Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àpéjọ Mẹ́ta Ṣe Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà

Bí Àpéjọ Mẹ́ta Ṣe Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà

Bí Àpéjọ Mẹ́ta Ṣe Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà

Gẹ́gẹ́ bí George Warienchuck ṣe sọ ọ́

ǸJẸ́ o ti lọ sí àpéjọ wa kan rí, tí ohun tó o gbọ́ níbẹ̀ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn débi tó o fi ṣe àwọn ìyípadà tó lágbára nínú ìgbésí ayé rẹ? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí. Tí mo bá rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, mo máa ń rí i pé àwọn àpéjọ mẹ́ta kan wà tó jẹ́ pé ohun tí mo gbọ́ níbẹ̀ ló yí ìgbésí ayé mi pa dà jù lọ. Àpéjọ àkọ́kọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe máa tijú ju bó ṣe yẹ lọ, èkejì ló kọ́ mi láti túbọ̀ máa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ìkẹta ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ yọ̀ǹda ara mi. Àmọ́ kí n tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyípadà yẹn, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ ṣàlàyé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé kó to di pé a ṣe àwọn àpéjọ wọ̀nyẹn. Ẹ̀san rere

Ọdún 1928 ni wọ́n bí mi, èmi sì ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọ mẹ́ta táwọn òbí mi bí. Obìnrin làwọn ẹ̀gbọ́n mi méjèèjì, ọ̀kan ń jẹ́ Margie ìkejì sì ń jẹ́ Olga. Ìlú South Bound Brook ní ìpínlẹ̀ New Jersey, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà. Nǹkan bí ẹgbàá [2,000] èèyàn ló ń gbénú ìlú yẹn nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tálákà ni wá, màmá wa lawọ́ gan-an ni. Nígbàkigbà tí màmá wa bá rí owó tó fi máa se oúnjẹ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó máa ń pín nínú oúnjẹ náà fún àwọn aládùúgbò wa. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó gbọ́ èdè Hungary tó jẹ́ èdè ìlú màmá mi wá sílé wa. Èyí sì mú kí màmá mi fetí sí ọ̀rọ̀ tó fẹ́ sọ látinú Bíbélì. Nígbà tó yá Bertha, arábìnrin kan tó lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún, ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ títí màmá mi fi di ìránṣẹ́ Jèhófà.

Èmi ò dà bíi màmá mi, onítìjú èèyàn ni mí, mi ò sì nígboyà. Ohun tó jẹ́ kọ́rọ̀ náà burú sí i ni pé màmá mi máa ń fojú kéré mi. Lọ́jọ́ kan, mo bi í léèrè pẹ̀lú omijé lójú pé: “Kí ló dé tó fi jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo bá ṣe ni kì í dáa lójú yín?” Ohun tó fi dáhùn ni pé torí pé òun nífẹ̀ẹ́ mi, òun kò fẹ́ sọ mí di àkẹ́bàjẹ́. Lóòótọ́, màmá mi nífẹ̀ẹ́ mi, àmọ́ bí kò ṣe ń yìn mí yẹn ń mú kó dà bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan.

Obìnrin kan wà ládùúgbò wa tó máa ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Lọ́jọ́ kan, ó sọ fún mi pé kí n tẹ̀ lé àwọn ọmọkùnrin òun lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi tí wọ́n ń ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Mo mọ̀ pé inú Jèhófà kò ní dùn sí mi tí mo bá lọ, àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí torí pé mi ò fẹ́ ṣẹ màmá tó ń ṣe dáadáa sí mi yẹn. Torí náà, ọ̀pọ̀ oṣù ni mo fi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ń gbà mí tì fúnra mi. Ní ilé ìwé wa, ìbẹ̀rù èèyàn tún mú kí n ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn mi. Kìígbọ́-kìígbà èèyàn ni ọ̀gá ilé ìwé wa, ó rí i dájú pé àwọn olùkọ́ ń mú kí gbogbo àwọn ọmọ ilé ìwé kí àsíá. Èmi náà bá wọn kí i. Ó tó bí ọdún kan tọ́rọ̀ náà fi ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ kó tó di pé ìyípadà kan wáyé.

Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Pé Ó Yẹ Kí N Jẹ́ Onígboyà

Lọ́dún 1939, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan nílé wa. Arákùnrin Ben Mieszkalski tó jẹ́ ọ̀dọ́ aṣáájú-ọ̀nà kan ló ń darí rẹ̀. Ben Ìgìrìpá ni orúkọ ìnagijẹ tá a máa ń pè é, orúkọ yẹn sì bá a mu. Lójú mi ó ga tó ilẹ̀kùn àbáwọlé wa, sísanra rẹ̀ sì gba gbogbo ẹnu ọ̀nà náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fìrìgbọ̀n rẹ̀ tó ba èèyàn lẹ́rù, síbẹ̀ ọlọ́kàn rere ni, bó sì ṣe máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ ń mú kí ara mi balẹ̀ tí mo bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Torí náà nígbà tí Ben sọ pé kémi àtohun jọ lọ sóde ẹ̀rí, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi fara mọ́ ọn. Bá a ṣe di ọ̀rẹ́ nìyẹn. Nígbà tí ohun kan bá bà mí nínú jẹ́, ó máa ń bá mi sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí ẹ̀gbọ́n onífẹ̀ẹ́ bá ń bá àbúrò rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń fún mi níṣìírí gan-an, mo sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.

Lọ́dún 1941, Ben sọ pé òun á fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ òun gbé ìdílé wa lọ sí àpéjọ kan ní ìlú St. Louis tó wà ní ìpínlẹ̀ Missouri. Ẹ ò lè mọ bó ṣe dùn mọ́ mi nínú tó! Mi ò tíì lọ síbi tó jìnnà ju ọgọ́rin [80] kìlómítà sílé wa rí, àmọ́ ní báyìí mo máa rìnrìn àjò lọ síbí tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] kìlómítà lọ! Àmọ́ a ní àwọn ìṣòro kan nígbà tá a dé ìlú St. Louis. Àwọn àlùfáà ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n fagi lé ètò èyíkéyìí tí wọ́n ti ṣe pé káwọn Ẹlẹ́rìí dé sínú ilé wọn. Ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ wọn ló sì fagi lé ètò tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n halẹ̀ mọ́ àwọn ìdílé tó ni ilé tí wọ́n pín àwa náà sí, àmọ́ wọ́n pàpà gbà wá sílé wọn. Wọ́n ní àwọn ti ṣèlérí pé àwọn á fún wa ní yàrá kan, àwọn sì gbọ́dọ̀ mú ìlérí àwọn ṣẹ. Ìgboyà wọn wú mi lórí gan-an ni.

Àpéjọ yìí ni àwọn ẹ̀gbọ́n mi ti ṣèrìbọmi. Lọ́jọ́ kan náà yẹn, Arákùnrin Rutherford tó wá láti Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn sọ àsọyé alárinrin kan. Nínú àsọyé yẹn ló ti sọ pé kí gbogbo àwọn ọmọdé tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dìde dúró. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000] ọmọdé ló dìde. Èmi náà dìde. Lẹ́yìn náà ló wá sọ pé kí àwa ọmọdé tá a bá fẹ́ ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé nínú iṣẹ́ ìwàásù sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Gbogbo àwa ọmọdé tó wà nídùúró la pariwo pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” Àtẹ́wọ́ wá dún lọ bí ààrá. Ìgbà yẹn ni ìtara mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í jó lala.

Lẹ́yìn àpéjọ yẹn, a lọ kí arákùnrin kan ní ìpínlẹ̀ West Virginia. Ó sọ ìrírí kan tó ní lọ́jọ́ kan lóde ẹ̀rí fún wa. Ó ní àwọn jàǹdùkú kan tínú ń bí lu játijàti sóun lára, wọ́n fi ọ̀dà kun òun lára, wọ́n sì lẹ ìyẹ́ mọ́ gbogbo ara òun láti fi òun ṣe ẹlẹ́yà. Ṣe ni mò ń wò ó tìyanutìyanu bí mo ṣe ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. Arákùnrin yìí sọ pé: “Ṣùgbọ́n mi ò ní jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe.” Nígbà tá a kúrò níbẹ̀, ó ti ń ṣe mí bíi pé kí n lọ ko ọ̀gá ilé ìwé wa lójú pé mi ò ní kí àsíá mọ́. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Dáfídì fẹ́ lọ kojú Gòláyátì.

Nígbà tí mo pa dà dé ilé ìwé, mo lọ bá ọ̀gá ilé ìwé wa. Ó ń wò mí tìkà tẹ̀gbin. Mo gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo wá yára sọ pé: “Mo ti lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mi ò ní kí àsíá mọ́!” Àwa méjèèjì dákẹ́ lọ gbári. Ọ̀gá náà rọra dìde kúrò níbi àga tó wà, ó sì rìn wá sọ́dọ̀ mi. Inú ń bí i burúkú burúkú, ojú ẹ̀ sì pọ́n koko. Ó jágbe mọ́ mi, ó ní: “Tó ò bá kí àsíá, a máa lé ọ kúrò nílé ìwé yìí!” Lọ́tẹ̀ yìí, mi ò juwọ́ sílẹ̀, nísàlẹ̀ ikùn mi lọ́hùn-ún, mo ń nímọ̀lára ayọ̀ tí mi ò tíì ní irú rẹ̀ rí.

Ara mi ti wà lọ́nà láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Ben. Nígbà tí mo rí i nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba mo pariwo pé: “Wọ́n ti lé mi kúrò ní ilé ìwé nítorí pé mi ò kí àsíá!” Ben wá fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn, ó rẹ́rìn-ín, ó ní: “Ó dájú pé Jèhófà fẹ́ràn rẹ.” (Diu. 31:6) Kóríyá ni gbólóhùn tó sọ yẹn jẹ́ fún mi. Nígbà tó di June 15, ọdún 1942, mo ṣèrìbọmi.

Mo Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Ní Ìtẹ́lọ́rùn

Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè wa búrẹ́kẹ́, ìfẹ́ láti kó ohun ìní jọ wá gbòde kan. Owó gọbọi ni mò ń gbà níbi iṣẹ́ ti mo ń ṣe, èyí mú kó ṣeé ṣe fún mi láti rówó ra àwọn ohun tí mi ò lálàá pé mo lè rà tẹ́lẹ̀. Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ra alùpùpù, àwọn míì tún ilé wọn ṣe. Àmọ́ ní tèmi, agánrán ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun ni mo rà. Kò pẹ́ tí ìfẹ́ ọkàn mi láti ní àwọn ohun amáyédẹrùn fi mú kí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn nígbèésí ayé mi. Mo sì mọ̀ fúnra mi pé ohun tí mo ń lépa yìí kò dára. Àmọ́ mo dúpẹ́ pé àpéjọ kan tá a ṣe lọ́dún 1950 ní ìlú New York City ràn mí lọ́wọ́ láti tún èrò ara mi pa.

Ní àpéjọ yẹn, àwọn olùbánisọ̀rọ̀ lọ́kan-ò-jọ̀kan rọ àwọn àwùjọ pé kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. Olùbánisọ̀rọ̀ kan tiẹ̀ sọ pé: “Ẹ já gbogbo ohun tí kò bá pọn dandan dà nù, kẹ́ ẹ sì máa sá eré ìje náà.” Ó dà bíi pé èmi gan-an ló ń bá wí. Mo tún wo ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, èyí sì mú kí n ronú pé, ‘Táwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ mi bá lè yááfì àwọn ìgbádùn ara wọn, tí wọ́n sì ń lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè, ó yẹ kémi náà lè ṣe irú rẹ̀ nílé níbí.’ Nígbà tí àpéjọ náà fi máa parí, mo ti pinnu pé màá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Ní gbogbo àkókò yẹn, èmi àti Evelyn Mondak, tó jẹ́ akéde onítara ní ìjọ kan tí mo lọ nígbà kan, ti ń fẹ́ ara wa sọ́nà. Ọmọ mẹ́fà ni ìyá Evelyn bí. Màmá yìí jẹ́ onígboyà èèyàn. Ó fẹ́ràn àtimáa ṣe ìjẹ́rìí òpópónà níwájú ṣọ́ọ̀ṣì ràgàjì kan tó jẹ́ tàwọn Kátólíìkì. Lemọ́lemọ́ ni àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì yẹn máa ń fìbínú sọ fún un pé kó kúrò níwájú ṣọ́ọ̀ṣì àwọn, ṣùgbọ́n màmá náà kò yéé lọ síbẹ̀. Evelyn náà fi àìṣojo jọ ìyá rẹ̀, kì í bẹ̀rù èèyàn.—Òwe 29:25.

Èmi àti Evelyn ṣègbéyàwó lọ́dún 1951, a pa iṣẹ́ tá à ń ṣe tì, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Alábòójútó àyíká kan gbà wá níyànjú pé ká lọ sí abúlé Amagansett, tó wà létí òkun Àtìláńtíìkì. Abúlé yẹn fi nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà jìnnà sí ìlú New York City. Àwọn ará ìjọ tó wà níbẹ̀ sọ fún wa pé àwọn ò ní ilé tí a ó máa gbé. La bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá ilé alágbèérìn, àmọ́ a ò rí èyí tówó wa ká. Nígbà tó yá, a rí ògbólógbòó ilé alágbèérìn kan. Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] owó dọ́là ni ẹni tó ni í dá lé e. Iye owó yẹn gan-an sì ni gbogbo ẹ̀bùn ìgbéyàwó tá a rí gbà. Bá a ṣe rà á nìyẹn, tá a tún un ṣe tá a sì gbé e lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tuntun. Àmọ́ nígbà tá a débẹ̀, kò sí owó kankan lọ́wọ́ wa, a sì wá ń ronú bá ó ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wa gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà.

Ìyàwó mi ń ṣiṣẹ́ atúnléṣe, èmi sì ríṣẹ́ sí ilé oúnjẹ kan tó jẹ́ tàwọn ará Ítálì. Alẹ́ ni mo máa ń tún ibẹ̀ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tajà tán. Ẹni tó ni ibẹ̀ sọ fún mi pé: “Máa kó àwọn oúnjẹ tó bá ṣẹ́ kù lọ sílé fún ìyàwó rẹ.” Torí náà tí mo bá ti ń délé ní aago méjì òru, ńṣe ni ilé wa máa ń ta sánsán fún òórùn búrẹ́dì tí wọ́n fi ẹran pẹ̀lú ewébẹ̀ há àti òórùn oúnjẹ alápòpọ̀ míì. Tá a bá wá gbé oúnjẹ wọ̀nyí gbóná, àjẹpọ́nnulá ni, pàápàá nígbà òtútù, tá a máa ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nínú yìnyín tó bo gbogbo ilé wa. Yàtọ̀ síyẹn, láwọn ìgbà míì, àwọn ará ìjọ máa ń gbé ẹja ńlá kan sẹ́nu àtẹ̀gùn àbáwọlé wa. Láwọn ọdún tá a fi ń sìn lábúlé Amagansett pẹ̀lú àwọn ará wa yẹn, a kẹ́kọ̀ọ́ pé téèyàn bá jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun kòṣeémánìí díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ìgbésí ayé á dùn fún onítọ̀hún. A mà gbádùn àwọn ọdún yẹn o!

A Rí ìṣírí Gbà Láti Túbọ̀ Yọ̀ǹda Ara Wa

Ní oṣù July ọdún 1953, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn míṣọ́nnárì ló wálé látibi tí wọ́n ti ń sìn nílẹ̀ òkèèrè, wọ́n wá ṣe àpéjọ àgbáyé nílùú New York City. Nígbà tá a lọ kí wọn, wọ́n sọ àwọn ìrírí alárinrin. Ó ń ṣe wá bíi káwa náà ní irú ayọ̀ tí wọ́n ń ní yẹn. Síwájú sí i, nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ kan sọ ní àpéjọ yẹn pé ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ló wà tí ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kò tíì dé, a mọ ohun tó yẹ ká ṣe. A mọ̀ pé ó yẹ ká túbọ̀ yọ̀ǹda ara wa ká mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i. Níbẹ̀ ní àpéjọ yẹn la ti gba fọ́ọ̀mù fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì. Ọdún yẹn kan náà ni wọ́n pè wá sí kíláàsì kẹtàlélógún Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù February ọdún 1954. Àbí ẹ ò rí àǹfààní ńlá tí ìyẹn jẹ́!

Inú wa dùn gan-an nígbà tá a gbọ́ pé orílẹ̀-èdè Brazil ni wọ́n ní ká ti lọ máa sìn. Kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́rìnlá nínú ọkọ̀ ojú omi, arákùnrin kan tó wà lára àwọn tó ń bójú tó Bẹ́tẹ́lì sọ fún mi pé: “Arábìnrin mẹ́sàn-án tí kò tíì lọ́kọ tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì máa bá ìwọ àti ìyàwó rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Brazil. Tọ́jú wọn dáadáa o!” Tẹ́ ẹ bá rí i báwọn tó ń tukọ̀ ojú omi yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín nígbà tí wọ́n rí èmi àtàwọn ọmọge mẹ́wàá tá à ń wọnú ọkọ̀ wọn lọ! Àmọ́ àwọn arábìnrin náà ti mọ bí wọ́n ṣe máa ṣe ọ̀ràn ara wọn. Síbẹ̀ ìgbà tá a tó dé orílẹ̀-èdè Brazil láìséwu lọkàn mi tó balẹ̀.

Lẹ́yìn tí mo ti kọ́ èdè Potogí, wọ́n ní kí n lọ máa ṣe alábòójútó àyíká ní ìpínlẹ̀ Rio Grande do Sul tó wà ní apá gúúsù lórílẹ̀-èdè Brazil. Alábòójútó àyíká tí mo fẹ́ lọ rọ́pò níbẹ̀ sọ fún mí pé: “Ó jọ mí lójú pé ẹni tó ti níyàwó ni wọ́n gbé wá síbí. Ibí yìí ò rọrùn o.” Ìgbèríko tó jìnnà síra ni àwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ wà, ọkọ̀ ńlá akẹ́rù nìkan ló lè gbé èèyàn dé àwọn ibì kan níbẹ̀. Kí dírẹ́bà tó gba èèyàn láyé láti gòkè sínú ọkọ̀ rẹ̀, èèyàn ní láti ra oúnjẹ fún un. Ńṣe la máa ń dà bí ẹni tó jókòó lórí ẹṣin, a ó la ẹsẹ̀ wa méjèèjì bá a ṣe jókòó lórí àwọn ẹrù, a ó sì fi ọwọ́ wa méjèèjì di okùn tó wà lára àwọn ẹrù náà mú. Nígbàkigbà tí ọkọ̀ akẹ́rù yẹn bá yí kọ́nà, ṣe la máa ń di nǹkan mú pinpin ká má bàa ṣubú, táwọn ẹrù yẹn á sì dà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. A ó sì máa rí àwọn àfonífojì tó wà ní ọ̀nà yẹn. Àmọ́ nígbà tá a bá dé ibi tá à ń lọ tá a rí àwọn ará tí wọ́n ti ń retí wa, inú wa máa ń dùn, a sì máa ń rí i pé ìsapá wa kò já sásán.

Ilé àwọn ará la máa ń dé sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìní ni wọ́n, ìyẹn ò dí wọn lọ́wọ́ ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún wa. Ní àgbègbè àdádó kan, ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń di ègé ẹran ni gbogbo àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́. Owó tó ń wọlé fún wọn kéré débi pé ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n ń jẹun lójúmọ́. Tí wọ́n ò bá sì ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kan, wọn ò ní gbowó ọjọ́ náà. Síbẹ̀ nígbà tá a bá ti wá bẹ̀ wọ́n wò, wọ́n máa ń gbàyè ọjọ́ méjì níbi iṣẹ́ kí wọ́n lè ráyè lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìjọ lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àwọn arákùnrin rírẹlẹ̀ yẹn kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ kan nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa yááfì àwọn nǹkan kan torí àtilè ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run, a ò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ yẹn láé. Gbígbé tá a gbé láàárín wọn kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ tá ò lè rí kọ́ nílé ìwé kankan. Tí mo bá tún rántí àwọn arákùnrin yẹn, omijé ayọ̀ máa ń dà lójú mi.

Lọ́dún 1976, a pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ tójú màmá mi tára rẹ̀ ò le mọ́. Kò rọrùn fún wa láti fi orílẹ̀-èdè Brazil sílẹ̀, àmọ́ a dúpẹ́ pé ìbísí kíkàmàmà tó ń wáyé níbẹ̀ ṣojú ẹ̀mí wa. Nígbàkigbà tá a bá gba lẹ́tà láti orílẹ̀-èdè Brazil, a máa ń rántí àwọn ohun àgbàyanu tá a ti gbádùn níbẹ̀.

A Tún Fojú Kan Àwọn Ọ̀rẹ́ Wa Ọ̀wọ́n

Nígbà tá à ń tọ́jú màmá mi, à ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, a sì ń fi iṣẹ́ atúnléṣe gbọ́ bùkátà ara wa. Ìyá mi kú lọ́dún 1980, gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Jèhófà. Lẹ́yìn ikú màmá mi, wọ́n ní kí n máa ṣe alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1990, èmi àti ìyàwó mi lọ bẹ ìjọ kan wò ní ìpínlẹ̀ Connecticut, la bá rí ẹni ọ̀wọ́n kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ náà. Ẹni náà ni Ben, ìyẹn Ben tó ràn mí lọ́wọ́ ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn láti ṣohun tó tọ́ lójú Jèhófà. Ẹ fojú inú wo bí ayọ̀ wa ṣe pọ̀ tó bá a ṣe dì mọ́ ara wa?

Láti ọdún 1996, èmi àti ìyàwó ń sìn ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí ní ìpínlẹ̀ New Jersey, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí kò lera. Mo ní àìlera tó ń bá mi fínra, àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ aya mi ọ̀wọ́n, mo ń ṣe ìwọ̀nba tágbára mi ká nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ìyàwó mi tún ń tọ́jú ìyá kan tó ti darúgbó kùjọ́kùjọ́ tó ń gbé ládùúgbò wa. Ǹjẹ́ ẹ mọ ẹni náà? Ìyá yìí ni Bertha, ẹni tó ran màmá mi lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà lóhun tó lé ní àádọ́rin ọdún sẹ́yìn! Inú wa dùn pé a láǹfààní láti sanjọ́ fún màmá yìí fún bó ṣe ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Mo dúpẹ́ pé àwọn àpéjọ tá a ṣe láwọn ìgbà yẹn ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi pinnu láti máa ṣe ìjọsìn tòótọ́, wọ́n tún ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ohun ìní tara díẹ̀ tẹ́ mi lọ́rùn, wọ́n sì tún ràn mí lọ́wọ́ láti fi kún ipa tí mò ń kó nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ó dájú pé àwọn àpéjọ yẹn ló yí ìgbésí ayé mi pa dà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìyá Evelyn rèé (lápá òsì) lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyá mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ben ọ̀rẹ́ mi rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Orílẹ̀-èdè Brazil la wà yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti ìyàwó mi rèé báyìí