Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí Jésù ti wàásù jákèjádò ilẹ̀ Ísírẹ́lì, kí nìdí tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé àwọn Júù àtàwọn olùṣàkóso wọn “gbé ìgbésẹ̀ ní àìmọ̀” nígbà tí wọ́n ní kí wọ́n pa Jésù?—Ìṣe 3:17.
Nígbà tí Pétérù ń bá àwùjọ àwọn Júù kan sọ̀rọ̀ nípa ipa tí wọ́n kó nínú ikú Mèsáyà, ó ní: “Èmi mọ̀ pé ẹ gbé ìgbésẹ̀ ní àìmọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣàkóso yín pẹ̀lú ti ṣe.” (Ìṣe 3:14-17) Àwọn Júù kan lè má lóye ẹni tí Jésù jẹ́ àtohun tó ń kọ́ni. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ara ìdí tí wọn ò fi mọ nǹkan kan nípa Jésù ni pé wọ́n ní ẹ̀tanú, owú, ìkórìíra, kò sì wù wọ́n láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
Wo bí àìfẹ́ láti ṣe ohun tó wu Jèhófà ṣe nípa lórí ojú tí ọ̀pọ̀ wọn fi wo ẹ̀kọ́ Jésù. Nígbà tí Jésù bá ń kọ́ni, ó sábà máa ń lo àpèjúwe, ó sì máa ń ṣàlàyé àwọn àpèjúwe náà fún àwọn tó fẹ́ mọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n ńṣe làwọn kan lára àwọn èèyàn náà kàn máa ń rìn kúrò níbẹ̀, wọn ò sì ní sapá láti lóye ohun tí wọ́n gbọ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàápàá bínú sí àkànlò èdè tó lò. (John 6:52-66) Àwọn wọ̀nyí ò mọ̀ pé ńṣe ni Jésù ń lo àwọn àpèjúwe yìí láti mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni wọ́n ṣe tán láti yí ìrònú àti ìṣe wọn pa dà. (Aísá. 6:9, 10; 44:18; Mát. 13:10-15) Wọn ò tún fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé Mèsáyà á máa lo àpèjúwe nígbà tó bá ń kọ́ni.—Sm. 78:2.
Àwọn míì kò tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Jésù nítorí ẹ̀tanú. Nígbà tí wọ́n rí Jésù tó ń kọ́ni nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárétì nílùú ìbílẹ̀ rẹ̀ “Háà . . . ṣe” àwọn èèyàn. Àmọ́ dípò kí wọ́n gbà pé òun ni Mèsáyà, ńṣe ni wọ́n ń béèrè pé, báwo ni tiẹ̀ ṣe jẹ́, wọ́n ní: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí nǹkan wọ̀nyí? . . . Èyí ni káfíńtà náà ọmọkùnrin Màríà àti arákùnrin Jákọ́bù àti Jósẹ́fù àti Júdásì àti Símónì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà pẹ̀lú wa níhìn-ín, àbí wọn kò sí?” (Máàkù 6:1-3) Ẹ̀kọ́ Jésù ò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn Násárétì, torí pé àwọn òbí tó tọ́ ọ dàgbà ò lókìkí.
Àwọn aṣáájú ìsìn wá ńkọ́? Ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò fí bẹ́ẹ̀ fetí sí Jésù nítorí onírúurú nǹkan tí wọ́n rò nípa ẹ̀. (Jòh. 7:47-52) Àwọn náà ò tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Jésù torí wọ́n ń jowú pé àwọn èèyàn ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. (Máàkù 15:10) Ńṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn bínú nígbà tí Jésù bá wọn wí nítorí àgàbàgebè àti ẹ̀tàn wọn. (Mát. 23:13-36) Jésù gégùn-ún fún wọn torí pé ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan tí ò dáa, ó ní: “Ègbé ni fún ẹ̀yin ògbóǹkangí nínú Òfin, nítorí tí ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ; ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé [sínú Ìjọba Ọlọ́run], àwọn tí wọ́n sì ń wọlé ni ẹ dí lọ́wọ́!”—Lúùkù 11:37-52.
Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ni Jésù fi wàásù ìhìn rere ní ilẹ̀ náà. Ó sì tún dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà. (Lúùkù 9:1, 2; 10:1, 16, 17) Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó dára gan-an débi pé àwọn Farisí ń ṣàròyé pé: “Wò ó! Ayé ti wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” (Jòh. 12:19) Nítorí náà, kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò mọ nǹkan kan nípa Jésù. Àmọ́ ńṣe ni wọ́n dìídì fẹ́ wà ní “àìmọ̀,” ìyẹn ni pé wọn ò gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Wọn ì bá ti mú kí ìmọ̀ wọn àti ìfẹ́ wọn jinlẹ̀ nípa Mèsáyà, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn kan lára wọn lọ́wọ́ nínú ikú Jésù. Ìyẹn ló mú kí àpọ́sítélì Pétérù gba ọ̀pọ̀ lára wọn níyànjú pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, kí ó sì lè rán Kristi tí a yàn sípò jáde fún yín, Jésù.” (Ìṣe 3:19, 20) Ó yani lẹ́nu pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sílẹ̀ títí kan “ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà.” Wọn ò ṣe bí aláìmọ̀kan mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ronúpìwàdà, wọ́n sì rí ojú rere Jèhófà.—Ìṣe 2:41; 4:4; 5:14; 6:7.