Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi

Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi

Ẹ Máa Hùwà Bíi Kristi

‘Ẹ ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.’—RÓÒMÙ 15:5.

1. Kì nìdí tó fi yẹ ká wá ọ̀nà láti máa hùwà bíi Kristi?

 JÉSÙ KRISTI sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Mát. 11:28, 29) Bí Jésù ṣe pe àwọn èèyàn tìfẹ́tìfẹ́ yìí fi hàn pé ó ní ìfẹ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Kò sí ẹlòmíì tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ tó dà bíi ti Jésù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, tó sì lágbára, síbẹ̀ ó gba tàwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ rò, ó sì máa ń ṣe wọ́n jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.

2. Èwo nínú àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fìwà jọ Jésù la máa gbé yẹ̀ wò?

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti méjì tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bá a ṣe lè máa hùwà bíi Jésù, kí ìgbésí ayé wa sì máa fi “èrò inú ti Kristi” hàn. (1 Kọ́r. 2:16) A máa jíròrò ọ̀nà márùn-ún pàtàkì tá a lè gbà fìwà jọ Jésù. Àwọn ọ̀nà náà ni: (1) Ìwà tútù àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀, (2) inú rere, (3) ìgbọràn sí Ọlọ́run, (4) ìgboyà àti (5) ìfẹ́ tí kìí kùnà.

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ìwà Tútù Kristi

3. (a) Kí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ìrẹ̀lẹ̀? (b) Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí àìlera àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

3 Jésù ẹni pípé, tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, fínnúfíndọ̀ wá sáyé láti wá ṣe iṣẹ́ ìsìn láàárín àwọn èèyàn aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Àwọn kan lára wọn ló sì pa á nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Síbẹ̀, gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń láyọ̀, tó sì máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu. (1 Pét. 2:21-23) Tá a bá “tẹjú mọ́” àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, ìyẹn ni pé ká ronú nípa rẹ̀, yóò jẹ́ ká máa hùwà bíi Jésù, nígbà táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá tàbí tí àìpé bá mú kí wọ́n ṣe ohun kan tó dùn wá. (Héb. 12:2) Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bọ́ sábẹ́ àjàgà òun, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun. (Mát. 11:29) Kí ni wọ́n máa rí kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù jẹ́ onínú tútù, ó sì máa ń fi sùúrù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò láìka àwọn àṣìṣe wọn sí. Lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù kú, ó fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ò ní gbàgbé láé, ìyẹn ni ẹ̀kọ́ nípa jíjẹ́ “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.” (Ka Jòhánù 13:14-17.) Lẹ́yìn náà, nígbà tí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù kùnà láti “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” ńṣe ni Jésù bá wọn kẹ́dùn, ó mọ̀ pé wọ́n jẹ́ aláìlera. Ó béèrè pé “Símónì, o ń sùn ni? Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa wá sínú ìdẹwò. Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Máàkù 14:32-38.

4, 5. Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú tó yẹ wo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará?

4 Kí la máa ṣe tá a bá rí ẹnì kan tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó lẹ́mìí ìbánidíje, tó máa ń tètè bínú tàbí tí kì í tètè ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn táwọn alàgbà bá fún un tàbí èyí tó wà látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (Mát. 24:45-47) Ó lè rọrùn fún wa láti gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn èèyàn ayé Sátánì, àmọ́ ó lè ṣòro fún wa láti gbójú fo irú àwọn àìpé bẹ́ẹ̀ lára àwọn ará. Tí àléébù àwọn ẹlòmíì bá tètè ń múnú bí wa, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo ní “èrò inú ti Kristi”?’ Gbìyànjú láti máa fi sọ́kàn pé Jésù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ múnú bí òun, kódà nígbà tí àìpé ẹ̀dá ò jẹ́ kí wọ́n ní èrò inú ti Kristi.

5 Gbé ọ̀ràn ti àpọ́sítélì Pétérù yẹ̀ wò. Nígbà tí Jésù sọ fún Pétérù pé kó jáde kúrò nínú ọkọ̀, kó sì máa rìn bọ̀ wá bá òun lórí omi, Pétérù rìn lórí omi. Àmọ́ nígbà tó yá ó bẹ̀rù nítorí ìjì tó ń jà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ṣé Jésù bínú, kó wá sọ fún Pétérù pé: “Ohun tó yẹ ọ́ nìyẹn! Ìyẹn á kọ́ ẹ lọ́gbọ́n lọ́jọ́ míì?” Rárá o! “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ní nína ọwọ́ rẹ̀, Jésù dì í mú, ó sì wí fún un pé: ‘Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?’” (Mát. 14:28-31) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin kan ń ṣe ohun tó fẹ́ fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò tó, ṣé àwa náà lè ràn án lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ lè túbọ̀ lágbára sí i, ká ṣe bíi ti Jésù tó na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti ran Pétérù lọ́wọ́? Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe fi inú tútù bá Pétérù lò nìyẹn.

6. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lórí ọ̀ràn wíwá ipò ńlá?

6 Pétérù tún wà lára àwọn àpọ́sítélì tó ń ṣe awuyewuye lórí ẹni tó tóbi jù láàárín wọn. Jákọ́bù àti Jòhánù fẹ́ jókòó sọ́wọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì Jésù nínú Ìjọba rẹ̀. Nígbà tí Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú gan-an. Jésù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà àwọn èèyàn ibi tí wọ́n dàgbà sí ló nípa lórí wọn. Ó pè wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” Lẹ́yìn náà, Jésù wá fi ara rẹ̀ ṣe àpẹẹrẹ, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”—Mát. 20:20-28.

7. Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kàn wa ṣe lè ṣàlékún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ?

7 Tá a bá ń ronú nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù, yóò jẹ́ ká máa “hùwà bí ẹni tí ó kéré jù” láàárín àwọn ará wa. (Lúùkù 9:46-48) Èyí á sì túbọ̀ ṣàlékún ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa. Jèhófà dà bíi baálé ilé kan, ó fẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ “máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan.” (Sm. 133:1) Jésù gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ pé káwọn Kristẹni tòótọ́ wà ní ìṣọ̀kan, kí “ayé lè ní ìmọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi jáde àti pé ìwọ nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti nífẹ̀ẹ́ mi.” (Jòh. 17:23) Ìyẹn fi hàn pé ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa ń fi wá hàn pé ọmọlẹ́yìn Kristi la jẹ́. Ká lè máa gbádùn ìṣọ̀kan yìí, a gbọ́dọ̀ máa wo àìpé àwọn míì bí Kristi ṣe ń wò ó. Jésù máa ń dárí jini, ó sì kọ́ni pé àfi táwa náà bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá la fi lè rí ìdáríjì gbà.—Ka Mátíù 6:14, 15.

8. Kí la lè rí kọ́ látara àwọn tó ti ń sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún?

8 A tún lè rí púpọ̀ kọ́ nípa bá a ó ṣe máa hùwà bíi Kristi tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àwọn tó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Bíi ti Jésù, àwọn wọ̀nyí sábà máa ń lóye àìpé àwọn èèyàn. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé fífi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn bí Kristi ti ń ṣe yóò jẹ́ ká lè “ru àìlera àwọn tí kò lókun.” Wọ́n tún mọ̀ pé ó máa ń fi kún ìṣọ̀kan àárín wa. Láfikún sí i, ó tún ń fún ìjọ lápapọ̀ ní ìṣírí láti máa hùwà bíi Kristi. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù làwọn náà fẹ́ fáwọn ará. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní, pé pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ lè fi ẹnu kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.” (Róòmù 15:1, 5, 6) Ó dájú pé bá a ṣe ń fi ìṣọ̀kan sin Jèhófà ń mú ìyìn bá a.

9. Kí nìdí tá a fi nílò ẹ̀mí mímọ́ ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

9 Ó hàn nínú ọ̀rọ̀ Jésù pé jíjẹ́ ẹni “rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” tan mọ́ níní ìwà tútù tó jẹ́ ara èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Torí náà, yàtọ̀ sí kíkọ́ àpẹẹrẹ Jésù, a tún nílò ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ká bàa lè máa tẹ̀ lẹ́ àpẹẹrẹ Jésù lọ́nà tó tọ́. A gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ká sì sapá láti máa so èso rẹ̀, ìyẹn “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gál. 5:22, 23) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù tí Jésù fi lélẹ̀, a óò máa ṣe ohun tí Jèhófà Baba wa ọ̀run fẹ́.

Jésù Fi Inú Rere Bá Àwọn Èèyàn Lò

10. Báwo ni Jésù ṣe lo inú rere?

10 Inú rere náà wà nínú èso tẹ̀mí. Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń fi inú rere hàn sáwọn èèyàn. Gbogbo àwọn tó wá sọ́dọ̀ Jésù ló rí i pé ó “fi inú rere gbà wọ́n.” (Ka Lúùkù 9:11.) Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú inú rere tí Jésù fi hàn? Onínúure èèyàn máa ń jẹ́ ẹni tó dùn-ún bá rìn, èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ẹlẹ́yinjú àánú. Bí Jésù ṣe rí gan-an nìyẹn. Àánú àwọn èèyàn máa ń ṣe é “nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.”—Mát. 9:35, 36.

11, 12. (a) Sọ ìgbà kan tí Jésù fi ìyọ́nú hàn. (b) Kí lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò níbí yìí?

11 Kì í ṣe pé Jésù kàn máa ń káàánú àwọn èèyàn nìkan ni, ó tún máa ń ṣe nǹkan kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Odindi ọdún méjìlá ni ẹ̀jẹ̀ fi ń sun lára obìnrin kan báyìí. Obìnrin yìí sì mọ̀ pé lábẹ́ Òfin Mósè, ipò tí òun wà yìí ti sọ òun àti ẹnikẹ́ni tó bá fọwọ́ kan òun di aláìmọ́. (Léf. 15:25-27) Síbẹ̀, irú ẹni tí obìnrin yìí mọ Jésù sí, àti ìwà tó mọ̀ pé ó máa ń hù jẹ́ kó dá a lójú pé ó máa wo òun sàn. Obìnrin náà ṣáà ń sọ pé: “Bí mo bá fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi yóò dá.” Ó ṣọkàn akin, ó fọwọ́ kan ẹ̀wù Jésù, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin yìí sì mọ̀ ọ́n lára pé a ti mú òun lára dá.

12 Jésù mọ̀ pé ẹnì kan ti fọwọ́ kan òun, ó sì wò yíká láti mọ ẹni náà. Torí obìnrin náà mọ̀ pé òun ti rú Òfin, ẹ̀rù bà á, ó rò pé Jésù máa bá òun wí, ló bá wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Ǹjẹ́ Jésù bá obìnrin tí ìyà ń jẹ́ yẹn wí? Kò sóhun tó jọ ọ́! Ńṣe ló fọkàn obìnrin náà balẹ̀, ó sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà.” (Máàkù 5:25-34) Ẹ ò rí i pé ìtùnú gbáà ló máa jẹ́ fún un láti gbọ́ irú ọ̀rọ̀ rere bẹ́ẹ̀!

13. (a) Báwo ni ìwà Jésù ṣe yàtọ̀ sí tàwọn Farisí? (b) Báwo ni Jésù ṣe ń hùwà sáwọn ọmọdé?

13 Kristi kò dà bí àwọn Farisí tó jẹ́ ọ̀dájú, kò sígbà kankan tó lo agbára rẹ̀ láti dá kún ìnira àwọn èèyàn. (Mát. 23:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi sùúrù kọ́ àwọn èèyàn nípa ọ̀nà Jèhófà. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni Jésù jẹ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó dùn-ún bá rìn, ó nífẹ̀ẹ́ wọn ó sì máa ń fi inú rere hàn sí wọn. (Òwe 17:17; Jòh. 15:11-15) Kódà ara tu àwọn ọmọdé lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì hàn gbangba pé òun náà kó wọn mọ́ra. Ọwọ́ rẹ̀ kò dí débi tí kò fi ní ráyè gbọ́ táwọn ọmọdé. Lákòókò kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó ń ka ara wọn sí pàtàkì bíi tàwọn aṣáájú ìsìn tó wà yí wọn ká gbìyànjú láti dá àwọn èèyàn dúró bí wọ́n ṣe ń mú àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ Jésù kó lè fọwọ́ kàn wọ́n. Inú Jésù kò dùn sóhun táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe yìí. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun, nítorí ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó lo àwọn ọmọdé láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kan, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnì yòówù tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò wọ inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Máàkù 10:13-15.

14. Àǹfààní wo làwọn ọmọ máa rí táwọn ará bá fún wọn láfiyèsí tó yẹ?

14 Ronú nípa bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára àwọn ọmọ náà nígbà tí wọ́n bá dàgbà, tí wọ́n bá ń rántí pé Jésù Kristi ‘gbé àwọn sí apá rẹ̀, ó sì súre fún àwọn.’ (Máàkù 10:16) Nígbà táwọn ọmọdé òní náà bá dàgbà lọ́la, wọn yóò máa rántí àwọn alàgbà àtàwọn míì tó fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, àwọn ọmọ tí àwọn ará ìjọ bá fìfẹ́ hàn sí lọ́nà yìí yóò ti kékeré mọ̀ pé ẹ̀mí Jèhófà wà lára àwọn èèyàn rẹ̀.

Jẹ́ Onínúure Nínú Ayé Tó Kún fún Ìwà Òǹrorò Yìí

15. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé inú rere ṣọ̀wọ́n lóde òní?

15 Lóde òní ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé kò sáyè fáwọn láti máa fi inú rere hàn sáwọn èèyàn. Torí náà, ojoojúmọ́ làwọn èèyàn Jèhófà máa ń rí báwọn èèyàn ṣe ń fi ẹ̀mí ayé yìí hàn, yálà níléèwé, lẹ́nu iṣẹ́, tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó lè dùn wá tá a bá rí i tí wọ́n hùwà tí kò dáa sí wà, àmọ́ kò yẹ kó yà wá lẹ́nu. Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ tẹ́lẹ̀ fún wa pé, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé yóò máa gbé àwọn Kristẹni tòótọ́ pàdé àwọn èèyàn tó jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá.”—2 Tím. 3:1-3.

16. Báwo la ṣe lè máa lo inú rere bíi ti Kristi nínú ìjọ?

16 Àmọ́, ìtura wà nínú ìjọ Kristẹni tòótọ́, èyí sì mú kó yàtọ̀ sí ayé tí kò sí inú rere yìí. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yóò máa ṣàlékún àlááfíà tó wà nínú ìjọ. Báwo la ṣe lè ṣe é? Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wà nínú ìjọ ló nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí, torí pé wọ́n ń ní ìṣòro àìlera àtàwọn ìṣòro lílekoko míì. Ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, àwọn ìṣòro náà lè pọ̀, àmọ́ wọn kì í ṣe nǹkan tójú ò rí rí. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn Kristẹni ní irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. Àmọ́, báwọn Kristẹni ṣe rí ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà yẹn ni àwa náà ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú, ó ní: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹs. 5:14) Èyí gba pé ká jẹ́ onínúure bíi Kristi.

17, 18. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ inú rere Jésù?

17 Ojúṣe àwa Kristẹni ni láti ‘fi inú rere gba àwọn arákùnrin wa,’ ká máa ṣe wọ́n bí Jésù ì bá ṣe ṣe wọ́n, ká máa fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sáwọn tá a ti mọ̀ látọjọ́ pípẹ́ àtàwọn tá ò rí rí. (3 Jòh. 5-8) Bí Jésù ṣe lo ìdánúṣe láti fi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn, ó yẹ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀, kí ara máa tu àwọn èèyàn tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ wa.—Aísá. 32:2; Mát. 11:28-30.

18 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè fi hàn pé a jẹ́ onínúure nípa ṣíṣe ohun táá fi hàn pé a fi ọ̀ràn àwọn ará wa sọ́kàn. Wá ọ̀nà tí wàá fi lè ṣe é, kó o sì múra tán láti ṣe é. Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Èyí túmọ̀ sí pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, ká máa ṣe àwọn ẹlòmíì jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ká sì máa fi inú rere hàn sí wọn, ká mọ bá a ṣe lè máa fi “ìfẹ́ tí kò ní àgàbàgebè” hàn. (2 Kọ́r. 6:6) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ìfẹ́ Kristi rèé, ó ní: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́r. 13:4) Dípò tá ó fi máa di àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sínú, ẹ jẹ́ ká máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfé. 4:32.

19. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi inú rere bíi ti Kristi hàn sáwọn èèyàn?

19 Tá a bá ń sapá láti máa fi inú rere bíi ti Kristi hàn nígbà gbogbo àti ní gbogbo ọ̀nà, ọ̀pọ̀ ìbùkún ló máa tibẹ̀ wá. Ẹ̀mí Jèhófà yóò lè máa ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìjọ, èyí á sì jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù. Láfikún sí i, tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, tá a sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, a ó jọ máa fi ayọ̀ àti ìṣọ̀kan sin Ọlọ́run yóò sì máa múnú rẹ̀ dùn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sapá nígbà gbogbo láti jẹ́ oníwà tútù àti onínúure bíi Jésù nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà”?

• Báwo ni Jésù ṣe lo inú rere?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ìwà tútù àti inú rere bíi ti Kristi hàn nínú ayé aláìpé yìí?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Tí ìgbàgbọ́ ẹnì kan bá ń mì bíi ti Pétérù, ṣé a ó ran ẹni náà lọ́wọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Báwo la ṣe lè mú kí ìjọ jẹ́ ibi tí inú rere ti máa gbilẹ̀?