Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Lè Lọ Sìn Níbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I?

Ṣé O Lè Lọ Sìn Níbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I?

Ṣé O Lè Lọ Sìn Níbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I?

“Ìgbé ayé ìrọ̀rùn là ń gbé nílẹ̀ Amẹ́ríkà, àmọ́ à ń ṣàníyàn nípa ohun kan. Ìyẹn ni báwọn èèyàn tó wà níbi tá à ń gbé ṣe ń lé ọrọ̀ lójú méjèèjì, a sì ń rò ó pé ó lè ṣàkóbá fún àwa àtàwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì. Èmi àtìyàwó mi ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nígbà kan rí, a sì tún fẹ́ pa dà máa gbé irú ìgbé ayé aláyọ̀ tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tá à ń gbé nígbà yẹn.”

OHUN tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ralph àti Pam aya rẹ̀ rò nìyẹn tí wọ́n fi pinnu láti kọ̀wé sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì mélòó kan pé ó wu àwọn láti sìn níbi tí wọ́n bá ti nílò oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mẹ́síkò fún wọn lésì pé, lójú méjèèjì, àwọn nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run táá lè lọ wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Kódà, ẹ̀ka ọ́fíìsì yẹn sọ pé pápá yẹn ti “funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Láìpẹ́, arákùnrin àti arábìnrin yìí gbà láti lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ mọ́, àwọn àtàwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì, ọ̀kan ọmọ ọdún méjìlá, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ.

Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Wọn Tóbi Gan-an

Arákùnrin Ralph sọ pé: “Ká tó kúrò nílẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan tí wọ́n rò pé àwọn ń ṣaájò wa sọ fún wa pé: ‘Ọ̀ràn lílọ sókè òkun léwu púpọ̀ o!’ ‘Tí àìsàn bá kọ lù yín níbẹ̀ ńkọ́?’ ‘Kí lẹ̀ ń wá lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ń gbé? Àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì níbẹ̀ ò lè nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́!’ Àmọ́ a ti pinnu lọ́kàn wa pé a máa lọ. A ṣáà ti rò ó dáadáa ká tó pinnu pé à ń lọ, kì í ṣe ohun tá a kàn dédé pinnu lọ́sàn-án kan òru kan. Ó ti tó ọdún mélòó kan tá a ti ń rò ó. Ìdí nìyẹn tá ò fi ki ọrùn bọ gbèsè táá pẹ́ ká tó san tán, a ti tọ́jú owó pa mọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìdílé wa sì ti jíròrò àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe ká bá pàdé níbẹ̀ pa pọ̀.”

Nígbà tí Arákùnrin Ralph àti ìdílé rẹ̀ dé orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà níbẹ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ lọ. Àwọn arákùnrin wa tó wà níbẹ̀ fi àwòràn ilẹ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè náà hàn wọ́n, wọ́n wá sọ fún wọn pé: “Ìpìnlẹ̀ ìwàásù yín rèé o!” Ìlú San Miguel de Allende, táwọn èèyàn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè pọ̀ sí, ni ìdílé yìí pinnu láti máa gbé. Ìlú náà fi nǹkan bí òjìlérúgba [240] kìlómítà jìnnà sí ìlú Mexico City, ní apá ìwọ̀ oòrùn àríwá. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti débẹ̀, ìjọ Gẹ̀ẹ́sì kan bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀, akéde mọ́kàndínlógún ló bẹ̀rẹ̀ ìjọ náà. Òun ni ìjọ Gẹ̀ẹ́sì àkọ́kọ́ nílẹ̀ Mẹ́síkò, àmọ́ iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún wọn láti ṣe.

Ìwádìí fi hàn pé á tó mílíọ́nù kan ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ọmọ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tó jẹ́ alákọ̀wé tàbí akẹ́kọ̀ọ́ ló tún gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn èdè ìbílẹ̀ wọn. Arákùnrin Ralph ṣàlàyé pé: “À gbàdúrà pé káwọn oníwàásù tó máa kún wa lọ́wọ́ wá. A fi yàrá kan sílẹ̀ nínú ilé wa torí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó lè fẹ́ wá wo ibẹ̀ bí ẹní wá ‘ṣe amí ilẹ̀’ náà láti rí i bóyá àwọn yóò lè sìn níbẹ̀.”—Núm. 13:2.

Wọ́n Jẹ́ Kí Ohun Díẹ̀ Tẹ́ Wọn Lọ́rùn Kí Wọ́n Lè Fi Kún Iṣẹ́ Ìwàásù Wọn

Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n fẹ́ fi kún iṣẹ́ ìwàásù wọn dé. Lára wọn ni Arákùnrin Bill àti Arábìnrin Kathy láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Wọ́n ti lo ọdún márùndínlọ́gbọ̀n láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti nílò oníwàásù gan-an. Wọ́n kọ́kọ́ ń gbèrò àtikọ́ èdé Sípáníìṣì, àmọ́ èrò wọn yí pa dà nígbà tí wọ́n kó lọ sí ìlú Ajijic tó wà létí Adágún Odò Chapala, níbi táwọn ará Amẹ́ríkà tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ máa ń fìdí kalẹ̀ sí. Arákùnrin Bill ṣàlàyé pé: “Ní ìlú Ajijic, a túbọ̀ tẹpẹlẹ mọ́ wíwá àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sí tí wọ́n sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Inú Bill àti Kathy dùn pé láàárín ọdún méjì tí wọ́n dé ìlú yẹn, ìjọ Gẹ̀ẹ́sì kan bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀ níṣojú wọn, èyí sì ni ìjọ Gẹ̀ẹ́sì tó ṣìkejì ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

Arákùnrin Ken àti Arábìnrin Joanne ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Kánádà pinnu láti jẹ́ kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè ráyè lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Làwọn náà bá gbéra pẹ̀lú Britanny ọmọbìnrin wọn, ó di Mẹ́síkò. Arákùnrin Ken sọ pé: “Ó pẹ́ díẹ̀ kó tó mọ́ wa lára láti máa gbé níbi tó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ èèyàn lè ṣàìrí omi gbígbóná àti iná mànàmáná, tàbí kí ẹ̀rọ tẹlifóònù má ṣiṣẹ́.” Àmọ́, iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe níbẹ̀ ń fún wa láyọ̀. Láìpẹ́, wọ́n yan Arákùnrin Ken gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì tún di alàgbà lẹ́yìn ọdún méjì tó di ìránṣẹ́. Níbẹ̀rẹ̀, Britanny ọmọbìnrin wọn kò gbádùn wíwà ní ìjọ Gẹ̀ẹ́sì níbi tí àwọn èwe bíi tiẹ̀ kò pọ̀ sí. Àmọ́, lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà jákèjádò orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

Inú Arákùnrin Patrick àti Arábìnrin Roxanne ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n wá láti ìpínlẹ̀ Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù àwọn míṣọ́nnárì kan wà tí kò jìnnà púpọ̀ sí ibì kan táwọn èèyàn ti gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Arákùnrin Patrick sọ pé: “Lẹ́yìn tá a ti lọ sí ìlú Monterrey tó wà ní apá ìlà oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó ṣe kedere nínú ọkàn wa pé Jèhófà ló darí wa síbẹ̀ láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́.” Láàárín ọjọ́ márùn-ún, wọ́n rí ilé wọn tó wà nílùú Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tà, wọ́n sì ré kọjá lọ sí orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò bí ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ‘ré kọjá lọ sí Makedóníà.’ (Ìṣe 16:9) Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, kò rọrùn fún wọn láti rówó tí wọ́n á fi máa gbọ́ bùkátà ara wọn, àmọ́ láàárín ọdún méjì tí wọ́n débẹ̀, ìdùnnú ló jẹ́ fún wọn pé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàdínlógún tí wọ́n bá níbẹ̀ ti di odindi ìjọ tó ní ogójì akéde.

Tọkọtaya míì tó jẹ́ kí nǹkan ìní tara díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn torí kí wọ́n lè fi kún iṣẹ́ ìwàásù wọn ni Arákùnrin Jeff àti Arábìnrin Deb ìyàwó rẹ̀. Wọ́n ta ilé ńlá wọn tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà, wọ́n sì kó lọ sí ilé kékeré kan tó wà ní erékùṣù Cancún ní etíkun ìhà ìlà oòrùn lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ibi tí kò jìnnà sílé, tó sì jẹ́ gbọ̀ngàn ńlá tó ní ẹ̀rọ amúlétutù ni wọ́n ti máa ń ṣe àpéjọ. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ní láti rìnrìn àjò wákàtí mẹ́jọ gbáko kí wọ́n tó lè dé ibi tó sún mọ́ wọn jù lọ tí wọ́n ti lè ṣe àpéjọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, tó sì tún máa jẹ́ ní pápá ìṣeré tí wọn kò bò lórí. Àmọ́ inú wọn dùn jọjọ pé nígbà tí wọ́n dé erékùṣù Cancún ni ìjọ kan bẹ̀rẹ̀ níṣojú wọn, èyí tó ní àádọ́ta akéde.

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò náà bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bí àpẹẹrẹ, gbàrà tí Arákùnrin Rubén àti ìdílé rẹ̀ gbọ́ pé wọ́n ti dá ìjọ Gẹ̀ẹ́sì kan sílẹ̀ ní ìlú San Miguel de Allende, àti pé gbogbo orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò pátá ni ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yẹn, wọ́n pinnu lójú ẹsẹ̀ pé àwọn á lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ní láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì kí wọ́n sì tún mọ àṣà àwọn èèyàn tó ń sọ èdè yẹn. Wọ́n á tún ní láti máa rìnrìn àjò ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lè máa lọ sípàdé. Arákùnrin Rubén sọ pé: “Bá a ṣe ń wàásù fáwọn àjèjì tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ń múnú wa dùn torí pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n ń gbọ́ ìhìn rere lédè Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wọn. Inú àwọn kan nínú wọn dùn débi pé wọ́n ń yọ omi lójú bí wọ́n ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa.” Lẹ́yìn tí Arákùnrin Rubén àti ìdílé rẹ̀ ti ran ìjọ tó wà ní ìlú San Miguel de Allende lọ́wọ́, wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Guanajuato tó wà ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, níbi tí wọ́n ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dá ìjọ Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀, èyí tó ní àkéde tó ju ọgbọ̀n lọ. Ní báyìí, wọ́n ń sìn pẹ̀lú àwùjọ èdè Gẹ̀ẹ́sì kan tó wà ní ìlú Irapuato nítòsí ìlú Guanajuato.

Bí Wọ́n Ṣe Ń Wàásù fún Àwọn Tó Ṣòro Láti Rí Bá Sọ̀rọ̀

Yàtọ̀ sáwọn àjèjì, a tún ráwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tó gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó máa ń sábà ṣòro láti rí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run torí pé àdúgbó àwọn olówó ni wọ́n ń gbé, ọmọ ọ̀dọ̀ ló sì máa ń yọjú sẹ́ni tó bá wá sílé wọn. Nígbà tẹ́ni tó nilé gan-an bá sì wá sẹ́nu ọ̀nà, wọ́n lè ṣàìfẹ́ gbọ́ torí pé wọ́n rò pé ẹ̀ya ìsìn kéréje kan tí kò kọjá àdúgbó ibẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ nígbà tírú àwọn onílé bẹ́ẹ̀ bá rí Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wá wáàsù fún wọn, àwọn kan lára wọn máa ń gbọ́.

Wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Gloria, tó wà ní ìlú Querétaro, ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí ará ilẹ̀ Mẹ́síkò tó ń sọ èdè Sípáníìṣì ti wàásù dé ọ̀dọ̀ mi rí, síbẹ̀ mi ò fetí sí wọn. Àmọ́ nígbà tó yá táwọn ará ilé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í níṣòro, ìdààmú ọkàn bá mi mo sì ké pe Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó fọ̀nà àbáyọ hàn mí. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí obìnrin kan tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wá sílé mi. Ó béèrè bóyá ẹni tó gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì wà nílé wa. Nítorí pé àjèjì ni, mo fẹ́ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ, mo ní mo gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Bó ṣe ń sọ ohun tó bá wá, mò ń sọ nínú ọkàn mi pé: ‘Kí ni obìnrin ará Amẹ́ríkà yìí ń wá ládùúgbó mi?’ Àmọ́ mo ti bẹ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ pé kó ṣèrànlọ́wọ́ fún mi. Mo wá rò ó pé ó mà lè jẹ́ àjèjì yíì ni Ọlọ́run rán sí mi láti dáhùn àdúrà mi.” Bí Gloria ṣe gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, ó sì tẹ̀ síwájú kíákíá débi tó fi ṣèrìbọmi, láìfi àtakò tí ìdílé rẹ̀ ń ṣe sí i pè. Ní báyìí Gloria ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ọkọ rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀ náà sì ti ń sin Jèhófà.

Èrè Táwọn Tó Fi Kún Iṣẹ́ Ìwàásù Wọn Ń Rí

Lóòọ́tọ́, sísìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i kò ṣàì láwọn ìṣòro tiẹ̀, àmọ́ èrè ibẹ̀ pọ̀ jaburata. Arákùnrin Ralph tá a fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Ara àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni àwọn èèyàn tó wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ṣáínà, Jàmáíkà àti Sweden, tó fi mọ́ àwọn èèyàn pàtàkì tó wá láti orílẹ̀-èdè Gánà. Àwọn kan lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yìí náà wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Látìgbà tí ìdílé wa ti wà níbẹ̀, ó ti di ìjọ Gẹ̀ẹ́sì méje tí wọ́n ti dá sílẹ̀ lójú wa. Àwọn ọmọ wa méjèèjì náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọnà, wọ́n sì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà báyìí.”

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, iye ìjọ Gẹ̀ẹ́sì tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ti di méjìdínláàádọ́rùn-ún [88], ọ̀pọ̀ àwùjọ míì ló sì tún wà tí kò tíì di ìjọ. Kí ló mú kí ìbísí yẹn yára tó bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tíì wàásù fún rí. Ohun tó jẹ́ káwọn míì fetí sáwọn Ẹlẹ́rìí ni pé kò sáwọn ẹbí àti ará wọn lórílẹ̀-èdè yẹn tí ì bá máa dí wọn lọ́wọ́ láti má ṣe gbọ́. Àwọn míì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nítorí pé wọ́n ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, ìgbà yẹn ni wọ́n sì ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ó ju ìdá mẹ́ta lára àwọn akéde tó wà láwọn ìjọ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, èyí ló fi kún ìtara àwọn ìjọ yẹn, tó sì ń mú kí wọ́n bí sí i.

Ìbùkún Ń Dúró De Ìwọ Náà

Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló máa fetí sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n bá gbọ́ ìwàásù lédè ìbílẹ̀ tiwọn. Torí náà, ó dùn mọ́ wa nínú bá a ṣe ń rí ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà, àpọ́n tàbí ẹni tó ti ṣègbéyàwó, tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn, tí wọ́n ń fẹ́ láti lọ sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Lóòótọ́, wọ́n lè ní láti fara da àwọn ìṣòro o, àmọ́ ìṣòro wọ̀nyẹn ò tó nǹkan tá a bá fi wé ayọ̀ tí wọ́n ń rí bí wọ́n ṣe ń ráwọn ọlọ́kàn rere tí wọ́n ń gba òtítọ́. Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ṣe ètò tó yẹ kó o bàa lè lọ síbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i, ì báà ṣe lórílẹ̀-èdè rẹ tàbí nílẹ̀ òkèèrè? a (Lúùkù 14:28-30; 1 Kọ́r. 16:9) Tó o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń dúró dè ọ́ níbẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ àláyé síwájú sí i nípa sísìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i, wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 111 sí 112.

[Àpọtí tó wà ní ojú ìwé 21]

Ayọ̀ Àwọn Tó Ti Fẹ̀yìn Tì Gbàfiyèsí

Láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Beryl ti ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà. Ó ti ṣe máníjà ní ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ tó ní ẹ̀ka sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ó tún jẹ́ akọni eléré ìdárayá orí ẹṣin, òun ni wọ́n sì yàn pé kó lọ ṣojú orílẹ̀-èdè Kánádà nínú ìdíje Òlíńpíìkì tí wọ́n ṣe lọ́dún 1980. Nígbà tí Beryl fẹ̀yìn tì, ìlú Chapala, nílẹ̀ Mẹ́síkò ló lọ fìdí kalẹ̀ sí, òun àti ọkọ rẹ̀ sì máa ń lọ jẹun láwọn ilé oúnjẹ tó wà lágbègbè wọn. Tó bá ti rí àwọn èèyàn elédè Gẹ̀ẹ́sì kan tó ti fẹ̀yìn tì, tí wọ́n ń láyọ̀, ó máa ń fi ara rẹ̀ hàn wọ́n, á sì béèrè ohun tí wọ́n ń ṣe ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àwọn tí wọ́n wá jẹun tí inú wọn sì ń dùn wọ̀nyẹn sábà máa ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Beryl àti ọkọ rẹ̀ wá rò ó pé tó bá jẹ́ pé mímọ Ọlọ́run ló ń mú kéèyàn láyọ̀ kí ìgbésí ayé èèyàn sì nítumọ̀, àwọn náà yóò fẹ́ mọ Ọlọrun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ń lọ sípàdé fún bí oṣù mélòó kan, Beryl gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì di Ẹlẹ́rìí. Ọ̀pọ̀ ọdún ló sì wá fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

[Àpọtí tó wà ní ojú ìwé 22]

“Àǹfààní Ńlá Ló Jẹ́ Pé Wọ́n Wà Lọ́dọ̀ Wa”

Àwọn ará tó wà láwọn ibi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i máa ń mọrírì àwọn tó wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì kan tó wà ní àgbègbè Caribbean ròyìn pé: “Tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wá sìn níbí bá fi lè pa dà, ẹsẹ̀ àwọn ìjọ tó wà níbí á mì. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé wọ́n wà lọ́dọ̀ wa.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.” (Sm. 68:11) Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ wà lára àwọn tó lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Ẹ̀mí tí wọ́n ní tó mú kí wọ́n lè yááfì àwọn nǹkan jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá fáwọn ẹlòmíì. Ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù sọ pé: “Àwọn obìnrin ló pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ wa, láwọn ìjọ míì, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ kó ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ṣì jẹ́ ẹni tuntun nínú òtítọ́, àmọ́ àwọn arábinrin aṣáájú-ọ̀nà tí kò lọ́kọ tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè máa ń ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti dá àwọn arábìnrin tuntun yìí lẹ́kọ̀ọ́. A mọ́rírì àwọn arábìnrin tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè yìí gan-an ni o!”

Kí ni èrò àwọn arábìnrin wọ̀nyẹn nípa iṣẹ́ ìsìn wọn ní ilẹ̀ òkèèrè? Ẹ gbọ́ ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Angelica tó ti lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún dáadáa, tó sì ti fi ọ̀pọ̀ ọdún sìn nílẹ̀ òkèèrè gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà tí kò lọ́kọ sọ. Ó ní: “Iṣẹ́ yìí ní ọ̀pọ̀ ìṣòro. Ìgbà kan wà tí mò ń sìn níbi tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mo máa ń rìn lójú ọ̀nà tí àbàtà wà. Ó sì máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́ bí mo ṣe máa ń rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí ìyà ń jẹ. Àmọ́ inú mi ń dùn bí mo ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tó tún máa ń wú mi lórí ni bí àwọn arábìnrin nínú ìjọ ṣe máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún bí mo ṣe wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Arábìnrin kan sọ fún mi pé àpẹẹrẹ bí mo ṣe wá láti ìyànníyàn orílẹ̀-èdè míì láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ló mú kóun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.”

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sue tó lé díẹ̀ lẹ́ni àádọ́ta ọdún sọ pé: “Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ló máa dojú kọ ẹ́, àmọ́ wọn ò tó nǹkan tá a bá fi wé àǹfààní tó o máa ní. Òde ẹ̀rí mà ń dùn mọ́ni o! Níwọn bó ti jẹ pé àwọn arábìnrin tó kéré sí mi lọ́jọ́ orí ni mo máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù pẹ̀lú wọn lóde ẹ̀rí, mo máa ń ṣàlàyé ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì àti látinú ìtẹ̀jáde wa fún wọn nípa ohun téèyàn lè ṣe nígbà tí ìṣòro bá dé. Wọ́n sábà máa ń sọ fún mi pé àpẹẹrẹ bí mo ṣe máa ń fara da ìṣòro tí mo sì máa ń borí rẹ̀ àti bí mo ṣe ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà tí kò lọ́kọ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ti mú kí wọ́n rí báwọn náà ṣe lè borí àwọn ìṣòro tó bá yọjú nígbèésí ayé wọn. Inú mi ń dùn gan-an bí mo ṣe ń ran àwọn arábìnrin yìí lọ́wọ́.”

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 20]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ORÍLẸ̀-ÈDÈ MẸ́SÍKÒ

Monterrey

Guanajuato

Irapuato

Ajijic

Chapala

Adágún Odò Chapala

San Miguel de Allende

Querétaro

MEXICO CITY

Cancún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn kan ń láyọ̀ pé wọ́n ń wàásù fún àwọn àjèjì tó jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa gbọ́ ìhìn rere