Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Tẹ̀ Lé “Kristi”?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Tẹ̀ Lé “Kristi”?
“Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, . . . kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.”—LÚÙKÙ 9:23.
1, 2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wa pé ká ṣàyẹ̀wò ìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé “Kristi”?
ẸWO bí inú Jèhófà á ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ ètò rẹ̀ àtàwọn ọ̀dọ́, láàárín àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tí wọ́n pọ̀ níye! Bó o ṣe ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó ò ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, tí ìmọ̀ rẹ nípa òtítọ́ tó ń gbani là tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń pọ̀ sí i, ó ṣe pàtàkì pé kó o fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí sọ́kàn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, ó yẹ kó o sẹ́ ara ẹ, kó o sì di ọmọlẹ́yìn òun. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa ronú lórí ìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé “Kristi.”—Mát. 16:13-16.
2 Àwọn tó ti wá ń tẹ̀ lé Jésù Kristi ńkọ́? Bíbélì rọ̀ wá pé ká “tẹra mọ́ títúbọ̀ ṣe é lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.” (1 Tẹs. 4:1, 2) Bóyá ẹnu àìpẹ́ yìí la ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni o, tàbí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ríronú lórí ìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé Kristi á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ sílò, ká sì túbọ̀ máa tẹ̀ lé Kristi lọ́jọ́ gbogbo. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí márùn-ún tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé Kristi.
Ká Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà
3. Ọ̀nà méjì wo la lè gbà mọ Jèhófà?
3 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù “dúró ní àárín Áréópágù,” tó ń bá àwọn ará Áténì sọ̀rọ̀, ó sọ fún wọn pé: “[Ọlọ́run] gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn, fún wọn láti máa wá Ọlọ́run, bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:22, 26, 27) A lè wá Ọlọ́run ká sì mọ̀ ọ́n lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, à ń kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ànímọ́ Ọlọ́run àti bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó látinú àwọn nǹkan tó dá. Torí náà, tá a bá mọrírì àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, tá a sì ń fara balẹ̀ ronú nípa wọn, a ó rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa. (Róòmù 1:20) Jèhófà tún jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa òun nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (2 Tím. 3:16, 17) Bá a bá ṣe ń ‘ṣàṣàrò lórí ìgbòkègbodò Jèhófà’ tá a sì ń “dàníyàn nípa ìbálò” rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe máa mọ̀ ọ́n tó.—Sm. 77:12.
4. Báwo ni títẹ̀lé Kristi ṣe lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
4 Ọ̀nà tó dáa tá a tún lè gbà túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ni pé, ká máa tẹ̀ lé Kristi. Ronú nípa ògo tí Jésù ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ “kí ayé tó wà.” (Jòh. 17:5) Òun ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Ìṣí. 3:14) Gẹ́gẹ́ bí “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” ó ti gbé lọ́run pẹ̀lú Jèhófà Baba rẹ̀ fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún. Nígbà tí Jésù fi wà lọ́run kó tó wá sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, kì í ṣe pé ó kàn ṣáá wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ lọ́run o, alábàáṣiṣẹ́ pàtàkì ló jẹ́ fún Ọlọ́run, tayọ̀tayọ̀ ló sì fi ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Olódùmarè, àjọṣe àárín wọn lágbára gan-an débi pé kò sẹ́ni tó tún sún mọ́ Jèhófà bíi Jésù láyé àtọ̀run. Yàtọ̀ sí pé Jésù ń kíyèsí bí Baba rẹ̀ ṣe ń ṣe nǹkan, ojú tó fi ń wo nǹkan àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, Jésù tún ń fàwọn nǹkan tó kọ́ sọ́kàn, ó sì ń fi ṣèwà hù. Èyí ló mú kí Ọmọkùnrin onígbọràn yìí dà bí Baba rẹ̀ gẹ́lẹ́, débi pé Bíbélì pè é ní “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (Kól. 1:15) Tá a bá ń tẹ̀ lé Kristi pẹ́kípẹ́kí, a máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Ká Lè Túbọ̀ Máa Fara Wé Jèhófà
5. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fara wé Jèhófà, kí sì nìdí?
5 ‘Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìrí rẹ̀,’ torí náà, ó ṣeé ṣe fún wa láti fìwà jọ ọ́. (Jẹ́n. 1:26) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfé. 5:1) Bá a bá ń tẹ̀ lé Kristi èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti máa fara wé Baba wa ọ̀run. Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó tíì ṣàgbéyọ èrò Ọlọ́run, kó sì kọ́ni nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ lọ́nà tó dáa bíi ti Jésù. Nígbà tí Jésù wà láyé, kì í ṣe pé ó kàn jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà nìkan, ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ irú Ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. (Ka Mátíù 11:27.) Jésù ṣe èyí nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, ó sì hàn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀.
6. Kí làwọn ẹ̀kọ́ Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
6 Jésù ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa, ó sì sọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀. (Mát. 22:36-40; Lúùkù 12:6, 7; 15:4-7) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù sọ ọ̀kan lára Òfin Mẹ́wàá, èyí tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà,” ó ṣàlàyé èrò Ọlọ́run nípa ohun tó máa ń wà nínú ọkàn èèyàn fún ìgbà pípẹ́ kó tó di pé ó hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Ẹ́kís. 20:14; Mát. 5:27, 28) Lẹ́yìn tó sọ ọ̀nà òdì táwọn Farisí gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ kan nínú Òfin, tí wọ́n sọ pé, “kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ,” Jésù wá sọ ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mát. 5:43, 44; Ẹ́kís. 23:4; Léf. 19:18) Tá a bá lóye ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lórí àwọn nǹkan àti ojú tó fi máa ń wo nǹkan, tá a sì mọ ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fara wé e.
7, 8. Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà látinú àpẹẹrẹ Jésù?
7 Jésù tún jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ nípa àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀. Nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, tá a bá kà nípa bí Jésù ṣe ṣàánú àwọn aláìní, bó ṣe gba táwọn tó ń jìyà rò, bó ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wí nítorí pé wọ́n ń ṣèdíwọ́ fáwọn ọmọdé láti má ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ǹjẹ́ a ò gbà pé irú ànímọ́ yẹn náà ni Jèhófà ní? (Máàkù 1:40-42; 10:13, 14; Jòh. 11:32-35) Ẹ wo bí ìwà àti ìṣe Jésù ṣe jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ̀ pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ní. Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Kristi ṣe ò fi hàn pé ó lágbára púpọ̀? Àmọ́, kò lo agbára yẹn fún èrè tara ẹ̀ tàbí kó fi pa àwọn èèyàn lára. (Lúùkù 4:1-4) Lílé tó lé àwọn oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ oníwọra kúrò nínú tẹ́ńpìlì fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni. (Máàkù 11:15-17; Jòh. 2:13-16) Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àtàwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tó ń sọ máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, èyí sì fi hàn pé ọgbọ́n rẹ̀ “ju [ti] Sólómọ́nì lọ.” (Mát. 12:42) Ìfẹ́ tí Jésù fi hàn nípa bó ṣe gbà láti kú nítorí àwa èèyàn jẹ́ ká gbà lóòótọ́ pé “kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ”!—Jòh. 15:13.
8 Ọmọkùnrin Ọlọ́run fìwà jọ Jèhófà lọ́nà pípé nínú gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ débi tí òun fúnra rẹ̀ fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Ka Jòhánù. 14:9-11.) Tá a bá ń tẹ̀ lé Kristi, Jèhófà là ń tẹ̀ lé yẹn.
Jésù Ni Ẹni Àmì Òróró Jèhófà
9. Ìgbà wo ni Jésù di Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀?
9 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìwọ́wé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jésù tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ́ sọ́dọ̀ Jòhánù Olùbatisí. “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀.” Ìgbà yẹn ló di Kristi tàbí Mèsáyà. Ìgbà yẹn ni Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹni Àmì Òróró òun ni Jésù, nígbà tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:13-17) Ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé Kristi lèyí jẹ́!
10, 11. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà lo orúkọ oyè náà, Kristi nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa rí i pé à ń tẹ̀ lé Jésù?
10 Nínú Bíbélì, oríṣiríṣi ọ̀nà la gbà lo orúkọ òye náà “Kristi,” irú bíi, Jésù Kristi, Kristi Jésù àti Kristi. Jésù fúnra ẹ̀ ló kọ́kọ́ pe ara ẹ̀ ní “Jésù Kristi,” ó fi orúkọ rẹ̀ ṣíwájú, ó wá fi orúkọ oyè ẹ̀ tẹ̀ lé e. Nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòh. 17:3) Ọ̀nà tí Jésù gbà pe ara ẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ ẹni tí Ọlọ́run rán tó sì wá di Ẹni àmì òróró rẹ̀. Bó bá jẹ́ pé orúkọ oyè la fi ṣíwájú, ìyẹn “Kristi Jésù,” oyè Jésù tàbí ipò ẹ̀ la fẹ́ fún láfiyèsí, kì í ṣe orúkọ ẹ̀. (2 Kọ́r. 4:5) Tá a bá sọ pé “Kristi náà,” ìyẹn orúkọ oyè Jésù pẹ̀lú ọ̀rọ̀ atọ́ka tó ṣe pàtó, ọ̀nà míì nìyẹn láti gbà tẹnu mọ́ ipò tí Jésù wà gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.—Ìṣe 5:42
11 Ọ̀nà yòówù ká gbà lo orúkọ oyè náà, “Kristi” tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, òtítọ́ tó ń fi hàn ni pé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọmọkùnrin Ọlọ́run wá sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, tó sì jẹ́ ká mọ ìfẹ́ Baba rẹ̀, kì í ṣe èèyàn lásán, tàbí wòlíì kan lásán, ńṣe ló wá láti jẹ́ Ẹni Àmì Òróró Jèhófà. A gbọ́dọ̀ rí i pé à ń tẹ̀ lé Ẹni Àmì Òróró yìí.
Jésù Ni Ọ̀nà Kan Ṣoṣo sí Ìgbàlà
12. Ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sọ fún àpọ́sítélì Tọ́másì tó ṣe pàtàkì fún wa?
12 A rí ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ̀ ká máa bá a nìṣó láti máa tẹ̀ lé Mèsáyà náà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n pa á. Nígbà tí Jésù fèsì ìbéèrè Tọ́másì nípa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé òun ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún wọn, Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 14:1-6) Àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ mọ́kànlá ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà yẹn. Ó ṣèlérí fún wọn pé òun á pèsè àyè sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run, àmọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ yìí tún nítumọ̀ fún àwọn tí wọ́n nírètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. (Ìṣí. 7:9, 10; 21:1-4) Lọ́nà wo?
13. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ọ̀nà náà”?
13 Jésù Kristi ni “ọ̀nà náà.” Èyí túmọ̀ sí pé ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan la fi lè dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Òótọ́ sì ni, torí pé tá a bá gbàdúrà nípasẹ̀ Jésù nìkan la fi lè ní ìdánilójú pé Baba máa ṣe ohunkóhun tá a bá béèrè níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (Jòh. 15:16) Àmọ́, ọ̀nà míì tún wà tí Jésù tún gbà jẹ́ “ọ̀nà náà.” Ẹ̀ṣẹ̀ ti mú kí ìran èèyàn yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Aísá. 59:2) Jésù fi “ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mát. 20:28) Ìyẹn ló mú kí Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ Jésù . . . ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòh. 1:7) Ọmọkùnrin Ọlọ́run wá tipa báyìí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìràn èèyàn láti pa dà bá Ọlọrun rẹ́. (Róòmù 5:8-10) Tá a bá gba Jésù gbọ́, tá a sì ń ṣègbọràn sí i, ìyẹn á jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—John 3:36.
14. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “òtítọ́”?
14 Jésù jẹ́ “òtítọ́,” yàtọ̀ sí pé ìgbà gbogbo ló máa ń sọ òtítọ́ tó sì gbé ìgbé ayé ẹ̀ níbàámu pẹ̀lú òtítọ́, ó tún jẹ́ òtítọ́ ní ti pé, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì nípa Mèsáyà ló ṣẹ sí i lára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ pé: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀.” (2 Kọ́r. 1:20) Kódà, “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀,” tó wà nínú Òfin Mósè ti di mímúṣẹ nípasẹ̀ Kristi Jésù. (Héb. 10:1; Kól. 2:17) Orí Jésù ni gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ dá lé, wọ́n sì jẹ́ ká mọ ipa pàtàkì tí Jésù kó nínú bí Jèhófà ṣe máa ṣàwọn ohun tó ní lọ́kàn. (Ìṣí. 19:10) Tá a bá fẹ́ jàǹfààní látinú ìmúṣẹ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún wá, àfi ká máa tẹ̀ lé Mèsáyà náà.
15. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ìyè”?
15 Jésù jẹ́ “ìyè” nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ara ẹ̀ ló fi ra ìran èèyàn àti pé ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni “nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Jésù tún jẹ́ “ìyè” fún àwọn tó ti kú. (Jòh. 5:28, 29) Tún ronú nípa ohun tó máa gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún. Àní, ó máa dá àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ nídè lọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú!—Héb. 9:11, 12, 28.
16. Kí nìdí tá a fi ń tẹ̀ lé Jésù?
16 A lè wá rí i báyìí pé ọ̀rọ̀ tí Jésù fi dá Tọ́másì lóhùn yẹn ní ìtúmọ̀ pàtàkì fún wa. Jésù ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè. Òun ni Ọlọ́run rán wá sáyé kí aráyé lè tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà. (Jòh 3:17) Kò sì sí ẹni tó lè wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù. Bíbélì sọ ní kedere pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.” (Ìṣe 4:12) Ohun yòówù ká ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ báyìí pé ká gba Jésù gbọ́, ká máa tẹ̀ lé e, ká bàa lè rí ìyè.—Jòh. 20:31.
Ọlọ́run Pàṣẹ Pé Ká Máa Fetí si Kristi
17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sí Ọmọ Ọlọ́run?
17 Pétérù, Jòhánù àti Jákọ́bù wà níbẹ̀ nígbà ìyípadà ológo. Nígbà yẹn, wọ́n gbọ́ ohùn kan látọ̀run tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí a ti yàn. Ẹ fetí sí i.” (Lúùkù 9:28, 29, 35) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé ká máa fetí sí Mèsáyà náà.—Ka Ìṣe 3:22, 23.
18. Ọ̀nà wo la lè gbà máa fetí sí Jésù Kristi?
18 Fífetí sí Jésù wé mọ́ ‘títẹjú mọ́ ọn, ká sì máa ronú jinlẹ̀ lórí àpẹẹrẹ rẹ̀.’ (Héb. 12:2, 3) Torí náà, á dáa ká máa fún àwọn ohun tá à ń kà nípa rẹ̀ nínú Bíbélì, nínú àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àtàwọn nǹkan tá à ń gbọ́ nípa rẹ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni ní “àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.” (Héb. 2:1; Mát. 24:45) Níwọ̀n bá a ti jẹ́ àgùntàn Jésù Kristi, ẹ jẹ́ ká máa hára gàgà láti máa fetí sí Jésù ká sì máa tẹ̀ lé e.—Jòh. 10:27.
19. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní títẹ̀ lé Kristi?
19 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá a nìṣó ní títẹ̀ lé Jésù, bá a tiẹ̀ wà nínú ìṣòro? Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣeé ṣe, tá a bá ń “di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” mú, tá à ń fàwọn nǹkan tá à ń kọ́ ṣèwàhù “pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—2 Tím. 1:13.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Báwo ni títẹ̀ lé “Kristi” ṣe lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
• Báwo ni fífarawé Jésù ṣe túmọ̀ sí fífarawé Jèhófà?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù ni “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè”?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fetí sí Ẹni Àmì òróró Jèhófà?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Awọn ẹ̀kọ́ Jésù ń ṣàgbéyọ èrò Jèhófà tó ta yọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
A gbọ́dọ̀ máa fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé Ẹni Àmì Òróró Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Jèhófà sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi . . . ẹ fetí sí i”