Ohun Tó Mú Kí Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ Wa Ta Yọ
Ohun Tó Mú Kí Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ Wa Ta Yọ
“Mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù.”—FÍLÍ. 3:8.
1, 2. Kí ni àwọn Kristẹni kan yàn láti ṣe, kí sì nìdí tí wọ́n fi yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀?
ÀTIKÉKERÉ ni ọmọdékùnrin kan tó ń jẹ́ Robert ti máa n ta àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ yọ nílé ìwé. Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ, obìnrin kan tó jẹ́ olùkọ́ rẹ̀ ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ̀, ó sì sọ fún un pé kò sóhun tí kò lè dà láyé yìí. Olùkọ́ náà sọ pé òun retí pé lọ́jọ́ kan Robert máa di dókítà. Bó ṣe ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nílé ìwé girama mú kó dẹni tó yẹ láti lọ sí ọ̀kan lára yunifásítì tó dára jù lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Àmọ́ Robert yááfì àǹfààní yìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kì í wá lẹ́ẹ̀mejì, ó sì yàn láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
2 Bíi ti Robert, ọ̀pọ̀ Kristẹni, tèwetàgbà ló ní àǹfààní láti rọ́wọ́ mú nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Àmọ́ àwọn kan lára wọn kọ̀ láti lo àwọn àǹfààní wọ̀nyẹn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ torí kí wọ́n bàa lè lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí. (1 Kọ́r. 7:29-31) Bíi ti Robert, kí ló sún àwọn Kristẹni yìí láti máa lo ara wọn nínú iṣẹ́ ìwàásù? Yàtọ̀ sí ìfẹ́ tí wọn ní fún Jèhófà tó jẹ́ ìdí pàtàkì tí wọ́n fi yan ohun tí wọ́n ṣe, wọ́n tún mọ̀ pé ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ta yọ gbogbo ẹ̀kọ́ yòókù. Ǹjẹ́ o ti ronú lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa bí ìgbésí ayé rẹ ì bá ti rí ká sọ pé o kò ní ìmọ̀ òtítọ́? Tá a bá ń ronú lórí díẹ̀ lára àwọn ìbùkún títayọ tá à ń gbádùn nítorí pé Jèhófà ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, yóò jẹ́ kí ìmọrírì tá a ní fún ìhìn rere náà máa pọ̀ sí i, a ó sì lè máa fìtara sọ ọ́ fáwọn èèyàn.
Àǹfààní Ló Jẹ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
3. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà múra tán láti kọ́ àwa ẹ̀dá aláìpé lẹ́kọ̀ọ́?
3 Torí pé ẹni rere ni Jèhófà, ó múra tán láti kọ́ àwa èèyàn aláìpé lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Aísáyà 54:13 ń sàsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ní: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.” Ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ yẹn kan “àwọn àgùntàn mìíràn” ti Kristi pẹ̀lú. (Jòh. 10:16) A rí èyí kedere látinú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ń ṣẹ lọ́wọ́ lákòókò wa yìí. Aísáyà rí i nínú ìran kan pé àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè ń rọ́ wá sínú ìjọsìn tòótọ́. Ó sọ pé wọ́n ń pe ara wọn pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” (Aísá. 2:1-3) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́, pé Ọlọ́run ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́!
4. Irú ẹni wo ni Jèhófà ń fẹ́ káwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́?
4 Kí ló lè mú ká dẹni táá jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ wa? Ohun pàtàkì kan tá a gbọ́dọ̀ ṣe ni pé ká jẹ́ ọlọ́kàn tútù àti ẹni tó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Dáfídì tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù sọ pé: “Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà . . . . Yóò sì kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.” (Sm. 25:8, 9) Jésù pẹ̀lú sọ pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Lúùkù 10:21) Ǹjẹ́ èyí kò mú kó wù ọ láti sún mọ́ Ọlọ́run tí “ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀”?—1 Pét. 5:5.
5. Kí lohun tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run?
5 Ǹjẹ́ a lè sọ pé mímọ̀ọ́ṣe àwa èèyàn Jèhófà la fi dẹni tó mọ òtítọ́? Rárá o. Tá a bá fi dá tiwa nìkan, kò sí bá a ṣe lè ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòh. 6:44) Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti ẹ̀mí mímọ́, Jèhófà ń fa àwọn ẹni bí àgùntàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ìyẹn “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Hág. 2:7) Ṣé kò yẹ kó o kún fún ọpẹ́ pé o wà lára àwọn tí Ọlọ́run fà sún mọ́ Ọmọ rẹ̀?—Ka Jeremáyà 9:23, 24.
Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Lágbára Láti Yí Ìgbésí Ayé Ẹni Pa Dà
6. Ipa tó kàmàmà wo ni gbígba “ìmọ̀ Jèhófà” ń ní lórí àwọn èèyàn?
6 Aísáyà lo àpèjúwe kan tó fakíki láti fi sàsọtẹ́lẹ̀ ìyípadà kan tó ń bá ìwà àwọn ẹ̀dá èèyàn lákòókò tiwa yìí. Àwọn èèyàn tó jẹ́ oníjàgídíjàgan nígbà kan rí ti dẹni aláàfíà. (Ka Aísáyà 11:6-9.) Àwọn tó ti ń bá ara wọn ṣọ̀tá tẹ́lẹ̀ nítorí pé ìran wọn, orílẹ̀-èdè wọn, ẹ̀yà tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀ síra ti wá kẹ́kọ̀ọ́ láti máa gbé pọ̀ níṣọ̀kan. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ti fi “ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.” (Aísá. 2:4) Kí ló mú kí àwọn ìyípadà tó kàmàmà yìí ṣeé ṣe? Ohun tó mú kó ṣeé ṣe ni pé àwọn èèyàn ti gba “ìmọ̀ Jèhófà,” wọ́n sì ti ń lò ó nígbèésí ayé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ aláìpé, wọ́n ti di ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Bí ìhìn rere ṣe ń fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra kárí ayé yìí tó sì ń nípa rere lórí wọn jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ta yọ gbogbo ẹ̀kọ́.—Mát. 11:19.
7, 8. (a) Kí ni díẹ̀ lára “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” tí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti dojú wọn dé? (b) Kí ló fi hàn pé ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa ń mú ìyìn bá a?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi iṣẹ́ ìwàásù táwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣe wé ogun tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Nítorí àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run fún dídojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé. Nítorí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni àwa ń dojú wọn dé.” (2 Kọ́r. 10:4, 5) Kí ni díẹ̀ lára “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” tí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run máa ń gba àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn? Díẹ̀ lára àwọn nǹkan náà ni ẹ̀kọ́ èké, ìgbàgbọ́ nínú ohun àsán àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí èèyàn. (Kól. 2:8) Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká borí àwọn ìwà búburú, ó sì ń jẹ́ kéèyàn ní ìwà tó wu Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 6:9-11) Ó ń mú kínú ilé tòrò. Ó ń tún ìgbésí ayé àwọn tí kò nírètí ṣe. Irú ẹ̀kọ́ yìí làwa èèyàn nílò lóde òní.
8 Ìrírí tá a fẹ́ sọ yìí fi hàn pé ìṣòtítọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní. (Héb. 13:18) Obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Íńdíà gbà ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì yá, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Lọ́jọ́ kan nígbà tó ń bọ̀ láti ibi tó ti lọ ṣiṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ó rí ṣéènì onígóòlù kan tí iye owó rẹ̀ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] owó dọ́là (nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́fà owó náírà [₦116,000.00]). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mẹ̀kúnnù ni obìnrin yìí, ó mú ṣéènì náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Ohun tó ṣe yìí ya ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀ lẹ́nu! Nígbà tó yá, ọlọ́pàá míì béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà pé, “Kí ló sún ọ láti mú ṣéènì tó o rí he yìí wá síbí?” Obìnrin náà ṣàlàyé pé, “Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ti yí mi pa dà, mo sì ti di olóòótọ́ èèyàn nísinsìnyí.” Ọ̀rọ̀ yìí wú ọlọ́pàá náà lórí, ló bá sọ fún alàgbà tó bá obìnrin náà wá sí àgọ́ ọlọ́pàá pé: “Ó ju mílíọ̀nù méjìdínlógójì èèyàn lọ tó wà ní ìpínlẹ̀ yìí. Tó o bá lè ran èèyàn mẹ́wàá péré lọ́wọ́ láti dà bí obìnrin yìí, àṣeyọrí ńlá ló máa jẹ́.” Tá a bá ronú lórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ti tún ayé wọn ṣe, ǹjẹ́ a kò ní ìdí tó pọ̀ láti máa yin Jèhófà?
9. Kí ló ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti ṣe ìyípadà pàtàkì nígbèésí ayé wọn?
9 Agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti yí èèyàn pa dà àti ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, máa ń mú káwọn èèyàn ṣe ìyípadà pàtàkì nígbèésí ayé wọn. (Róòmù 12:2; Gál. 5:22, 23) Kólósè 3:10 sọ pé: “Ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.” Ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní agbára láti fi ohun tí èèyàn jẹ́ nínú hàn, ó sì lè yí ọ̀nà téèyàn ń gbà ronú pa dà, kódà ó tún ń jẹ́ ká máa fojú tó tọ́ wo nǹkan. (Ka Hébérù 4:12.) Béèyàn bá ní ìmọ̀ pípéye nínú Ìwé Mímọ́, tó sì mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìlànà òdodo Jèhófà mu, ẹni náà yóò di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, yóò sì ní ìrètí láti wà láàyè títí láé.
Ó Ń Múra Wa Sílẹ̀ De Ọjọ́ Ọ̀la
10. (a) Kí nìdí tá fi lè sọ pé Jèhófà nìkan lẹni tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la? (b) Ìyípadà tó pabanbarì wo ló máa dé bá ayé láìpẹ́?
10 Jèhófà nìkan lẹni tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la nítorí ó mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ó mọ bí ọjọ́ ọ̀la aráyé ṣe máa rí. (Aísá. 46:9, 10) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” (Sef. 1:14) Ọ̀rọ̀ tó wà ní Òwe 11:4 yóò ṣẹ lọ́jọ́ yẹn, ó sọ pé: “Àwọn ohun tí ó níye lórí kì yóò ṣàǹfààní rárá ní ọjọ́ ìbínú kíkan, ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.” Ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run lohun tó máa ṣe pàtàkì jù nígbà tí àkókò Jèhófà bá tó láti ṣèdájọ́ ayé Sátánì yìí. Owó kò ní já mọ́ nǹkan kan nígbà yẹn. Bó ṣe rí gan-an ni Ìsíkíẹ́lì 7:19 ṣe sọ ọ́, pé: “Wọn yóò sọ fàdákà wọn pàápàá sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn.” Ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nísinsìnyí.
11. Ọ̀nà wo ni ẹ̀kọ́ Ọlọ́run gbà ń múra wa sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la?
11 Ọ̀nà pàtàkì tí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run gbà ń múra wa sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà ni pe, ó ń jẹ́ ká fi ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” Bí a kì í tiẹ̀ ṣe ọlọ́rọ̀ pàápàá, a lè jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yìí. Kí la ní láti ṣe? Dípò ká máa kó ohun ìní ti ara jọ, a ní láti sapá “láti máa ṣe rere” ká sì “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Nípa fífi ìjọsìn wa sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa, a ó máa ‘tó ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wa de ẹ̀yìn ọ̀la.’ (1 Tím. 6:17-19) Tá a bá lè ń yááfì àwọn nǹkan lọ́nà bẹ́ẹ̀, ó máa fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n, nítorí Jésù sọ pé, “àǹfààní wo ni yóò jẹ́ fún ènìyàn kan bí ó bá jèrè gbogbo ayé ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ọkàn rẹ̀?” (Mát. 16:26, 27) Bí ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an yìí, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ibo ni mò ń kó ìṣúra tèmi pa mọ́ sí? Ṣé Ọlọ́run ni mo ń sìnrú fún ni àbí Ọrọ̀?’—Mát. 6:19, 20, 24.
12. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ rẹ̀wẹ̀sì táwọn kan bá ń fojú àbùkù wo iṣẹ́ ìwàásù wa?
12 Èyí tó gbà iwájú jù lọ lára “àwọn iṣẹ́ àtàtà” tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la lẹ́sẹẹsẹ fáwọn Kristẹni ni iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Àwọn èèyàn kan lè máa fojú àbùkù wo iṣẹ́ náà báwọn kan ti ṣe nígbà ayé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ka 1 Kọ́ríńtì 1:18-21.) Àmọ́ ìyẹn kò sọ iṣẹ́ náà di ohun yẹpẹrẹ, kò sì sọ pé kò ṣe pàtàkì pé kéèyàn fún àwọn èèyàn láǹfààní láti lo ìgbàgbọ́ nígbà tí àkókò ṣì wà. (Róòmù 10:13, 14) Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ Ọlọ́run, ńṣe làwa náà ń fi ara wa sípò ẹni tó máa gba ìbùkún rẹpẹtẹ.
Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Tí Wọ́n Yááfì Nǹkan Kan
13. Àwọn ohun wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yááfì nítorí ìhìn rere?
13 Kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, wọ́n tí dá a lẹ́kọ̀ọ́ láti di ẹni ńlá nínú ìgbé ayé àwọn Júù. Ó jọ pé kò ju ọmọ ọdún mẹ́tàlá lọ nígbà tó kúrò ní Tásù ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì olùkọ́ Òfin tó gbayì gan-an láwùjọ. (Ìṣe 22:3) Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù dẹni tó tá yọ láàárín àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀, ká ni ó ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ ni, ì bá di èèyàn ńlá nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. (Gál. 1:13, 14) Nígbà tó gba ìhìn rere, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyẹn sílẹ̀. Ǹjẹ́ Pọ́ọ̀lù kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe yẹn? Rárá o. Kódà ó sọ pé: “Mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí.”—Fílí. 3:8.
14, 15. Ìbùkún wo là ń rí gbà bá a ti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”?
14 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa Kristẹni òde òní máa ń yááfì àwọn nǹkan kan nítorí ìhìn rere. (Máàkù 10:29, 30) Ǹjẹ́ a ń pàdánù ohunkóhun? Robert, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ bọ́rọ̀ náà ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ní: “Mi ò kábàámọ̀ ohunkóhun. Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti fún mi ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, ó sì ti jẹ́ kí n ‘tọ́ Jèhófà wò, kí n sì rí i pé ẹni rere ni.’ Ìgbàkúùgbà tí mo bá yááfì nǹkan kan kí n bàa lè lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí, Jèhófà máa ń bù kún mi ju ohun tí mo yááfì lọ. Ńṣe ló máa ń dà bíi pé mi ò yááfì nǹkan kan. Èrè ni mo jẹ!”—Sm. 34:8; Òwe 10:22.
15 Tó o bá ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ìgbà kan títí di ìsinsìnyí, kò sí àní-àní pé o ti láǹfààní láti tọ́ Jèhófà wò, tó o sì ti rí i pé ẹni rere ni. Ǹjẹ́ ìgbà kan wà tó o rí ìrànwọ́ ẹ̀mí rẹ̀ bó o ti ń sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn? Ǹjẹ́ o ti rí i tí ayọ̀ hàn lójú àwọn èèyàn bí Jèhófà ti ń ṣí ọkàn wọ́n payá láti gbọ́ ìhìn rere náà? (Ìṣe 16:14) Ǹjẹ́ Jèhófà ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro, bóyá nípa ṣíṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ láti mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ gbòòrò sí i? Ǹjẹ́ ó ti tì ọ́ lẹ́yìn nígbà ìṣòro, tó jẹ́ kó o máa sin òun nìṣó bó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò fi bẹ́ẹ̀ lókun tó? (Fílí. 4:13) Nígbà táwa fúnra wa bá rí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà, a óò túbọ̀ máa mọ Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ la ó sì túbọ̀ máa sún mọ́ ọn. (Aísá. 41:10) Ǹjẹ́ ìbùkún kọ́ ló jẹ́ láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” lẹ́nu iṣẹ́ bàǹtàbanta ti kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?—1 Kọ́r. 3:9.
16. Kí lèrò rẹ nípa ìsapá rẹ àtohun tó o yááfì nítorí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run?
16 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ káwọn rí nǹkan gidi tó máa wà jálẹ̀ ìgbà ayé wọn gbé ṣe. Ṣùgbọ́n a ti rí i pé kì í pẹ́ táráyé fi ń gbàgbé àwọn tó ṣe àṣeyọrí tó kàmàmà pàápàá. Àmọ́, kò sí àní-àní pé Jèhófà máa mú kí àṣeyọrí èyíkéyìí tó bá wáyé nítorí ìyàsímímọ́ orúkọ rẹ̀ lákòókò yìí wà lákọọ́lẹ̀ títí lọ gbére nínú ìtàn àwọn èèyàn rẹ̀. Títí láé ni iṣẹ́ náà yóò wà ní rántí. (Òwe 10:7; Héb. 6:10) Ǹjẹ́ kí a mọyì àǹfààní tá a ní bá a ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn iṣẹ́ tí a kò ní gbàgbé láé.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Irú ẹni wo ni Jèhófà ń fẹ́ káwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́?
• Báwo ni ẹ̀kọ́ Ọlọrun ṣe ń tún ìgbésí ayé àwọn èèyàn ṣe?
• Àwọn ọ̀nà wo la ti ń rí ìbùkún gbà bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní ẹ̀kọ́ Ọlọ́run?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn tí Jèhófà ń kọ́ ti di ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ ìbùkún kọ́ ni láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”?