Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí Jèhófà Ṣe Láti Dá Ọ Nídè?

Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí Jèhófà Ṣe Láti Dá Ọ Nídè?

Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí Jèhófà Ṣe Láti Dá Ọ Nídè?

“Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, nítorí ó ti yí àfiyèsí rẹ̀, ó sì ti ṣe iṣẹ́ ìdáǹdè fún àwọn ènìyàn rẹ̀.”—LÚÙKÙ 1:68.

1, 2. Kí la lè fi ṣàkàwé bí ipò tá a wà ti le tó, àwọn ìbéèrè wo la ó sì jíròrò?

 RÒ Ó wò ná, ká ní o wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn nílé ìwòsàn. O wà ní wọ́ọ̀dù tí wọ́n gba àwọn tí àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan tí ò gbóògùn ń ṣe sí. Ọkàn rẹ balẹ̀ díẹ̀ nígbà tó o gbọ́ pé dókítà kan ń wá oògùn tó máa wo àrùn náà. Ara rẹ wà lọ́nà láti gbọ́ ibi tí dókítà náà máa bá ọ̀rọ̀ yẹn dé. Lọ́jọ́ kan, ó gbọ́ pé wọ́n ti rí oògùn tó lè wo àrùn náà! Dókítà tó ṣe ìwádìí náà ti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó kó tó lè rí oògùn náà ṣe. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Ó dájú pé wàá dúpẹ́ lọ́wọ́ dókítà náà gidigidi, wàá sì bọ̀wọ̀ fún ún tórí pé ó gba ìwọ àti ọ̀pọ̀ èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú.

2 Ọ̀ràn yẹn lè fẹ́ dà bí ìròyìn kàyéfì kan, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé irú ipò tí gbogbo èèyàn wà nìyẹn. Ipò tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa wà tiẹ̀ burú ju èyí tá a sọ yẹn lọ fíìfíì. A nílò ẹnì kan tó máa gbà wá sílẹ̀ lójú méjèèjì. (Ka Róòmù 7:24.) Jèhófà ti ṣe ohun tó pọ̀ gan-an láti gbà wá sílẹ̀. Ọmọ rẹ̀ náà ti yááfì àwọn nǹkan pàtàkì lórí ọ̀ràn yìí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè mẹ́rin pàtàkì yìí yẹ̀ wò. Kí nìdí tá a fi nílò ìdáǹdè? Kí ni ìdáǹdè wa ná Jésù? Kí ló ná Jèhófà? Báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ìdáǹdè tí Ọlọ́run pèsè fún wa?

Ìdí Tá A Fi Nílò Ìdáǹdè

3. Ọ̀nà wo ni ẹ̀ṣẹ̀ gbà jọ àjàkálẹ̀ àrùn?

3 Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí ti sọ, àjàkálẹ̀ àrùn tó burú jù lọ nínú ìtàn aráyé ni àrùn gágá tó jà lọ́dún 1918 tó sì pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé. A rí àwọn àrùn míì tó ń ṣọṣẹ́ ju àrùn gágá lọ lọ́nà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye ẹni táwọn àrùn náà kọ lù lè má pọ̀ tó ti àrùn gágá, àwọn tó pọ̀ jù nínú àwọn tí irú àwọn àrùn bẹ́ẹ̀ kọ lù ló máa ń kú. a Ṣùgbọ́n tá a bá wá fi ẹ̀ṣẹ̀ wé irú àjàkálẹ̀ àrùn bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Rántí ohun tí Róòmù 5:12 sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” Gbogbo èèyàn pátá ni ẹ̀ṣẹ̀ ti ràn nítorí pé gbogbo ẹ̀dá èèyàn aláìpé ló máa ń dẹ́ṣẹ̀. (Ka Róòmù 3:23.) Àwọn mélòó lára wọn ni ikú máa ń pa? Pọ́ọ̀lù sọ pé, ẹ̀ṣẹ̀ mú ikú bá “gbogbo ènìyàn.”

4. Lójú Jèhófà, báwo ni ẹ̀mí àwa èèyàn ṣe kúrú tó, báwo nìyẹn sì ṣe yàtọ̀ sí èrò ti ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí?

4 Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí kò fi bẹ́ẹ̀ ka ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sí àjàkálẹ̀ àrùn. Ó máa ń dùn wọ́n tí ẹnì kan bá kú láìtọ́jọ́, àmọ́ tí arúgbó bá kú, wọ́n gbà pé ó dára bẹ́ẹ̀, pé ńṣe ló re ibi tágbà ń rè. Àwọn èèyàn máa ń tètè gbàgbé ojú tí Ẹlẹ́dàá fi ń wo ikú àti ìwàláàyè. Ẹ̀mí àwa èèyàn kì í gùn rárá tó bí Ọlọ́run ṣe fẹ́. Àní sẹ́, kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó tíì lò tó “ọjọ́ kan” lójú Jèhófà. (2 Pét. 3:8) Ìdì nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé ẹ̀mí àwa èèyàn kúrú púpọ̀, ó fi wé koríko tó yọ tó sì rọ dà nù láìtọ́jọ́ tàbí èémí téèyàn mí jáde ní imú. (Sm. 39:5; 1 Pét. 1:24) Ó yẹ ká máa rántí kókó pàtàkì yẹn. Kí nìdí? Tá a bá mọ bí ohun tó dà bí àrùn tó ń bá aráyé fínra yìí ṣe burú tó, a ó mọyì ohun tó dà bí ìwòsàn tá a nílò, ìyẹn ìdáǹdè látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

5. Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ká pàdánù?

5 Ká tó lè mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ àti ipa tó ń ní lórí wa ṣe lágbára tó, a ní láti kọ́kọ́ mọ bí ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ fi ń dù wá ṣe pọ̀ tó. Ìyẹn lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa torí pé àǹfààní tá ò tíì ní rí ni ẹ̀ṣẹ̀ fi dù wá. Níbẹ̀rẹ̀, Ádámù àti Éfà ń gbádùn ìwàláàyè pípé. Ara wọn àti ọpọlọ wọn jí pépé, wọ́n lè ronú lọ́nà tó pé pérépéré, wọ́n sì lè darí èrò ọkàn wọn, ìṣe wọn àti bí ọ̀ràn ṣe má ń rí lára wọn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti máa bá ìgbésí ayé wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa lo àwọn ẹ̀bùn àgbàyanu wọn yìí títí láé. Àmọ́, nígbà tó yá, ńṣe ni wọ́n gbé ẹ̀bùn iyebíye tí wọ́n ní náà sọ nù. Nítorí wọ́n pinnu láti ṣẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n pàdánù irú ìwàláàyè tí Jèhófà fẹ́ fún wọn, wọ́n sì tún jẹ́ káwọn àtọmọdọ́mọ wọn pàdánù rẹ̀. (Jẹ́n. 3:16-19) Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n kó àrùn burúkú tá à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí, wọ́n sì tún kó o ran àwa àtọmọdọ́mọ wọn. Ó tọ́ bí Jèhófà ṣe dà wọ́n lẹ́bi. Àmọ́ ṣá o, ó fún àwa nírètí pé òun á dá wa nídè.—Sm. 103:10.

Ohun Tí Ìdáǹdè Wa Ná Jésù

6, 7. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe kọ́kọ́ fi hàn pé ohun kékeré kọ́ ni ìdáǹdè wa máa gbà? (b) Kí la rí kọ́ nínú ẹbọ tí Ébẹ́lì rú àtèyí táwọn àgbààgbà ayé àtijọ́ tó gbé ayé ṣáájú Òfin Mósè rú?

6 Jèhófà mọ̀ pé ohun kékeré kọ́ ló máa gbà láti dá àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà nídè. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15, a rí ohun tí ìdáǹdè máa gbà. Jèhófà yóò pèsè “irú-ọmọ” kan, tó máa gbà wá, tí yóò pa Sátánì run lọ́jọ́ kan, tí yóò sì tẹ̀ ẹ́ rẹ́ pátá. Àmọ́ ṣá o, ẹni tó máa gbà wá yẹn yóò jìyà kó tó lè rí i ṣe, ńṣe ló máa dà bíi pé wọ́n ṣe é léṣe ní gìgísẹ̀. Ìyẹn á roni lára gan-an, ó sì máa mú ẹ̀dùn ọkàn wá. Àmọ́ kí ló túmọ̀ sí? Kí ni ohun náà gan-an tí Àyànfẹ́ Jèhófà yẹn yóò ní láti fara dà?

7 Nítorí kí agbanilà náà lè gba aráyé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ó ní láti pèsè ohun ètùtù, ìyẹn ọ̀nà láti mú aráyé pa dà bá Ọlọ́run rẹ́, èyí tó ṣe nípa bó ṣe mú oró ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lórí wa. Báwo ló ṣe máa ṣe é? Àtìbẹ̀rẹ̀ la ti rí ẹ̀rí pé ẹbọ ló máa yanjú ọ̀ràn náà. Ébẹ́lì ọkùnrin olóòótọ́ àkọ́kọ́, rí ojú rere Jèhófà nígbà tó fi ẹran rúbọ sí i. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn àgbààgbà ayé àtijọ́ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run bíi Nóà, Ábúráhámù, Jékọ́bù àti Jóòbù rú irú ẹbọ kan náà, inú Ọlọ́run sì dún sí i. (Jẹ́n. 4:4; 8:20, 21; 22:13; 31:54; Jóòbù 1:5) Lẹ́yìn ìgbà náà, Òfin Mósè wá jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ dáadáa nípa ẹbọ rírú.

8. Kí ni àlùfáà àgbà máa ń ṣe ní Ọjọ́ Ètùtù lọ́dọọdún?

8 Lára àwọn ẹbọ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó wà tí Òfin Mósè ní kí wọ́n máa rú lọ́dọọdún ni ti Ọjọ́ Ètùtù. Lọ́jọ́ yẹn, àlùfáà àgbà máa ń ṣe ohun kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Yóò rú àwọn ẹbọ sí Jèhófà fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀. Ó máa kọ́kọ́ rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn àlùfáà, lẹ́yìn náà ló máa wá rú ti àwọn ẹ̀yà tí kì í ṣe àlùfáà. Àlùfáà àgbà yóò wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn tàbí nínú tẹ́ńpìlì. Òun nìkan ló lè wọ ibẹ̀, lọ́jọ́ kan ṣoṣo yẹn láàárín ọdún ló sì gbọ́dọ̀ wọ ibẹ̀. Yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ síwájú àpótí májẹ̀mú. Ìkùukùu tó mọ́lẹ̀ rekete máa ń fara hàn nígbà míì lókè àpótí mímọ́ náà, èyí tó ṣàpẹẹrẹ pé Jèhófà Ọlọ́run wà níbẹ̀.—Ẹ́kís. 25:22; Léf. 16:1-30.

9. (a) Ní Ọjọ́ Ètùtù, ta ni àlùfáà àgbà ṣàpẹẹrẹ, kí sì ni àwọn ẹbọ tó rú yẹn ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni wíwọ̀ tí àlùfáà àgbà wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ ṣàpẹẹrẹ?

9 Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ ìtúmọ̀ ohun tí àwọn nǹkan yẹn ṣàpẹẹrẹ. Ó fi hàn pé àlùfáà àgbà ṣàpẹẹrẹ Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi, nígbà tí àwọn ẹbọ tó ń rú náà sì ṣàpẹẹrẹ ikú ìrúbọ tí Kristi kú. (Héb. 9:11-14) Ẹbọ pípé yẹn yóò pèsè ètùtù gidi fún àwùjọ méjì. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, ìyẹn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. Àwùjọ kejì ni “àwọn àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) Wíwọ̀ tí àlùfáà àgbà wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ ṣàpẹẹrẹ bí Jésù yóò ṣe wọ ọ̀run lọ láti gbé ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run.—Héb. 9:24, 25.

10. Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà?

10 Ó ṣe kedere pé ìdáǹdè àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà yóò gba ìrúbọ ńlá. Mèsáyà ní láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ! Àwọn wòlíì inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣàlàyé òtítọ́ yìí lọ́nà tó ṣe kedere. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Dáníẹ́lì sọ gbangba pé wọn yóò ké “Mèsáyà Aṣáájú” kúrò, ìyẹn ni pé wọn yóò pa á, “láti ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà.” (Dán. 9:24-26) Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n yóò kọ Mèsáyà sílẹ̀, wọ́n á ṣenúnibíni sí i, wọ́n á sì pa á tàbí gún un, láti ru ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹ̀dá aláìpé.—Aísá. 53:4, 5, 7.

11. Àwọn ọ̀nà wo ni Ọmọ Jèhófà gbà fi hàn pé òun ṣe tán láti fi ara òun rúbọ nítorí ìdáǹdè wa?

11 Kí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run tó wá sáyé ló ti mọ ohun tí ìdáǹdè wa máa ná òun. Ó ní láti jìyà tó bùáyà, wọ́n á sì pa á. Nígbà tí Baba rẹ̀ ń sọ àwọn ohun tójú ẹ̀ máa rí fún un, ǹjẹ́ ó sá sẹ́yìn tàbí kó ṣọ̀tẹ̀? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fínnúfíndọ̀ tẹrí ba, ó fara mọ́ ìtọ́ni Baba rẹ̀. (Aísá. 50:4-6) Bákan náà, nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Kí nìdí? Ó fún wa ní ìdáhùn kan, ó ní: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” Ó tún fún wa ní ìdáhùn míì, ó ní: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 14:31; 15:13) Nítorí náà, ìdáǹdè wa jẹ́ nítorí ìfẹ́ tí Ọmọ Jèhófà ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ná an ní ìwàláàyè rẹ̀ pípé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, inú rẹ̀ dùn láti ṣe é nítorí ìdáǹdè wa.

Ohun Tí Ìdáǹdè Wa Ná Jèhófà

12. Ìfẹ́ inú ta ni ìràpadà jẹ́, kí sì nìdí tó fi pèsè rẹ̀?

12 Jésù kọ́ ni Ẹni tó pilẹ̀ ẹbọ ìràpadà náà, òun sì kọ́ ló ṣètò rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà ìdáǹdè yìí jẹ́ apá pàtàkì lára ìfẹ́ inú Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé pẹpẹ tó wà ní tẹ́ńpìlì, tí wọ́n máa ń rúbọ lórí rẹ̀, ṣàpẹẹrẹ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà. (Héb. 10:10) Nítorí náà, ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáǹdè wa nípasẹ̀ ẹbọ Kristi ti wá. (Lúùkù 1:68) Ó jẹ́ ẹ̀rí tó fi ìfẹ́ inú rẹ̀ pípé àti ìfẹ́ ńlá tó ní fún àwa èèyàn hàn.—Ka Jòhánù 3:16.

13, 14. Báwo ni àpẹẹrẹ Ábúráhámù ṣe jẹ́ ká lóye ohun tí Jèhófà ṣe nítorí wa ká sì mọyì rẹ̀?

13 Kí ló ná Jèhófà láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa lọ́nà yìí? Ó ṣòro fún wa láti lóye rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Àmọ́ àkọsílẹ̀ kan wà nínú Bíbélì tó máa jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ náà kedere. Jèhófà sọ fún ọkùnrin olóòótọ́ náà, Ábúráhámù láti ṣe ohun kan tó ṣòroó ṣe gan-an, ìyẹn ni pé kó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ. Baba onífẹ̀ẹ́ ni Ábúráhámù. Ohun tí Jèhófà sọ fún un nípa Ísákì ni: “Ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi.” (Jẹ́n. 22:2) Síbẹ̀, Ábúráhámù mọ̀ pé ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà ṣe pàtàkì fóun ju ìfẹ́ tí òun ní fún Ísákì lọ. Ábúráhámù gbéra, ó sì fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ fún un. Àmọ́ Jèhófà kò gba Ábúráhámù láyè láti ṣe ohun tí Òun fúnra rẹ̀ yóò ṣe lọ́jọ́ kan. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan láti dá Ábúráhámù dúró nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. Ábúráhámù ti pinnu láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run nínú ìdánwò tó le yìí, ó sì mọ̀ dájú pé ìrètí kan ṣoṣo tó wà fóun láti pa dà rí ọ̀dọ́kùnrin náà láàyè jẹ́ nípasẹ̀ àjíǹde. Àmọ́, ó gbà gbọ́ gidi pé Ọlọ́run á jí i dìde. Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ pé “lọ́nà àpèjúwe” Ábúráhámù gba Ísákì pa dà nípasẹ̀ àjíǹde.—Héb. 11:19.

14 Ǹjẹ́ o lè fọ̀rọ̀ Ábúráhámù ro ara rẹ wò kó o rí bí ìrora rẹ̀ á ti pọ̀ tó nígbà tó fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ rúbọ? Lọ́nà kan, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù jẹ́ ká mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó fi ẹnì kan ṣoṣo tó pè ní “Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n” rúbọ. (Mát. 3:17) Àmọ́ rántí pé, ó ṣeé ṣe kí ìrora Jèhófà túbọ̀ pọ̀ gan-an jùyẹn lọ. Fún ọ̀pọ̀ àìmọye ọdún ni òun àti Ọmọ rẹ̀ fi jọ wà pa pọ̀. Ọmọ náà ń fayọ̀ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààyò “àgbà òṣìṣẹ́” àti Agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, ìyẹn “Ọ̀rọ̀ náà.” (Òwe 8:22, 30, 31; Jòh. 1:1) Kò tiẹ̀ sí bá a ṣe lè mọ ohun tí Jèhófà fara dà ni, bí wọ́n ṣe ń dá Ọmọ rẹ̀ lóró, tí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì pa á gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn. Ìdáǹdè wa ná Jèhófà ní ohun tó pọ̀ gan-an! Ní báyìí, báwo la ṣe ń fi hàn pé a mọyì ìdáǹdè yẹn gan-an?

Báwo Lo Ṣe Máa Fi Hàn Pé O Mọyì Ìdáǹdè?

15. Báwo ni Jésù ṣe parí ètùtù ńlá tó ṣe náà pátápátá, kí ni ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe?

15 Jésù parí ètùtù ńlá tó ṣe náà pátápátá lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀ sí ọ̀run. Ó pa dà sọ́dọ̀ Baba rẹ̀, ó sì gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ fún Baba rẹ̀ lọ́run. Àwọn ìbùkún ńlá ló tẹ̀ lé e. Ara rẹ̀ ni pé ó jẹ́ ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà pátápátá, lákọ̀ọ́kọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi, lẹ́yìn náà ẹ̀ṣẹ̀ “ti gbogbo ayé.” Lónìí, nítorí ẹbọ yẹn, gbogbo àwọn tó fi òótọ́ ọkàn ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí wọ́n sì di ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi lè rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run. (1 Jòh. 2:2) Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe kàn ọ́?

16. Kí la lè fi ṣàpèjúwe ìdí tó fi yẹ ká mọyì ìdáǹdè tí Jèhófà pèsè fún wa?

16 Ẹ jẹ́ ká pa dà sí àpèjúwe tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ká ní dókítà tó ṣàwárí ìwòsàn fún àrùn náà wá lọ́ ń bá aláìsàn kọ̀ọ̀kan ní wọ́ọ̀dù rẹ tó sì ń sọ fún wọn pé: Aláìsàn èyíkéyìí tó bá gba ìtọ́jú yìí, tó sì ń tẹ̀ lé bá a ṣe ní kó lo oògùn náà ni ara rẹ̀ máa yá. Tí ọ̀pọ̀ lára àwọn aláìsàn tẹ́ ẹ jọ wà níbẹ̀ bá kọ̀ láti tẹ̀ lé ohun tí dókítà náà sọ, tí wọ́n ń sọ pé ó ṣòro jù láti tẹ̀ lé ìlànà lílo oògùn náà ńkọ́? Ṣe ìwọ náà á dara pọ̀ mọ́ wọn láti máa sọ bẹ́ẹ̀, nígbà tó o ní ẹ̀rí tó dájú pé oògùn náà ń ṣiṣẹ́? Ó dájú pé, o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Láìsí àní-àní, wàá dúpẹ́ lọ́wọ́ dókítà náà pé ó wá oògùn náà rí, wàá sì rí i dájú pé o lo oògùn náà bó ṣe ní kó o lò ó, ó ṣeé ṣe kó o tiẹ̀ tún sọ fáwọn ẹlòmíì nípa bí oògùn náà ṣe dára tó. Lọ́nà tó jùyẹn lọ, gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a mọyì ìdáǹdè tó pèsè fún wa nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà tó fi Ọmọ rẹ̀ rú.—Ka Róòmù 6:17, 18.

17. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fi hàn pé ó mọyì ohun tí Jèhófà ti ṣe láti gbà ọ́ là?

17 Tá a bá mọyì ohun tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ṣe láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ńṣe la óò máa fi hàn. (1 Jòh. 5:3) A ó máa gbógun ti èròkerò tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. A ó yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, a ò sì ní máa ṣe bíi pé olóòótọ́ ni wá lójú àwọn èèyàn ká wá máa yọ́ ohun búburú ṣe níkọ̀kọ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń dọ́gbọ́n sọ pé ìràpadà náà kò já mọ́ nǹkan kan lójú wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa fi ìmọrírì wa hàn nípa sísa gbogbo ipá wa láti wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run. (2 Pét. 3:14) A óò máa fi ìmọrírì hàn nípa sísọ ìrètí ìdáǹdè àgbàyanu tá a ní fáwọn èèyàn, kí àwọn náà lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì nírètí láti wà láàyè títí láé. (1 Tím. 4:16) Kò sí àní-àní pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ yẹ lẹ́ni tá à ń fi gbogbo okun àti àkókò wa yìn! (Máàkù 12:28-30) Rò ó wò ná! À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ọlọ́run yóò mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò. Nígbà yẹn, a óò má gbé ayé nínú ìjẹ́pípé títí láé gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe fẹ́, nítorí ó ti ṣe ohun kan láti dá wa nídè!—Róòmù 8:21.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọ́n sọ pé iye àwọn tí àrùn gágá kọ lù tó ìdá márùn-ún iye àwọn tó wà láyé nígbà tó jà, tàbí kó tiẹ̀ tó ìdajì wọn pàápàá. Àmọ́ tí àrùn náà bá kọ lu ọgọ́rùn-ún èèyàn, ó máa pa ẹnì kan ó kéré tán, tàbí kó tiẹ̀ pa tó mẹ́wàá. Tá a bá fi àrùn Ebola wé àrùn gágá, àrùn Ebola kì í fi bẹ́ẹ̀ jà, àmọ́ láwọn ìgbà kan tó jà, ó máa ń pa tó bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn tó ń kọ lù.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó o fi nílò ìdáǹdè kíákíá?

• Báwo ni yíyọ̀ǹda tí Jésù yọ̀ǹda láti fi ara rẹ̀ rúbọ ṣe kàn ọ́?

• Ojú wo lo fi ń wo ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà fún wa?

• Kí ni ohun tó o ti kọ́ yìí máa sún ọ ṣe láti fi hàn pé o mọyì ìdáǹdè tí Jèhófà pèsè fún ọ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì ṣàpẹẹrẹ Mèsáyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Bí Ábúráhámù ṣe múra tán láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ nípa ẹbọ tó tóbi jùyẹn lọ fíìfíì tí Jèhófà rú