Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”

“Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—RÓÒMÙ 12:18.

1, 2. (a) Kí ni Jésù sọ pé yóò máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Ibo la ti lè rí ìmọ̀ràn lórí bó ṣe yẹ ká ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtakò sí wa?

 JÉSÙ sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n máa rí àtakò látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Ó sì ṣàlàyé ìdí rẹ̀ fún wọn lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀. Ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòh. 15:19.

2 Ohun tí Jésù sọ yìí ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nínú lẹ́tà kejì tó kọ sí Tímótì alájọṣiṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀dọ́, ó ní: “Ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi, ète mi, ìgbàgbọ́ mi, ìpamọ́ra mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, àwọn inúnibíni mi, àwọn ìjìyà mi.” Ó fi kún un pé: “Ní ti tòótọ́, gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tím. 3:10-12) Ní orí kejìlá ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó fún wọn ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣàtakò sí wọn. Àwọn ohun tó sọ níbẹ̀ lè tọ́ àwa náà sọ́nà lákòókò òpin yìí.

“Ẹ Pèsè Àwọn Ohun Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀”

3, 4. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà ní Róòmù 12:17 (a) nínú ilé tó jẹ́ pé ọkọ tàbí aya nìkan ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí? (b) nínú bá a ṣe ń ṣe sí àwọn èèyàn?

3 Ka Róòmù 12:17. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa. Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ṣe pàtàkì gan-an, pàápàá nínú ilé tó jẹ́ pé ọkọ tàbí aya nìkan ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ó lè fẹ́ ṣe èyí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nínú àwọn méjèèjì bíi pé kó fi ọ̀rọ̀ burúkú fèsì ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ sí i, tàbí kó foró yaró. Ṣùgbọ́n kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Kò sí èrè kankan nídìí kéèyàn máa “fi ibi san ibi.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń fọ́ ọ̀rọ̀ lójú pọ̀.

4 Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó yẹ ká máa ṣe dípò ìyẹn, ó ní: “Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn.” Tí aya kan bá fi inú rere bá ọkọ rẹ̀ lò nínú ilé lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ ti sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ẹ̀sìn rẹ̀, èyí lè bomi paná ọ̀rọ̀ tó ṣeé ṣe kó di iṣu ata yán-an-yàn-an. (Òwe 31:12) Carlos tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì nísinsìnyí sọ bí ìyá òun ṣe borí àtakò líle tí bàbá òun ń ṣe. Ó ní màmá òun máa ń hùwà rere ó sì máa ń tọ́jú ilé dáadáa. Carlos ṣàlàyé pé: “Màmá mi kọ́ àwa ọmọ pé ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún bàbá wa nígbà gbogbo. Ó sọ ọ́ di dandan fún mi láti máa bá bàbá mi lọ gbá boules (irú eré bọ́ọ̀lù kan nílẹ̀ Faransé), bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí eré bọ́ọ̀lù yẹn. Àmọ́, eré bọ́ọ̀lù yẹn máa ń mú kí ara bàbá mi yá gágá.” Nígbà tó yá, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi. Tó bá dọ̀ràn ká “pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn,” àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábàá máa ń ṣẹ́gun ẹ̀tanú nípa ṣíṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

Bá A Ṣe Lè Fi “Ẹyín Ìná” Mú Kí Inú Àwọn Alátakò Yọ́

5, 6. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti kó “ẹyín iná” jọ sórí ọ̀tá wa? (b) Sọ ìrírí kan ládùúgbò rẹ tó fi hàn pé títẹ̀lé ìmọ̀ràn tó wà ní Róòmù 12:20 lè so èso rere.

5 Róòmù 12:20. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ọ̀rọ̀ tó wà ní ẹsẹ yìí, kò sí àní-àní pé ohun tó wà ní Òwe 25:21, 22 ló ní lọ́kàn, ibẹ̀ yẹn sọ pé: “Bí ebi bá ń pa ẹni tí ó kórìíra rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí ẹyín iná ni ìwọ ń wà jọ lé e ní orí, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì san ọ́ lẹ́san.” Tá a bá wo ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Róòmù orí 12 yẹn látòkèdélẹ̀, a óò rí i pé àpèjúwe Pọ́ọ̀lù nípa ẹyín iná yẹn kò lè túmọ̀ sí pé ká máa fìyà jẹ alátakò kan tàbí ká ṣe ohun tó máa dójú tì í. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jọ pé ohun tí òwe yẹn, àti ọ̀rọ̀ tó jọ ọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ń sọ ni ọ̀nà tí wọ́n ń gbà yọ́ irin táwọn awakùsà wà jáde látinú ilẹ̀ láyé àtijọ́. Ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Charles Bridges tó gbáyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún sọ pé: “Fi irin tó le gan-an sí àárín ẹyín iná, má kàn gbé e sórí iná, ńṣe ni kó o kó òkìtì ẹyín iná lé e lórí. Ṣàṣà ni ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ní rọ̀ lójú sùúrù, ìsẹ́ra-ẹni àti ìfẹ́ tó ń jó bí iná.”

6 Bí “ẹyín iná” ṣe lè yọ́ irin, ìwà rere wa lè wọ àwọn alátakò lọ́kàn ó sì lè mú kí inú wọn yọ́, kí wọ́n sì ṣíwọ́ ṣíṣe àtakò sí wa. Ìwà rere àwa èèyàn Jèhófà lè mú káwọn èèyàn dọ̀rẹ́ wa kí wọ́n sì máa fojúure wo ọ̀rọ̀ Bíbélì tá à ń wàásù. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.”—1 Pét. 2:12.

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”

7. Àlàáfíà wo ni Kristi fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí ló sì yẹ kí èyí mú ká máa ṣe?

7 Ka Róòmù 12:18. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín, mo fi àlàáfíà mi fún yín.” (Jòh. 14:27) Àlááfíà tí Kristi fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n máa ń ní látàrí mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n dùn sáwọn, àti pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn. Àlàáfíà ọkàn yìí yẹ kó mú wa máa gbé lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni àwọn Kristẹni tòótọ́.—Mát. 5:9.

8. Báwo la ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà nínú ilé àti nínú ìjọ?

8 Ọ̀nà kan tá a lè gbà jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà nínú ilé ni pé ká máa tètè yanjú èdèkòyédè dípò tí a ó fi jẹ́ kí ọ̀ràn kan pẹ́ nílẹ̀ táá fi wá burú sí i. (Òwe 15:18; Éfé. 4:26) Bó ṣe yẹ ká máa ṣe nínú ìjọ náà nìyẹn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu tó bá ń wá àlàáfíà. (1 Pét. 3:10, 11) Lẹ́yìn tí Jákọ́bù pẹ̀lú ti fúnni ní ìmọ̀ràn tó ṣe ṣàkó lórí bó ṣe yẹ kéèyàn máa lo ahọ́n àti béèyàn ṣe lè yẹra fún owú àti asọ̀, ó sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.”—Ják. 3:17, 18.

9. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ti ń sapá láti jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn”?

9 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Róòmù 12:18 kọjá kéèyàn jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà nínú ilé àti nínú ìjọ. Ó sọ pé a ní láti jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” Ìyẹn kan àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù fi gbólóhùn kan ṣáájú ìmọ̀ràn rẹ̀ yẹn, ó ní: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti jẹ́ “ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,” láìtẹ ìlànà òdodo Ọlọ́run lójú.

Ti Jèhófà Ni Ẹ̀san

10, 11. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fúnra wa gbẹ̀san?

10 Ka Róòmù 12:19. Kódà, a ní láti máa kó ara wa “ní ìjánu lábẹ́ ibi” ká sì máa hu “ìwà tútù” sí àwọn tí kò ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ wa àti ẹ̀kọ́ wa, títí kan àwọn alátakò. (2 Tím. 2:23-25) Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn láti má ṣe fúnra wa gbẹ̀san, ṣùgbọ́n ká “yàgò fún ìrunú.” Èyí túmọ̀ sí pé kò yẹ káwa Kristẹni máa fa ìbínú yọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló yẹ ká fi ẹ̀san sílẹ̀ fún Ọlọ́run. A mọ̀ pé kì í ṣe tiwa láti gbẹ̀san. Onísáàmù kan sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sm. 37:8) Sólómọ́nì sì gbáni nímọ̀ràn pé: “Má ṣe wí pé: ‘Dájúdájú, èmi yóò san ibi padà!’ Ní ìrètí nínú Jèhófà, òun yóò sì gbà ọ́.”—Òwe 20:22.

11 Táwọn alátakò bá ṣe wá ní jàǹbá, ohun tó bọ́gbọ́n mu fún wa láti ṣe ni pé ká fi ọ̀ràn náà sọ́wọ́ Jèhófà. Tó bá wù ú pé kó fìyà jẹ wọ́n, kó fìyà jẹ wọ́n lákòókò tó bá tọ́ lójú rẹ̀. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn torí ó fi kún un pé: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Fi wé Diutarónómì 32:35.) Tá a bá ní a fẹ́ gbẹ̀san lára ẹni tó ṣẹ̀ wá, a jẹ́ pé a ń kọjá àyè wa nìyẹn, ohun tí Jèhófà fẹ́ fúnra rẹ̀ ṣe la fẹ́ gbà ṣe yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ńṣe là ń fi hàn pé a kò nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé: “Èmi yóò san ẹ̀san.”

12. Báwo la ó ṣe ṣí ìrunú Jèhófà payá, ìgbà wo sì ni?

12 Lápá ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó ti kọ́kọ́ sọ pé: “Ìrunú Ọlọ́run ni a ń ṣí payá láti ọ̀run lòdì sí gbogbo àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti àìṣòdodo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ òtítọ́ rì ní ọ̀nà àìṣòdodo.” (Róòmù 1:18) A óò ṣí ìrunú Jèhófà payá láti ọ̀run nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣí. 7:14) Ìyẹn yóò jẹ́ “ẹ̀rí ìdánilójú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run,” gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà míì tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ, ó ní: “Èyí jẹ́ nítorí pé ó jẹ́ òdodo níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n yín lójú, ṣùgbọ́n, fún ẹ̀yin tí ń ní ìpọ́njú, ìtura pa pọ̀ pẹ̀lú wa nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹs. 1:5-8.

Bá A Ṣe Lè Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi

13, 14. (a) Kí nìdí tí kì í fi í yà wá lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtakò sí wa? (b) Ọ̀nà wo la lè máa gbà súre fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa?

13 Ka Róòmù 12:14, 21. Níwọ̀n bó ti dá wa lójú gbangba pé Jèhófà yóò mú gbogbo ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, a lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ láìfòyà, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) A mọ̀ pé iṣẹ́ táwa Kristẹni ń ṣe yìí lè mú ká rí ìbínú àwọn ọ̀tá wa nítorí Jésù ti sọ fún wa pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mát. 24:9) Torí náà, kì í yà wá lẹ́nu tí wọ́n bá gbé àtakò dìde sí wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò, bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀ níwọ̀n bí ẹ ti jẹ́ alájọpín nínú àwọn ìjìyà Kristi.”—1 Pét. 4:12, 13.

14 Kàkà ká máa fi ìkórìíra bá àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa lò, ńṣe ló yẹ ká máa sapá láti là wọ́n lọ́yẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé àìmọ̀kan ló ń ṣe àwọn míì lára wọn. (2 Kọ́r. 4:4) À ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni; ẹ máa súre, ẹ má sì máa gégùn-ún.” (Róòmù 12:14) Ọ̀nà kan tá a lè gbà máa súre fáwọn alátakò ni pé ká máa gbàdúrà fún wọn. Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òke pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, láti máa ṣe rere sí àwọn tí ó kórìíra yín, láti máa súre fún àwọn tí ń gégùn-ún fún yín, láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.” (Lúùkù 6:27, 28) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù alára jẹ́ kó mọ̀ pé onínúnibíni èèyàn kan lè di olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi àti onítara ìránṣẹ́ Jèhófà. (Gál. 1:13-16, 23) Nínú ìwé míì tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wa, àwa ń súre; nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń mú un mọ́ra; nígbà tí wọ́n ń bà wá lórúkọ jẹ́, àwa ń pàrọwà.”—1 Kọ́r. 4:12, 13.

15. Ọ̀nà wo ló dára jù lọ láti gbà fi ire ṣẹ́gun ibi?

15 Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹsẹ tó parí Róòmù orí 12 tó sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” Sátánì Èṣù lẹni tó dá gbogbo ibi sílẹ̀. (Jòh. 8:44; 1 Jòh. 5:19) Nínú ìran tí Jésù fi han àpọ́sítélì Jòhánù, ó ṣí i payá fún un pé àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró ti “ṣẹ́gun [Sátánì] nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn.” (Ìṣí. 12:11) Èyí fi hàn pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣẹ́gun Sátánì, àti iṣẹ́ ibi rẹ̀ tó kún inú ètò nǹkan ìsinsìnyí, ni pé kéèyàn máa ṣe rere nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí

16, 17. Kí ni Róòmù orí 12 kọ́ wa nípa (a) bó ṣe yẹ ká máa lo ìgbésí ayé wa? (b) bó ṣe yẹ ká máa ṣe nínú ìjọ? (d) bó ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn tó ń ṣàtakò sí wa?

16 Àwọn kókó díẹ̀ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú orí kejìlá ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù yìí ti rán wa létí ohun tó pọ̀. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wa sí mímọ́ múra tán láti máa gbé ìgbésí ayé onífara-ẹni-rúbọ. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú kó ti ọkàn wa wá láti gbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀, nítorí agbára ìmọnúúrò wa ti jẹ́ kó dá wa lójú pé ìfẹ́ Ọlọ́run là ń ṣe. À ń jẹ́ kí iná ẹ̀mí máa jó nínú wa, a sì ń fi ìtara lo àwọn ẹ̀bùn tó yàtọ̀ síra tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní. À ń fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, à ń sa gbogbo ipá wa láti rí i pé ìṣọ̀kan wà láàárín àwa Kristẹni. À ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò a sì ń ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn.

17 Róòmù orí 12 tún fún wa ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn lórí bó yẹ ká máa ṣe sáwọn tó ń ṣàtakò sí wa. Kò yẹ ká máa foró yaró. Ńṣe ló yẹ ká máa fi ìwà rere borí àtakò. Ó yẹ ká sapá láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn, débi tá a bá lè ṣe é dé láìtẹ ìlànà Bíbélì lójú. A ní láti máa ṣe èyí nínú ilé, nínú ìjọ, sáwọn aládùúgbò wa, níbi iṣẹ́, níléèwé àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ ń gbógun tì wá, a ní láti sa gbogbo ipá wa láti fi ire ṣẹ́gun ibi, ká máa rántí pé ti Jèhófà ni ẹ̀san.

18. Àmọ̀ràn mẹ́ta wo ni Pọ́ọ̀lù gbà wá ní Róòmù 12:12?

18 Ka Róòmù 12:12. Ní àfikún sí gbogbo ìmọ̀ràn àtàtà tó mọ́gbọ́n dání wọ̀nyí, Pọ́ọ̀lù tún fún wa nímọ̀ràn láti ṣe ohun mẹ́ta kan. Níwọ̀n bí a kò ti lè ṣe gbogbo ohun tó ní ká ṣe yìí láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé ká “máa ní ìforítì nínú àdúrà.” Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn míì tó tún fún wa, pé ká “máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú.” Paríparí rẹ̀, a ní láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú ká sì “máa yọ̀ nínú ìrètí” ìyè àìnípẹ̀kun, tí a ó gbà, yálà lọ́run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.

Àtúnyẹ̀wò

• Kí ló yẹ ká ṣe tí wọ́n bá ṣàtakò sí wa?

• Àwọn ibo ló ti yẹ ká jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, lọ́nà wo sì ni?

• Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa wá ọ̀nà láti fúnra wa gbẹ̀san?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn èèyàn tó nílò rẹ̀ lè jẹ́ ká borí ẹ̀tanú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ǹjẹ́ ò ń sapá láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà nínú ìjọ?