Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí

Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí

Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí

“Nǹkan wọ̀nyí ni mo pa láṣẹ fún yín, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—JÒH. 15:17.

1. Kí nìdí táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ wọn já?

 LÁLẸ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ wọn já. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, ó ti kọ́kọ́ sọ fún wọn pé ohun tó máa fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn òun ni ìfẹ́ tí wọ́n bá ń fi hàn sí ara wọn. (Jòh. 13:35) Àwọn àpọ́sítélì ní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, tí wọ́n bá fẹ́ borí àdánwò tó máa tó dojú kọ wọ́n, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ tí Jésù máa tó yàn fún wọn láṣeyọrí. Bó sì ṣe rí nìyẹn, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wá dẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí olùfọkànsìn Ọlọ́run tí wọ́n ní ìfẹ́ alọ́májàá sí ara wọn.

2. (a) Kí la ti pinnu pé a ó máa ṣe, kí sì nìdí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

2 Lóde òní, ìdùnnú ńlá ló jẹ́ fún wa bá a ṣe wà nínú ètò Jèhófà tó kárí ayé táwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. A ti pinnu pé a ó máa tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa fún wa pé ká máa fi ojúlówó ìfẹ́ ba ara wa lò. Àmọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, àwọn èèyàn lápapọ̀ ti di aláìdúróṣinṣin, wọn ò sì ní ìfẹ́ni àdánidá. (2 Tím. 3:1-3) Ọ̀rẹ́ dábẹ̀-n-yànkọ ni wọ́n sábàá máa ń bá ara wọn ṣe. Àmọ́ ká má bàa sọ ìwà Kristẹni wa nù, a kò gbọ́dọ̀ máa bá wọn ṣe irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèré yìí yẹ̀ wò: Orí kí ni àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà máa ń gbé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn kà? Báwo la ṣe lè yan ọ̀rẹ́ àtàtà? Ìgbà wo ló yẹ ká fòpin sí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àwa àti ẹnì kan? Báwo ni àárín àwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kò ṣe ní dà rú?

Orí Kí Ni Àwọn Ọ̀rẹ́ Àtàtà Máa Ń Gbé Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Wọn Kà?

3, 4. Orí kí ni àwọn ọ̀rẹ́ tí àjọṣe wọn gún régé jù lọ máa ń gbé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn kà, kí sì nìdí?

3 Àwọn ọ̀rẹ́ tó bá gbé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn karí ìfẹ́ fún Jèhófà ni àjọṣe wọn máa ń gún régé jù lọ. Sólómọ́nì ọba sọ pé: “Bí ẹnì kan bá sì lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́. Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.” (Oníw. 4:12) Táwọn méjì tó ń bára wọn ṣọ̀rẹ́ bá fi Jèhófà ṣe ẹnì kẹta wọn, irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ló máa ń bá ara wọn kalẹ́.

4 Lóòótọ́, àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè yan ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́, kó sì pé wọn. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló so àwọn ọ̀rẹ́ méjì kan pọ̀, mìmì kan kò ní mi ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn. Tí èdèkòyédè bá wáyé, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà yòó yanjú rẹ̀ lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Táwọn ọ̀tá Ọlọ́run bá fẹ́ da àárín wọn rú, àwọn ọ̀tá náà yóò rí i pé okùn ọ̀rẹ́ àárín àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ṣeé já. Látìgbà láéláé la ti ń rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń múra tán láti kú dípò tí wọ́n á fi ṣe ohun tó máa ṣàkóbá fún àwọn ará wọn.—Ka 1 Jòhánù 3:16.

5. Kí ló mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó wà láàárín Rúùtù àti Náómì tọ́jọ́?

5 Láìsí àní-àní, àwọn tá a lè bá ṣọ̀rẹ́ tá a sì máa gbádùn ara wa jù lọ ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ ti Rúùtù àti Náómì yẹ̀ wò. Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó wà láàárín àwọn obìnrin yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èyí tó wúni lórí jù lọ nínú Bíbélì. Kí ló mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn tọ́jọ́? Rúùtù sọ ìdí rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fún Náómì, ó ní: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. . . . Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì fi kún un, bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá ya èmi àti ìwọ.” (Rúùtù 1:16, 17) Ó ṣe kedere pé Rúùtù àti Náómì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ yìí hàn nínú bí wọ́n ṣe ń ṣe sí ara wọn. Nítorí náà, Jèhófà bù kún àwọn obìnrin méjèèjì yìí.

Bá A Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Àtàtà

6-8. (a) Kí ni àwọn tó bá máa bá ara wọn ṣọ̀rẹ́ kalẹ́ ní láti máa ṣe? (b) Báwo lo ṣe lè lo ìdánúṣe láti yan ọ̀rẹ́?

6 Àpẹẹrẹ Rúùtù àti Náómì fi hàn pé ohun kan ní láti wà tó máa mú kí ẹni méjì di ọ̀rẹ́ àtàtà. Àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àwọn tó bá máa bá ara wọn ṣọ̀rẹ́ kalẹ́ ní láti máa sapá gidigidi, kí wọ́n sì máa yááfì àwọn nǹkan. Kódà, àwọn ọmọ ìyá tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà nínú ìdílé Kristẹni ṣì nílò kí wọ́n máa sapá láti lè bá ara wọn rẹ́. Báwo wá lo ṣe lè ní ọ̀rẹ́ àtàtà?

7 Máa lo ìdánúṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ tó wà ní Róòmù pé kí wọ́n máa “tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Téèyàn bá fẹ́ tọ ipa ọ̀nà kan, ó máa gba pé kéèyàn máa gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Bákan náà, téèyàn bá fẹ́ tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò, ó gba pé kéèyàn máa gbé ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan kó má sì dúró. Wọn kì í bá èèyàn ní ẹ̀mí aájò àlejò. (Ka Òwe 3:27.) Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn ni pé kó o máa pe ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìjọ láti wá bá ọ jẹ oúnjẹ ráńpẹ́. Ǹjẹ́ o lè sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sáwọn ará ìjọ rẹ?

8 Ọ̀nà míì tó o tún lè gbà máa lo ìdánúṣe láti yan ọ̀rẹ́ ni pé kó o máa bá onírúurú àwọn èèyàn ṣíṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Tó o bá dé ẹnu ọ̀nà ilé kan, tó o sì ń gbọ́ tí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ń sọ̀rọ̀ látọkàn wá nípa ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà, wàá túbọ̀ sún mọ́ ẹni náà dáadáa.

9, 10. Àpẹẹrẹ wo ni Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀, báwo la sì ṣe lè fara wé e?

9 Mú kí ìfẹ́ rẹ gbòòrò sí i. (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:12, 13.) Ǹjẹ́ ó ti rò ó rí pé kò sẹ́nì kankan tó o lè bá ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ yín? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé kì í ṣe pé ó lójú irú àwọn èèyàn tó wù ẹ́ láti bá ṣọ̀rẹ́? Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká mú ìfẹ́ wa gbòòrò sí i. Ìgbà kan wà tí Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ bá ẹni tí kì í ṣe Júù ṣọ̀rẹ́. Àmọ́, nígbà tó yá, ó di “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.”—Róòmù 11:13.

10 Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù nìkan ló yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ òun àti Tímótì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, láìwo ti ọjọ́ orí wọn àti ipò wọn tó yàtọ̀ síra. Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni inú wọn ń dùn pé àwọn yan àwọn tó dàgbà ju àwọn lọ nínú ìjọ lọ́rẹ̀ẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vanessa, sọ pé: “Mo ní ọ̀rẹ́ àtàtà kan tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta ọdún. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo lè sọ fún ọ̀rẹ́ tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ni mo lè sọ fún un. Kì í sì í fọ̀rọ̀ mi ṣeré rárá.” Báwo ni wọ́n ṣe dọ̀rẹ́? Vanessa sọ pé: “Mo sapá gan-an kí èmi àti arábìnrin yẹn tó dọ̀rẹ́.” Ṣé ìwọ náà fẹ́ láti yan àwọn èèyàn tẹ́ ẹ kì í jọ ṣe ojúgbà lọ́rẹ̀ẹ́? Ó dájú pé Jèhófà yóò jẹ́ kí ìsapá rẹ yọrí sí rere.

11. Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jónátánì àti Dáfídì?

11 Jẹ́ adúróṣinṣin. Sólómọ́nì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀ pẹ̀lú Jónátánì ni Sólómọ́nì ní lọ́kàn nígbà tó kọ ọ̀rọ̀ yẹn. (1 Sám. 18:1) Sọ́ọ̀lù ọba fẹ́ kí Jónátánì ọmọ òun gorí ìtẹ́ ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn òun. Àmọ́ Jónátánì fara mọ́ yíyàn tí Jèhófà yan Dáfídì láti jọba. Jónátánì kò bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì bí Sọ́ọ̀lù ti ṣe. Kò di Dáfídì sínú nígbà táwọn èèyàn ń yin Dáfídì, bẹ́ẹ̀ ni kò séyìí tó fara mọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sọ́ọ̀lù ń sọ kiri láti ba Dáfídì lórúkọ jẹ́. (1 Sám. 20:24-34) Ṣé àwa náà fìwà jọ Jónátánì? Táwọn ọ̀rẹ́ wa bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, ṣé inú wa máa ń dùn sí wọn? Tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro kan, ṣé a máa ń tù wọ́n nínú ká sì tì wọ́n lẹ́yìn? Tẹ́nì kan bá sọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ wa kan láìdáa lójú wa, ṣé a máa ń tètè gbà á gbọ́? Àbí, a máa ń gbèjà ọ̀rẹ́ wa bí Jónátánì ti ṣe?

Ìgbà Tó Yẹ Ká Fòpin sí Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Àwa àti Ẹnì Kan?

12-14. Ìṣòro wo làwọn kan tó ṣẹ̀sẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń ní, báwo la sì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

12 Nígbà tí ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ọ̀ràn àwọn tó ń bá ṣọ̀rẹ́ lè di ìṣòro fún un. Ó lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń rìn tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì ń gbádùn ara wọn, àmọ́ tí wọn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà rere. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí, ó lè jẹ́ pé lemọ́lemọ́ ni wọ́n jọ máa ń jáde. Ní báyìí, ó ti wá rí i pé àwọn nǹkan táwọn ọ̀rẹ́ òun ń ṣe lè ṣàkóbá fún òun, ó sì rí i pé ó yẹ kóun yẹra fún wọn díẹ̀. (1 Kọ́r. 15:33) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè rò pé tóun ò bá bá wọn rìn mọ́, òun ti di aláìdáa nìyẹn.

13 Tó o bá jẹ́ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà nípò yìí, inú ọ̀rẹ́ tòótọ́ yóò dùn pé ò ń sapá láti mú ìgbésí ayé rẹ dára sí i. Òun náà sì lè fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ọ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àmọ́, àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ́rùnrẹ́rùn yóò máa “bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ [rẹ] tèébútèébú” torí pé o kò bá wọn rìn lọ sínú “kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bíà” mọ́. (1 Pét. 4:3, 4) Ká sòótọ́, kì í ṣe ìwọ lo ṣe àìdáa sí wọn, àwọn ọ̀rẹ́ yìí gan-an ló jẹ́ aláìdáa.

14 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, táwọn ọ̀rẹ́ tó ń bá rìn tẹ́lẹ̀ tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run sì tìtorí ìyẹn pa á tì, àwọn ará ìjọ ló kù tó máa tẹ́wọ́ gbà á. (Gál. 6:10) Ǹjẹ́ o mọ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa ń wá sáwọn ìpàdé ìjọ yín? Ǹjẹ́ o lè máa sún mọ́ wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè rí i pé àwọn lẹ́ni tó lè fún àwọn níṣìírí?

15, 16. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tí ọ̀rẹ́ wa kan kò bá sin Jèhófà mọ́? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

15 Tó bá wá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ wa kan tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí ló pinnu láti kọ ẹ̀yìn sí Jèhófà, tó sì wá di dandan pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń bani lọ́kàn jẹ́ gan-an. Arábìnrin kan sọ bó ṣe ṣe nígbà tí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ kan kò sin Jèhófà mọ́, ó ní: “Ńṣe ló dà bíi pé nǹkan kan kú nínú mi. Gbogbo èrò mi ni pé ọ̀rẹ́ mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú òtítọ́, àṣé kò dúró déédéé. Mo wá ń rò ó pé, ó ní láti jẹ́ torí kó lè tẹ́ àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́run ló ṣe ń sin Jèhófà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í yẹ ara mi wò láti rí ohun tó mú kí èmi náà máa sin Jèhófà. Ṣé ìdí tó yẹ kí n fi máa sin Jèhófà ni mo fi ń sìn ín?” Kí ni arábìnrin yìí wá ṣe? Ó sọ pé: “Mó ju ẹrù ìnira mi sọ́dọ̀ Jèhófà. Mo pinnu láti fi han Jèhófà pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, kì í ṣe torí pé ó jẹ́ kí n lọ́rẹ̀ẹ́ nínú ètò rẹ̀ ló mú kí n máa sìn ín.”

16 A ò lè retí pé a óò jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tá a bá ń gbè sẹ́yìn àwọn tó pinnu láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Ják. 4:4) Nígbà tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú ẹnì kan bá dópin torí pé a fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé e pé yóò ràn wá lọ́wọ́. (Ka Sáàmù 18:25.) Arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo ti wá rí i pé a ò lè fipá mú ẹnikẹ́ni nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tàbí kó nífẹ̀ẹ́ wa. Ìpinnu ara ẹni ni.” Kí la lè ṣe tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú àwọn ará tí kò kúrò nínú ìjọ yóò fi máa lọ déédéé tí yòó sì máa ṣe wá láǹfààní?

Bí Àárín Àwa àti Ọ̀rẹ́ Wa Kò Ṣe Ní Dà Rú?

17. Báwo ló ṣe yẹ káwọn ọ̀rẹ́ àtàtà máa bá ara wọn sọ̀rọ̀?

17 Táwọn ọ̀rẹ́ méjì bá jọ ń sọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ọ̀rẹ́ wọn á túbọ̀ máa wọ̀. Bó o ṣe ń ka ìtàn Rúùtù àti Náómì, Dáfídì àti Jónátánì pẹ̀lú ti Pọ́ọ̀lù àti Tímótì nínú Bíbélì, wàá rí i pé àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà kì í fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún ara wọn, wọ́n sì máa ń fọ̀wọ̀ wọ ara wọn. Pọ́ọ̀lù sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.” Bó ṣe yẹ ká máa bá àwọn “tí ń bẹ lóde,” ìyẹn àwọn tí kì í ṣe ará wa sọ̀rọ̀ lohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yìí. (Kól. 4:5, 6) Tó bá yẹ ká máa bá ẹni tí kì í ṣe onígbàgbọ́ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, dájúdájú, ó yẹ ká máa bá àwọn ọ̀rẹ́ wa nínú ìjọ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀!

18, 19. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìmọ̀ràn èyíkéyìí tí ọ̀rẹ́ wa tó jẹ́ Kristẹni bá fún wa, àpẹẹrẹ wo sì làwọn alàgbà ìjọ Éfésù fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí?

18 Àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà máa ń ka èrò ọ̀rẹ́ wọn sí, torí náà wọ́n máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọn kì í sì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún ara wọn. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé: “Òróró àti tùràrí ni ohun tí ń mú kí ọkàn-àyà yọ̀, bákan náà ni dídùn alábàákẹ́gbẹ́ ẹni jẹ́ nítorí ìmọ̀ràn ọkàn.” (Òwe 27:9) Ṣé ojú tó o fi ń wo ìmọ̀ràn tí ọ̀rẹ́ rẹ bá fún ẹ nìyẹn? ( Sáàmù 141:5.) Tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá sọ pé o ń ṣe nǹkan kan tó ń kọ òun lóminú, kí lo máa ń ṣe? Ṣé o máa ń wo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ bí ọ̀nà kan tí ọ̀rẹ́ rẹ gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí ọ, àbí ńṣe lo máa ń gbà á sí ìbínú?

19 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ Éfésù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà táwọn kan lára wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ló ti mọ̀ wọ́n. Àmọ́ nígbà tó ṣe ìpàdé pẹ̀lú wọn kẹ́yìn, ó fún wọn ní ìmọ̀ràn láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀. Kí làwọn alàgbà yẹn ṣe? Àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù yìí kò gba ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọrírì ìfẹ́ tó ní sí wọn, kódà wọ́n sunkún nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn àti Pọ́ọ̀lù lè má fojú kanra mọ́.—Ìṣe 20:17, 29, 30, 36-38.

20. Kí ni ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ máa ń ṣe?

20 Kì í ṣe pé àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà máa ń gba ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nìkan ni, àwọn náà máa ń fúnni nímọ̀ràn. Àmọ́, ó yẹ ká fòye mọ ìgbà tí kò yẹ ká “yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.” (1 Tẹs. 4:11) Ó tún yẹ ká máa rántí pé “olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Àmọ́ nígbà tó bá yẹ, ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ yóò rán ẹnì kejì rẹ̀ létí àwọn ìlànà Jèhófà. (1 Kọ́r. 7:39) Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe tó o bá rí i pé ọkàn ọ̀rẹ́ rẹ kan tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó ń fà sí ẹnì kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́? Ṣé wàá torí pé o ò fẹ́ kí àárín yín dà rú, o ò ní sọ ohun tó ń kọ ẹ́ lóminú? Tàbí tí ọ̀rẹ́ rẹ kò bá ka ìmọ̀ràn tó o fún un sí, kí lo máa ṣe? Ńṣe lọ̀rẹ́ gidi á gbé ọ̀ràn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣi ẹsẹ̀ gbé náà. Àmọ́ èyí gba ìgboyà? Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé orí ìfẹ́ fún Jèhófà làwọn èèyàn méjì gbé ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn kà, àjọṣe wọn kò ní bà jẹ́ títí lọ.

21. Kí ni gbogbo wa máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa jẹ́ kí ìdè ọ̀rẹ́ tó so wá pọ̀ nínú ìjọ lágbára?

21 Ka Kólósè 3:13, 14. Nígbà míì àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń “ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí” wa, àwọn náà sì máa ń ṣe ohun tó bí wa nínú tàbí kí wọ́n sọ ohun tó dùn wá. Jákọ́bù sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Ják. 3:2) Àmọ́, kì í ṣe iye ìgbà tá a ṣẹ ara wa ló ń fi bí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú ẹnì kan ṣe rí hàn, bí kò ṣe bá a ṣe ń dárí ji ara wa tó. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká jẹ́ kí àjọṣe àwa àti ọ̀rẹ́ wa lágbára nípa bíbá ara wa sọ̀rọ̀ fàlàlà, ká sì máa dárí ji ara wa! Tá a bá ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn, yóò di “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo la ṣe lè yan ọ̀rẹ́ àtàtà?

• Ìgbà wo lo lè yẹ kó o fòpin sí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àárín ìwọ àti ẹnì kan?

• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú ẹnì kan lè máa lágbára sí i?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Orí kí ni ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó tọ́jọ́ tó wà láàárín Rúùtù àti Náómì dá lé?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣé o máa ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn déédéé?