Ṣé Àwọn Òbí Mi—Ni Yóò Pinnu Ẹ̀sìn Mi Àbí Èmi Fúnra Mi?
Ṣé Àwọn Òbí Mi—Ni Yóò Pinnu Ẹ̀sìn Mi Àbí Èmi Fúnra Mi?
LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ Poland, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Inú ẹ̀sìn tí wọ́n bí mi sí nìyí, ibẹ̀ sì ni màá kú sí.” Gbólóhùn yìí fi hàn pé lójú tiwọn, ẹ̀sìn téèyàn bá bá lọ́wọ́ àwọn òbí èèyàn ló yẹ kó máa ṣe. Ṣé èrò táwọn èèyàn ní nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn ládùúgbò rẹ náà nìyẹn? Kí ni irú èrò bẹ́ẹ̀ sábàá máa ń fà? Ó máa ń jẹ́ kí ìsìn di ohun táwọn èèyàn ń fara lásán ṣe tí kò dọ́kàn wọn tàbí kó di ààtò ìsìn ìdílé lásán. Ǹjẹ́ irú èyí lè ṣẹlẹ̀ sí ìjọsìn àwọn kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn àwọn tó jẹ́ pé àwọn òbí wọn tàbí àwọn òbí wọn àgbà ló fi ojú wọn mọ òtítọ́ àgbàyanu yìí?
Tímótì kò jẹ́ kí irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sóun. Ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn Ọlọ́run ló kọ́ ọ tó fi dẹni tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tòótọ́ tó sì tún nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àti “ìgbà ọmọdé jòjòló” ni Tímótì ti mọ Ìwé Mímọ́. Nígbà tó yá, ó wá dá Tímótì pẹ̀lú ìyá rẹ̀ àti ìyá ìyá rẹ̀ lójú pé ẹ̀sìn Kristẹni ni ìsìn tòótọ́. Ó dẹni tá a ‘yí lérò padà láti nígbàgbọ́’ nínú àwọn ohun tó gbọ́ látinú Ìwé Mímọ́ nípa Jésù Kristi. (2 Tím. 1:5; 3:14, 15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà, àwọn ọmọ fúnra wọn ló ní láti pinnu pé Jèhófà làwọn máa sìn.—Máàkù 8:34.
Tá a bá fẹ́ máa fi ìfẹ́ sin Jèhófà, ká sì máa di ìṣòtítọ́ wa mú láìwo ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀, olúkúlùkù wa ló gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rí tó dájú láti fi ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn. Ìgbà yẹn ni ìgbàgbọ́ wa yóò tó lágbára táá sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in.—Éfé. 3:17; Kól. 2:6, 7.
Ojúṣe Àwọn Ọmọ
Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Albert a tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí, sọ pé, “Kì í ṣe pé mi ò gbà pé ẹ̀sìn tòótọ́ ni ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó ṣòro fún mi láti gba ohun tí wọ́n ń sọ nípa bó ṣe yẹ kí n lo ìgbésí ayé mi.” Tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ ni ẹ́, ìwọ náà lè nírú èrò yìí. Àmọ́ ńṣe lò bá gbìyànjú láti wo àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa gbé ayé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa gbé e, kó o bàa lè rí ìdùnnú. (Sm. 40:8) Albert sọ pé: “Ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà. Ó kọ́kọ́ máa ń ṣòro fún mi, àmọ́ mo ní láti tiraka kí n lè gbà á. Kòpẹ́ kò jìnnà tí mo fi wá rí i pé màá wúlò fún Ọlọ́run tí mo bá gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́ lójú rẹ̀. Èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ.” Tíwọ náà bá sún mọ́ Jèhófà tó o sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀, á máa wù ẹ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa ṣe.—Sm. 25:14; Ják. 4:8.
Ronú nípa ayò kan tó o ti ta rí, irú bí ayò Héb. 10:24, 25.
lúdò tàbí ayò míì. Bí o kò bá mọ bí wọ́n ṣe ń ta á, o ò ní lè ta á dáadáa, ó tiẹ̀ lè sú ọ pàápàá. Tó o bá kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta á, tó o sì wá mọ̀ ọ́n ta, ó dájú pé ayò náà yóò máa wù ẹ́ ta, kódà wàá máa wá ọ̀nà láti rẹ́ni tó o máa bá ta ayò náà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ̀? Bọ́rọ̀ àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni náà ṣe rí nìyẹn. Torí náà, máa fúnra rẹ wá àyè láti máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀. Máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni déédéé. Àpẹẹrẹ rẹ tiẹ̀ tún lè máa fún àwọn míì níṣìírí, láìwo ti ọjọ́ orí rẹ!—Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn tó bá kan sísọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ fáwọn èèyàn. Ìfẹ́ ló yẹ kó máa sún ẹ ṣe é, kò yẹ kó jẹ́ àfipáṣe. Bi ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ máa sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn? Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó mú mi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?’ Ó yẹ kó o mọ̀ pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Ó tipasẹ̀ Jeremáyà sọ pé: “Ní ti gidi, ẹ óò wá mi, ẹ ó sì rí mi, nítorí ẹ ó fi gbogbo ọkàn-àyà yín wá mi.” (Jer. 29:13, 14) Kí lèyí ń béèrè pé kó o ṣe? Jakub sọ pé: “Mo ní láti tún ọ̀nà tí mò ń gbà ronú ṣe. Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni mo ti ń lọ sípàdé tí mo sì ń jáde òde ẹ̀rí, àmọ́ ó ti fẹ́ dohun tá à ń ṣe déédéé tí kò fi bẹ́ẹ̀ nítumọ̀ sí mi mọ́. Ìgbà tí mo wá mọ Jèhófà dáadáa, tí àjọṣe mi pẹ̀lú rẹ̀ sì dára gan-an ni mo tó wá fọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́.”
Tó o bá ń bá àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn kẹ́gbẹ́, ó máa nípa rere lórí bó o ṣe máa gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ sí. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Torí náà, àwọn tó ń lépa nǹkan tẹ̀mí tí wọ́n sì ń rí ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni kó o máa bá ṣọ̀rẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jola sọ pé: “Mo rí i pé bí mo ṣe ń bá àwọn ọ̀dọ́ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn kẹ́gbẹ́ máa ń fún mi níṣìírí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ gan-an nígbà tí mo ń jáde òde ẹ̀rí déédéé.”
Ojúṣe Àwọn Òbí
Jola tún sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi pé wọ́n kọ́ mi nípa Jèhófà.” Èyí fi hàn pé àwọn òbí lè nípa tó pọ̀ lórí ìpinnu táwọn ọmọ wọn máa ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin, baba, . . . ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí yìí fi hàn kedere pé ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà Jèhófà, kì í ṣe ọ̀nà tara wọn. Dípò tẹ́ ẹ ó fi máa tẹ ohun tẹ́ ẹ fẹ́ mọ́ àwọn ọmọ yín lọ́kàn, ó máa dáa gan-an tẹ́ ẹ bá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa lépa bí wọ́n á ṣe gbé ìgbésí ayé tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu!
Ẹ lè gbin ọ̀rọ̀ Jèhófà sọ́kàn àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì máa ‘sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí ẹ bá jókòó nínú ilé yín àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.’ (Diu. 6:6, 7) Tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Ewa àti Ryszard tí wọ́n bí ọmọkùnrin mẹ́ta sọ pé: “A máa ń sọ̀rọ̀ gan-an nípa onírúurú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn téèyàn lè ní.” Kí ló wá tẹ̀yìn rẹ̀ wá? Wọ́n sọ pé, “Ìgbà táwọn ọmọ wa ṣì kéré ni wọ́n ti fẹ́ forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, nígbà tó yá wọ́n fúnra wọn pinnu láti ṣe ìrìbọmi. Nígbà tí wọ́n sì dàgbà, a rí èyí tó lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, a sì rí èyí tó di aṣáájú-ọ̀nà.”
Ó tún ṣe pàtàkì káwọn òbí fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ryszard sọ pé: “A pinnu pé a ò ní gbé ìgbé ayé méjì, ìyẹn ni pé, a ò ní máa ṣe nǹkan kan nílé ká sì máa ṣe nǹkan míì lójú àwọn ará.” Torí náà ẹ̀yin òbí, ẹ béèrè lọ́wọ́ ara yín pé: ‘Kí làwọn ọmọ mi ń rí nínú ìgbésí ayé mi? Ṣé wọ́n ń rí i pé lóòótọ́ ni mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Ǹjẹ́ wọ́n ń kíyè sí ìfẹ́ yìí nínú àdúrà mi àti nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ mi tí mo ń ṣe déédéé? Ṣé wọ́n ń rí i nínú ọwọ́ tí mo fi mú lílọ sóde ẹ̀rí, ọ̀ràn eré ìnàjú, ọ̀ràn ohun ìní tara àti ohun tí mò ń sọ nípa àwọn ará nínú ìjọ?’ (Lúùkù 6:40) Àwọn ọmọ yóò máa rí bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ lójoojúmọ́, wọ́n á sì mọ̀ bóyá ohun tó ò ń sọ bá ohun tó ò ń ṣe mu.
Ìbáwí tún ń kó ipa pàtàkì nínú ọ̀ràn ọmọ títọ́. Àmọ́ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni pé kí á “tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.” (Òwe 22:6) Ewa àti Ryszard sọ pé, “A máa ń wá àyè láti bá ọmọ kọ̀ọ̀kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiẹ̀.” Lóòótọ́, àwọn òbí ló ní láti pinnu bóyá àwọn á máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Bó ti wù kó rí, àwọn òbí ní láti máa kíyè sí ọmọ kọ̀ọ̀kan kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó yẹ fún un. Èyí gba pé kẹ́ ẹ mọwọ́ yí pa dà, kẹ́ ẹ sì máa lo ìfòyemọ̀. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí ẹ ó kàn fi máa sọ fáwọn ọmọ yín pé orin kan kò dára, ńṣe ló yẹ kẹ́ ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n á ṣe ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa ọ̀ràn náà àti ohun táwọn ìlànà Bíbélì sọ nípa rẹ̀.
Àwọn ọmọ lè mọ nǹkan tẹ́ ẹ fẹ́ kí wọ́n ṣe gan-an, ó sì lè dàbí pé wọ́n máa ń fẹ́ ṣe é. Síbẹ̀, ẹ ní láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa dénú ọkàn wọn. Ẹ rántí pé “ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yóò fà á jáde.” (Òwe 20:5) Ẹ máa lo ìfòyemọ̀, ẹ máa wá àwọn àmì tí ẹ óò fi mọ bí ìṣòro kan bá fara sin sínú ọkàn àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì tètè wá nǹkan ṣe láti yanjú ìṣòro náà. Ẹ fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ yín lógún, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bíi pé ẹ̀ ń fẹ̀sùn kàn wọ́n, kẹ́ ẹ máa béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ tinú wọn. Síbẹ̀, ẹ má ṣe jẹ kó dà bíi pé ẹ̀ ń da ìbéèrè bò wọ́n o. Àníyàn yín lórí wọn kò ní já sásán, ó máa dénú ọkàn wọn.
Ojúṣe Ìjọ
Ìwọ gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ǹjẹ́ o lè ran àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ láti mọrírì òtítọ́ tó jẹ́ ogún iyebíye táwọn òbí wọn ti fi lé wọn lọ́wọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe àwọn òbí ni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn, àwọn míì nínú ìjọ lè kún wọn lọ́wọ́, pàápàá jù lọ àwọn alàgbà. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ṣèrànwọ́ fáwọn ọmọ tó jẹ́ pé ọ̀kan lára òbí wọn ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí.
Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wúlò àti pé a mọyì àwọn? Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mariusz tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ kan lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Àwọn alàgbà ní láti máa bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́. Kò yẹ kó jẹ́ nígbà tí ìṣòro bá yọjú nìkan, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n máa bá wọn sọ̀rọ̀ láwọn ìgbà míì pẹ̀lú, irú bí ìgbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí, lẹ́yìn ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n bá ń gbafẹ́.” O lè ní káwọn ọ̀dọ́ sọ èrò tí wọ́n ní nípa ìjọ. Irú ìjíròrò àtọkànwá bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ sún mọ́ àwọn ará, kí wọ́n sì rí i pé ara ìjọ làwọn náà jẹ́.
Tó o bá jẹ́ alàgbà, ṣé o mọ gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ yín? Arákùnrin Albert tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ti di alàgbà báyìí, àmọ́ òun náà ní oríṣiríṣi àdánwò nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ó sọ pé, “Nígbà témi náà wà lọ́dọ̀, ẹni tó yẹ kí wọ́n máa ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ rẹ̀ dáadáa ni mí.” Àwọn alàgbà tún lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ jẹ́ àwọn lógún nípa gbígbàdúrà pé kí wọ́n máa ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí.—2 Tím. 1:3.
Ó yẹ kẹ́ ẹ jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ máa lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè gbájú mọ́ lílépa àwọn nǹkan ayé. Ǹjẹ́ ẹ̀yin àgbà lè máa jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn, kó o sì mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́? Máa wá àkókò láti máa bá wọn ṣeré, jẹ́ kára tù wọ́n, kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ, kí wọ́n sì mú ẹ lọ́rẹ̀ẹ́. Jola sọ pé: “Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan wà tó fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn. Òun lẹni àkọ́kọ́ tí mo bá jáde òde ẹ̀rí, tí òde ẹ̀rí sì ń wù mí lọ torí pé ó tinú mi wá.”
Ìpinnu Tìẹ Fúnra Rẹ
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ bi ara yín pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni mò ń lépa? Tí mi ò bá tíì ṣèrìbọmi, ṣé mò ń lépa àtiṣe é?’ Ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú ẹ pinnu láti ṣe ìrìbọmi, kò yẹ kó jẹ́ torí pé àwọn ará ilé yín ṣèrìbọmi.
Ǹjẹ́ kí Jèhófà di Ọ̀rẹ́ fún ọ, kí òtítọ́ sì jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ pé: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Jèhófà yóò wà pẹ̀lú rẹ, tó o bá ṣì ń jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó sì dájú pé yóò máa fún ẹ lókùn, “yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo [rẹ̀] dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísá. 41:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Gbìyànjú láti fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìfẹ́ àtọkànwá téèyàn ní fún Jèhófà ló ń mú kéèyàn ṣe ìrìbọmi