Bíbélì kan. Arábìnrin kan fi Bíbélì náà han Valentina lọ́jọ́ kan. Ọjọ́ ayọ̀ gbáà lọ́jọ́ náà jẹ́ fún Valentina! Ìwọ wò ó ná, Bíbélì kan ṣoṣo tí Valentina tíì rí rí láyé ẹ̀ ni èyí tó rí lọ́wọ́ arákùnrin tó wàásù fún un lọ́dún 1945!

11 Ní ọdún 1967, wọ́n fi Valentina sílẹ̀, ó sì láǹfààní láti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà. Ó lo òmìnira tó ní yìí láti máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù títí di ọdún 1969. Ọdún 1969 yìí ni wọ́n tún mú un lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta ni wọ́n rán an lọ lọ́tẹ̀ yìí. Síbẹ̀ Valentina ò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Kó tó kú lọ́dún 2001, ó ti ran àwọn mẹ́rìnlélógójì [44] lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó lo ọdún mọ́kànlélógún ní oríṣiríṣi ẹ̀wọ̀n àti àgọ́ ìfìyàjẹni. Kò kọ̀ láti yááfì gbogbo nǹkan, títí kan òmìnira rẹ̀ pàápàá, torí kó ṣáà lè di ìṣòtítọ́ rẹ̀ mú. Ní òpin ìgbésí ayé Valentina, ó sọ pé: “Mi ò fìgbà kankan rí ní ibùgbé tèmi tí mò ń gbé. Inú àpò kan ṣoṣo ni gbogbo ohun tí mo ní láyé mi wà, àmọ́ ó tẹ́ mi lọ́rùn, inú mi sì ń dùn pé mo ń sin Jèhófà.” Ẹ ò rí i pé èsì tó rinlẹ̀ ni Valentina fún Sátánì, tó sọ pé àwọn èèyàn ò ní sin Ọlọ́run pẹ̀lú ìdúróṣinṣin tí wọ́n bá rí àdánwò! (Jóòbù 1:9-11) Ó dá wa lójú pé Valentina ti mú ọkàn Jèhófà yọ̀, Jèhófà sì ń dúró de ọjọ́ tó máa jí Valentina àtàwọn yòókù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú dìde.—Jóòbù 14:15.

12. Ipa wo ni ìfẹ́ ń kó nínú àjọṣe àwa pẹ̀lú Jèhófà?

12 Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló mú ká jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn ànímọ́ rẹ̀ wù wá gan-an ni, a sì ń ṣe ohunkóhun tá a bá lè ṣe láti rí i pé ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu là ń ṣe. Ohun tí Èṣù sọ nípa wa ò rí bẹ́ẹ̀, tinútinú la fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò sì béèrè ohunkóhun ká tó ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní yìí ló ń mú ká dúró ṣinṣin nígbà ìdánwò. Jèhófà náà “yóò sì máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.”—Òwe 2:8; Sm. 97:10.

13. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ohun tá a ṣe fún un?

13 Ìfẹ́ máa ń mú ká bọlá fún orúkọ Jèhófà, kódà tá a bá tiẹ̀ ń rò pé a ò lè ṣe púpọ̀. Jèhófà rí ọkàn wa pé rere la fẹ́ ṣe, kì í sì í dá wa lẹ́jọ́ tá ò bá lè ṣe gbogbo ohun tó wù wá láti ṣe. Kì í ṣe ohun tá a ṣe nìkan ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe ìdí tá a fi ṣe é. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dùn ọkàn bá Jóòbù tó sì ti fara da ọ̀pọ̀ ìjìyà, síbẹ̀ ó ṣì sọ fáwọn tó ń fẹ̀sùn kàn án pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀nà Jèhófà. (Ka Jóòbù 10:12; 28:28.) Ní orí tó gbẹ̀yìn ìwé Jóòbù, Ọlọ́run sọ pé inú bí òun sí Élífásì, Bílídádì àti Sófárì torí pé òtítọ́ kọ́ ni wọ́n sọ. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà sọ bí inú òun ti dùn sí Jóòbù tó nípa pípè é ní “ìránṣẹ́ mi” lẹ́ẹ̀mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó sì sọ fún un pé kó bá àwọn olùtùnú èké yẹn tọrọ àforíjì. (Jóòbù 42:7-9) Ẹ jẹ́ káwa náà máa hùwà lọ́nà tí Jèhófà á fi lè máa fojúure wò wá.

Jèhófà Ń Ran Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Adúróṣinṣin Lọ́wọ́

14. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jóòbù lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ̀nà?

14 Jóòbù jẹ́ olóòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ẹni pípé. Láwọn ìgbà kan tí wàhálà dé bá a, ó ní èrò tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún Jèhófà pé: “Mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn . . . Ìwọ fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá ọwọ́ rẹ ṣe kèéta sí mi.” Yàtọ̀ síyẹn, ìgbà kan wà tí Jóòbù ń tẹnu mọ́ bóun ṣe jẹ́ aláìlẹ́bi, ìgbà yẹn ló sọ pé: “Èmi kò jẹ̀bi,” tó tún sọ pé “kò sí ìwà ipá ní àtẹ́lẹwọ́ mi, àdúrà mi sì mọ́ gaara.” (Jóòbù 10:7; 16:17; 30:20, 21) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ran Jóòbù lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Ó bi Jóòbù láwọn ìbéèrè kan tó gbé ọ̀ràn náà kúrò lórí Jóòbù. Àwọn ìbéèrè yìí sì tún mú kí Jóòbù rí i pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba àti pé kékeré kọ́ ló fi ju èèyàn lọ. Jóòbù gba ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un ó sì wá ní èrò tó tọ̀nà.—Ka Jóòbù 40:8; 42:2, 6.

15, 16. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ran àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní?

15 Jèhófà máa ń tọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní sọ́nà bákan náà, ó sì máa ń bá wa wí tìfẹ́tìfẹ́. Síwájú sí i, a tún láwọn nǹkan pàtàkì tá à ń jàǹfààní wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù Kristi fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ìràpadà ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ọlá ẹbọ yẹn la fi lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run bá a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé. (Ják. 4:8; 1 Jòh. 2:1) Nígbà tí àdánwò bá dojú kọ wá, a tún máa ń gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ kó sì fún wa lókun. Yàtọ̀ síyẹn, a ní Bíbélì lódindi, tá a bá sì ń kà á tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú rẹ̀, ńṣe là ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ ìdánwò ìgbàgbọ́. Ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe ń jẹ́ ká lóye ọ̀ràn nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ọ̀ràn ìṣòtítọ́ wa.

16 Bákan náà, a tún ń jàǹfààní tó pọ̀ bá a ṣe wà nínú ẹgbẹ́ ará kárí ayé tí Jèhófà ń fún ní oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45-47) Nínú gbogbo nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, à ń ṣe àwọn ìpàdé tá a ti ń gba ìtọ́ni tó sì ń fún wa lágbára láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ tó ṣeé ṣe kó yọjú. Àpẹẹrẹ ohun tá a sọ yìí ló ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́bìnrin Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Sheila tó ń gbé nílẹ̀ Jámánì, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé èyí.

17. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni ètò Jèhófà lónìí.

17 Lọ́jọ́ kan nílé ìwé àwọn Sheila, láàárín àkókò kan, kò sí olùkọ́ kankan nínú kíláàsì. Ni àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bá ní àwọn fẹ́ lo ọpọ́n ìwoṣẹ́ kan tó ń jẹ́ Ouija láti mọ bó ṣe máa ń rí. Sheila bá tètè jáde kúrò nínú kíláàsì ní tiẹ̀. Ohun tó gbọ́ pé ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà mú kí inú rẹ̀ dùn pé òun tètè jáde. Wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo ọpọ́n yẹn, àwọn kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ kàn dédé rí i pé ẹ̀mí èṣù ti wà láàárín àwọn, gbogbo wọn bá fẹsẹ̀ fẹ pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo. Àmọ́ kí ló mú kí Sheila tètè jáde kúrò nínú kíláàsì lọ́jọ́ yẹn? Ó ní: “Kò tíì pẹ́ tá a jíròrò ewu tó wà nínú ọpọ́n ìwoṣẹ́ Ouija nípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀. Torí náà mo mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Mo fẹ́ ṣe ohun tó wu Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Òwe 27:11 ṣe sọ.” Ẹ ò rí i pé ìpàdé tí Sheila lọ àti bó ṣe fetí sílẹ̀ dáadáa nípàdé ló kó o yọ!

18. Kí ni ìwọ ti pinnu láti ṣe?

18 Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pátá pinnu láti máa tẹ̀ lé ìtọ́ni ètò Ọlọ́run. Tá a bá ń lọ sípàdé déédéé, tá à ń ka Bíbélì, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, tá à ń gbàdúrà tá a sì ń bá àwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́, a óò máa rí ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́ tá a nílò gbà. Jèhófà fẹ́ ká borí ìdánwò ìgbàgbọ́, ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ pé a ó máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó. Àǹfààní ńlá gbáà mà la ní o, pé a lè máa gbé orúkọ Jèhófà ga ká sì pa ìwà títọ́ wa mọ́, ká sì tún mú ọkàn Jèhófà yọ̀!

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn àdánwò àti ìṣòro wo ni Sátánì ń fà?

• Kí lohun tá a ní tó ṣeyebíye jù lọ nígbèésí ayé wa?

• Kí ló mú ká jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ṣé ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé kó o lọ wàásù fáwọn ẹlòmíràn káwọn náà lè ní ìmọ̀ ṣíṣeyebíye tó o ní?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

A lè ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Valentina ò kọ̀ láti yááfì gbogbo nǹkan torí kó ṣáà lè di ìṣòtítọ́ rẹ̀ mú