Olùṣòtítọ́ Ìríjú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí Rẹ̀
Olùṣòtítọ́ Ìríjú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí Rẹ̀
“Ta ni olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye, tí ọ̀gá rẹ̀ yóò yàn sípò lórí ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti máa fún wọn ní ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?”—LÚÙKÙ 12:42.
1, 2. Ìbéèrè pàtàkì wo ni Jésù béèrè nígbà tó ń sọ àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn?
NÍGBÀ tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn, ó béèrè ìbéèrè yìí pé: “Ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?” Jésù wá ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ nìṣó pé, a máa san ẹrú yìí lẹ́san fún ìṣòtítọ́ rẹ̀ nípa yíyàn án láti máa bójú tó gbogbo nǹkan ìní Ọ̀gá rẹ̀.—Mát. 24:45-47.
2 Jésù ti béèrè ìbéèrè tó jọ èyí lóṣù bíi mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. (Ka Lúùkù 12:42-44.) Ó pe ẹrú náà ní “ìríjú,” ó sì tọ́ka sí “àwọn ará ilé” gẹ́gẹ́ bí “ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀.” Ìríjú ni alámòójútó ilé tàbí ọ̀gá àwọn ẹrú. Àmọ́, ẹrú lòun náà. Ta ni ẹrú tàbí ìríjú yìí, báwo ló sì ṣe ń pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu”? Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa mọ orísun tí oúnjẹ tẹ̀mí ti ń wá.
3. (a) Báwo làwọn tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Jésù nípa “ẹrú” náà? (b) Ta ni “ìríjú,” tàbí “ẹrú,” náà, àwọn wo sì ni “ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà,” tàbí “àwọn ará ilé”?
3 Àwọn tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń sọ pé àwọn abẹnugan lára àwọn tó pera wọn ní Kristẹni lọ̀rọ̀ Jésù yìí ń tọ́ka sí. Àmọ́ Jésù tó jẹ́ “ọ̀gá” nínú àpèjúwe náà ò sọ pé ẹrú yìí á pọ̀, táá sì wà káàkiri nínú oríṣiríṣi ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Kàkà bẹ́ẹ̀, kedere ló sọ pé, “ìríjú,” tàbí “ẹrú,” kan lóun máa yàn sórí gbogbo nǹkan ìní òun. Torí náà, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn yìí ṣe máa ń ṣàlàyé, ìríjú náà ní láti jẹ́ “agbo kékeré” ti àwọn ẹni àmì òróró, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ara kan tàbí àwùjọ kan. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa agbo kékeré tán ni nínú Ìhìn Rere Lúùkù nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí. (Lúùkù 12:32) Àwùjọ yìí kan náà ni “ẹgbẹ́ àwọn ẹmẹ̀wà” tàbí “àwọn ará ilé” ń tọ́ka sí, àmọ́ ńṣe lèyí ń sọ ipa tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń kó. Ìbéèrè kan tó gba ìrònú rèé o: Ṣé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú yìí ló ń lọ́wọ́ nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu? A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.
Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Láyé Ọjọ́un
4. Báwo ni Jèhófà ṣe pe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, nǹkan pàtàkì wo ló sì yẹ ká kíyè sí nípa orílẹ̀-èdè náà?
4 Jèhófà sọ nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pé gbogbo wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ òun. “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ [ọ̀rọ̀ tó ń tọ́ka sí ẹnì kan] mi tí mo ti yàn.’” (Aísá. 43:10) Gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè yìí pátá ló wà nínú àwùjọ tí Ọlọ́run pè ní ìránṣẹ́ òun yìí. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká kíyè sí i pé àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì tí wọn kì í ṣe àlùfáà nìkan ló ni ojúṣe kíkọ́ orílẹ̀-èdè náà lẹ́kọ̀ọ́ Òfin.—2 Kíró. 35:3; Mál. 2:7.
5. Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù, àtúnṣe pàtàkì wo ló máa wáyé?
5 Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ẹrú tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Rárá o. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn Júù ìgbà ayé ẹ̀ ló jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe àwọn, ó ní: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mát. 21:43) Bẹ́ẹ̀ ni, àtúnṣe ní láti wáyé. Jèhófà máa lo orílẹ̀-èdè tuntun. Bó ti wù kó rí, tó bá dọ̀rọ̀ fífúnni nítọ̀ọ́ni tẹ̀mí, iṣẹ́ ẹrú inú àkàwé Jésù yìí kò yàtọ̀ sí ti “ẹrú” Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ìgbàanì.
Ẹrú Olóòótọ́ Náà Fara Hàn
6. Orílẹ̀-èdè tuntun wo ló fara hàn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn wo ló sì di ara ẹ̀?
6 Ísírẹ́lì tẹ̀mí ló para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tuntun náà, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16; Róòmù 2:28, 29; 9:6) Ìgbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run tú sórí wọn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló fara hàn. Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wá di ara orílẹ̀-èdè náà tó jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ tí Ọ̀gá náà, Jésù Kristi yàn. Ẹnì kọ̀ọ̀kàn lára orílẹ̀-èdè yìí ló gba àṣẹ́ náà láti wàásù ìhìn rere kó sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Àmọ́, ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kàn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí láá máa lọ́wọ́ nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Ẹ jẹ́ ká wo bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn ìbéèrè yìí.
7. Níbẹ̀rẹ̀, kí ni olórí iṣẹ́ àwọn àpọ́sítélì, àfikún iṣẹ́ wo ni wọ́n sì tún wá ní nígbà tó yá?
7 Nígbà tí Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá, olórí iṣẹ́ wọn ni pé kí wọ́n jáde láti lọ wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. (Ka Máàkù 3:13-15.) Iṣẹ́ yìí wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà apostolos, tá a mú jáde látinú ọ̀rọ̀ ìṣe náà tó túmọ̀ sí “rán jáde.” Àmọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tó sì ku díẹ̀ kí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, àwọn àpọ́sítélì wá wà ní “ipò iṣẹ́ àbójútó.”—Ìṣe 1:20-26.
8, 9. (a) Kí lohun pàtàkì tó jẹ àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà lọ́kàn? (b) Àwọn wo ni wọ́n tún fún ní àfikún iṣẹ́ táwọn ìgbìmọ̀ olùdarí sì fọwọ́ sí?
8 Kí lohun pàtàkì tó jẹ àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà lọ́kàn? A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. Nígbà tí awuyewuye kan wáyé nípa oúnjẹ tí wọn ń pín fáwọn opó, àwọn àpọ́sítélì méjìlá kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n wá sọ pé: “Kò dùn mọ́ wa nínú láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ lọ máa pín oúnjẹ sórí àwọn tábìlì.” (Ka Ìṣe 6:1-6.) Àwọn àpọ́sítélì wá yan àwọn arákùnrin míì tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí láti máa rí sí “iṣẹ́ àmójútó tí ó pọndandan yìí” káwọn àpọ́sítélì bàa lè ráyè fún “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” Jèhófà bù kún ètò tí wọ́n ṣe yìí torí pé ńṣe ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 6:7) Torí náà, olórí iṣẹ́ àwọn àpọ́sítélì ni láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí.—Ìṣe 2:42.
9 Nígbà tó yá wọ́n yan iṣẹ́ tó wúwo fáwọn ẹlòmíì. Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, ìjọ tó wà ní Áńtíókù rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jáde gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. A wá mọ àwọn náà sí àpọ́sítélì nígbà tó yá, àmọ́ wọn ò sí lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà. (Ìṣe 13:1-3; 14:14; Gál. 1:19) Nígbà tó ṣe, ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù fọwọ́ sí yíyàn tí wọ́n yan Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. (Gál. 2:7-10) Lẹ́yìn tí wọ́n yan Pọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, ó lọ́wọ́ nínú pípín oúnjẹ tẹ̀mí. Ó kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́.
10. Ní ọ̀rúndún kìíní, ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló lọ́wọ́ nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí? Ṣàlàyé.
10 Àmọ́, ṣé gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù àti pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo wọn ni àpọ́sítélì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wòlíì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni olùkọ́, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, àbí gbogbo wọn ni?” (1 Kọ́r. 12:29) Lóòótọ́, gbogbo àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí bí yìí ló ń wàásù, àmọ́ àwọn ọkùnrin mẹ́jọ péré ni Ọlọ́run mí sí láti kọ ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tó jẹ́ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
Ẹrú Olóòótọ́ Lóde Òní
11. “Àwọn ohun ìní” wo la yan ẹrú náà láti máa bójú tó?
11 Ọ̀rọ̀ Jésù tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 24:45 fi hàn kedere pé, ẹrú olóòótọ́ àti olóye á ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lákòókò òpin. Ìwé Ìṣípayá 12:17 tọ́ka sí wọn gẹ́gẹ́ bí “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” lára irú ọmọ obìnrin náà. A ti yan àwùjọ yìí sórí gbogbo ohun ìní Kristi tó wà lórí ilẹ̀ ayé. “Àwọn ohun ìní” tá a yan olóòótọ́ ìríjú náà láti máa bójú tó ni àwọn ohun ṣíṣeyebíye tó jẹ́ ti Ọ̀gá náà lórí ilẹ̀ ayé, tó ní nínú àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn nǹkan tá à ń lò fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.
12, 13. Báwo ni Kristẹni kan ṣe máa ń mọ̀ bóyá òun gba ìpè ti ọ̀run?
12 Báwo ni Kristẹni kan ṣe máa ń mọ̀ bóyá òun nírètí ti ọ̀rún, tóun sì wà lára àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí yìí? Ìdáhùn yẹn wà nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tó nírètí ti ọ̀run bíi tiẹ̀, ó ní: “Nítorí gbogbo àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣamọ̀nà, àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ọlọ́run. Nítorí ẹ kò gba ẹ̀mí ìsìnrú tí ó tún ń fa ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.”—Róòmù 8:14-17.
13 Lẹ́nu kan, a ti fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí, wọ́n sì ti gba “ìpè,” tàbí “ìkésíni” ti ọ̀run. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló pe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí. Wọ́n tẹ́wọ́ gba ìkésíni yìí láìṣiyèméjì, wọn ò sì bẹ̀rù láti di ọmọ Ọlọ́run. (Ka 1 Jòhánù 2:20, 21.) Torí náà, kì í ṣe àwọn fúnra wọn ló yàn láti lọ sọ́run, àmọ́ Jèhófà ló fi èdìdì rẹ̀ tàbí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí wọn.—2 Kọ́r. 1:21, 22; 1 Pét. 1:3, 4.
Ojú Ìwòye Tó Tọ́
14. Irú èrò wo làwọn ẹni àmì òróró ní nípa ìpè tí wọ́n gbà?
14 Irú èrò wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró ní nípa ara wọn bí wọ́n ṣe ń dúró de ìrètí wọn ti ọ̀run? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìkésíni àgbàyanu ni wọ́n gbà, síbẹ̀ ìkésíni lásán ṣì ni. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ títí dójú ikú kí wọ́n bàa lè rí èrè yìí gbà. Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, àwọn náà ní irú èrò tí Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀yin ará, èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 3:13, 14) Àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe ‘láti máa rìn lọ́nà tó yẹ ìpè tá a fi pè wọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú,’ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ “pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Éfé. 4:1, 2; Fílí. 2:12; 1 Tẹs. 2:12.
15. Ojú wo ló yẹ káwọn ará máa fi wo àwọn tó ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Ìrántí Ikú Kristi, èrò wo ló sì yẹ káwọn ẹni àmì òróró ní nípa ara wọn?
15 Yàtọ̀ síyẹn, ojú wo ló yẹ káwọn ará tó kù máa fi wo ẹni tó sọ pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yan òun, tó sì ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi? Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ṣèdájọ́ ẹni náà. Àárín ẹni yẹn àti Jèhófà lọ̀ràn náà wà. (Róòmù 14:12) Àmọ́, Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn lóòótọ́ fún ìpè ti ọ̀run kò ní máa pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sára ẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró kò sọ àwọn dẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ju táwọn kan lára àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó nírìírí lọ. (Ìṣí. 7:9) Wọn ò sì wò ó pé àwọn ní ẹ̀mí mímọ́ tó ju tàwọn “àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn lọ. (Jòh. 10:16) Wọn ò retí pé ká máa gbé wọn gẹ̀gẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò sọ pé jíjẹ táwọn ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ sọ àwọn dẹni pàtàkì ju àwọn alàgbà tá a yàn nínú ìjọ lọ.
16-18. (a) Ṣé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ló ń lọ́wọ́ nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí? Ṣàlàyé. (b) Kí nìdí tí kò fi pọn dandan pé kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí kàn sí gbogbo àwọn tó ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ kí wọ́n tó ṣèpinnu?
16 Ṣé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ló jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tuntun látinú Bíbélì fún wa? Rára o. Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, ojúṣe ẹrú yìí ni láti pèsè oúnjẹ fún agbo ilé tẹ̀mí, àmọ́ ojúṣe tàbí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kàn wọn yàtọ̀ síra. (Ka 1 Kọ́ríńtì 12:14-18.) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ní ọ̀rúndún kìíní, gbogbo wọn ló ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì. Àmọ́ àwọn díẹ̀ lára wọn ni Ọlọ́run lò láti kọ àwọn Ìwé Bíbélì àti láti ṣàbójútó ìjọ Kristẹni.
17 Àpẹẹrẹ kan rèé: Ìwé Mímọ́ máa ń sọ nípa “ìjọ” pé ó ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́. (Mát. 18:17) Àmọ́, àwọn alàgbà nìkan ló ń ṣojú fún ìjọ láti bójú tó irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Àwọn alàgbà kì í kàn sí gbogbo àwọn ará ìjọ láti mọ èrò wọn kí wọ́n tó ṣe ìpinnu. Lọ́nà tó bá ti ètò Ọlọ́run mu, wọ́n máa ń ṣe ojúṣe tá a gbé lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì ń tipa báyìí ṣojú fún gbogbo ìjọ.
18 Bákan náà, lóde òní, ìwọ̀nba àwọn ọkùnrin ẹni àmì òróró ló ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú náà. Àwọn ló para pọ̀ di Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí yàn yìí ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń jẹ. Bíi ti ọ̀rúndún kìíní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí kì í kàn sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹgbẹ́ ẹrú náà kí wọ́n tó ṣe ìpinnu. (Ka Ìṣe 16:4, 5.) Àmọ́, gbogbo ẹni àmì òróró ló ń lọ́wọ́ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìkórè tó ṣe pàtàkì tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” jẹ́ ara kan, àmọ́ iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀.—1 Kọ́r. 12:19-26.
19, 20. Èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ní nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀?
19 Ipa wo ló yẹ káwọn ohun tá a ti gbé yẹ wò yìí ní lórí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń pọ̀ sí i tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé? Gẹ́gẹ́ bí apá kan lára ohun ìní Ọba náà, tìdùnnú-tìdùnnú ni wọ́n fi ń kọ́wọ́ ti ètò tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣe. Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí tó ń wá nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Lẹ́sẹ̀ kan náà, bó ṣe jẹ́ pé ńṣe ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú náà, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá máa ń ṣọ́ra láti má ṣe máa gbé ẹni kẹ́ni lára ẹrú náà ga. Kò sí Kristẹni ẹni àmì òróró tí ẹ̀mí Ọlọ́run yàn lóòótọ́ táá máa fẹ́ tàbí táá máa retí láti gba irú ìkàsí bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 10:25, 26; 14:14, 15.
20 Bóyá “ará ilé,” tó jẹ́ apá kan àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ni wá ni o tàbí ara àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, ẹ jẹ́ ká fi ṣe ìpinnu wa láti máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú olóòótọ́ ìríjú náà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀. Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” ká sì máa fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ títí dé òpin.—Mát. 24:13, 42.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” àwọn wo sì ni ará ilé?
• Báwo lẹnì kan ṣe ń mọ̀ pé òun ti gba ìpè ti ọ̀run?
• Àwọn wo ló ni ojúṣe pípèsè àkọ̀tun oúnjẹ tẹ̀mí?
• Èrò wo ló yẹ kí àwọn ẹni òróró ní nípa ara wọn?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Lóde òní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Ìṣètò yìí ò sì yàtọ̀ sí ti ọ̀rúndún kìíní