Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìgbà wo ni wọ́n lé Sátánì kúrò ní ọ̀run?—Ìṣí. 12:1-9.
Ìwé Ìṣípayá kò sọ ìgbà náà gan-an tí wọ́n máa lé Sátánì kúrò lọ́run, àmọ́ ó sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé nígbà tí wọ́n bá máa lé e tó jẹ́ ká lè fojú díwọ̀n ìgbà tí wọ́n lé e kúrò lọ́run. Àkọ́kọ́ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ti ìbí Ìjọba Mèsáyà. Ẹ̀yìn náà ni ‘ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run’ èyí tó yọrí sí ṣíṣẹ́gun Sátánì tí wọ́n sì lé e kúrò lọ́run nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Ìwé Mímọ́ fi hàn kedere pé ọdún 1914 ni “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” parí, tí Ọlọ́run sì dá Ìjọba rẹ̀ sílẹ̀. a (Lúùkù 21:24) Báwo ló ṣe wá pẹ́ tó lẹ́yìn náà tí ogun fi bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run, tó sì yọrí sí lílé Sátánì kúrò lọ́run?
Ìwé Ìṣípayá 12:4 sọ pé: “Dírágónì náà sì dúró pa síwájú obìnrin tí ó máa tó bímọ, pé, nígbà tí ó bá bímọ, kí ó lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.” Èyí fi hàn pé, ní gbogbo ọ̀nà, Sátánì fẹ́ rẹ́yìn ọmọ tuntun náà, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run ní kíákíá, gbàrà tí wọ́n bá ti dá a sílẹ̀. Bí Jèhófà ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà kò jẹ́ kí ètekéte Sátánì ṣẹ, torí pé Sátánì ti pinnu láti ṣèpalára fún Ìjọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà, kò sì jáwọ́ nínú ìpètepèrò ẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká gbà pé “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀” kò ní fàkókò ṣòfò láti rí i pé àwọn lé “dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀” kúrò ní ọ̀run kí wọ́n má bàa ṣèpalára fún Ìjọba náà. Torí náà, a lè sọ pé ṣíṣẹ́gun Sátánì àti lílé tí wọ́n lé e kúrò ní ọ̀run wáyé kété lẹ́yìn tí wọ́n dá Ìjọba náà sílẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914.
Ohun míì tó tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni ti àjíǹde àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, èyí tí Ìwé Mímọ́ fẹ̀rí hàn pé ó bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn tí wọ́n dá Ìjọba náà sílẹ̀. b (Ìṣí. 20:6) Níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ kò ti sọ pé àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà ogun tí Jésù bá dírágónì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jà, á jẹ́ pé ogun náà ti parí, wọ́n sì ti lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run kó tó di pé àjíǹde àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi bẹ̀rẹ̀.
Torí náà, Bíbélì kò sọ ìgbà náà gan-an tí wọ́n lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. Àmọ́, ó dájú pé kété lẹ́yìn tí Ọlọrun fi Jésù Kristi jọba lọ́run, lọ́dún 1914 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Wo Ilé Ìṣọ́ January 1, 2007, ojú ìwé 27 àti 28, ìpínrọ̀ 9 sí 13.