Ṣé O ‘Ta Gbòǹgbò Tó O sì Fìdí Múlẹ̀ Lórí Ìpìlẹ̀ Náà’?
Ṣé O ‘Ta Gbòǹgbò Tó O sì Fìdí Múlẹ̀ Lórí Ìpìlẹ̀ Náà’?
ǸJẸ́ o ti rí igi ńlá kan tí ìjì líle ń rọ́ lù rí? O rí i tí atẹ́gùn ń bì í síwá sẹ́yìn àmọ́ kò wó. Kí nìdí? Ohun tó fà á ni pé ó ti ta gbòǹgbò sínú ilẹ̀, ó sì ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. A lè dà bí igi yẹn. Táwa náà bá dojú kọ àwọn àdánwò tó dà bí ìjì líle, a ó lè fara dà á tá a bá “ta gbòǹgbò, [tá a] sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.” (Éfé 3:14-17) Ìpìlẹ̀ wo nìyẹn?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “Kristi Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ igun” ìjọ Kristẹni. (Éfé. 2:20; 1 Kọ́r. 3:11) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé ká “máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí [a] ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé [wa] ró nínú rẹ̀, kí [a] sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè dúró gbọn-in tó bá ṣẹlẹ̀ pé ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ gbéjà ko ìgbàgbọ́ wa, kódà lójú “àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà” tí wọ́n gbé ka “ẹ̀tàn òfìfo” àwọn èèyàn pàápàá.—Kól. 2:4-8.
“Ìbú àti Gígùn àti Gíga àti Jíjìn”
Báwo wá la ṣe lè dẹni tó “ta gbòǹgbò” tó sì “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́”? Ọ̀nà pàtàkì kan ni pé ká jẹ́ kí gbòǹgbò wa wọlẹ̀ lọ, ìyẹn ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jèhófà fẹ́ kí àwa “pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ . . . fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ jẹ́. (Éfé. 3:18) Nítorí náà, kò yẹ kí Kristẹni kan jẹ́ kí ìmọ̀ oréfèé tẹ́ òun lọ́rùn, kó wá jẹ́ kí ìwọ̀nba “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀” tó mọ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó òun. (Héb. 5:12; 6:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kàn wa máa hára gàgà láti mú kí òye òtítọ́ Bíbélì tá a ní túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i.—Òwe 2:1-5.
Àmọ́ ṣá o, èyí kò túmọ̀ sí pé a ní láti di àká ìmọ̀ ká tó lè ‘ta gbòǹgbò ká sì fìdí múlẹ̀’ nínú òtítọ́ o. Ṣebí Sátánì náà ṣáà mọ àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ ìmọ̀ Bíbélì nìkan kò tó. A ní láti “mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀.” (Éfé. 3:19) Síbẹ̀ náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, bí ìmọ̀ pípéye tá a ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ṣe ń pọ̀ sí i, ìgbàgbọ́ wa yóò máa lágbára sí i.—Kól. 2:2.
Dán Ara Rẹ Wò Láti Mọ Bí Òye Rẹ Ṣe Jinlẹ̀ Tó
Ní báyìí, dán ara rẹ wò láti lè mọ bí òye tó o ní nípa díẹ̀ lára àwọn òtítọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì ṣe jinlẹ̀ tó. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o túbọ̀ múra sí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ka orí kìíní, ẹsẹ kẹta sí ìkẹwàá nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí la kọ jáde sínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. (Wo àpótí náà “Sí Àwọn Ará Éfésù.”) Lẹ́yìn tó o bá kà á tán, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo lóye àwọn ọ̀rọ̀ tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn?’ Ẹ jẹ́ ká wá gbé wọn yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
Ó Yàn Wọ́n “Ṣáájú Ìgbà Pípilẹ̀ Ayé”
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “[Ọlọ́run] yàn wá ṣáájú sí ìsọdọmọ fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.” Jèhófà ti pinnu láti sọ àwọn kan lára aráyé dọmọ kí wọ́n lè di ara ìdílé rẹ̀ pípé lọ́run. Àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ yìí yòó ṣàkóso pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Róòmù. 8:19-23; Ìṣí. 5:9, 10) Nígbà tí Sátánì kọ́kọ́ ta ko Jèhófà pé bó ṣe jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run kò tọ̀nà, ohun tó dọ́gbọ́n sọ ni pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá èèyàn ní àbùkù nínú. Ẹ ò rí i pé ó bá a mu bí Jèhófà ṣe yàn lára ìran ẹ̀dá èèyàn láti kópa nínú mímú gbogbo láabi kúrò láyé, tó fi mọ́ ẹni tó dá ibi sílẹ̀, ìyẹn Sátánì Èṣù! Àmọ́ ṣá o, Jèhófà kò pinnu pé ẹni báyìí lòun máa yàn, ẹni báyìí lòun kò ní yàn láti sọ di ọmọ òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Ọlọ́run pinnu ni pé àwùjọ kan tàbí ẹgbẹ́ kan máa wà lára ọmọ aráyé tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run.—Ìṣí. 14:3, 4.
“Ayé” wo ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé, Ọlọ́run ti yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé”? Kì í ṣe àkókò kan ṣáájú kí Ọlọ́run tó dá ayé tàbí èèyàn ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, á lòdì sí ìlànà ìdájọ́ òdodo. Ṣé ó yẹ ká bá Ádámù àti Éfà wí lórí ohun tí wọ́n ṣe tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ti pinnu tẹ́lẹ̀ kó tó dá wọn pé wọ́n máa dẹ́ṣẹ̀? Ìgbà wo wá ni Ọlọ́run pinnu bó ṣe máa ṣàtúnṣe sí ohun tó bà jẹ́ látàrí bí Ádámù àti Éfà ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run? Ìgbà tí Jèhófà pinnu ìyẹn ni ẹ̀yìn ìgbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn ọmọ tí wọ́n di aráyé aláìpé, àmọ́ tí wọ́n ṣeé rà pa dà.
“Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ọrọ̀ Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Rẹ̀”
Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ìṣètò Jèhófà tá à ń jíròrò yìí jẹ́ “ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Ọlọ́run? Ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ fi hàn kedere pé kì í ṣe ọ̀ranyàn fún Jèhófà láti ra aráyé tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà.
Tá a bá fi dá tiwa fúnra wa, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó lẹ́tọ̀ọ́ láti rí ìràpadà gbà. Àmọ́ torí pé Jèhófà ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ìran ẹ̀dá èèyàn, ó ṣe àwọn ètò pàtàkì kan láti gbà wá là. Tá a bá wo ti jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀, a óò rí i pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ló jẹ́ pé Ọlọ́run tún wa rà pa dà, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ.
Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run
Níbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run kò sọ bó ṣe máa tún ohun tí Sátánì ti bà jẹ́ ṣe. “Àṣírí ọlọ́wọ̀” ló jẹ́. (Éfé. 3:4, 5) Àmọ́ nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀, Jèhófà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bó ṣe máa ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀ ayé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀,” Ọlọ́run gbé “iṣẹ́ àbójútó kan” kalẹ̀, ìyẹn ìṣètò kan tí yóò mú kí gbogbo ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ láyé àti lọ́run wà ní ìṣọ̀kan.
Apá àkọ́kọ́ lára ìmúṣọ̀kan yẹn bẹ̀rẹ̀ nígbà àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ìgbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn tó máa bá Kristi ṣàkóso lọ́run jọ. (Ìṣe 1:13-15; 2:1-4) Apá kejì rẹ̀ yóò jẹ́ kíkó àwọn tó máa gbé inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà jọ. (Ìṣí. 7:14-17; 21:1-5) Kì í ṣe Ìjọba Mèsáyà ni ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́ àbójútó” ń tọ́ka sí, torí pé ọdún 1914 ni Ìjọba yẹn tó bẹ̀rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà bójú tó nǹkan táá fi lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ pé kí gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run wà níṣọ̀kan.
“Dàgbà Di Géńdé Nínú Agbára Òye”
Ó dájú pé tó o bá ti sọ ọ́ dàṣà láti máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ó máa jẹ́ kó o lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa “ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ jẹ́. Àmọ́ kò sí àní-àní pé kòókòó jàn-án-jàn-án táwọn èèyàn ń bá kiri nínú ayé yìí ti jẹ́ kó rọrùn fún Sátánì láti mú ká ṣíwọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ká dín in kù. Má ṣe gba Èṣù láyé láti ṣe irú ẹ̀ fún ẹ. Máa lo “agbára ìmòye” tí Ọlọ́run fún ọ kó o bàa lè “dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” (1 Jòh. 5:20; 1 Kọ́r. 14:20) Máa rí i dájú pé o mọ ìdí tó o fi nígbàgbọ́ nínú ohun tó o gbà gbọ́ àti pé gbogbo ìgbà lo lè sọ “ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú [rẹ].”—1 Pét. 3:15.
Ká sọ pé o wà ní Éfésù nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ka lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ yẹn, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní mú kó wù ẹ́ láti ní “ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run”? (Éfé. 4:13, 14) Ó dájú pé bó ṣe máa rí nìyẹn! Torí náà, jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí Ọlọ́run mí sí yẹn sún ẹ láti ṣe ohun kan náà lónìí. Tó o bá ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà, tó o sì ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀, yóò jẹ́ kó o lè “ta gbòǹgbò, kó o sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà” Kristi. Lọ́nà yẹn, wàá lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó lè dà bí ìjì líle tí Sátánì bá gbé kò ọ́ lójú, kó tó di pé òpin ètò nǹkan búburú yìí dé.—Sm. 1:1-3; Jer. 17:7, 8.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
“Sí Àwọn Ará Éfésù”
“Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ó ti fi gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí ní àwọn ibi ọ̀run bù kún wa ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yàn wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé, kí a lè jẹ́ mímọ́ àti láìní àbààwọ́n níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́. Nítorí ó yàn wá ṣáájú sí ìsọdọmọ fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere ìfẹ́ rẹ̀, nínú ìyìn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ológo èyí tí ó fi dá wa lọ́lá pẹ̀lú inú rere nípasẹ̀ olólùfẹ́ rẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. Èyí ni ó mú kí ó pọ̀ gidigidi sọ́dọ̀ wa nínú ọgbọ́n àti agbára ìmòye rere gbogbo, ní ti pé ó sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ èyí tí ó pète nínú ara rẹ̀ fún iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, èyíinì ni, láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.”—Éfé. 1:3-10.