Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Mọyì Jésù Tó Jẹ́ Mósè Títóbi Jù

Bá A Ṣe Lè Mọyì Jésù Tó Jẹ́ Mósè Títóbi Jù

Bá A Ṣe Lè Mọyì Jésù Tó Jẹ́ Mósè Títóbi Jù

“Jèhófà Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láti àárín àwọn arákùnrin yín. Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí i.”—ÌṢE 3:22.

1. Ipa wo ni Jésù Kristi ní lórí ọ̀ràn ọmọ aráyé?

 NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, wọ́n bí Jésù Kristi sílé ayé. Nígbà tí wọ́n bí i, ògìdìgbó àwọn áńgẹ́lì ń yin Ọlọ́run, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan sì ń gbọ́. (Lúùkù 2:8-14) Nígbà tó pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ péré ló fi ṣe é, àmọ́ iṣẹ́ tó ṣe yẹn yí gbogbo nǹkan pa dà fọ́mọ aráyé. Ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ wú òpìtàn kan tó ń jẹ́ Philip Schaff, tó gbáyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún lórí débi tó fi sọ nípa rẹ̀ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kò kọ ìwé kankan, àìmọye ìwé làwọn èèyàn kọ nípa rẹ̀, tó fi mọ́ ìwé ńláńlá táwọn ọ̀mọ̀wé kọ, bẹ́ẹ̀ sì ni àìmọye ìwàásù, ọ̀rọ̀ àti ìjíròrò, iṣẹ́ ọnà àti orin ìyìn ló dá lórí rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ayé àtijọ́ àti tòde òní, kò sẹ́ni táwọn èèyàn ṣe irú àwọn nǹkan tó pọ̀ tó báyẹn nípa rẹ̀.”

2. Kí ni àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?

2 Àpọ́sítélì Jòhánù kọ ìwé nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó sì sọ níparí ìwé náà pé: “Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn wà pẹ̀lú tí Jésù ṣe, tí ó jẹ́ pé, bí a bá ní láti kọ̀wé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn ní kíkún, mo rò pé, ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.” (Jòh. 21:25) Jòhánù mọ̀ pé ìwọ̀nba díẹ̀ lòun lè kọ lára gbogbo ohun tí Jésù sọ àtohun tó ṣe láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi ṣe àwọn ohun tó gbé ṣe. Síbẹ̀, ìwọ̀nba ohun tó kọ sínú ìwé Ìhìn Rere rẹ̀ ṣàǹfààní tó pọ̀ jọjọ.

3. Kí ló lè jẹ́ ká túbọ̀ lóye ipa tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ?

3 Yàtọ̀ sóhun táwọn ìwé Ìhìn Rere pàtàkì mẹ́rin sọ, àwọn ibòmíì tún wà nínú Bíbélì tó sọ àwọn nǹkan kan nípa ìgbésí ayé Jésù, èyí sì lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wo ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọkùnrin olóòótọ́ kan tó gbé láyé ṣáájú Jésù, a óò rí àwọn ẹ̀kọ́ tó lè jẹ́ ká túbọ̀ lóye ipa tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ìwọ̀nyí.

Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Tí Ìgbésí Ayé Wọn Ṣàpẹẹrẹ Ìgbésí Ayé Kristi

4, 5. Àwọn wo ni ìgbésí ayé wọn jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìgbésí ayé Jésù ṣe máa rí, láwọn ọ̀nà wo sì ni?

4 Jòhánù àtàwọn mẹ́ta yòókù tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere tọ́ka sí Mósè, Dáfídì àti Sólómọ́nì, pé ìgbésí ayé wọn jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìgbésí ayé Jésù ṣe máa rí gẹ́gẹ́ bí Ẹni Àmì Òróró àti Ọba lọ́la. Ọ̀nà wo làwọn ẹni àtijọ́ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí gbà jẹ́ ká mọ bí ìgbésí ayé Jésù ṣe máa rí, kí la sì lè rí kọ́ látinú ìtàn wọn?

5 Láìfọ̀rọ̀gùn, Bíbélì pe Mósè ní wòlíì, alárinà àti olùdáǹdè. Ohun tí Jésù náà sì jẹ́ nìyẹn. Dáfídì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti ọba tó ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì. Jésù náà jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti ọba ajagunṣẹ́gun. (Ìsík. 37:24, 25) Nígbà tí Sólómọ́nì ṣì jẹ́ olóòótọ́, ọlọ́gbọ́n ọba ni, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sì ní àlàáfíà púpọ̀ nígbà ìṣàkóso rẹ̀. (1 Ọba 4:25, 29) Ọgbọ́n Jésù pẹ̀lú ga jù, Bíbélì tún pè é ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísá. 9:6) Ó ṣe kedere pé Kristi Jésù kó ipa tó jọ tàwọn ọkùnrin ayé ìgbà yẹn, àmọ́ ipa tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ju tiwọn lọ fíìfíì. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ fi Jésù àti Mósè wéra ká wá rí bí ìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye ipa tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.

Mósè Jẹ́ Àpẹẹrẹ Irú Ẹni Tí Jésù Máa Jẹ́

6. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe ṣàlàyé ìdí tó fi pọn dandan láti máa fetí sí Jésù?

6 Kété lẹ́yìn àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù ń bá ogunlọ́gọ̀ èrò tí wọ́n wá jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fa àsọtẹ́lẹ̀ Mósè kan yọ, ó sì jẹ́ kí wọ́n rí bó ṣe ṣẹ sí Jésù Kristi lára. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Pétérù àti Jòhánù wo alágbe kan tó ti yarọ látìgbà tí wọ́n ti bí i sàn, àwọn èrò yẹn ń rọ́ wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nítorí pé “ó yà wọ́n lẹ́nu gidigidi.” Pétérù wá ṣàlàyé fún wọn pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ Jésù Kristi ló mú kí iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n ń rí yìí ṣẹlẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló wá fa gbólóhùn kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù yọ, ó ní: “Ní ti tòótọ́, Mósè wí pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láti àárín àwọn arákùnrin yín. Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí i ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó bá ń sọ fún yín.’”—Ìṣe 3:11, 22, 23; ka Diutarónómì 18:15, 18, 19.

7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù máa lóyè ohun tó sọ nípa wòlíì tó tóbi ju Mósè lọ?

7 Ó jọ pé ọ̀rọ̀ Mósè tí Pétérù sọ yẹn kò ṣàjèjì sáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù lọ́jọ́ yẹn. Ìdí ni pé Júù ni wọ́n, ẹni tí wọ́n sì ń gbé gẹ̀gẹ̀ ni Mósè. (Diu. 34:10) Torí náà, lójú méjèèjì ni wọ́n ń retí ìgbà tí wòlíì tó tóbi ju Mósè lọ yẹn máa dé. Wòlíì tí wọ́n ń retí yìí kò ní jẹ́ ẹni àmì òróró kan tá a kàn lè pè ní àyànfẹ́ Ọlọ́run, bíi ti Mósè. Kàkà bẹ́ẹ̀ òun ló máa jẹ́ Mèsáyà gan-gan, ìyẹn “Kristi ti Ọlọ́run, Àyànfẹ́” Jèhófà.—Lúùkù 23:35; Héb. 11:26.

Àwọn Ohun Tí Mósè àti Jésù Fi Jọra

8. Àwọn ọ̀nà wo ni ìgbésí ayé Mósè àti ti Jésù fi jọra?

8 Àwọn ọ̀nà kan wà tí ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé fi jọ ti Mósè. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn méjèèjì wà lọ́mọdé, wọ́n bọ́ lọ́wọ́ òǹrorò alákòóso tí ì bá pa wọ́n. (Ẹ́kís. 1:22–2:10; Mát. 2:7-14) Bákan náà, àwọn méjèèjì la ‘pè jáde láti Íjíbítì.’ Wòlíì Hóséà sọ pé: “Nígbà tí Ísírẹ́lì jẹ́ ọmọdékùnrin, nígbà náà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, láti Íjíbítì ni mo sì ti pe ọmọkùnrin mi.” (Hós. 11:1) Ọ̀rọ̀ tí Hóséà sọ yẹn tọ́ka sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Mósè, aṣáájú tí Ọlọ́run yàn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kó wọn jáde kúrò ní Íjíbítì. (Ẹ́kís. 4:22, 23; 12:29-37) Àmọ́ kì í ṣe ohun tó ti kọjá sẹ́yìn nìkan ni ọ̀rọ̀ Hóséà yẹn ń tọ́ka sí o, ó tún tọ́ka sí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà ayé Hóséà. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Hóséà sọ yẹn ló nímùúṣẹ nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà gbé Jésù pa dà wá láti Íjíbítì lẹ́yìn ikú Hẹ́rọ́dù Ọba.—Mát. 2:15, 19-23.

9. (a) Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo ni Mósè àti Jésù ṣe? (b) Sọ àwọn ohun míì tí Mósè àti Jésù fi jọra wọn. (Wo àpótí náà “Àwọn Ọ̀nà Míì Tí Jésù Gbà Dà Bíi Mósè,” lójú ìwé 26.)

9 Àti Mósè, àti Jésù ló ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, tí èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà wà lẹ́yìn wọn. Kódà, Mósè lẹni tó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ ìyanu nínú Bíbélì. (Ẹ́kís. 4:1-9) Bí àpẹẹrẹ Mósè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kan tó jẹ mọ́ omi, bí irú ìgbà tó sọ omi odò Náílì àtàwọn adágún odò rẹ̀ tó kún fún esùsú di ẹ̀jẹ̀, ìgbà tó pín Òkun Pupa níyà àti ìgbà tó mú kí omi tú jáde látinú àpáta tó wà ní aṣálẹ̀. (Ẹ́kís. 7:19-21; 14:21; 17:5-7) Jésù náà ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó jẹ mọ́ omi. Iṣẹ́ ìyanu tó kọ́kọ́ ṣe ni pé ó sọ omi di wáìnì níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan. (Jòh. 2:1-11) Nígbà tó yá, ó mú kí Òkun Gálílì tó ń ru gùdù pa rọ́rọ́. Ìgbà kan wà tó tiẹ̀ rìn lórí omi! (Mát. 8:23-27; 14:23-25) A lè rí àwọn ohun míì tí Mósè àti Jésù tó jẹ́ Mósè Títóbi Jù fi jọra nínú  àpótí tó wà ní ojú ìwé 26.

Mọyì Jíjẹ́ Tí Kristi Jẹ́ Wòlíì

10. Àwọn iṣẹ́ wo ni wòlíì tòótọ́ máa ń ṣe, báwo sì ni Mósè ṣe ṣe àwọn iṣẹ́ ọ̀hún?

10 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé ẹni tó bá ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú nìkan ni wòlíì, àmọ́ ọ̀kan péré ni sísọ àsọtẹ́lẹ̀ jẹ́ lára àwọn iṣẹ́ wòlíì. Wòlíì tòótọ́ lẹni tó jẹ́ agbẹnusọ tí Jèhófà mí sí, tó sì máa ń polongo “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:11, 16, 17) Ara ohun tó máa ń wà nínú iṣẹ́ wòlíì ni kíkéde ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, ṣíṣí àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe payá tàbí pípolongo ìdájọ́ Ọlọ́run. Gbogbo èyí ni Mósè ṣe gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Ó sàsọtẹ́lẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan Ìyọnu Mẹ́wàá tó kọ lu àwọn ará Íjíbítì. Ó gba Òfin tó jẹ́ májẹ̀mú ó sì fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Sínáì. Ó sì tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. Síbẹ̀, wòlíì kan tó ju Mósè lọ ṣì máa wá tó bá yá.

11. Ọ̀nà wo ni Jésù gba ṣe iṣẹ́ wòlíì tó ju ti Mósè lọ?

11 Nígbà tó wá di ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sekaráyà ṣe iṣẹ́ wòlíì nígbà tó jẹ́ kí aráyé mọ ìfẹ́ Ọlọ́run fún Jòhánù ọmọ rẹ̀. (Lúùkù 1:76) Ọmọ náà ló wá di Jòhánù Olùbatisí, tó kéde pé wòlíì tó tóbi ju Mósè lọ tí wọ́n ti ń retí tipẹ́, ìyẹn Jésù Kristi, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. (Jòh. 1:23-36) Jésù náà sàsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan, èyí tó fi hàn pé òun náà jẹ́ wòlíì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀, ó sọ bóun ṣe máa kú, ibi tóun máa kú sí, àti àwọn ẹni tó máa ṣekú pa òun. (Mát. 20:17-19) Kódà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ya àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ó ní Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ máa pa run. (Máàkù 13:1, 2) Ó tiẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun táá máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí pàápàá.—Mát. 24:3-41.

12. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé lélẹ̀? (b) Kí nìdí tá a fi ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lónìí?

12 Yàtọ̀ sí pé Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó tún jẹ́ oníwàásù àti olùkọ́. Ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kò sì sẹ́ni tó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ju tiẹ̀ lọ. (Lúùkù 4:16-21, 43) Kò sí olùkọ́ tó lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àwọn kan tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Jòh. 7:46) Jésù fi ìtara tan ìhìn rere kálẹ̀, àpẹẹrẹ ìtara rẹ̀ yìí làwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sì fi ń kéde Ìjọba Ọlọ́run. Bó ṣe fi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé tó ṣì ń bá a lọ títí dòní lélẹ̀ nìyẹn. (Mát. 28:18-20; Ìṣe 5:42) Lọ́dún tó kọjá, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ mílíọ̀nù méje lo ohun tó tó bílíọ̀nù kan àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù [1,500,000,000] wákátì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti kíkọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ǹjẹ́ ò ń kópa tó jọjú lẹ́nu iṣẹ́ náà?

13. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti “wà lójúfò”?

13 Kò sí àní-àní pé Jèhófà ti mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ pé òun á gbé wòlíì kan bíi Mósè dìde. Kí ló yẹ kó o wá ṣe nípa mímọ̀ tó o mọ ìyẹn? Ǹjẹ́ ó mú kó túbọ̀ dá ọ lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ máa nímùúṣẹ? Ó dájú pé tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ Mósè Títóbi Jù, a ó lè “wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́” láti máa kíyè sí ohun tí Ọlọ́run máa ṣe láìpẹ́.—1 Tẹs. 5:2, 6.

Mọyì Jíjẹ́ Tí Kristi Jẹ́ Alárinà

14. Báwo ni Mósè ṣe jẹ́ alárinà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Ọlọ́run?

14 Bíi ti Mósè, Jésù pẹ̀lú jẹ́ alárinà. Alárinà máa ń mú kí àwọn ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jọ ní àjọṣe tó gún régé. Mósè ni Jèhófà lò gẹ́gẹ́ bí alárinà nígbà tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin. Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Jékọ́bù yìí ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run ni, wọn ì bá ṣì máa jẹ́ àkànṣe dúkìá Ọlọ́run, ìyẹn ìjọ rẹ̀. (Ẹ́kís. 19:3-8) Májẹ̀mú tó bá wọn dá yìí ṣiṣẹ́ láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni.

15. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ alárinà tó ju alárinà lọ?

15 Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà dá májẹ̀mú kan tó dára ju ìyẹn lọ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tuntun, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tó wá di ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó kárí ayé. (Gál. 6:16) Ara òkúta ni Ọlọ́run sì kọ àwọn òfin tó wà nínú májẹ̀mú tí Mósè jẹ́ alárinà rẹ̀ sí, àmọ́ májẹ̀mú tí Jésù jẹ́ alárinà rẹ̀ ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ. Inú ọkàn àwọn èèyàn ni Ọlọ́run kọ àwọn òfin tó wà nínú májẹ̀mú ti Jésù yìí sí. (Ka 1 Tímótì 2:5; Hébérù 8:10.) Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ni dúkìá àkànṣe fún Ọlọ́run báyìí, àwọn ni ‘orílẹ̀-èdè tó ń so èso’ Ìjọba tó wà níkàáwọ́ Mèsáyà. (Mát. 21:43) Àwọn tó jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” yìí làwọn tó ń nípìn-ín nínú májẹ̀mú tuntun yẹn. Àmọ́ kì í ṣàwọn nìkan ló máa jàǹfààní rẹ̀. Àìmọye ogunlọ́gọ̀ èrò míì pẹ̀lú, kódà tó fi mọ́ àwọn tó ń sùn lọ́wọ́ nínú ikú, ṣì máa gbádùn àwọn ìbùkún ayérayé tí májẹ̀mú tó ga lọ́lá yìí máa mú wá.

Mọyì Jíjẹ́ Tí Kristi Jẹ́ Olùdáǹdè

16. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo Mósè láti dá Ísírẹ́lì nídè? (b) Gẹ́gẹ́ bí Ẹ́kísódù 14:13 ṣe sọ, ta ni Ẹni náà gan-an tó dá wọn nídè?

16 Ewu rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí lóru ọjọ́ tí wọ́n lò kẹ́yìn nílẹ̀ Íjíbítì. Ìdí ni pé áńgẹ́lì Ọlọ́run máa tó la ilẹ̀ Íjíbítì kọjá láti pa gbogbo àkọ́bí tó wà níbẹ̀. Àmọ́ Jèhófà sọ fún Mósè pé àjálù yìí ò ní kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n máa fi ṣe Ìrékọjá sí ara òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn wọn. (Ẹ́kís. 12:1-13, 21-23) Bí nǹkan sì ṣe lọ gan-an nìyẹn. Nígbà tó yá ewu míì tún dojú kọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ti há, Òkun Pupa wà níwájú wọn, àwọn ọmọ Íjíbítì sì ń fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun lé wọn bọ̀ lẹ́yìn. Àmọ́ Jèhófà tún dá wọn nídè nípasẹ̀ Mósè, tó fi iṣẹ́ ìyanu pín òkun níyà tí ọ̀nà sì là.—Ẹ́kís. 14:13, 21.

17, 18. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ olùdáǹdè tó ju Mósè lọ?

17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdáǹdè tí Jèhófà tọwọ́ Mósè pèsè yìí jọni lójú lóòótọ́, wọn ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìdáǹdè tí Jèhófà tipasẹ̀ Jésù pèsè. Ipasẹ̀ Jésù làwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lára ọmọ aráyé máa gbà rí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12, 18) “Ìdáǹdè àìnípẹ̀kun” sì lèyí. (Héb. 9:11, 12) Ìtumọ̀ orúkọ Jésù ni “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Yàtọ̀ sí pé Jésù Olùdáǹdè wa, ìyẹn Olùgbàlà wa, gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá kọjá, ó tún ṣí ọ̀nà ìgbádùn ọjọ́ iwájú sílẹ̀ fún wa. Bí Jésù ṣe dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ńṣe ló gbà wọ́n lọ́wọ́ ìbínú Ọlọ́run tó sì jẹ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.—Mát. 1:21.

18 Tó bá yá, ara àǹfààní tó máa wá látinú ìdáǹdè tí Jésù pèsè fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé wọ́n máa bọ́ lọ́wọ́ àìsàn àti ikú tó jẹ́ oró ẹ̀ṣẹ̀. Láti lè fojú inú rí bó ṣe máa rí nígbà yẹn, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù lọ sílé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jáírù, ẹni tí ọmọbìnrin rẹ̀ ọmọ ọdún méjìlá kú. Jésù fi Jáírù lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Má bẹ̀rù, sáà ti fi ìgbàgbọ́ hàn, a ó sì gbà á là.” (Lúùkù 8:41, 42, 49, 50) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ọmọbìnrin yẹn jíǹde lóòótọ́! Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí inú àwọn òbí ọmọ yẹn á ti dùn tó lọ́jọ́ yẹn? Nígbà náà, wàá lè máa fojú inú wo bí ìdùnnú á ṣe máa ṣubú lu ayọ̀ fún wa nígbà tí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù tí], wọn yóò sì jáde wá” nígbà àjíǹde. (Jòh. 5:28, 29) Ní tòótọ́, Jésù ni Olùgbàlà àti Olùdáǹdè wa!—Ka Ìṣe 5:31; Títù 1:4; Ìṣí. 7:10.

19, 20. (a) Àǹfààní wo ló máa ṣe fún wa tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ipa tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bíi Mósè Títóbi Jù? (b) Kí ni àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé?

19 Bá a ṣe wá mọ̀ pé a láǹfààní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní iṣẹ́ ìgbàlà tí Jésù ṣe, ó yẹ kó sún wa láti kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (Aísá. 61:1-3) Bákan náà, tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ipa tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bí ẹni tó tóbi lọ́lá ju Mósè lọ, yóò mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa dá gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nídè nígbà tó bá mú ìdájọ́ wá sórí àwọn ẹni ibi.—Mát. 25:31-34, 41, 46; Ìṣí. 7:9, 14.

20 Láìsí àní-àní, Jésù ni Mósè Títóbi Jù. Ó ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu tí Mósè ò lè ṣe láé. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì àti ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí alárinà kan gbogbo ìran èèyàn. Gẹ́gẹ́ bí Olùdáǹdè, kì í ṣe ìgbàlà tó wà fúngbà díẹ̀ ni Jésù mú wá, bí kò ṣe ìgbàlà ayérayé fún àwọn tó ṣeé rà pa dà nínú ọmọ aráyé. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tá a lè rí kọ́ nípa Jésù látara àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé àtijọ́. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé Jésù ni Dáfídì àti Sólómọ́nì Títóbi Jù.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

Ọ̀nà wo ni Jésù gbà tóbi lọ́lá ju Mósè gẹ́gẹ́ bíi

• wòlíì?

• alárinà?

• olùdáǹdè?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

 Àwọn Ọ̀nà Míì Tí Jésù Gbà Dà Bíi Mósè

◻ Àwọn méjèèjì ló fi ipò ńlá sílẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ sin Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.—2 Kọ́r. 8:9; Fílí. 2:5-8; Héb. 11:24-26.

◻ Àwọn méjèèjì ló ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni àmì òróró tàbí àyànfẹ́ Jèhófà.—Máàkù 14:61, 62; Jòh. 4:25, 26; Héb. 11:26.

◻ Àwọn méjèèjì ló wá lórúkọ Jèhófà.—Ẹ́kís. 3:13-16; Jòh. 5:43; 17:4, 6, 26.

◻ Àwọn méjèèjì ló jẹ́ ọlọ́kàn tútù.—Núm. 12:3; Mát. 11:28-30.

◻ Àwọn méjèèjì lọ́wọ́ nínú bíbọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn.—Ẹ́kís. 16:12; Jòh. 6:48-51.

◻ Àwọn méjèèjì ló ṣiṣẹ́ onídàájọ́ àti afúnnilófin.—Ẹ́kís. 18:13; Mál. 4:4; Jòh. 5:22, 23; 15:10.

◻ Àwọn méjèèjì ni Ọlọ́run fi ṣe olórí ilé rẹ̀.—Núm. 12:7; Héb. 3:2-6.

◻ Àwọn méjèèjì ni Ìwé Mímọ́ pè ní ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà.—Héb. 11:24-29; 12:1; Ìṣí. 1:5.

◻ Lẹ́yìn ikú Mósè, Ọlọ́run palẹ̀ òkú rẹ̀ mọ́, bó sì ṣe palẹ̀ òkú Jésù náà mọ́ nìyẹn.—Diu. 34:5, 6; Lúùkù 24:1-3; Ìṣe 2:31; 1  Kọ́r. 15:50; Júúdà 9.