Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni pa ìwà títọ́ wa mọ́?

Pípa ìwà títọ́ wa mọ́ jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé ìfẹ́ ló mú ká gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, ó tún ń jẹ́ ká lè fi Sátánì hàn gẹ́gẹ́ bí òpùrọ́. Ìwà títọ́ wa tún ni Ọlọ́run máa fi ṣe ìdájọ́ wa, ìdí rèé tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní ìwà títọ́ kọ́wọ́ wa bàa lè tẹ ohun tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú.—12/15, ojú ìwé 4 sí 6.

• Àwọn orúkọ oyè wo ló jẹ́ ká mọ ipa tí Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ?

Ọmọ bíbí kan ṣoṣo. Ọ̀rọ̀ náà. Àmín. Alárinà májẹ̀mú tuntun. Àlùfáà Àgbà. Irú Ọmọ Náà.—12/15, ojú ìwé 15.

• Kí nìdí tó fi yani lẹ́nu pé wòlíì Èlíjà ní kí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ máa wo apá ibi tí òkun wà nígbà tó ń gbàdúrà fún òjò? (1 Ọba 18:43-45)

Èlíjà fi hàn pé òun mọ̀ nípa bí omi ṣe máa ń lọ sókè táá sì wá rọ̀ bí òjò. Ìkùukùu tó máa ń kóra jọ lójú ọ̀run lókè ibi tí òkun wà máa ń lọ títí táá fi débi tó ti máa rọ̀ sórí ilẹ̀ bí òjò.—1/1, ojú ìwé 15 sí 16.

• Báwo la ṣe lè fi kún ayọ̀ tá à ń ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

A lè múra sílẹ̀ látọkànwá, ká máa wá gbogbo ọ̀nà tá a bá lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Nígbà tá a bá ń wàásù, ká máa wá àwọn tá a lè máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ò bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, a lè wá kókó ọ̀rọ̀ tó máa fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra.—1/15, ojú ìwé 8 sí 10.

• Ṣé àrùn tí Bíbélì pè ní ẹ̀tẹ̀ náà ni àrùn tá a mọ̀ sí ẹ̀tẹ̀ lónìí?

Òótọ́ ni pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àrùn kan wà tí kòkòrò máa ń fà síni lára tí wọ́n ń pè ní ẹ̀tẹ̀. (Léf. 13:4, 5) Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀tẹ̀ tó máa ń hàn lára aṣọ àti ilé. “Ẹ̀tẹ̀” yẹn lè jẹ́ olú tó máa ń sú yọ sára ògiri balùwẹ̀ tàbí sára àwọn nǹkan tómi bá wà. (Léf. 13:47-52)—2/1, ojú ìwé 19.

• Ipa wo ló yẹ kí ẹ̀kọ́ Bibélì ní lórí bí Kristẹ́ni kan ṣe ní láti wo àwọn àṣà ìsìnkú?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni kan lè banú jẹ́ lórí èèyàn rẹ̀ tó kú, ó mọ̀ pé òkú kò mọ ohunkóhun. Kódà táwọn aláìgbàgbọ́ bá ń ta kò ó, kò ní bá wọn lọ́wọ́ sáwọn àṣà tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé òkú lè ṣe nǹkan kan fún alààyè. Kí ìṣòro má bàa yọjú, ńṣe làwọn Kristẹni kan ṣàkọsílẹ̀ ìtọ́ní lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ kí wọ́n sin òkú àwọn.—2/15, ojú ìwé 29 sí 31.

• Bó ṣe wà nínú Sáàmù 1:1, àwọn nǹkan mẹ́ta wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún tá a bá fẹ́ láyọ̀?

Ẹsẹ yẹn mẹ́nu kan “ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú,” “ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” àti “ìjókòó àwọn olùyọṣùtì.” Tá a bá fẹ́ láyọ̀, a ò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tó ń yọ ṣùtì sí òfin Ọlọ́run rìn, ìyẹn àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká ní inú dídùn nínú òfin Jèhófà.—3/1, ojú ìwé 17.

• Ṣé àwọn “ìwé Jáṣárì” àti “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà” jẹ́ ara àwọn ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì àmọ́ tó ti sọ nù ni? (Jóṣ. 10:13; Núm. 21:14)

Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó dà bíi pé àwọn ìwé kan tí kò ní ìmísí Ọlọ́run àmọ́ tó wà nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ni wọ́n, táwọn kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sì mẹ́nu kàn wọ́n.—3/15, ojú ìwé 32.

• Àyípadà ńlá wo ni wọ́n ṣe sí Bíbélì èdè Látìn kan tí wọ́n ṣe jáde lóde òní?

Lọ́dún 1979, Póòpù John Paul Kejì fọwọ́ sí ẹ̀dá Bíbélì tuntun kan ní èdè Látìn, èyí tí wọ́n pè ní Nova Vulgata. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe Bíbélì yìí jáde pàá, orúkọ Ọlọ́run fara hàn níbẹ̀ lọ́nà mélòó kan, bí wọ́n sì ṣe kọ ọ́ rèé lédè Látìn: Iahveh. (Ẹ́kís. 3:15; 6:3) Àmọ́ nígbà tí wọ́n fi máa gbé àtúnṣe rẹ̀ jáde lọ́dún 1986, wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ náà, Dominus, tó túmọ̀ sí Olúwa rọ́pò Iahveh tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run.—4/1, ojú ìwé 22.