Bó O Ṣe Lè Láyọ̀ Láìlọ́kọ Tàbí Aya
Bó O Ṣe Lè Láyọ̀ Láìlọ́kọ Tàbí Aya
“NÍGBÀ tó yá, wọ́n ṣègbéyàwó wọ́n sì ń gbé pẹ̀lú ìdùnnú.” Irú ọ̀rọ̀ báyìí ló sábà máa ń parí ọ̀pọ̀ ìtàn nípa àwọn ọmọdé. Èrò tó jọ èyí láwọn eré àtàwọn ìwé tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ sábà máa ń gbé yọ, ìyẹn ni pé ìgbéyàwó ló máa ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀! Ìyẹn nìkan kọ́, nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, ńṣe ni wọ́n máa ń fúngun mọ́ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n lọ ṣègbéyàwó. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Debby tó wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń jẹ́ kéèyàn máa lérò pé ohun kan ṣoṣo tí ọ̀dọ́bìnrin lè ṣe ni pé kó lọ́kọ. Èrò wọn ni pé lẹ́yìn ìgbéyàwó ni ìgbádùn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.”
Ẹni tó lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan kò ní ní irú èrò yìí. Lóòótọ́ gbígbéyàwó jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ Bíbélì tún sọ nípa àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin kan tí wọn ò ṣègbéyàwó tí ìgbésí ayé wọn sì nítumọ̀. Lóde òní, àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn ò ní lọ́kọ tàbí láya, nígbà tó sì jẹ́ pé ipò táwọn kan wà ni ò jẹ́ kí wọ́n ṣègbéyàwó. Ohun yòówù kó fà á tí wọn ò fi ṣègbéyàwó, ìbéèrè pàtàkì náà ṣì wà síbẹ̀ pé: Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè kẹ́sẹ járí láìlọ́kọ tàbí láya?
Jésù fúnra ẹ̀ ò gbéyàwó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tó gbà ló fà á. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé àwọn kan lára wọn náà máa “wá àyè fún” wíwà láìṣègbéyàwó. (Mát. 19:10-12) Jésù fi hàn pé kéèyàn tó lè kẹ́sẹ járí láìlọ́kọ tàbí láya, àfi kéèyàn wá àyè fún irú ọ̀nà ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀.
Ṣé àwọn kan tí wọ́n ti pinnu láti wà láìlọ́kọ tàbí láya ní ìgbésí ayé wọn kí wọ́n bàa lè gbájú mọ́ iṣẹ́ Ọlọ́run nìkan ni ìmọ̀ràn Jésù yìí kàn ni? (1 Kọ́r. 7:34, 35) Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ronú nípa Kristẹni kan tó fẹ́ láti ṣègbéyàwó àmọ́ tí ò tíì rẹ́ni tó wù ú. Arábìnrin Ana tó ti lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún tí ò sì tíì lọ́kọ, sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kọnu ìfẹ́ sí mi. Inú mi kọ́kọ́ dùn, àmọ́ lójú ẹsẹ̀ ni mó ti gbé èrò yìí kúrò lọ́kàn mi torí ẹni tó máa jẹ́ kí n sún mọ́ Jèhófà ni mo fẹ́ fi ṣọkọ.”
Ìfẹ́ láti ṣègbéyàwó “nínú Olúwa,” ti ran ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin bí Ana lọ́wọ́ láti má ṣe fẹ́ aláìgbàgbọ́. a (1 Kọ́r. 7:39; 2 Kọ́r. 6:14) Torí pé wọ́n fẹ́ ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí, wọ́n pinnu láti wà láìlọ́kọ, títí wọ́n á fi rí onígbàgbọ́ bíi tiwọn fẹ́. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe èyí láṣeyọrí?
Kọ́ Láti Máa Ní Èrò Tó Dáa
Bí nǹkan bá ṣe ń rí lára wa ló máa pinnu bóyá a máa lè fara da ipò nǹkan bí ò tiẹ̀ bára dé. Arábìnrin Carmen tó ti lé lọ́mọ ogójì [40] ọdún tí kò sì tíì lọ́kọ sọ pé: “Mo máa ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tí mo ní, mi ò kì í sì í jẹ́ kí ìrònú ohun tí mi ò ní gbà mí lọ́kàn.” Lóòótọ́, àwọn ìgbà kan lè wà táá máa ṣe wá bíi pé a dáwà tàbí kí nǹkan tojú sú wa. Àmọ́ tá a bá mọ̀ pé ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn ará wa karí ayé, èyí á fún wa lókun láti máa fi ìdánilójú bá a nìṣó. Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ àwọn tí ò lọ́kọ tàbí 1 Pét. 5:9, 10.
láya lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro míì.—Ọ̀pọ̀ ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ò lọ́kọ tàbí láya ti rí àǹfààní tó wà níbẹ̀. Arábìnrin Ester tó wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún márùndínlógójì [35] tí kò sì tíì lọ́kọ sọ pé: “Ní tèmi, àṣírí ayọ̀ ni pé kéèyàn máa gbádùn apá tó dáa nínú ipò yòówù téèyàn bá bára ẹ̀.” Arábìnrin Carmen tún sọ pé: “Ó dá mi lójú pé bóyá mo lọ́kọ o tàbí mi ò ní, tí mo bá ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, Jèhófà ò ní fawọ́ ohun rere èyíkéyìí sẹ́yìn lọ́dọ̀ mi. (Sm. 84:11) Lóòótọ́, ìgbésí ayé lè má tíì rí bí mo ṣe fẹ́ kó rí o, àmọ́ mò ń láyọ̀, màá sì máa bá a nìṣó láti láyọ̀.”
Àwọn Tí Bíbélì Sọ Pé Wọn Ò Ṣègbéyàwó
Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ò pinnu láti wà láìlọ́kọ. Àmọ́ ẹ̀jẹ́ tí baba ẹ̀ jẹ́ mú kó di dandan fún un láti fèyí tó kù nínú ìgbésí ayé ẹ̀ ṣiṣẹ́ sìn nínú ibùjọsìn látìgbà ọ̀dọ́. Kò sí iyèméjì pé iṣẹ́ tí kò rò tẹ́lẹ̀ yìí mú kí ìpinnu ẹ̀ yí pa dà, kò sì bá ìmọ̀lára ẹ̀ mu. Oṣù méjì gbáko ló fi sunkún nígbà tó mọ̀ pé òun ò ní lọ́kọ, òun ò sì ní ní ìdílé. Síbẹ̀síbẹ̀, ó fara mọ́ ipò tuntun tó bá ara ẹ̀ yìí, ó sì lo èyí tó kù nínú ìgbésí ayé ẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sìn tọkàntọkàn. Àwọn obìnrin láti Ísírẹ́lì sì máa ń lọ gbóríyìn fún un lọ́dọọdún fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ rẹ̀.—Oníd. 11:36-40.
Ó ṣeé ṣe kí ìbànújẹ́ bá àwọn ọkùnrin kan nígbà ayé Aísáyà nítorí tí wọ́n jẹ́ ìwẹ̀fà. Bíbélì ò sọ ohun tó sọ wọ́n dà bẹ́ẹ̀. Torí ipò tí wọ́n wà yìí, wọn ò lè wọnú ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn ò lè fẹ́yàwó, wọn ò sì lè bímọ. (Diu. 23:1) Àmọ́, Jèhófà mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára wọn, ó sì gbóríyìn fún wọn bí wọ́n ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí májẹ̀mú tó bá wọn dá. Ó sọ fún wọn pé wọ́n máa ní “ohun ìránnilétí” àti “orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” nínú ilé òun. Ìyẹn ni pé, àwọn ìwẹ̀fà tó jẹ́ olóòótọ́ yìí máa ní ìrètí tó dájú láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ ìṣàkóso Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Jèhófà ò ní gbàgbé wọn láé.—Aísá. 56:3-5.
Àmọ́, ọ̀rọ̀ ti Jeremáyà yàtọ̀ gan-an. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti yàn án bíi wòlíì, ó sọ fún un pé kó má ṣe fẹ́yàwó torí àkókò eléwu tó ń gbé àti nítorí iṣẹ́ tí òun gbé lé e lọ́wọ́. Jèhófà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fẹ́ aya fún ara rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ní ibí yìí.” (Jer. 16:1-4) Bíbélì ò sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Jeremáyà, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jeremáyà dùn sí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ. (Jer. 15:16) Kò sí àní-àní pé lẹ́yìn tí Jeremáyà ti fara da ìnira fún odindi oṣù méjìdínlógún tí wọ́n fi sàga ti Jerúsálẹ́mù, ó rí i pé ó bọ́gbọ́n mu bóun ṣe ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé òun ò gbọ́dọ̀ fẹ́yàwó.—Ìdárò 4:4, 10.
Bó O Ṣe Lè Gbádùn Ìgbésí Ayé Ẹ
Àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn látinú Bíbélì lókè yìí ò fẹ́yàwó wọn ò sì lọ́kọ, àmọ́ wọ́n rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà, wọ́n sì lo ara wọn gidigidi nínú iṣẹ́ rẹ̀. Bákan náà lóde òní, tá a bá ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tó nítumọ̀, èyí lè mú kí ìgbésí ayé wa dùn. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn obìnrin tó ń wàásù ìhìn rere máa jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá. (Sm. 68:11) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arábìnrin tí wọn ò lọ́kọ wà lára wọn. Bí iṣẹ́ wọn sì ti ń méso jáde, ọ̀pọ̀ wọn ló ti ní ọmọ nípa tẹ̀mí lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ìbùkún lèyí sì jẹ́ fún wọn.—Máàkù 10:29, 30; 1 Tẹs. 2:7, 8.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá tí Arábìnrin Loli ti wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, ó sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò lọ́kọ, àmọ́ mo jẹ́ kí ọwọ́ mi dí, èyí sì ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìdánìkanwà. Lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, torí mo mọ̀ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní tòótọ́. Èyí sì ń fún mi láyọ̀ tó pọ̀.”
Ọ̀pọ̀ arábìnrin ló ti kọ́ èdè tuntun, wọ́n sì ti mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i nípa wíwàásù fáwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Arábìnrin Ana tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nílùú tí mò ń gbé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn àjèjì ló wà níbẹ̀.” Arábìnrin yìí fẹ́ràn láti máa wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Faransé. Ó sọ pé, “Kíkọ́ èdè tí mo lè fi wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè yìí ti jẹ́ kí n ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun, mo sì ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù.”
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba ni bùkátà táwọn tí kò lọ́kọ tàbí láya máa ń gbọ́, àwọn kan ti lo àǹfààní yìí láti lọ sìn láwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Arábìnrin Lidiana tó jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún márùndínlógójì [35] tí kò sì tíì lọ́kọ, tó sì ti sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i sọ pé: “Ó dá mi lójú pé, bọ́wọ́ èèyàn bá ṣe dí tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rọrùn tó láti láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, tẹ́ni náà á sì rí i pé lóòótọ́ ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Mo ti ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n tọ́ dàgbà lọ́nà tó yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ọ̀rẹ́ yìí sì ti mú kí ìgbésí ayé mi ládùn gan-an ni.”
Bíbélì sọ nípa Fílípì ajíhìnrere pé ó ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí wọn ò lọ́kọ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 21:8, 9) Ó ṣeé ṣe káwọn náà jẹ́ onítara bíi ti bàbá wọn. Ǹjẹ́ wọ́n lo ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ní fún ire àwọn Kristẹni bíi tiwọn tó wà nílùú Kesaréà? (1 Kọ́r. 14:1, 3) Lóde òní, bíi táwọn ọmọbìnrin mẹ́rin yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tí ò tíì lọ́kọ ń gbé àwọn míì ró bí wọ́n ṣe ń wá sáwọn ìpàdé déédéé tí wọ́n sì ń lóhùn sí i.
Bíbélì gbóríyìn fún obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà tó wá láti ìlú Fílípì ní ọ̀rúndún kìíní fún bó ṣe lẹ́mìí aájò àlejò. (Ìṣe 16:14, 15, 40) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé obìnrin yìí ò lọ́kọ tàbí kò jẹ́ pé ọkọ ẹ̀ ti kú, ó jẹ́ ọ̀làwọ́, èyí sì fún un láǹfààní láti gba àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò bíi Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Lúùkù lálejò. Báwa náà bá jẹ́ ọ̀làwọ́, a máa gbádùn ìbùkún bí irú èyí.
Bá A Ṣe Lè Dẹni Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́
Yàtọ̀ sí pé ká máa ṣiṣẹ́ tó nítumọ̀ kọ́wọ́ wa lè dí, gbogbo wa la nílò pé káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa. Báwo làwọn tí ò tíì lọ́kọ tàbí láya ṣe máa bójú tó apá yìí? Ohun kan ni pé, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń nífẹ̀ẹ́ wa, tó ń fún wa lókun, tó sì ń fetí sí wa. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Dáfídì Ọba máa ń nímọ̀lára pé òun “dá nìkan wà, a sì ń ṣẹ́ [òun] níṣẹ̀ẹ́,” ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé kò sígbà tóun ò lè yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. (Sm. 25:16; 55:22) Ó kọ̀wé pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sm. 27:10) Ọlọ́run ń ké sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n sún mọ́ òun, kí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́.—Sm. 25:14; Ják. 2:23; 4:8.
Síwájú sí i, láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé, a lè rí àwọn bàbá, ìyá, arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa á mú kí ìgbésí ayé wa dùn. (Mát. 19:29; 1 Pét. 2:17) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ò lọ́kọ tàbí láya ló ti rí àǹfààní tó pọ̀ nínú títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dọ́káàsì, ẹni tó “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú tí òun ń fi fúnni.” (Ìṣe 9:36, 39) Arábìnrin Loli ṣàlàyé pé: “Ibi yòówù tí mo bá lọ, mo máa ń wá àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ nínú ìjọ tí wọ́n á nífẹ̀ẹ́ mi, tí wọ́n á sì ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan bá tojú sú mi. Láti lè mú kí àjọṣe wa yìí túbọ̀ lágbára, mo máa ń gbìyànjú láti fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Mo ti sìn nínú ìjọ mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kò sì sígbà tí mi ò kì í rí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn arábìnrin tí mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́ yìí la kì í ṣe ẹgbẹ́, àwọn kan tómi bí lọ́mọ, àwọn kan sì kéré sí mi.” Gbogbo ìjọ ló láwọn èèyàn tó yẹ ká fìfẹ́ hàn sí, ká sì sún mọ́. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ látọkàn wá, ìrànlọ́wọ́ ńlá ló máa jẹ́ fún wọn, ọkàn ti wa náà á sì bálẹ̀ pé à ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, àwọn náà á sì nífẹ̀ẹ́ wa.—Lúùkù 6:38.
Ọlọrun Ò Ní Gbàgbé
Bíbélì fi hàn pé gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ yááfì nǹkan kan nítorí àkókò líle tá à ń gbé yìí. (1 Kọ́r. 7:29-31) Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn tí ò lọ́kọ tàbí láya torí wọ́n pinnu láti ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé ká gbéyàwó kìkì nínú Olúwa. (Mát. 19:12) A gbóríyìn fún wọn gan-an fún irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní yìí, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọn ò lè gbádùn ìgbésí ayé wọn o.
Arábìnrin Lidiana sọ pé: “Ohun tó mú kí ìgbésí ayé mi dùn ni àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà àti iṣẹ́ ìsìn mi. Mo mọ àwọn tọkọtìyàwó tí wọ́n láyọ̀ àtàwọn tí ò láyọ̀. Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé kò dìgbà tí n bá lọ́kọ kí n tó láyọ̀.” Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ohun pàtàkì tó máa ń fúnni láyọ̀ ni, fífúnni àti lílo ara wa fún àwọn èèyàn, ohun tí gbogbo àwa Kristẹni sì lè ṣe ni.—Jòh. 13:14-17; Ìṣe 20:35.
Kò sí àní-àní pé, ohun tó ń fún wa láyọ̀ jù lọ ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà máa bù kún wa fún ohun yòówù tá a bá yááfì torí pé a fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Héb. 6:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arábìnrin la tọ́ka sí níbí yìí, àwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí kan àwọn arákùnrin náà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
“Mo máa ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tí mo ní, mi ò kì í sì í jẹ́ kí ìrònú ohun tí mi ò ní gbà mí lọ́kàn.”—Carmen
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Arábìnrin Loli àti Lidiana ṣiṣẹ́ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọlọ́run ń ké sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n sún mọ́ òun