Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

“Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.”—JÓÒBÙ 1:21.

1. Ta ló ṣeé ṣe kó kọ ìwé Jóòbù, ìgbà wo ló sì kọ ọ́?

 MÓSÈ ti tó ẹni ogójì ọdún nígbà tó sá kúrò nílẹ̀ Íjíbítì tó lọ ń gbé nílẹ̀ Mídíánì kí Fáráò má bàa pa á. (Ìṣe 7:23) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó wà nílẹ̀ Mídíánì ló gbọ́ nípa àdánwò tó dé bá Jóòbù tó ń gbé ní ilẹ̀ Úsì tí kò jìnnà síbẹ̀. Ó sì lè wá jẹ́ pé ìgbà tí Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn dé tòsí ilẹ̀ Úsì ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n parí ìrìn àjò wọn nínú aginjù, ni Mósè wá mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù nígbẹ̀yìn ayé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn Júù ṣe sọ, ẹ̀yìn ikú Jóòbù ni Mósè kọ ìwé Jóòbù.

2. Àwọn ọ̀nà wo ni ìwé Jóòbù gbà fún ìgbàgbọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lágbára lóde òní?

2 Ìwé Jóòbù yìí ń fún ìgbàgbọ́ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run òde òní lágbára. Láwọn ọ̀nà wo? Ìtàn yẹn jẹ́ ká lóye ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́run, ó sì pàfiyèsí wa sí ọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn ọ̀ràn ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ìtàn Jóòbù tún jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tá ó ṣe láti pa ìwà títọ́ wa mọ́, ó sì jẹ́ ká mọ̀dí tí Jèhófà fi máa ń gbà káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jìyà láwọn ìgbà míì. Ìwé Jóòbù tún fi hàn pé Sátánì Èṣù ni olórí Elénìní Ọlọ́run àti ọ̀tá ọmọ aráyé. Ìwé náà tún jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn aláìpé bíi Jóòbù lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lójú ìdánwò lílekoko. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Jóòbù.

Sátánì Dán Jóòbù Wò

3. Kí la mọ̀ nípa Jóòbù, kí sì nìdí tí Sátánì fi dájú sọ ọ́?

3 Jóòbù jẹ́ ọlọ́rọ̀ tẹ́nu ẹ̀ tólẹ̀ láàárín ìlú, ó sì tún jẹ́ olórí ẹbí tó mọ àbójútó ilé ṣe. Ẹ̀rí wà pé àgbà agbani-nímọ̀ràn tó ń ṣàánú àwọn aláìní ni. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé Jóòbù bẹ̀rù Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jóòbù ni pé ó “jẹ́ aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, ó ń bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” Ìfọkànsìn Ọlọ́run tí Jóòbù ní yìí ló mú kí Sátánì Èṣù dájú sọ ọ́, kì í ṣe ọrọ̀ tó ní tàbí ipò rẹ̀ láwùjọ.—Jóòbù 1:1; 29:7-16; 31:1.

4. Kí ni ọ̀rọ̀ náà, ìwà títọ́ túmọ̀ sí?

4 Níbẹ̀rẹ̀ ìtàn inú ìwé Jóòbù, ìwé náà ṣàlàyé nípa ìpàdé kan tó wáyé lọ́run níbi tí àwọn áńgẹ́lì ti dúró níwájú Jèhófà. Sátánì náà wá sí ìpàdé yìí, ó sì fẹ̀sùn kan Jóòbù níbẹ̀. (Ka Jóòbù 1:6-11.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì mẹ́nu kan àwọn ohun ìní Jóòbù, ohun tó gbájú mọ́ ni bó ṣe máa fi hàn pé Jóòbù kì í ṣe oníwà títọ́. Ọ̀rọ̀ náà “ìwà títọ́,” túmọ̀ sí kéèyàn jẹ́ adúróṣánṣán, aláìlẹ́bi, olódodo àti aláìní-àléébù. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, ìwà títọ́ èèyàn túmọ̀ sí ìfọkànsìn tó pé pérépéré tá a ní fún Jèhófà.

5. Kí ni Sátánì sọ nípa Jóòbù?

5 Sátánì sọ pé ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú kí Jóòbù sin Ọlọ́run kì í ṣe torí pé ó jẹ́ oníwà títọ́. Ó tún sọ pé kò sí bí Jóòbù ò ṣe ní jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tó bá ti ń rí nǹkan gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run tó sì ń dáàbò bò ó. Ni Jèhófà bá gba Sátánì láyè láti gbéjà ko ọkùnrin olóòótọ́ yẹn, láti lè fi dáhùn ẹ̀sùn tó kà sílẹ̀ yẹn. Nígbà tí Sátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lu Jóòbù, kí ilẹ̀ ọjọ́ kan ṣoṣo tó ṣú Jóòbù gbọ́ pé wọ́n jí àwọn ẹran ọ̀sìn òun kan gbé lọ, àwọn yòókù sì ti pa run. Wọ́n pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá sì kú mọ́ ọn lójú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. (Jóòbù 1:13-19) Ǹjẹ́ Jóòbù juwọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí Sátánì fojú ẹ̀ rí yìí? Ìwé Mímọ́ sọ ohun tí Jóòbù sọ nípa gbogbo aburú tó dé bá a, ó ní: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fi fúnni, Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti gbà lọ. Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.”—Jóòbù 1:21.

6. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n tún ṣèpàdé míì lọ́run? (b) Ta ni Sátánì tún ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Jóòbù kò ní lè pa ìwà títọ́ mọ́?

6 Nígbà tó yá, ìpàdé míì tún wáyé lọ́run. Níbẹ̀ Sátánì tún fẹ̀sùn kan Jóòbù, ó ní: “Awọ fún awọ, ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀. Fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fi kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” Kíyè sí i pé Sátánì ti kó àwọn míì mọ́ ẹ̀sùn tó fi kan Jóòbù yẹn. Bí Èṣù ṣe sọ pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé kì í ṣe Jóòbù nìkan ni kò ní lè pa ìwà títọ́ mọ́, gbogbo “ènìyàn” tó ń sin Jèhófà ni kò ní lè pa á mọ́. Nítorí náà, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí Sátánì lọ fi àrùn burúkú kan kọ lu Jóòbù. (Jóòbù 2:1-8) Àmọ́ àdánwò Jóòbù kò parí síbẹ̀ yẹn o.

Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìdúróṣinṣin Jóòbù

7. Báwo ni ìyàwó Jóòbù àtàwọn tó wá kí i tún ṣe fúngun mọ́ ọn?

7 Nígbà tí àdánwò Jóòbù kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, òun àtìyàwó rẹ̀ làwọn àjálù náà jọ dé bá. Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ obìnrin yìí bí gbogbo ọmọ rẹ̀ ṣe kú, àdánù ńlá ló sì bá a bí gbogbo ọrọ̀ ìdílé wọn ṣe run. Bó ṣe ń wo Jóòbù ọkọ rẹ̀ nínú ìrora níbi tí àrùn dá a gúnlẹ̀ sí, ó ní láti jẹ́ ìbànújẹ́ ńlá fún un. Ó pariwo mọ́ ọkọ rẹ̀, ó ní: “Ìwọ ha ṣì di ìwà títọ́ rẹ mú ṣinṣin? Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” Àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan tó ń jẹ́ Élífásì, Bílídádì àti Sófárì náà tún dé, wọ́n láwọn fẹ́ tu Jóòbù nínú. Àmọ́ kàkà kí wọ́n tù ú nínú, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ló ń jáde lẹ́nu wọn, “olùtùnú tí ń dani láàmú” ni wọ́n jẹ́ fún Jóòbù. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Bílídádì sọ fi hàn pé ó gbà pé ikú tó pa àwọn ọmọ Jóòbù yẹn ló yẹ wọ́n nítorí pé wọ́n ti hùwà àìtọ́. Élífásì náà ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Jóòbù ló ń jẹ. Ó tiẹ̀ lóun ò rò pé ìwà títọ́ àwọn èèyàn já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run! (Jóòbù 2:9, 11; 4:8; 8:4; 16:2; 22:2, 3) Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe fúngun mọ́ Jóòbù tó, ó di ìwà títọ́ rẹ̀ mú síbẹ̀. Lóòótọ́, kò tọ̀nà bí Jóòbù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í “polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.” (Jóòbù 32:2) Síbẹ̀, ó dúró ṣinṣin ní gbogbo ìgbà tó fi wà nínú àdánwò.

8. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Élíhù fi lélẹ̀ fáwọn tó ń gbani nímọ̀ràn lónìí?

8 A tún rí i kà nínú Bíbélì pé ẹlòmíì tó wá kí Jóòbù ni Élíhù. Élíhù kọ́kọ́ tẹ́tí sí oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ tí Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń sọ kó tó wá sọ tiẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Élíhù kéré lọ́jọ́ orí sí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àmọ́ ohun tó sọ fa ọgbọ́n yọ ju ti gbogbo wọn lọ. Ó bá Jóòbù sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Élíhù yin Jóòbù fún bó ṣe jẹ́ adúróṣinṣin. Àmọ́ ó sọ pé ohun tó ká Jóòbù lára jù ni bó ṣe máa fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi. Élíhù wá fi dá Jóòbù lójú pé kéèyàn máa sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ohunkóhun lọ. (Ka Jóòbù 36:1, 11.) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fáwọn tó bá fẹ́ gbani nímọ̀ràn! Élíhù ṣe sùúrù, ó fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó gbóríyìn fún Jóòbù láwọn ibi tó ti ṣe dáadáa, ó sì fún un nímọ̀ràn tó ń gbéni ró.—Jóòbù 32:6; 33:32.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jóòbù lọ́wọ́?

9 Níkẹyìn, Jèhófà fúnra rẹ̀ tọ Jóòbù wá! Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì ẹlẹ́fùúùfù.” Kí Jóòbù bàa lè ní èrò tó tọ́, Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ fún un ní ìbáwí nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè mélòó kan lọ́wọ́ rẹ̀. Tinútinú ni Jóòbù fi gba ìbáwí yẹn, ó ní: “Mo ti di aláìjámọ́ pàtàkì . . . Mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.” Lẹ́yìn tí Jèhófà bá Jóòbù sọ̀rọ̀ tán, ó bá àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wí nítorí wọn kò sọ “ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.” Kódà Jóòbù ní láti gbàdúrà fún wọn. Lẹ́yìn náà, “Jèhófà tìkára rẹ̀ sì yí ipò òǹdè Jóòbù padà nígbà tí ó gbàdúrà nítorí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fún Jóòbù ní àfikún ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀ rí, ní ìlọ́po méjì.”—Jóòbù 38:1; 40:4; 42:6-10.

Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Ṣe Jinlẹ̀ Tó Lọ́kàn Wa?

10. Kí nìdí tí Jèhófà kò fi gbójú fo ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun àti Jóòbù tàbí kó pa Sátánì run?

10 Ṣebí Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run, òun ni Ọba Aláṣẹ lórí gbogbo ìṣẹ̀dá. Kí wá nìdí tí kò fi gbójú fo ẹ̀sùn tí Èṣù fi kan òun àti Jóòbù? Ọlọ́run mọ̀ pé tóun bá kàn gbójú fo ẹ̀sùn yẹn tàbí tóun bá pa Sátánì run, ìyẹn kò ní yanjú ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀. Ó ti sọ pé Jóòbù, ìránṣẹ́ Jèhófà tí ìwà títọ́ rẹ̀ ta yọ nígbà yẹn máa fi Jèhófà sílẹ̀ tí ọrọ̀ rẹ̀ bá pa run. Àmọ́ Jóòbù dúró ṣinṣin lójú ìdánwò tó dé bá a. Sátánì tún sọ pé kò sẹ́ni tí ọwọ́ ìyà máa bà tí kò ní pa dà lẹ́yìn Ọlọ́run. Ìyà jẹ Jóòbù lóòótọ́ o, àmọ́ ó dúró ṣinṣin sí Ọlọ́run. Nípa báyìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù ọkùnrin adúróṣinṣin, aláìpé yẹn àti ohun tó ṣe, fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì ńkọ́?

11. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere jù lọ pé irọ́ ni Sátánì ń pa?

11 Gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bá pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, lójú ohunkóhun tí Sátánì lè fi bá a jà, ló ń fi hàn pé ní tòun, ẹ̀sùn èké làwọn ẹ̀sùn tí alénimádẹ̀yìn ọ̀tá yẹn fi kàn wá. Jésù wá sáyé ó sì fi hàn lọ́nà tó ṣe kedere pé irọ́ ni Sátánì ń pa. Ẹni pípé bí Ádámù bàbá wa àkọ́kọ́ ni Jésù. Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú ló fi hàn kedere jù lọ pé òpùrọ́ ni Sátánì àti pé èké làwọn ẹ̀sùn tó fi kàn wá.—Ìṣí. 12:10.

12. Àǹfààní àti ojúṣe wo ni gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

12 Síbẹ̀, Sátánì ò tíì jáwọ́ nínú dídán àwọn olùjọ́sìn Jèhófà wò. Olúkúlùkù wa la láǹfààní láti fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló ń mú wa sìn ín, kì í ṣe torí ohun tó ń ṣe fún wa. Ojúṣe wa sì ni láti fi èyí hàn nípa dídi ìdúróṣinṣin wa mú. Báwo la ṣe ń wo ojúṣe yìí? Àǹfààní la kà á sí láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ohun ìtùnú ló tún jẹ́ fún wa pé Jèhófà ń fún wa ní okun láti fara dà á, kò sì ní gbà kí àdánwò náà kọjá ibi tó yẹ, nítorí pé ó níbi tó fàyè gba ti Jóòbù dé.—1 Kọ́r. 10:13.

Aláfojúdi àti Apẹ̀yìndà Ni Sátánì Ọ̀tá Wa

13. Kí ni ìwé Jóòbù jẹ́ ká mọ̀ sí i nípa Sátánì?

13 Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun ìtìjú tí Sátánì ṣe, ìyẹn bó ṣe ń ta ko Jèhófà tó sì ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a rí àlàyé síwájú sí i nípa bí Sátánì ṣe ń ta ko Jèhófà. Ìwé Ìṣípayá sì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun gan-an ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ó sì tún jẹ́ ká mọ bí Sátánì ṣe máa pa run. Ìwé Jóòbù fi kún ohun tá a mọ̀ nípa ìwà ọ̀tẹ̀ Sátánì. Nígbà tí Sátánì bá wọn pésẹ̀ sí ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́run yẹn, kì í ṣe torí kó lè yin Jèhófà ló ṣe wá síbẹ̀. Ẹ̀mí ìkórìíra àti ìkà ni Èṣù gbé sọ́kàn lọ síbẹ̀. Nígbà tó ti fẹ̀sùn kan Jóòbù tán, tó sì gbàṣẹ láti lọ dán an wò, “Sátánì jáde kúrò níwájú Jèhófà.”—Jóòbù 1:12; 2:7.

14. Irú ẹ̀mí wo ni Sátánì ní sí Jóòbù?

14 Ìwé Jóòbù tipa báyìí fi hàn pé Sátánì ni aláìláàánú ọ̀tá ọmọ aráyé. Àkókò kan tí a ò mọ bó ṣe gùn tó wà láàárín ìpàdé tí Jóòbù 1:6 mẹ́nu kàn pé ó wáyé lọ́run àti èyí tí Jóòbù 2:1 mẹ́nu kàn, ìyẹn àkókò tí Sátánì kọ́kọ́ fi Jóòbù sínú ìdánwò burúkú. Àmọ́ bí Jóòbù ṣe dúró ṣinṣin mú kí Jèhófà lè sọ fún Sátánì pé: “Àní [Jóòbù] ṣì di ìwà títọ́ rẹ̀ mú ṣinṣin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ru mí lọ́kàn sókè sí i, láti gbé e mì láìnídìí.” Síbẹ̀, Sátánì kò gbà pé irọ́ ni gbogbo ohun tóun ń sọ nípa Jóòbù. Kàkà kó gbà, ṣe ló ní kí Jèhófà jẹ́ kóun tún fi ìdánwò lílekoko míì dán Jóòbù wò. Torí náà, àtìgbà tí Jóòbù lọ́rọ̀, àtìgbà tó tòṣì ni Èṣù dán an wò. Èyí fi hàn kedere pé Sátánì kì í ṣàánú àwọn aláìní pàápàá títí kan àwọn tó wà nínú ìṣòro. Gbogbo ẹni tó bá ṣáà ti jẹ́ oníwà títọ́ ló kórìíra. (Jóòbù 2:3-5) Síbẹ̀síbẹ̀, ìdúróṣinṣin Jóòbù fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì.

15. Ọ̀nà wo làwọn apẹ̀yìndà òde òní gbà dà bíi Sátánì?

15 Sátánì ni ẹ̀dá tó kọ́kọ́ di apẹ̀yìndà. Ìṣe àwọn apẹ̀yìndà òde òní náà kò yàtọ̀ sí ti Èṣù. Ó lè jẹ́ inú tí wọ́n ń bí sáwọn ará ìjọ, àwọn alàgbà tàbí àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí pàápàá, ló mú wọn gbin oró sọ́kàn. Àwọn apẹ̀yìndà kan máa ń ta ko lílo orúkọ Jèhófà. Wọn ò ṣe tàn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọn ò sì fẹ́ láti sìn ín. Bíi ti Sátánì bàbá wọn, àwọn tó bá di ìṣòtítọ́ wọn mú ni wọ́n ń dojú ìjà kọ. (Jòh. 8:44) Ìdí rèé táwa ìránṣẹ́ Jèhófà kì í fi í bá wọn da ohunkóhun pọ̀ rárá!—2 Jòh. 10, 11.

Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

16. Kí ni ìṣarasíhùwà Jóòbù sí Jèhófà nígbà tí àdánwò bá a?

16 Jóòbù máa ń lo orúkọ Jèhófà, ó sì gbé e ga. Kódà nígbà tí ìròyìn burúkú nípa ikú àwọn ọmọ rẹ̀ ṣì ń jó o lára, kò ka ohunkóhun tí kò tọ́ sí Ọlọ́run lọ́rùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù fi àṣìṣe gbà pé Ọlọ́run ló fa àdánù tó dé bá òun, ó pàpà gbé orúkọ Jèhófà ga. Nínú ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ òwe tí Jóòbù sọ nígbà tó yá, ó ní: “Wò ó! Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n, yíyípadà kúrò nínú ìwà búburú sì ni òye.”—Jóòbù 28:28.

17. Kí ló ran Jóòbù lọ́wọ́ tó fi lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́?

17 Kí ló ran Jóòbù lọ́wọ́ tó fi lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́? Ó ṣe kedere pé kí àjálù tó dé bá a ló ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Lóòótọ́ a kò rí ẹ̀rí pé Jóòbù mọ̀ pé Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà, síbẹ̀ ó pinnu láti dúró ṣinṣin. Ohun tó sọ ni pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Báwo ni Jóòbù ṣe dẹni tó ní irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà? Ó ní láti jẹ́ pé ó fọwọ́ pàtàkì mú ohun tó gbọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe bá Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù, tí wọ́n jọ wá láti ìlà ìdílé kan náà lò. Ó sì ti ní láti mọ ọ̀pọ̀ ànímọ́ Jèhófà bó ṣe ń kíyè sí ohun tó dá.—Ka Jóòbù 12:7-9, 13, 16.

18. (a) Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé olùfọkànsìn Jèhófà lòun? (b) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà Jóòbù?

18 Àwọn ohun tí Jóòbù ti kọ́ ló jẹ́ kó fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wu Jèhófà. Ó máa ń rú ẹbọ déédéé nítorí pé ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ rẹ̀ ti ṣohun tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú tàbí bóyá wọ́n “ti bú Ọlọ́run nínú ọkàn-àyà wọn.” (Jóòbù 1:5) Kódà nígbà tó wà nínú ìdánwò tó lé kenkà, ó ṣì sọ àwọn ohun tó dára nípa Jèhófà. (Jóòbù 10:12) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn! Àwa náà gbọ́dọ̀ máa gba ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà àti nípa àwọn ìpinnu rẹ̀ sínú ọkàn wa. Ó yẹ ká ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a óò máa tẹ̀ lé déédéé nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, irú bíi kíkẹ́kọ̀ọ́, lílọ sípàdé, gbígbàdúrà àti wíwàásù ìhìn rere. Bákan náà, a ní láti máa sa gbogbo ipá wa láti rí i pé à ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀. Bí ìdúróṣinṣin Jóòbù sì ṣe múnú Jèhófà dùn ni ìwà títọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tòde òní náà ṣe ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. Ohun tá a óò jíròrò nìyẹn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí Sátánì Èṣù fi dájú sọ Jóòbù?

• Àwọn ìdánwò wo ló dé bá Jóòbù, kí ló sì ṣe nígbà ìdánwò wọ̀nyẹn?

• Kí ló máa jẹ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ bíi ti Jóòbù?

• Kí la rí kọ́ nípa Sátánì látinú ìwé Jóòbù?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìtàn inú ìwé Jóòbù túbọ̀ jẹ́ ká fi ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀ nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run sọ́kàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa dán ìwà títọ́ rẹ wò?