Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’

‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’

‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’

Ó LÉ ní ọgbọ̀n iṣan tó wà ní iwájú orí mọ́ gbogbo ojú èèyàn. Mẹ́rìnlá nínú iṣan wọ̀nyí ló máa ṣiṣẹ́ pọ̀ kéèyàn tó lè rẹ́rìn-ín lásán! Ká sọ pé kò sáwọn iṣan yìí, ṣó o rò pé ó máa rọrùn fáwa èèyàn láti máa bá ara wa sọ̀rọ̀ ká sì máa gbádùn rẹ̀? Kò dájú. Àmọ́ ní ti àwọn adití, iṣẹ́ táwọn iṣan iwájú orí mọ́ gbogbo ojú èèyàn ń ṣe ju pé kó kàn mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ gbádùn mọ́ni. Lílò tí wọ́n ń lo àwọn iṣan yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ìfaraṣàpèjúwe míì ni ọ̀nà pàtàkì kan tí wọ́n ń gbà sọ èrò wọn jáde. Ó máa ń ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu láti rí i pé èèyàn lè fi èdè àwọn adití ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó díjú.

Lóde òní, àwọn adití jákèjádò ayé ti rí ojú ẹnì kan tó ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fani mọ́ra ju ti èèyàn èyíkéyìí lọ. A lè sọ pé wọ́n ti ń “rí ojú Jèhófà.” (Ẹ́kís. 34:24) Àmọ́ kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń fìfẹ́ hàn sáwọn adití. Ó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ bọ̀ látìgbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Léf. 19:14) Lóde òní, a ṣì ń rí i kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn adití. “Ìfẹ́ [Ọlọ́run ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Bí ọ̀pọ̀ adití ṣe ń ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run yìí ló mú ká lè sọ pé wọ́n ń rí ojú rẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe ní ìmọ̀ pípéye nígbà tó jẹ́ pé wọn kì í lè fetí gbọ́ ọ̀rọ̀? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bí èdè àwọn adití ti ṣe pàtàkì tó fáwọn adití.

Ojú Ni Wọ́n Fi Ń Gbọ́ Ọ̀rọ̀

Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò tọ̀nà làwọn èèyàn máa ń sọ nípa àwọn adití àti èdè wọn. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká sọ àwọn òótọ́ kan tó yẹ ká mọ̀ nípa wọn. Àwọn adití lè wakọ̀. Ó máa ń ṣòro fún wọn gan-an láti mọ ohun tẹ́nì kan ń sọ nípa wíwo ẹnu onítọ̀hún. Òmíràn ni pé èdè àwọn adití kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìwé àwọn afọ́jú, kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ kéèyàn kàn máa fara ṣàpèjúwe ohun téèyàn ń sọ. Oríṣiríṣi èdè àwọn adití ló wà káàkiri ayé. Bákan náà, ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà nínú bí wọ́n ṣe ń sọ oríṣi èdè àwọn adití kan náà láwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ṣé àwọn adití lè kàwé? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan mọ̀wé kà, síbẹ̀ ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ wọn láti kàwé. Kí nìdí? Ìdí ni pé inú ọ̀rọ̀ tá a ń sọ lohun tá à ń kọ sílẹ̀ ti wá. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bí ọmọ tó gbọ́ ọ̀rọ̀ ṣe máa ń kọ́ èdè. Gbàrà tí wọ́n bá ti bí ọmọ kan ló ti máa ń gbọ́ táwọn tó wà ládùúgbò rẹ̀ ń sọ èdè kan. Láìpẹ́, òun náà á máa sọ̀rọ̀ tá-tà-tá, títí táá fi lè máa sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ ní èdè tó ń gbọ́. Kò sí pé ó ṣẹ̀sẹ̀ ń kọ́ èdè náà, ohun tó ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ lòun náà ń sọ. Torí náà, nígbà tí ọmọ tó gbọ́rọ̀ bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé, gbogbo ohun tó kù kò ju pé kó dá àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fetí gbọ́ mọ̀ tó bá rí i lákọọ́lẹ̀.

Jẹ́ ká tún sọ pé o wà ní orílẹ̀-èdè míì, wọ́n sì fi ọ́ sínú yàrá kan tí wọ́n fi gíláàsì ṣe, tí o kò sì lè gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ níta. O ò sì tíì gbọ́ kí wọ́n sọ èdè orílẹ̀-èdè yẹn rí. Lójoojúmọ́, àwọn èèyàn ibẹ̀ á wá síbi gíláàsì yẹn wọ́n á sì máa gbìyànjú láti bá ẹ sọ̀rọ̀. O ò gbọ́ ohùn wọn. O kàn ṣáà rí i pé ẹnu wọn ń là ó sì ń pa dé. Nígbà tí wọ́n wá rí i pé ohun táwọn ń sọ kò yé ọ, wọ́n wá lọ kọ ọ̀rọ̀ náà sínú ìwé kan, wọ́n wá fi hàn ẹ́ látinú gíláàsì náà. Wọ́n rò pé ó yẹ kó o lóye ohun táwọn kọ. Ṣé o rò pé wàá lóye wọn? Ó dájú pé ó máa ṣòro fún ẹ gan-an láti lè bá wọn sọ̀rọ̀ nírú ipò yìí. Kí nìdí? Torí pé èdè tó ò gbọ́ rí ni wọ́n kọ sílẹ̀ fún ẹ pé kó o kà. Bí ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ adití tá a bá ní kó kàwé ṣe rí gan-an nìyẹn.

Èdè àwọn adití jẹ́ ọ̀nà tó dáa jù lọ táwọn adití fi ń sọ̀rọ̀. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé wọ́n máa ń fi ọwọ́ àtàwọn ẹ̀yà ara míì ṣe àmì síwá sẹ́yìn, sọ́tùn-ún sósì, láti ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn wọn. Kí ohun tí wọ́n ń sọ tó lè nítumọ̀, ó ní bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ ṣe ojú wọn àti ẹ̀yà ara wọn míì, èyí sì gbọ́dọ̀ bá ìlànà gírámà èdè àwọn adití mu. Nípa báyìí èèyàn á lè máa sọ èdè tá a ń fojú rí táá fi jẹ́ pé ojú la lè fi gbọ́ ọ.

Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo bí adití kan ṣe ń ṣe ọwọ́, ojú àti ara rẹ̀ ló nítumọ̀. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ojú nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ kì í kàn-án ṣe láti fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ yẹn lásán. Ó nípa pàtàkì tó ń kó nínú gírámà èdè àwọn adití. Bí àpẹẹrẹ: Tí adití kan bá gbé ìpéǹpéjú sókè nígbà tó ń béèrè ìbéèrè, ìyẹn lè fi hàn pé ó ń fẹ́ kẹ́ni tó bi ní ìbéèrè dáhùn sínú tàbí kó dáhùn bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Tí kò bá gbé ìpéǹpéjú sókè, ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ń béèrè ìbéèrè bíi, ta ni, kí ni, ibo, ìgbà wo, kí nìdí tàbí báwo. Bí wọ́n ṣe ṣẹnu lè fi bí nǹkan ṣe tóbi tó hàn tàbí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe lágbára tó. Báwọn adití bá ṣe mi orí wọn, bí wọ́n bá ṣe gbé èjìká wọn, bí wọ́n bá ṣe mi ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn àti bí wọ́n bá ṣe ṣẹ́jú máa ń gbé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ń sọ yọ.

Lílo ara lọ́nà yìí máa ń jẹ́ kí àwọn tó gbọ́ èdè àwọn adití lóye ohun tí wọ́n ń sọ kí wọ́n sì gbádùn rẹ̀. Tí adití kan tó gbédè náà dáadáa bá ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà yìí láti sọ̀rọ̀, kò sírú ọ̀rọ̀ tí kò ní lè fi sọ, ì báà jẹ mọ́ ewì tàbí ọ̀rọ̀ míì tó ṣòro ṣàlàyé. Kódà ó lè fi sọ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí kó fi ṣàwàdà, ó sì lè fi ṣàlàyé ohun tó ṣeé fojú rí tàbí tí kò ṣeé fojú rí.

Fídíò Èdè Àwọn Adití Mú Nǹkan Rọrùn Sí I

Téèyàn bá lè fi èdè àwọn adití gbé ìmọ̀ Jèhófà jáde lọ́nà tó ṣeé fojú rí, á jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn adití láti lè lóye ìhìn rere náà bí ẹni tó fetí gbọ́ ọ, wọ́n á sì lè “ní ìgbàgbọ́” nínú Ẹni tó ni ìhìn rere náà. Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń sapá gan-an láti lè wàásù fáwọn adití kárí ayé, a sì ń ṣe àwọn fídíò tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Róòmù 10:14) Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a ní ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè méjìdínlọ́gọ́ta [58] kárí ayé tó ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè àwọn adití, ó sì tó ogójì èdè àwọn adití [40] tá a túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí nípasẹ̀ fídíò tá a ṣe sórí àwo DVD. Ǹjẹ́ gbogbo àwọn akitiyan yìí tiẹ̀ sèso rere?

Ẹnì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jeremy, táwọn òbí rẹ̀ jẹ́ adití sọ pé: “Mo rántí ọjọ́ kan tí bàbá mi lo ọ̀pọ̀ wákàtí nínú yàrá láti lè kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́, tó sì jẹ́ pé ìpínrọ̀ díẹ̀ ló lè kà, tó sì ń gbìyànjú láti lóye wọn. Lójijì ó kàn sáré jáde látinú yàrá tìdùnnú-tìdùnnú, ó wá fi èdè àwọn adití sọ fún mi pé: ‘Ó ti yé mi!’ Lẹ́yìn náà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àpilẹ̀kọ náà fún mi. Ọmọ ọdún méjìlá péré ni mí nígbà yẹn. Mo wá sáré ka ìpínrọ̀ yẹn, mo wá fi èdè adití sọ fún bàbá mi pé: ‘Dádì mi ò rò pé nǹkan tó túmọ̀ sí nìyẹn o. Ohun tó túmọ̀ sí ni . . .’ Dádì wá dá ọ̀rọ̀ náà mọ́ mi lẹ́nu, ó sì pa dà sínú yàrá ẹ̀, kó bàa lè mọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sílẹ̀ náà. Mi ò lè gbàgbé bó ṣe dun bàbá mi tó àti bó ṣe yà mí lẹ́nu tó bí mo ṣe ń wò ó tó ń pa dà sínú yàrá rẹ̀. Àmọ́ ní báyìí táwọn ìtẹ̀jáde ti wà lédè àwọn adití nínú fídíò lórí àwo DVD, ó ti ṣeé ṣe fún bàbá mi láti lóye àwọn ìsọfúnni náà dáadáa. Bí mo ṣe máa ń rí ayọ̀ tó ń hàn lójú rẹ̀ nígbà tó bá ń sọ èrò rẹ̀ nípa Jèhófà máa ń mú kí n kún fún ọpẹ́.”

Tún wo àpẹẹrẹ àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n bá Jessenia, ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ adití láti orílẹ̀-èdè Chile sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí ìyá Jessenia ti gbà wọ́n láyè pé kí wọ́n fi fídíò Ìwé Ìtàn Bíbélì tó wà lórí àwo DVD ní Èdè Adití Lọ́nà ti Chile han Jessenia, wọ́n sọ pé: “Nígbà tí Jessenia bẹ̀rẹ̀ sí í wo fídíò náà, ńṣe ló bú sẹ́rìn-ín, lẹ́yìn náà ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Nígbà tí màmá rẹ̀ béèrè pé kí ló ń pa á lẹ́kún, ó sọ pé òun gbádùn nǹkan tóun ń wò. Màmá ẹ̀ wá rí i pé gbogbo nǹkan tó wò nínú fídíò náà ló yé e.”

Obìnrin kan tó jẹ́ adití ní ìgbèríko kan lórílẹ̀-èdè Venezuela ti bí ọmọ kan, ó sì ti lóyún èkejì. Bẹ́ẹ̀ òun àti ọkọ rẹ̀ kò fẹ́ bímọ míì torí pé wọn ò lówó tí wọ́n á fi tọ́ ọ. Torí náà wọ́n gbèrò àtiṣẹ́ oyún náà. Lọ́jọ́ kan àwọn Ẹlẹ́rìí kan yà lọ́dọ̀ wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n fi ẹ̀kọ́ 12 hàn wọ́n nínú fídíò Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Venezuela. Ẹ̀kọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìṣẹ́yún àti ìpànìyàn. Lẹ́yìn náà, obìnrin náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé wọ́n kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó sọ pé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ àwọn yẹn ti mú káwọn pinnu pé àwọn ò ní ṣẹ́ oyún náà mọ́. Tí kì í bá ṣe ti fídíò ìtẹ̀jáde lédè àwọn adití tó wà lórí àwo DVD, bí wọn ò bá ṣe pa ọmọ kan dà nù nìyẹn!

Arábìnrin adití kan tó ń jẹ́ Lorraine ṣàlàyé pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan kan ò yé mi dáadáa nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ńṣe ló dà bí àwòrán kan tó gé kélekèle tí wọ́n wá ní kéèyàn tò pa pọ̀, téèyàn ò sì ráwọn ègé rẹ̀ kan. Àmọ́ nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í ní fídíò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lédè àwọn adití, mo wá lóye òtítọ́ dáadáa.” Arákùnrin adití kan tó ń jẹ́ George tó ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ọdún méjìdínlógójì [38] sẹ́yìn sọ pé: “Kò sí àní-àní pé téèyàn bá lóye ọ̀rọ̀ kan fúnra rẹ̀, ó máa ń jẹ́ kéèyàn níyì lọ́wọ́ ara ẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan, ó sì máa ń fini lọ́kàn balẹ̀. Mo rí i pé àwọn fídíò èdè àwọn adití tó wà lórí àwo DVD ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti dàgbà nípa tẹ̀mí.”

“Ìpàdé Tí Wọ́n Ń Ṣe Lédè Mi Gan-an Nìyí!”

Yàtọ̀ sí àwọn fídíò tá a ṣe lédè àwọn adití, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti láwọn ìjọ tá a ti ń ṣe ìpàdé ní kìkì èdè àwọn adití. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100] ìjọ elédè àwọn adití tó wà kárí ayé. Nínú àwọn ìjọ yìí, èdè àwọn adití ni wọ́n fi ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀, wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà táwọn adití gbà ń ronú, ìyẹn lédè wọn. Wọ́n ń kọ́ wọn lọ́nà tó bá àṣà àti òye wọn mu.

Ǹjẹ́ dídá tá à ń dá ìjọ sílẹ̀ lédè àwọn adití tìẹ ṣàǹfààní kankan? Wo ìrírí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Cyril tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1955. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé wa débi tí òye ẹ̀ gbé e dé, ó sì máa ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé. Nígbà míì ó máa ń rẹ́ni túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ fún un lédè àwọn adití, ìgbà míì sì wà tí kò ní rí. Láwọn ìgbà tí kò bá sẹ́ni tó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ fún un, àwọn ará máa ń kọ ohun tí wọ́n ń sọ lórí pèpéle sínú ìwé fún un. Ọdún 1989 ni wọ́n tó dá ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití sílẹ̀ ní New York City lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] tó ti di Ẹlẹ́rìí. Báwo lọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Cyril tó jẹ́ ará ìjọ yẹn? Ó ní: “Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá jáde látinú igbó kìjikìji tàbí látinú òkùnkùn àjà ilẹ̀ sínú ìmọ́lẹ̀. Ìpàdé tí wọ́n ń ṣe lédè mi gan-an nìyí!”

Inú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití làwọn adití ti lè máa pàdé déédéé láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì sìn ín. Ibẹ̀ ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lè máa láyọ̀ láàárín ara wọn. Nínú ayé yìí, táwọn adití ti sábà máa ń nímọ̀lára pé àwọn dá nìkan wà, tí wọn kì í sì í rẹ́ni bá rìn torí pé wọn ò lè sọ̀rọ̀, àwọn ìjọ yìí ló jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń rẹ́ni tí wọ́n lè jùmọ̀ máa sọ̀rọ̀ pọ̀, tí wọ́n á sì máa bá rìn. Nínú àwọn ìjọ yìí, àwọn adití lè kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì mú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà gbòòrò sí i. Ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn adití tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti sìn gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò kíkún. Àwọn adití kan ti kó lọ sórílẹ̀-èdè míì, kí wọ́n lè lọ ran àwọn adití tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà. Àwọn arákùnrin tó jẹ́ adití ti di olùkọ́ tó dáńgájíá, olùṣọ́ àgùntàn àti ẹni tó mọ ètò ṣe, èyí mú kí ọ̀pọ̀ wọn tóótun láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.

Ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìjọ tó jẹ́ elédè àwọn adití ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríka, wọ́n sì tún ní nǹkan bí ọgọ́rin àwùjọ míì tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn àdití. Ní orílẹ̀-èdè Brazil, ìjọ elédè àwọn adití tó ọ̀ọ́dúnrún [300], wọ́n sì ní àwùjọ̀ tó lé ní ìrínwó [400]. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún [300] ìjọ elédè àwọn adití tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ó lé ní ọgbọ̀n ìjọ elédè àwọn adití tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n sì ní àwùjọ tó jẹ́ mẹ́tàléláàádọ́fà [113] míì. Èyí kàn wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ìbísí tá à ń rí kárí ayé ni.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń ṣe àpéjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè ní kìkì èdè àwọn adití. Lọ́dún tó kọjá, ó lé ní ọgọ́fà [120] àpéjọ àgbègbè tá a ṣe kárí ayé lónírúurú èdè àwọn adití. Àwọn àpéjọ yìí jẹ́ káwọn adití tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí rí i pé àwọn jẹ́ ara ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó ń jàǹfààní látinú oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sásìkò.

Arákùnrin adití kan tó ń jẹ́ Leonard, ti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Ó sọ pé: “Mo ti mọ̀ tipẹ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́. Àmọ́, ìdí tó fi fàyè gba ìjìyà kò yé mi dáadáa. Nígbà míì èyí máa ń mú kí n bínú sí Ọlọ́run. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń sọ àsọyé kan ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe lédè àwọn adití, ibẹ̀ ni mo ti wá mọ ohun tó fà á tó fi fàyè gba ìjìyà. Lẹ́yìn tásọyé náà parí, ìyàwó mi wá rọra fi ìgúnpá gbún mi lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì bi mí pé: ‘Ṣó ti wá yé ẹ báyìí?’ Tọkàntọkàn ni mo fi sọ pé bẹ́ẹ̀ ni! Lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, mo dúpẹ́ pé mi ò fi Jèhófà sílẹ̀. Kò sígbà tí mi ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ mi ò tíì mọ̀ ọ́n dáadáa. Ní báyìí, mo ti wá mọ̀ ọ́n!”

Ọkàn Wọn Kún fún Ọpẹ́

Kí làwọn adití ń rí lójú Jèhófà bó ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́? Ohun tí wọ́n ń rí ni ìfẹ́, ìyọ́nú, ìdájọ́ òdodo, ìdúróṣinṣin, inú rere onífẹ̀ẹ́ àti ọ̀pọ̀ nǹkan míì.

Àwọn adití tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí jákèjádò ayé ń rí ojú Jèhófà, wọn á sì túbọ̀ máa rí i kedere jù bẹ́ẹ̀ lọ. Pẹ̀lú ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn adití, ó ti ‘mú kí ojú rẹ̀ tàn sí wọn lára.’ (Núm. 6:25) Inú àwọn adití wọ̀nyí mà ń dùn gan-an ni o, pé wọ́n ti mọ Jèhófà!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100] ìjọ elédè àwọn adití tó wà kárí ayé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ojú Jèhófà ti tàn yòò sára àwọn adití