Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Ló Yẹ Kó O Wà Nígbà Tí Òpin Bá Dé?

Ibo Ló Yẹ Kó O Wà Nígbà Tí Òpin Bá Dé?

Ibo Ló Yẹ Kó O Wà Nígbà Tí Òpin Bá Dé?

KÍ LÓ máa ṣẹlẹ̀ sáwọn adúróṣinṣin nígbà tí Jèhófà bá fòpin sí ètò àwọn nǹkan búburú yìí nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì? Òwe 2:21, 22 dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”

Báwo làwọn aláìlẹ́bi ṣe máa ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé? Ǹjẹ́ ibì kankan máa wà tí wọ́n máa forí pa mọ́ sí? Ibo ló yẹ káwọn adúróṣinṣin wà nígbà tí òpin bá dé? Àkọsílẹ̀ mẹ́rin tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa báwọn kan ṣe la ìparun já jẹ́ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.

Àwọn Ìgbà Tí Ibi Téèyàn Wà Ṣe Pàtàkì

Ìwé 2 Pétérù 2:5-7 sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn baba ńlá náà Nóà àti Lọ́ọ̀tì nídè, ó ní: “[Ọlọ́run] kò . . . fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run; àti nípa sísọ àwọn ìlú ńlá náà Sódómù àti Gòmórà di eérú, ó dá wọn lẹ́bi, ní fífi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀; ó sì dá Lọ́ọ̀tì olódodo nídè, ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi.”

Báwo ni Nóà ṣe la Ìkún-omi yẹn já? Ọlọ́run sọ fún Nóà pé: “Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi, nítorí tí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nítorí wọn; sì kíyè sí i, èmi yóò run wọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ayé. Fi igi ṣe áàkì kan fún ara rẹ láti ara igi olóje.” (Jẹ́n. 6:13, 14) Nóà kan ọkọ̀ áàkì náà gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un pé kó ṣe. Ní ọjọ́ méje kí Ìkún-omi náà tó bẹ̀rẹ̀, Jèhófà sọ fún Nóà pé kí ó kó àwọn ẹranko sínú ọkọ̀ áàkì, kóun àtàwọn ìdílé ẹ̀ náà sì wọnú ọkọ̀. Nígbà tí ọjọ́ méje pé, ilẹ̀kùn ọkọ̀ tì pa, “eji wọwọ lórí ilẹ̀ ayé sì ń bá a lọ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.” (Jẹ́n. 7:1-4, 11, 12, 16) Nóà àti ìdílé ẹ̀ “la omi já láìséwu.” (1 Pét. 3:20) Torí pé wọ́n wà nínú ọkọ̀ ni wọ́n ò ṣe pa run. Kò síbòmíì lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n ti lè rí ààbò.—Jẹ́n. 7:19, 20.

Àmọ́, ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún Lọ́ọ̀tì yàtọ̀. Àwọn áńgẹ́lì méjì sọ ibi tí yẹ kó wà fún un. Wọ́n sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: “Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tìrẹ nínú ìlú ńlá [Sódómù] yìí, ni kí o mú jáde kúrò ní ibí yìí! Nítorí àwa yóò run ibí yìí.” Lọ́ọ̀tì àtàwọn ìdílé ẹ̀ ní láti “sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá.”—Jẹ́n. 19:12, 13, 17.

Àpẹẹrẹ Nóà àti Lọ́ọ̀tì yìí jẹ́ ẹ̀rí pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (2 Pét. 2:9) Nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí, a rí i pé ibi tí wọ́n wà ni kò jẹ́ kí wọ́n pa run. Nóà ní láti wọnú ọkọ̀ áàkì, Lọ́ọ̀tì sì ní láti kúrò ní Sódómù. Àmọ́ ṣé gbogbo ìgbà náà lèyí pọn dandan? Ṣé Jèhófà lè dáàbò bo àwọn olóòótọ́ níbikíbi tí wọ́n bá wà láìjẹ́ pé wọ́n kúrò níbẹ̀? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ kíyè sí àpẹẹrẹ ìdáǹdè méjì míì.

Ṣé Gbogbo Ìgbà Ni Ibi Téèyàn Wà Ṣe Pàtàkì?

Kí Jèhófà tó mú ìyọnu kẹwàá tó ba àwọn ọmọ Íjíbítì nínú jẹ́ gan-an wá sórí wọn nígbà ayé Mósè, Jèhófà pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran Ìrékọjá tí wọ́n pa sára àwọn òpó ilẹ̀kùn àti àtẹ́rígbà ilé wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ‘nígbà tí Jèhófà bá kọjá láti kọ lu àwọn ará Íjíbítì tí ó sì rí ẹ̀jẹ̀ náà ní apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn àti lára àwọn òpó méjèèjì ilẹ̀kùn, á ré ẹnu ọ̀nà wọn kọjá, kò sì ní jẹ́ kí ìparun náà wọnú ilé wọn láti kọ lù wọ́n.’ Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, “Jèhófà kọlu gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì, láti orí àkọ́bí Fáráò tí ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ títí dórí àkọ́bí òǹdè tí ó wà nínú ihò ẹ̀wọ̀n, àti gbogbo àkọ́bí ẹranko.” Kò sóhun tó ṣe àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn ò kúrò níbi tí wọ́n wà lọ síbòmíì.—Ẹ́kís. 12:22, 23, 29.

Ẹ jẹ́ ká tún wo ọ̀rọ̀ Ráhábù aṣẹ́wó tó ń gbé nílùú Jẹ́ríkò. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun àwọn tó ń gbé Ilẹ̀ Ìlérí ni. Nígbà tí Ráhábù rí i pé ìlú Jẹ́ríkò ò lè bọ́ lọ́wọ́ ìparun, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tó wá ṣe amí ilẹ̀ náà pé, ẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì ń ba àwọn aráàlú yìí. Ó fàwọn amí náà pa mọ́, ó sì ní kí wọ́n búra fóun pé wọ́n á dá òun àti agboolé òun sí nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò. Àwọn amí yẹn sọ fún Ráhábù pé kó kó agboolé ẹ̀ sínú ilé ẹ̀ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri ìlú náà. Ńṣe lẹni tó bá jáde nínú ilé yẹn máa pa run pẹ̀lú ìlú náà. (Jóṣ. 2:8-13, 15, 18, 19) Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé “ògiri ìlú ńlá náà yóò . . . wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.” (Jóṣ. 6:5) Ibi táwọn amí náà fojú sùn pé ó máa jẹ́ ibi ààbò ti wá dà bíi pé kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí. Báwo ni Ráhábù àti agboolé rẹ̀ ò ṣe ní pa run báyìí?

Nígbà tí àkókò tó láti ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í fun ìwo, wọ́n sì ń pariwo. Ìwé Jóṣúà 6:20 sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn ènìyàn náà [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] gbọ́ ìró ìwo tí àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe ogun ńlá, nígbà náà ni ògiri náà bẹ̀rẹ̀ sí wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.” Kò séèyàn tó lè sọ pé ibi tóun fẹ́ kí ògiri náà wó dé rèé. Àmọ́ lọ́nà ìyanu, ògiri ìlú tó ń wó bọ̀ náà dúró nígbà tó délé Ráhábù. Jóṣúà wá pàṣẹ fáwọn ọkùnrin tó lọ ṣamí ìlú náà pé: “Ẹ wọnú ilé obìnrin náà lọ, kárùwà náà, kí ẹ sì mú obìnrin náà àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀ jáde kúrò níbẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.” (Jóṣ. 6:22) Kò sẹ́ni tó kú nínú ilé Ráhábù.

Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Kí la lè rí kọ́ nínú bí Ọlọ́run ṣe dá Nóà, Lọ́ọ̀tì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Mósè àti Ráhábù nídè? Báwo ni àkọsílẹ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ibi tó yẹ ká wà nígbà tí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí bá dé?

Òótọ́ ni pé Nóà ò pa run torí pé ó wà nínú ọkọ̀ áàkì. Àmọ́ kí ló jẹ́ kó wà níbẹ̀? Ǹjẹ́ kì í ṣe torí pé ó lo ìgbàgbọ́, tó sì jẹ́ onígbọràn ni? Bíbélì sọ pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́n. 6:22; Héb. 11:7) Àwa ńkọ́? Ṣé à ń ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wa? Nóà tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Bíi ti Nóà, ṣé àwa náà ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà báwọn èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́?

Lọ́ọ̀tì ò pa run torí pé ó sá jáde kúrò nílùú Sódómù. Ó la ìparun yẹn já tórí pé ó jẹ́ olóòótọ́ lójú Ọlọ́run àti pé ohun táwọn èèyàn búburú ìlú Sódómù àti Gòmórà tí ìwà ìbàjẹ́ ti wọ̀ lẹ́wù ń ṣe bà á nínú jẹ́ gan-an ni. Ṣé ìwà àìníjàánu tó gbalẹ̀ gbòde lónìí máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwa náà? Àbí rírí tá à ń rí i ti mọ́ wa lára dé bi tí kò fi jọ wá lójú mọ́? Ṣé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká bàa lè wà ní “àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà”?—2 Pét. 3:14.

Ní tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Íjíbítì àti Ráhábù tó ń gbé nílùú Jẹ́ríkò, tí wọ́n bá wà nínú ilé wọn nìkan ni wọ́n á rí ìdáǹdè. Ìyẹn gba pé kí wọ́n nígbàgbọ́ kí wọ́n sì ṣègbọràn. (Héb. 11:28, 30, 31) Fojú inú wo báwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣe tẹjú mọ́ àwọn àkọ́bí wọn roro bí “igbe ẹkún ńláǹlà” ṣe ń sọ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan ilé àwọn ọmọ Íjíbítì. (Ẹ́kís. 12:30) Fojú inú wo bí Ráhábù á ṣe dì mọ́ àwọn aráalé ẹ̀ bó ṣe ń gbọ́ bí ògiri ìlú Jẹ́ríkò tó ń wó ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ ilé ẹ̀. Obìnrin yìí ti ní láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára kó sì jẹ́ onígbọràn kó tó lè dúró sínú ilé náà.

Òpin máa tó dé bá ayé búburú Sátánì yìí. A ò tíì mọ bí Jèhófà ṣe máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ‘lọ́jọ́ ìbínú rẹ̀’ tó jẹ́ ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ náà. (Sef. 2:3) Àmọ́, ibi yòówù ká wà, ipò yòówù ká sì wà lákòókò yẹn, ó dá wa lójú pé ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àti ìgbọràn wa ló máa pinnu bóyá a máa là á já. Ní báyìí ná, ó yẹ ká ní ojú ìwòye tó tọ́ nípa ohun tí Aísáyà pè ní ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ.

“Wọnú Yàrá Rẹ Ti Inú Lọ́hùn-ún”

Ìwé Aísáyà 26:20 sọ pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.” Ó ṣeé ṣe kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti kọ́kọ́ nímùúṣẹ lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà táwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun ìlú Bábílónì. Nígbà tí Kírúsì ará Páṣíà wọ ìlú Bábílónì, ó jọ pé ó pàṣẹ pé káwọn èèyàn má ṣe jáde nínú ilé wọn torí ó ti sọ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí níta.

Lákòókò tiwa yìí, a lè fí ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí wé ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] tó wà kárí ayé. Àǹfààní ńláǹlà làwọn ìjọ yìí ń ṣe fún wa. Wọ́n á sì máa bá a nìṣó láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ “ìpọ́njú ńlá náà.” (Ìṣí. 7:14) Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ sínú ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ kí wọ́n sì fara pa mọ́ “títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.” Ó ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ máa fojú tó tọ́ wo ìjọ, ká sì pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mú wa kúrò níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ sọ́kàn pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Héb. 10:24, 25.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kí la lè rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn èèyàn nídè?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Kí la lè fi ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ wé lákòókò tá a wà yìí?