Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọsìn Ìdílé Ṣe Pàtàkì Fún Ìgbàlà Ìdílé Wa!

Ìjọsìn Ìdílé Ṣe Pàtàkì Fún Ìgbàlà Ìdílé Wa!

Ìjọsìn Ìdílé Ṣe Pàtàkì Fún Ìgbàlà Ìdílé Wa!

“OGUN ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” yóò mà kún fún ẹ̀rù gan-an o! (Ìṣí. 16:14) Wòlíì Míkà lo àkànlò èdè tó ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Àwọn òkè ńlá yóò sì yọ́ . . . , àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ yóò sì pínyà, bí ìda nítorí iná, bí omi tí a dà sórí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.” (Míkà 1:4) Àjálù wo ló máa mú wá bá àwọn tí kò sin Jèhófà? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.”—Jer. 25:33.

Látàrí irú ìkìlọ̀ báwọ̀nyí, ó yẹ káwọn olórí ìdílé, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ, bi ara wọn ní ìbéèrè kan nípa àwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà tó láti ṣèpinnu. Ìbéèrè náà ni: ‘Ṣé àwọn ọmọ mi yóò la ogun yìí já?’ Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé wọn yòó là á já tí wọ́n bá wà láàyè nípa tẹ̀mí, tí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sì lágbára níbi tí ọjọ́ orí wọn dé.—Mát. 24:21.

Ó Ṣe Pàtàkì Ká Ní Àkókò fún Ìjọsìn Ìdílé

Gẹ́gẹ́ bí òbí, máa rí i dájú pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kó o máa bá àwọn ọmọ rẹ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A fẹ́ káwọn ọmọ wa kéékèèké fìwà jọ àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì. Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún wọn torí bí wọ́n ṣe múra tán láti ṣègbọràn sí Jèhófà, ó ní: “Ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, lọ́nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí pẹ̀lú ìmúratán púpọ̀ sí i nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Fílí. 2:12.

Ṣé àwọn ọmọ rẹ máa ń pa òfin Jèhófà mọ́ nígbà tí o kò bá sí lọ́dọ̀ wọn? Ṣé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nílé ìwé? Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti gbà pé òfin Jèhófà mọ́gbọ́n dání, àti pé òun ló yẹ kó máa ṣamọ̀nà wọn nígbà tí wọn kò bá sí lọ́dọ̀ rẹ?

Ohun kékeré kọ́ ni Ìjọsìn Ìdílé lè ṣe nínú mímú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ rẹ lágbára débi tí wọ́n á fi lè máa tẹ̀ lé òfin Jèhófà nígbà tí ìwọ òbí wọn kò bá sí níbi tí wọ́n wà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun pàtàkì mẹ́ta tó lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé yín yọrí sí rere.

Ẹ Máa Ṣe É ní Àkókò àti Ọjọ́ Tẹ́ Ẹ Fi Sí

Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run pe àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n pàdé ní àkókò kan pàtó. (Jóòbù 1:6) Ohun kan náà ni kó o máa ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ. Yan ọjọ́ àti àkókò kan pàtó tẹ́ ẹ ó máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé nírọ̀lẹ́, kẹ́ ẹ sì máa ṣe é déédéé. Yàtọ̀ síyẹn yan ìgbà míì tẹ́ ẹ lè ṣe é tó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun tẹ́ ò retí wáyé lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fi sí.

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹ má ṣe gbà kí Ìjọsìn Ìdílé yín di èyí tẹ́ ẹ ó máa ṣe ní ìdákúrekú. Máa rántí pé àwọn ọmọ rẹ ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ṣe pàtàkì jù lọ fún ẹ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Sátánì ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n jẹ. (1 Pét. 5:8) Tó o bá pa Ìjọsìn Ìdílé tó ṣe pàtàkì yìí jẹ lálẹ́ ọjọ́ kan torí pé ó fẹ́ wo tẹlifíṣọ̀n tàbí torí nǹkan míì tí kò pọn dandan, Sátánì ti borí lọ́jọ́ yẹn nìyẹn.—Éfé. 5:15, 16; 6:12; Fílí. 1:10.

Darí Rẹ̀ Lọ́nà Táá Fi Ṣe Wọ́n Láǹfààní

Ìgbà Ìjọsìn Ìdílé kì í ṣe àkókò láti rọ́ ìmọ̀ sórí àwọn ọmọ bí ìgbà tí wọ́n ń kọ́ wọn níléèwé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o darí rẹ̀ lọ́nà táá fi ṣe wọ́n láǹfààní. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Nígbà míì, o lè yan kókó ọ̀rọ̀ tó bá ohun táwọn ọmọ rẹ máa bá pàdé lọ́jọ́ kan mu. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi ṣíṣe ìdánrawò ohun tí wọ́n máa sọ lóde ẹ̀rí kún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín. Àwọn ọmọdé máa ń gbádùn kí wọ́n máa ṣe ohun tí wọ́n mọ̀-ọ́n ṣe. Fífi bí wọ́n ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí dánra wò àti ríronú lórí bí wọ́n ṣe máa fèsì nígbà tí onílé bá gbé àtakò dìde yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ nígboyà tí wọ́n bá ń lọ́wọ́ nínú onírúurú apá ẹ̀ka iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.—2 Tím. 2:15.

Ẹ tún lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe nípa ṣíṣe ìdánrawò ohun tí wọ́n máa ṣe nígbà táwọn ẹgbẹ́ wọn bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ wọ́n. Ẹ lè lo, orí 15 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, fún ìjíròrò ìdílé. Apá tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” tó wà lójú ìwé 132 àti 133, sọ ìṣòro tó lè wáyé àti ohun téèyàn lè ṣe, ó sì tún fún àwọn ọmọ láǹfààní láti ronú ọ̀nà tó máa rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti fèsì nígbà táwọn ẹgbẹ́ wọn bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ wọ́n. Gbólóhùn kan nísàlẹ̀ ojú ìwé 133 sọ pé: “Ìwọ àti òbí ẹ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè fàwọn ìdáhùn ẹ dánra wò.” Látìgbàdégbà, fi irú ìdánrawò yẹn kún Ìjọsìn Ìdílé yín.

Ìjọsìn Ìdílé máa ń fún àwọn òbí láyè láti gbin àǹfààní tó wà nínú lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí sọ́kàn àwọn ọmọ. Lórí kókó yìí, orí 38 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, ní àwọn ìsọfúnni tó gbéṣẹ́ gan-an, àkòrí ẹ̀ ni “Kí Ni Màá Fayé Mi Ṣe?” Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò orí yìí, ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti rí i pé, fífi gbogbo ìgbésí ayé ẹni sin Jèhófà ni ohun tó dára jù lọ. Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà, kí wọ́n lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí kí wọ́n lépa iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún míì.

Ohun kan tẹ́ ẹ ní láti ṣọ́ra fún rèé o: Àwọn òbí kan tí wọ́n fẹ́ ohun tó dára fún ọmọ wọn máa ń ṣàṣìṣe kan, wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ kọ́mọ wọn dà débi pé wọn kì í gbóríyìn fún ọmọ náà tórí ohun tó dáa tó ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́. Lóòótọ́, ó dára pé kó o fún àwọn ọmọ rẹ níṣìírí láti fi iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì àti iṣẹ́ míṣọ́nnárì ṣe àfojúsùn wọn. Àmọ́, máa ṣọ́ra kó o má bàa dá ọmọ rẹ lágara débi táá fi soríkodò torí ohun tó pọ̀ jù tó o ń retí pé kó gbé ṣe. (Kól. 3:21) Máa rántí pé ọmọ rẹ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látinú ọkàn rẹ̀ wá, kì í ṣe látinú ọkàn tìrẹ. (Mát. 22:37) Torí náà, máa wá ọ̀nà láti gbóríyìn fún ọmọ rẹ níbi tó bá ti ń ṣe dáadáa, kó o sì yẹra fún títẹnu mọ́ àwọn ohun tí kò tíì ṣe. Ràn án lọ́wọ́ láti máa mọrírì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe. Kó o sì jẹ́ kí ọmọ rẹ náà mọyì oore Jèhófà látọkàn rẹ̀ wá.

Jẹ́ Kó Gbádùn Mọ́ni

Nǹkan kẹta tó máa mú kí Ìjọsìn Ìdílé yín yọrí sí rere ni pé, kó o jẹ́ kó máa gbádùn mọ́ ìdílé rẹ. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ lè gbọ́ àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀, tàbí kẹ́ ẹ wo ọ̀kan lára fídíò táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Ẹ sì tún lè ka ìtàn kan pa pọ̀ nínú Bíbélì, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá kó ipa àwọn tó wà nínú ìtàn yẹn.

Àwọn àpilẹ̀kọ kan tún máa ń wà nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, tó dára gan-an fún ìjíròrò ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè lo àpilẹ̀kọ tó máa ń wà lójú ìwé 31 nínú gbogbo ìtẹ̀jáde Jí!, èyí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?” Lẹ́ẹ̀kan lóṣù méjì, Ilé Ìṣọ́ tá a ń fi sóde máa ń ní àpilẹ̀kọ kan tó wúlò fún ìkẹ́kọ̀ọ́, àkòrí rẹ̀ ni “Abala Àwọn Ọ̀dọ́.” Òmíràn tó máa ń jáde láàárín oṣù tí “Abala Àwọn Ọ̀dọ́” kò bá jáde ni “Kọ́ Ọmọ Rẹ,” èyí wà fún àwọn ọmọdé lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ń wà lábẹ́ àkòrí náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìtẹ̀jáde Jí! máa wúlò fún àwọn òbí tó lọ́mọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, náà sì wúlò gan-an fún wọn. Tẹ́ ẹ bá ń lo ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, ẹ má ṣe gbójú fo àpótí tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Kí Lèrò Ẹ” tó máa ń wà níparí orí kọ̀ọ̀kan. Kì í ṣe àtúnyẹ̀wò nìkan ni àpótí yẹn wà fún o. Ẹ lè lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpótí yẹn gẹ́gẹ́ bí àwọn kókó tí ìjíròrò ìdílé yín á dá lé lórí.

Ẹ ṣọ́ra kẹ́ ẹ má bàa sọ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín di ibi tí ẹ ó ti máa da ìbéèrè bo àwọn ọmọ. Bí àpẹẹrẹ, má ṣe fipá mú ọmọ rẹ láti ka ohun tó kọ sí ojú ìwé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ohun Tí Mo Rò” tàbí láwọn apá míì tó jẹ́ ìjíròrò nínú ìwé náà. Ìwé náà sọ kókó yìí nínú àkòrí tó sọ pé “Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí” tó wà lójú ìwé 3, ó ní: “Káwọn ọmọ ẹ bàa lè máa kọ ohun tó wà lọ́kàn wọn gan-an sínú ìwé yìí, ọwọ́ wọn ni kó o jẹ́ kí ìwé náà máa gbé. Bó bá yá, àwọn fúnra wọn lè wá fẹnu ara wọn ṣàlàyé ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀.”

Tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé ní àkókò àti ọjọ́ tẹ́ ẹ fi sí, tẹ́ ẹ̀ ń ṣe é lọ́nà tá a fi ṣeni láǹfààní tó sì ń gbádùn mọ́ni, Jèhófà yóò bù kún ìsapá yín. Àkókò pàtàkì tẹ́ ẹ̀ ń lò pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé yìí, á jẹ́ kí ìdílé yín wà láàyè nípa tẹ̀mí á sì jẹ́ kí àjọṣe àwọn àti Ọlọ́run lágbára.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

Máa Lo Oríṣiríṣi Ọ̀nà

“Tá a bá ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin wa kékeré lẹ́kọ̀ọ́, èmi àtọkọ mi yóò ka ibi tá a máa jíròrò nípàdé, lẹ́yìn náà á óò wá sọ pé káwọn ọmọbìnrin wa ya àwòrán tó bá ẹ̀kọ́ náà mu. Nígbà míì, a máa ń fi àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe eré tàbí ká fi bá a ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí dánra wò. A máa ń jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ọjọ́ orí wọn mu, kó lárinrin, kó ṣe wọ́n láǹfààní kó sì gbádùn mọ́ wọn.”—J. M., United States.

“Kí n lè ran ọmọ ẹnì kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mọ bí lílo àkájọ ìwé ṣe rí láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, a fi kọ̀ǹpútà tẹ ìwé Aísáyà sórí ìwé lẹ́yìn tá a ti yọ nọ́ńbà orí àti ẹsẹ kúrò níbẹ̀. A wá lẹ àwọn ìwé náà pọ̀, a sì so ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí rẹ̀ mọ igi róbótó kan lọ́tùn ún àti lósì. Ọmọkùnrin náà wá gbìyànjú láti ṣe ohun ti Jésù ṣe nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárétì. Àkọsílẹ̀ Lúùkù 4:16-21 sọ pé, Jésù: “ṣí àkájọ ìwé [Aísáyà] ó sì rí” ibi tí ó fẹ́ kà. (Aísá. 61:1, 2) Àmọ́ nígbà tí ọmọkùnrin náà gbìyànjú láti ṣohun tí Jésù ṣe, ó ṣòro fún un láti rí Aísáyà 61 nínú àkájọ ìwé tá a ṣe yẹn tí kò ní orí àti ẹsẹ. Bó ṣe ṣeé ṣe fún Jésù láti lo àkájọ ìwé wú ọmọkùnrin náà lórí gan-an, ló bá sọ pé: ‘Ọ̀gá ni Jésù!’”—Y. T., Japan.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ṣíṣe ìdánrawò ohun táwọn ọmọ máa ṣe nígbà táwọn ẹgbẹ́ wọn bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Sapá láti mú kí Ìjọsìn Ìdílé yín gbádùn mọ́ni