Bá a Ṣe Lè Mọyì Jésù Tó Jẹ́ Dáfídì Àti Sólómọ́nì Títóbi Jù
Bá a Ṣe Lè Mọyì Jésù Tó Jẹ́ Dáfídì Àti Sólómọ́nì Títóbi Jù
“Wò ó! ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín.”—MÁT. 12:42.
1, 2. Kí nídì tó fi lè ya èèyàn lẹ́nu pé Dáfídì ni Jèhófà ní kí Sámúẹ́lì fòróró yàn lọ́ba?
WÒLÍÌ Sámúẹ́lì ò rò pé Dáfídì nipò ọba tọ́ sí. Ó ń wo Dáfídì bí ọmọ kékeré kan tí kò lè ṣe ju pé kó máa da àgùntàn kiri. Yàtọ̀ síyẹn, ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n ti bí Dáfìdí gan-an kì í tún ṣe ìlú òlókìkí. Ìwé Mímọ́ tiẹ̀ sọ pé ìlú náà “kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà.” (Míkà 5:2.) Àmọ́, ọmọkùnrin kékeré tó dà bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan yìí, tó sì wá láti ìlú kékeré yìí ni Sámúẹ́lì máa ní láti fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa jẹ lórí Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú.
2 Dáfídì ọmọ kékeré yìí kọ́ ni Jésè bàbá rẹ̀ kọ́kọ́ mú wá fún Sámúẹ́lì láti fòróró yàn lọ́ba. Ó ti kọ́kọ́ mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀gbọ́n Dáfídì méjèèje wá, kò sì sí ìkankan nínú wọn tí Jèhófà yàn. Dáfídì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn gan-an kò tiẹ̀ sí níbẹ̀ nígbà tí Sámúẹ́lì fi wà nílé Jésè ọkùnrin olóòótọ́ yẹn, tó fẹ́ yan ẹni tí ọba kàn nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Dáfídì tí kò sí níbẹ̀ yìí gan-an ni Jèhófà yàn lọ́ba, ẹni tí Jèhófà sì fẹ́ ló yàn yẹn.—1 Sám. 16:1-10.
3. (a) Kí ni Jèhófà máa ń kà sí pàtàkì nígbà tó bá ń ṣàyẹ̀wò olúkúlùkù èèyàn? (b) Lẹ́yìn ìgbà tí Sámúẹ́lì ti fòróró yan Dáfídì, kí ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lára Dáfídì?
3 Ó ní ohun kan tí Jèhófà ń wò àmọ́ tí Sámúẹ́lì kò rí. Ọlọ́run ti rí ọkàn Dáfídì, ohun tó sì rí nínú ọkàn rẹ̀ dùn mọ́ ọn. Kì í ṣe ìrísí èèyàn ni Ọlọ́run máa ń kà sí pàtàkì, bí kò ṣe irú ẹni tí onítọ̀hún jẹ́ nínú gan-an. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:7.) Torí náà, nígbà tí Sámúẹ́lì rí i pé Jèhófà kò yan èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀gbọ́n Dáfídì méjèèje, ó sọ pé kí wọ́n lọ mú èyí àbígbẹ̀yìn wá láti ibi tó da ẹran lọ. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, [Jésè] ránṣẹ́, ó sì mú kí [Dáfídì] wá. Wàyí o, ó jẹ́ apọ́nbéporẹ́, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ojú rẹ̀ lẹ́wà, ó sì rẹwà ní ìrísí. Nígbà náà ni Jèhófà sọ pé: ‘Dìde, fòróró yàn án, nítorí pé òun nìyí!’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sámúẹ́lì mú ìwo òróró, ó sì fòróró yàn án láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára Dáfídì láti ọjọ́ yẹn lọ.”—1 Sám. 16:12, 13.
Ìgbésí Ayé Dáfídì Ṣàpẹẹrẹ Ìgbésí Ayé Kristi
4, 5. (a) Sọ àwọn ohun tí Dáfídì àti Jésù fi jọra. (b) Kí nìdí tá a fi lè pe Jésù ní Dáfídì Títóbi Jù?
4 Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n bí Dáfídì sí náà ni wọ́n bí Jésù sí ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Dáfídì. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, Jésù náà kò jọ ẹni tí ọba tọ́ sí. Ìyẹn ni pé wọn ò gbà pé irú ọba táwọn èèyàn Ísírẹ́lì ti ń retí nìyẹn. Àmọ́ bíi ti Dáfídì, òun ni Jèhófà yàn lọ́ba. Olùfẹ́ ọ̀wọ́n ló jẹ́ fún Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ṣe jẹ́. a (Lúùkù 3:22) “Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára” Jésù pẹ̀lú.
5 Àwọn ohun tí Dáfídì àti Jésù fi jọra tún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, Áhítófẹ́lì tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn Dáfídì dà á, bákan náà, Júdásì Ísíkáríótù tó jẹ́ àpọ́sítélì Jésù da Jésù. (Sm. 41:9; Jòh. 13:18) Àti Dáfídì àti Jésù ló ní ìtara tó ga fún ilé ìjọsìn Jèhófà. (Sm. 27:4; 69:9; Jòh. 2:17) Jésù tún jẹ́ ajogún Dáfídì. Kó tó di pé wọ́n bí Jésù, áńgẹ́lì kan ti sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò . . . fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un.” (Lúùkù 1:32; Mát. 1:1) Àmọ́ nítorí pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ló ní láti ṣẹ sára Jésù, ó ju Dáfídì lọ fíìfíì. Òun ni Dáfídì Títóbi Jù táwọn èèyàn ti ń retí pé ó máa jẹ́ Mèsáyà Ọba.—Jòh. 7:42.
Máa Tẹ̀ Lé Ọba Tó Jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn
6. Àwọn ọ̀nà wo ni Dáfídì gbà jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn rere?
6 Olùṣọ́ àgùntàn tún ni Jésù. Kí la fi ń mọ olùṣọ́ àgùntàn rere? Ohun tá a fi ń mọ̀ ọ́n ni pé tọkàntọkàn àti tìgboyàtìgboyà ni yóò fi máa tọ́jú àwọn àgùntan, tí yóò fi máa bọ́ wọn tí yóò sì fi máa ṣọ́ wọn. (Sm. 23:2-4) Olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó sì tọ́jú àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ dáadáa. Ó nígboyà débi pé nígbà tí kìnnìún kan àti béárì kan fẹ́ pa àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀, ó fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti dáàbò bo àwọn àgùntàn náà.—1 Sám. 17:34, 35.
7. (a) Báwo ni Dáfídì ṣe kọ́ ẹ̀kọ́ tó wúlò fún un láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà lòun?
7 Ní gbogbo ọdún tí Dáfídì fi ń bójú tó àwọn àgùntàn nínú pápá àti lórí òkè, ó ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó máa wúlò fún un láti lè ṣe iṣẹ́ ńlá tó wà nínú bíbójú tó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. b (Ps. 78:70, 71) Ìwà Jésù náà ti fi hàn pé olùṣọ́ àgùntàn rere tó ṣeé tẹ̀ lé ni. Jèhófà fún un lókun ó sì tọ́ ọ sọ́nà bó ṣe ń bójú tó “agbo kékeré” àti “àgùntàn mìíràn” rẹ̀. (Lúùkù 12:32; Jòh. 10:16) Ìdí rèé tí Jésù fi jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà. Ó mọ àwọn àgùntàn rẹ̀ dáadáa débi pé orúkọ ló fi ń pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn débi pé nígbà tó wà láyé, tinútinú ló fi fi ara rẹ̀ jìn fún wọn. (Jòh. 10:3, 11, 14, 15) Gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà, Jésù ṣe ohun kan tí Dáfídì kò lè ṣe láé. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rú ẹbọ ìràpadà kí aráyé bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ikú. Kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ tí kò fi ní darí “agbo kékeré” rẹ̀ débi tí wọ́n ti máa gba àìleèkú lọ́run. Kò sì sóhun tó lè ní kó má darí “àwọn àgùntàn mìíràn” débi tí wọ́n ti máa ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun, níbi tí kò ti ní sáwọn ẹni bí ìkookò ajẹranjegun mọ́.—Ka Jòhánù 10:27-29.
Máa Tẹ̀ Lé Ọba Ajagunṣẹ́gun
8. Kí nìdí tá a fi lè pe Dáfídì ní ọba ajagunṣẹ́gun?
8 Gẹ́gẹ́ bí ọba, Dáfídì jẹ́ akíkanjú jagunjagun tó ń dáàbò bo ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run, “Jèhófà sì ń bá a nìṣó ní gbígba Dáfídì là ní ibikíbi tí ó bá lọ.” Nígbà tí Dáfídì ń ṣàkóso, ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì dé ibi odò tó wà ní Íjíbìtì, ó sì tún dé odò Yúfírétì. (2 Sám. 8:1-14) Pẹ̀lú ìránlọ́wọ́ Jèhófà, Dáfídì di ọba alágbára ńlá. Bíbélì sọ pé: “Òkìkí Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì fi ìbẹ̀rùbojo rẹ̀ sára gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—1 Kíró. 14:17.
9. Ṣàlàyé bí Jésù ṣe jẹ́ ajagunṣẹ́gun nígbà tó ṣì jẹ́ Ọba lọ́la.
9 Nígbà tí Jésù wà láyé, kì í bẹ̀rù ohunkóhun bíi ti Dáfídì Ọba. Nígbà tó ṣì jẹ́ Ọba lọ́la, ó fi hàn pé òun lágbára lórí àwọn ẹ̀míèṣù, ó tú àwọn tí wọ́n mú ní òǹdè sílẹ̀. (Máàkù 5:2, 6-13; Lúùkù 4:36) Kódà, Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run kò lágbára lórí rẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, Jésù ṣẹ́gun ayé tó wà lábẹ́ agbára Sátánì.—Jòh. 14:30; 16:33; 1 Jòh. 5:19.
10, 11. Kí ni iṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba Ajagunṣẹ́gun lọ́run?
10 Ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí Jésù ti kú tó sì ti jíǹde sí ọ̀run, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba Ajagunṣẹ́gun lọ́run. Jòhánù sọ pé: “Wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 6:2) Jésù lẹni tó gun ẹṣin funfun yẹn. Ọdún 1914 sì ni wọ́n “fún un ní adé” nígbà tó di Ọba lọ́run. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ‘ó jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun.’ Nítorí náà bíi ti Dáfídì, Ọba Ajagunṣẹ́gun ni Jésù. Láìpẹ́ lẹ́yìn tó di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó bá Sátánì jagun ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó lé òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jù sí ilẹ̀ ayé. (Ìṣí. 12:7-9) Ńṣe ni yóò máa jagun ṣẹ́gun nìṣó títí tí yóò fi “parí ìṣẹ́gun rẹ̀,” ìyẹn nígbà tó bá pa ètò nǹkan Sátánì run pátápátá.—Ka Ìṣípayá 19:11, 19-21.
11 Àmọ́ bíi ti Dáfídì, ọba ẹlẹ́yinjú àánú ni Jésù, ó máa dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ ńlá” nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣí. 7:9, 14) Yàtọ̀ síyẹn, lábẹ́ àkóso Jésù àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàájì [144,000] tó máa bá a ṣàkóso, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Gbogbo àwọn tí wọ́n máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé ló máa ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ẹ ò rí i pé ọjọ́ iwájú wọn máa lárinrin gan-an! Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fi ṣe ìpinnu wa pé a óò “máa ṣe rere,” ká bàa lè wà láàyè nígbà tí gbogbo ayé bá kún fún àwọn olódodo èèyàn tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀ lábẹ́ àkóso Jésù tó jẹ́ Dáfídì Títóbi Jù.—Sm. 37:27-29.
Sólómọ́nì Tọrọ Ọgbọ́n, Jèhófà sì Fún Un
12. Kí ni Sólómọ́nì tọrọ lọ́wọ́ Jèhófà?
12 Ìgbésí ayé Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì náà jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìgbésí ayé Jésù ṣe máa rí. c Nígbà tí Sólómọ́nì di ọba, Jèhófà fara hàn án lójú àlá, Jèhófà sì ní òun á ṣe ohunkóhun tó bá tọrọ fún un. Sólómọ́nì kò tọrọ pé kí ọlá òun àti agbára òun pọ̀ sí i tàbí pé kóun lẹ́mìí gígùn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó tọrọ lọ́wọ́ Jèhófà fi hàn pé kò nímọtara ẹni nìkan, ó ní: “Wàyí o, fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí n lè máa jáde lọ níwájú àwọn ènìyàn yìí, kí n sì lè máa wọlé, nítorí ta ní lè ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yìí?” (2 Kíró. 1:7-10) Jèhófà sì dáhùn àdúrà Sólómọ́nì.—Ka 2 Kíróníkà 1:11, 12.
13. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kò sẹ́ni tó lọ́gbọ́n tó Sólómọ́nì, ta ló sì fún un ní ọgbọ́n yẹn?
13 Ní gbogbo ìgbà tí Sólómọ́nì jẹ́ adúróṣinṣin tó ń sin Jèhófà, kò sẹ́ni tó lè sọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání bíi tiẹ̀ láàárín àwọn tó wà nígbà ayé rẹ̀. Ó “pa ẹgbẹ̀ẹ́dógún òwe.” (1 Ọba 4:30, 32, 34) Ọ̀pọ̀ nínú àwọn òwe yìí ló wà lákọọ́lẹ̀, àwọn tó sì ń wá ọgbọ́n kì í fojú kékeré wò wọ́n. Ọbabìnrin Ṣébà rin nǹkan bí egbèjìlá [2,400] kìlómítà wá sọ́dọ̀ Sólómọ́nì “láti fi àwọn ìbéèrè apinnilẹ́mìí dán an wò” kó lè mọ bó ṣe lọ́gbọ́n tó. Ọ̀rọ̀ ẹnu Sólómọ́nì àti aásìkí ìjọba rẹ̀ jọ ọbabìnrin náà lójú gan-an. (1 Ọba 10:1-9) Bíbélì sọ Ẹni tó fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n rẹ̀, ó ní: “Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé sì ń wá ojú Sólómọ́nì láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—1 Ọba 10:24.
Máa Tẹ̀ Lé Ọlọgbọ́n Ọba
14. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ”?
14 Ẹnì kan ṣoṣo la tíì rí rí tí ọgbọ́n rẹ̀ ju ti Sólómọ́nì lọ fíìfíì. Ẹni náà ni Jésù Kristi, tó sọ pé òun ni “ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ.” (Mát. 12:42) Jésù sọ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:68) Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù ṣàláyé síwájú sí i lórí ìlànà tó wà nínú àwọn kan lára òwe Sólómọ́nì. Sólómọ́nì ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mú káwọn olùjọsìn Jèhófà ní ayọ̀. (Òwe 3:13; 8:32, 33; 14:21; 16:20) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ohun tó lè mú kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́ ni àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà àti ìmúṣẹ́ ìlérí rẹ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mát. 5:3) Àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀kọ́ Jésù yóò máa sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ “orísun ìye.” (Sm. 36:9; Òwe 22:11; Mát. 5:8) Kristi gan-an la lè pè ní “ọgbọ́n Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 1:24, 30) Gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba, Jésù Kristi ní “ẹ̀mí ọgbọ́n.”—Aísá. 11:2.
15. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
15 Báwo ni àwa ọmọlẹ́yìn Jésù, tó jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù, ṣe lè jàǹfààní látinú ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Níwọ̀n bí ọgbọ́n Jèhófà ti hàn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti wá ọgbọ́n náà kàn nípa fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pàápàá jù lọ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú rẹ̀, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí bá a ṣe ń kà á. (Òwe 2:1-5) Gbogbo ìgbà la tún gbọ́dọ̀ máa tọrọ ọgbọ́n lọ́wọ́ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé tá a bá ń gbàdúrà látọkànwá pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́, yóò ṣe bẹ́ẹ̀. (Ják. 1:5) Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ á sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó lè mú ká ní ọgbọ́n. Ọgbọ́n yìí la ó máa fi yanjú àwọn ìṣòro wa, òun la ó sì máa fi ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Lúùkù 11:13) Ìwé Mímọ́ tún pe Sólómọ́nì ní “akónijọ” tó máa “ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ nígbà gbogbo.” (Oníw. 12:9, 10) Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni náà jẹ́ akónijọ tó kó àwọn èèyàn rẹ̀ jọ. (Jòh. 10:16; Kól. 1:18) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé níbi tó ti ‘ń kọ́ wa nígbà gbogbo.’
16. Kí ni Sólómọ́nì àti Jésù fi jọra?
16 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Sólómọ́nì Ọba gbé ṣe. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ló dáwọ lé tó sì rí i pé wọ́n di ṣíṣe káàkiri orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lára iṣẹ́ náà ni pé ó kọ́ ààfin, ó la ọ̀nà, ó gbẹ́ odò, ó kọ́ ìlú ńlá tí wọ́n ń tọ́jú nǹkan pa mọ́ sí, àwọn ìlú ńlá kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ìlú ńlá fún àwọn ẹlẹ́ṣin. (1 Ọba 9:17-19) Gbogbo àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìjọbà rẹ̀ pátá ló sì jàǹfààní iṣẹ́ kíkọ́ ilé, ìlú àtàwọn ohun míì tó ṣe. Jésù náà ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé. Ó kọ́ ìjọ rẹ̀ sórí “àpáta ràbàtà.” (Mát. 16:18) Nínú ayé tuntun, ó tún máa bójú tó iṣẹ́ kíkọ́ ilé àti ìlú àtàwọn ohun míì tí a óò máa kọ́ nígbà yẹn.—Aísá. 65:21, 22.
Máa Tẹ̀ Lé Ọba Àlàáfíà
17. (a) Ohun pàtàkì wo ni ìṣàkóso Sólómọ́nì fi yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tó jọba ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (b) Kí ni Sólómọ́nì ò rí ṣe?
17 Orúkọ Sólómọ́nì wá látinú ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ sí “àlàáfíà.” Sólómọ́nì Ọba ṣàkóso láti ìlú Jerúsálẹ́mù tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Níní Àlàáfíà Onílọ̀ọ́po Méjì.” Ogójì ọdún tó fi ṣàkóso ni àkókò tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tíì ní àlàáfíà tó pọ̀ jù lọ. Bíbélì sọ pé ní àkókò yẹn: “Júdà àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀, láti Dánì dé Bíá-ṣébà, ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì.” (1 Ọba 4:25) Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n tí Sólómọ́nì ní, kò lè rí àwọn èèyàn rẹ̀ gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ Jésù tó jẹ́ Sólómọnì Títóbi Jù máa gba àwọn tó wà lábẹ́ Ìjọba rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìyẹn.—Ka Róòmù 8:19-21.
18. Kí là ń gbádùn nínú ìjọ Kristẹni?
18 Kódà ní báyìí, àwa tá a wà nínú ìjọ Kristẹni ń gbádùn àlàáfíà. Àní sẹ́, inú Párádísè tẹ̀mí la wà. Àlàáfíà wà láàárín àwa àti Ọlọ́run, ó sì wà láàárín ara wa. Kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Aísáyà ti sọ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín wa lónìí, ó ní: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísá. 2:3, 4) Bá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, à ó máa ṣàlékún àlàáfíà tó wà nínú Párádísè tẹ̀mí yìí.
19, 20. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó máa fún wa láyọ̀?
19 Àmọ́ kékeré la tíì rí yìí tá a bá fi wé ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àwọn tó jẹ́ onígbọràn láàárín ọmọ aráyé bá ṣe ń gbádùn àlàáfíà tí kò lẹ́gbẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso Jésù, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni wọ́n á dẹni tí ‘a óò dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹru fún ìdíbàjẹ́’ títí wọ́n á fi di ẹ̀dá èèyàn pípé. (Róòmù 8:21) Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yege ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé lópin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò wá nímùúṣẹ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sm. 37:11; Ìṣí. 20:7-10) Dájúdájú, ìṣàkóso Kristi Jésù yóò dára ju ti Sólómọnì lọ láwọn ọ̀nà míì tá ò tiẹ̀ lè sọ báyìí!
20 Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń yọ̀ láwọn ìgbà tí Mósè, Dáfídì tàbí Sólómọ́nì ń darí wọn, làwa náà yóò ṣe máa yọ̀, àní jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá lábẹ́ ìṣàkoso Kristi. (1 Ọba 8:66) Ọpẹ́ ńlá ni fún Jèhófà tó fún wa ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ìyẹn Jésù Kristi tó jẹ́ Mósè Títóbi Jù, Dáfídì Títóbi Jù àti Sólómọ́nì Títóbi Jù!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí orúkọ Dáfídì túmọ̀ sí “Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n.” Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi àti nígbà ìyípadà ológo rẹ̀, Jèhófà sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, ẹ̀ẹ̀mejèèjì ló sì pe Jésù ní “Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—Mát. 3:17; 17:5.
b Lẹ́sẹ̀ kan náà, Dáfídì dà bí àgùntàn tó fọkàn tán olùṣọ́ rẹ̀. Ojú Jèhófà Olùṣọ́ Àgùntàn Àgbà ló ń wò pé kó máa dáàbò bo òun kó sì máa tọ́ òun sọ́nà. Ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá tó ní nínú Jèhófà ló fi sọ gbólóhùn yìí pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” (Sm. 23:1) Jòhánù Olùbatisí pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.”—Jòh. 1:29.
c Sólómọ́nì yìí sì tún wá ní orúkọ kejì tó ń jẹ́ Jedidáyà, tó túmọ̀ sí “Àyànfẹ́ Jáà.”—2 Sám. 12:24, 25.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ Dáfídì Títóbi Jù?
• Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù?
• Kí lohun tó o kọ́ tó wù ọ́ jù lọ nípa Jésù tó jẹ́ Dáfídì Títóbi Jù tó tún jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún Sólómọ́nì jẹ́ àpẹẹrẹ ọgbọ́n Jésù tó jẹ́ Sólómọ́nì Títóbi Jù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ìṣàkóso Jésù yóò dára ju ti Sólómọnì àti Dáfídì lọ láwọn ọ̀nà míì tá ò tiẹ̀ lè sọ báyìí!