Irúgbìn Òtítọ́ Dé Àwọn Ibi Jíjìnnà Réré
Irúgbìn Òtítọ́ Dé Àwọn Ibi Jíjìnnà Réré
ÌLÚ Tuva tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wà ní ìpẹ̀kun lápá gúúsù ìlú Siberia, orílẹ̀-èdè Mongolia sì wà lápá gúúsù àti ìlà oòrùn. Àdúgbò kan tó jìnnà gan-an, tí kò sì rọrùn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìlú Tuva ń gbé. Àmọ́, nígbà kan, àwùjọ àwọn èèyàn kan rìnrìn àjò láti àwọn ibi jíjìnnà kan nílùú Tuva lọ sílùú Kyzyl, tó jẹ́ olú ìlú Tuva fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan. Arábìnrin Maria tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà nílùú Kyzyl, gbọ́ nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì rí i gẹ́gẹ́ bí àǹfààní ńlá kan láti wàásù ìhìn rere.
Maria sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Níléèwé tí mo ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́, wọ́n ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan tó dá lórí béèyàn ṣe lè tọ́jú àwọn tó ti sọ lílo oògùn, ọtí líle, àtàwọn nǹkan míì nílòkulò di bárakú. Nǹkan bí àádọ́ta èèyàn ló sì máa wá láti àwọn ibi tó jìnnà jù lọ nílùú Tuva. Lára àwọn tó máa wá ni, àwọn olùkọ́, àwọn onímọ̀ nípa ìrònú àti ìwà ẹ̀dá, àwọn tó ń rí sí àbójútó àwọn ọmọdé àtàwọn míì.” Àǹfààní ńlá lèyí jẹ́ fún Maria, àmọ́ kò rọrùn rárá. Ó sọ pé: “Ojú máa ń tì mí gan-an, kò sì rọrùn fún mi láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà. Àmọ́, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi nígboyà kí n lè borí ìbẹ̀rù, kí n sì lè lo àǹfààní yìí láti wàásù.” Ǹjẹ́ ó ṣàṣeyọrí?
Maria ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Mo rí ìwé ìròyìn Jí! tó sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀rù. Mo ronú pé, ‘ó ṣeé ṣe káwọn onímọ̀ nípa ìrònú àti ìwà ẹ̀dá fẹ́ láti kà á,’ ni mo bá mú ìwé ìròyìn náà lọ síléèwé. Lọ́jọ́ yẹn, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ tó fẹ́ lọ síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà wá sí ọ́fíìsì mi, mo sì fún un ní ìwé ìròyìn náà. Tayọ̀tayọ̀ ló fi gbà á. Ó tiẹ̀ sọ pé ẹ̀rù máa ń ba òun náà. Lọ́jọ́ kejì, mo fún un ní ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní. Ó tún gba ìyẹn náà tayọ̀tayọ̀. Bí mo ṣe rí i pé inú ẹ̀ dùn láti gba àwọn ìwé náà, mo wá ronú pé àwọn olùkọ́ tó kù náà lè fẹ́ láti kà á. Ni mo bá gbé páálí kan ìwé Àwọn Ọ̀dọ̀ Béèrè àtàwọn ìwé míì lọ síléèwé.” Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi gba ìwé náà tán. Maria sọ pé: “Àwọn mélòó kan lára àwọn tí wọ́n wà níbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú olùkọ́ tí mo fún ní ìwé Àwọn Ọ̀dọ̀ Béèrè wá sí ọ́fíìsì mi, wọ́n béèrè pé, ‘Ibo ni wọ́n ti ń pín ìwé yẹn ná?’” Ibi tó yẹ kí wọ́n wá gan-an rèé!
Ọjọ́ Sátidé ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà parí. Maria ò ní ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ náà. Ló bá kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ síbi mélòó kan lórí tábìlì lọ́fíìsì ẹ̀. Ó wá kọ nǹkan sójú pátákó ìkọ̀wé pé: “Ẹ̀yin Olùkọ́ Ọ̀wọ́n! Ẹ lè mú àwọn ìwé yìí fún ara yín àti fáwọn ọ̀rẹ́ yín. Àwọn ìwé yìí á ràn yín lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yín àti nínú ìdílé yín.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Màríà sọ pé: “Nígbà tí mo pa dà dé ọ́fíìsì mi lọ́jọ́ yẹn, wọ́n ti kó èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ni mo bá tún lọ gba àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìwé ìròyìn sí i.” Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn fi máa parí, Maria ti fìwé ìròyìn okòó-dín-nírínwó [380] síta, ó sì fìwé ńlá àádọ́sàn-án lé mẹ́ta [173] àti ìwé pẹlẹbẹ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] síta. Nígbà táwọn tó wá síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà pa dà sí àdádó tí wọ́n ń gbé tí wọ́n sì ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dání. Maria sọ pé, “Inú mi dùn gan-an pé, ní báyìí, irúgbìn òtítọ́ ti dé àpá ibi jíjìnnà jù lọ nílùú Tuva!”—Oníw. 11:6.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 32]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
RỌ́ṢÍÀ
ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TUVA