Mo Rí Ohun Rere Gbé Ṣe Nígbèésí Ayé Mi
Mo Rí Ohun Rere Gbé Ṣe Nígbèésí Ayé Mi
Gẹ́gẹ́ bí Gaspar Martínez ṣe sọ ọ́
Ní ṣókí ìtàn ìgbésí ayé mi fẹ́ jọ ìtàn ọmọ oko kan tó jẹ́ tálákà, àmọ́ tó lọ di ọlọ́rọ̀ nígbà tó dé ìlú ńlá. Ṣùgbọ́n ẹ óò rí i pé kì í ṣe irú ọ̀rọ̀ tí mo ń wá kiri ni mo wá rí.
OKO kan tó jẹ́ aṣálẹ̀ tó wà lágbègbè Rioja ní àríwá orílẹ̀-èdè Sípéènì ni mo gbé dàgbà, ìyẹn láàárín ọdún 1931 sí ọdún 1940. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó di dandan fún mi láti kúrò nilé ìwé, àmọ́ nígbà yẹn mo ti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Àwa méje làwọn òbí mi bí. Oko lèmi àtàwọn ọmọ yòókù máa ń lọ kùrà, bá ò bá máa tọ́jú àwọn àgùntàn, a ó máa ro oko kékeré tá a ń dá.
Nítorí pé tálákà ni wá, a gbà pé dandan ni kéèyàn lówó kó sì lọ́rọ̀ láyé yìí. A bẹ̀rẹ̀ sí í jowú àwọn tó ní lọ́wọ́ jù wá lọ. Àmọ́ bíṣọ́ọ̀bù sọ nígbà kan rí pé abúlé yìí ní wọ́n ti múra sí ọ̀ràn ẹ̀sìn jù lọ nínú gbogbo ẹkùn òun. Kò mọ̀ nígbà yẹn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn wọ̀nyí ló máa pa ẹ̀sìn Kátólíìkì tì tó bá yá.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wá Ohun Tó Dára Jù
Mo gbé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Mercedes lábúlé wa níyàwó. Kò pẹ́ kò jìnnà tá a fi bí ọmọkùnrin kan. Lọ́dún 1957, a kó lọ sí ìlú kan tó wà nítòsí tó ń jẹ́ Logroño. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ gbogbo ìdílé wa kó wá síbẹ̀. Nígbà tó yá, mo wá rí i pé bí mi ò ṣe mọ iṣẹ́ ọwọ́ kankan yìí, ó máa ṣòro fún mi láti rí iṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé. Mo wà bẹ̀rẹ̀ sí í wá ohun tó máa fọ̀nà hàn mí kiri. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí nínú ilé ìkówèésí tó wà ládùúgbò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tí mò ń wá.
Nígbà tó yá, mo gbọ́ nípa ètò orí rédíò kan tó sọ nípa béèyàn ṣe lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípasẹ̀ ìkọ̀wéránṣẹ́. Kò pẹ́ sígbà tí mo parí ẹ̀kọ́ Bíbélì náà ni àwọn kan lára ẹlẹ́sìn Evangelical Protestants wá bá mi. Nígbà tí mo lọ sí ilé ìjọsìn wọn bí ẹ̀ẹ̀melòó kan, mo rí ẹ̀mí ìbánidíje tó wà láàárín àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn nínú ẹ̀sìn náà. Ni mi ò bá lọ síbẹ̀ mọ́, mo wá gbà pé ọ̀kan náà ni gbogbo ẹ̀sìn.
Ojú Mi Là
Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Eugenio wá sílé wa lọ́dún 1964. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Mi ò tíì gbọ́ nípa ẹ̀sìn yìí rí. Àmọ́, ó wù mí gan-an kí n sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Mo rò pé mo ti ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ dáadáa. Mo ń ju àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan tí mo kọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ìkọ̀wéránṣẹ́ sí i. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé mo gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ rere nípa àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Protestant kan, àmọ́ lọ́kàn mi lọ́hùn ún, mi ò gbà wọ́n gbọ́.
Lẹ́yìn tá a ti jọ fi ọ̀pọ̀ àkókò jíròrò nígbà Sm. 37:11, 29; Aísá. 9:6, 7; Mát. 6:9, 10.
méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo gbà pé ọ̀jáfáfá ni Eugenio nínú ká ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó yà mí lẹ́nu gan-an bó ṣe ń ṣí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sì ń ṣàlàyé bí wọ́n ṣe bá ohun tó ń sọ mu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kàwé tó mi. Eugenio fi hàn mí nínú Bíbélì pé àkókò òpin la wà yìí àti pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú Párádísè dé láìpẹ́. Nǹkan wọ̀nyí wú mi lórí gan-an ni.—Kíá ni mo gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo ń kọ́ ló tuntun létí mi, ó sì wọ̀ mí lọ́kàn. Àǹfààní kan ti ṣí sílẹ̀ fún mi wàyí, èyí tó máa jẹ́ kí n fi ìgbésí ayé mi ṣe ohun tó dára jù lọ. Mi ò ní nǹkan tí mò ń wá kiri mọ́. Gbogbo kìràkìtà mi láti rọ́wọ́ mú láwùjọ kò jámọ́ nǹkan lójú mi mọ́. Bákan náà, ìṣòrò ti iṣẹ́ mi tí kò tó gbọ́ bùkátà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí mi mọ́. Kódà ọkàn mi balẹ̀ pé àìsàn àti ikú pàápàá kò ní sí mọ́.—Aísá. 33:24; 35:5, 6; Ìṣí. 21:4.
Ojú ẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí mi nípa ohun tí mo ń kọ́, mo sì ń ṣàlàyé fún wọn pé Ọlọ́run ṣèlérí pé Párádísè máa wà lórí ilẹ̀ ayé tí àwọn olóòótọ́ yóò sì máa gbénú rẹ̀ títí láé.
Àwọn Mọ̀lẹ́bí Mi Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Láìpẹ́, àwa bíi méjìlá kan pinnu láti máa pàdé pọ̀ ní gbogbo ọ̀sán ọjọ́ Sunday nílé bàbá kan tó jẹ́ àbúrò bàbá mi láti jíròrò àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì. A máa ń lo wákàtí méjì tàbí mẹ́ta lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí Eugenio rí i pé àwọn tó pọ̀ nínú ẹbí mi nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó ṣètò láti máa kọ́ ìdílé kọ̀ọ̀kan lẹ́kọ̀ọ́.
Mo ní àwọn mọ̀lẹ́bí míì ní ìlú kan tó ń jẹ́ Durango, tó fi nǹkan bí ọgọ́fà [120] kìlómítà jìnnà síbi tí mò ń gbé. Kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó ń gbébẹ̀ nígbà yẹn. Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo lọ lo ìsinmi ọjọ́ díẹ̀ lọ́dọ̀ wọn kí n lè fi àǹfààní yẹn ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tuntun tí mo kọ́ fún wọn. Nígbà yẹn, àwa bíi mẹ́wàá là ń pé jọ lálaalẹ́, mo sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ títí dìgbà tí ilẹ̀ á fi fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Tìdùnnú-tìdùnnú ni gbogbo wọn fi fetí sí ohun tí mò ń sọ. Nígbà tí mo parí ìbẹ̀wò ráńpẹ́ tí mo ṣe sọ́dọ̀ wọn, mo fi Bíbélì díẹ̀ àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, à ń kàn sí ara wa déédéé.
Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí dé sí ìlú Durango níbi tí ẹnì kankan kò tíì wàásù rí, wọ́n rí èèyàn méjìdínlógún tí ara wọn ti wà lọ́nà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí náà dùn láti ṣètò fún ìdílé kọ̀ọ̀kan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Títí di àkókò yẹn, Mercedes ìyàwó mi kò tíì tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì, àmọ́ ìbẹ̀rù èèyàn ni kò jẹ́ kó tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe pé kò nífẹ̀ẹ́ sí i. Lákòókò yẹn, wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Sípéènì, torí náà, ìyàwó mi rò pé àwọn aláṣẹ máa lé àwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì kúrò nílé ẹ̀kọ́, a ó sì dẹni ẹ̀gàn láwùjọ. Àmọ́ nígbà tó rí i pé gbogbo ìdílé wa ló tẹ́wọ́ gba òtítọ́, òun náà fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Láàárín ọdún méjì, ogójì èèyàn nínú ẹbí mi ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ láti sin Ọlọ́run. Àwọn ará ilé mi náà wá ń lépa ohun tí mò ń lépa nígbèésí ayé. Mo mọ̀ pé mo ti rí ohun pàtàkì gbé ṣe. Ọlọ́run ti fi ọrọ̀ tẹ̀mí bù kún wa jìngbìnnì.
Bí Mo Ti Ń Dàgbà Sí I Bẹ́ẹ̀ Ni Ìgbésí Ayé Mi Túbọ̀ Ń Nítumọ̀
Ohun tí mo fi ogún ọdún tó tẹ̀ lé èyí ṣe ni pé mo gbájú mọ́ títọ́ àwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì àti ríran ìjọ tá a wà lọ́wọ́. Nígbà tí èmi àti ìyàwó mi kọ́kọ́ kó dé ìlú Logroño, nǹkan bí ogún péré ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àpapọ̀ iye àwọn èèyàn ibẹ̀ tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Kò pẹ́ tá a débẹ̀ tí mo fi ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí mò ń bójú tó nínú ìjọ.
Nígbà tí mo wá pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta, àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ wa ti ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ pa láìròtẹ́lẹ̀, bí iṣẹ́ ṣe bọ́ lọ́wọ́ mi nìyẹn. Ó ti jẹ́ ìfẹ́ mi láti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tẹ́lẹ̀, nítorí náà mo lo àǹfààní iṣẹ́ tó bọ́ lọ́wọ́ mi yìí láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n fún mi kò tó nǹkan, kò sì tó gbọ́ bùkátà. Ibi iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ kan tí ìyàwó mi ń ṣe ló ti ń rí owó tó
fi ń ràn mí lọ́wọ́. Bá a ṣe ń rówó gbọ́ bùkátà ara wa nìyẹn, a kò sì ṣàìní ohun tó yẹ. Mo ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyàwó mi sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbà dégbà, ó sì ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an.Ní bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ìyàwó mi máa ń fún Merche, obìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé ọkọ ní ìwé ìròyìn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó wà lọ́mọdé. Merche ń ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tọkàntọkàn, ìyàwó mi sì rí i pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Níkẹyìn, Merche gbà ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́. Àmọ́ ọkọ rẹ̀, Vicente máa ń mu ọtí lámujù, bó bá sì ṣe ń rí iṣẹ́ kan ni iṣẹ́ ọ̀hún máa ń bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí èyí, kò lè gbọ́ bùkátà ìyàwó rẹ̀, ọtí àmujù rẹ̀ sì ti fẹ́ tú ìgbéyàwó wọn ká.
Ìyàwó mi dá a lábàá fún Merche pé kó jẹ́ kí Vicente ọkọ rẹ̀ àtèmi ríra, Vicente sì gbà níkẹyìn. Lẹ́yìn tí mo lọ sọ́dọ̀ Vicente nígbà mélòó kan, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà, ó kọ́kọ́ ń ṣíwọ́ ọtí mímu fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́tà, nígbà tó yá, ó ṣe é fún odindi ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Níkẹyìn, ó jáwọ́ nínú ọtí mímu pátápátá. Ìrísí rẹ̀ wá dùn-ún wò gan-an, ìdílé rẹ̀ sì wà níṣọ̀kan. Òun àtìyàwó rẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn ń ran ìjọ kékeré kan tó wà ní Canary Islands lọ́wọ́ gan-an. Ibẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní báyìí.
Mo Ń Rántí Ohun Rere Tí Mo Ti Fayé Mi Ṣe
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára mọ̀lẹ́bí mi tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ti kú nísinsìnyí, ńṣe làwọn ìbátan mi ń pọ̀ sí i nínú òtítọ́, Ọlọ́run sì ti bù kún wa jìngbìnnì. (Òwe 10:22) Ó mà múnú mi dùn gan-an ni o, láti mọ̀ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ogójì ọdún sẹ́yìn, pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọ àti ọmọ ọmọ wọn ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà nìṣó!
Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí, púpọ̀ nínú wọn ló jẹ́ alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, a sì tún rí aṣáájú-ọ̀nà lára wọn. Àkọ́bí mi àti ìyàwó rẹ̀ ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Madrid lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Nígbà tí mo di Ẹlẹ́rìí, àwa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] Ẹlẹ́rìí ló wà ní Sípéènì. Nísinsìnyí a ti lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000]. Mo ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù alákòókò-kíkún tí mo ń ṣe. Mo sì kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run pé ó jẹ́ kí n lè lo ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lọ́nà tó lárinrin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò kàwé púpọ̀, mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká látìgbà dégbà.
Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, mo rí i pé gbogbo àwọn èèyàn abúlé mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kó kúrò níbẹ̀ tán. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín ipò òṣì mú kí gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ fi oko àti ilé wọn sílẹ̀ láti wá ìgbé ayé rere lọ. Ó dùn mọ́ mi pé, ọ̀pọ̀ nínú wọn, títí kan èmi náà ló ti rí ọrọ̀ tẹ̀mí. A ti wá mọ̀ pé ìgbésí ayé nítumọ̀ àti pé sísin Jèhófà ń mú ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ wá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo mọ̀lẹ́bí Arákùnrin Martínez ló wà nínú òtítọ́