Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ó yẹ kí arábìnrin tó bá ń túmọ̀ àsọyé Bíbélì sí èdè àwọn adití ní ìpàdé ìjọ tàbí ní àwọn àpéjọ fi nǹkan bo orí rẹ̀?

Ní kúkúrú, ó yẹ kí arábìnrin kan bo orí rẹ̀ tó bá ń bójú tó iṣẹ́ kan tó yẹ kí ọkọ rẹ̀ tàbí arákùnrin kan nínú ìjọ bójú tó, tí nǹkan bá lọ bó ṣe yẹ. Èyí bá ìlànà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ mu, pé “olúkúlùkù obìnrin tí ń gbàdúrà tàbí tí ń sọ tẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀ dójú ti orí rẹ̀” nítorí pé “orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́r. 11:3-10) Tí arábìnrin kan bá fi ohun tó mọ níwọ̀n tó sì bójú mu bo orí rẹ̀ nígbà tó bá ń ṣe irú iṣẹ́ báyẹn, ńṣe ló ń fi hàn pé òun fara mọ́ bí Ọlọ́run ṣe ṣètò àwọn nǹkan nínú ìjọ Kristẹni.—1 Tím. 2:11, 12. a

Àmọ́ tí arábìnrin kan bá ń túmọ̀ àsọyé tí arákùnrin kan ń sọ sí èdè àwọn adití ńkọ́? Lóòótọ́, arábìnrin náà kò ṣe ju iṣẹ́ ògbufọ̀ lọ. Ìyẹn ni pé òun gan-an kọ́ ló ń kọ́ni, ṣe ló wulẹ̀ ń túmọ̀ ohun tí arákùnrin tó ń kọ́ni ń sọ. Ṣùgbọ́n, títúmọ̀ àsọyé sí èdè àwọn adití yàtọ̀ gan-an sí títúmọ̀ àsọyé sáwọn èdè míì tá à ń sọ lẹ́nu. Ní ti èdè tá à ń sọ lẹ́nu, àwọn tó ń gbọ́ àsọyé yẹn ṣì lè máa wo olùbánisọ̀rọ̀, síbẹ̀ kí wọ́n máa gbọ́ ẹni tó ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun tó tún mú kí títúmọ̀ àsọyé sáwọn èdè tá a ń sọ lẹ́nu yàtọ̀ sí títúmọ̀ àsọyé sí èdè àwọn adití ni pé, ibi tí arábìnrin tó ń ṣe ògbufọ̀ èdè tá a ń sọ lẹ́nu sábà máa ń wà kì í jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lérò pé òun gan-an ló ń sọ àsọyé. Kódà nígbà míì, wọ́n láǹfààní láti jókòó bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ lọ́wọ́. Tí wọ́n bá sì wà lórí ìnàró, wọ́n láǹfààní láti kọjú sí olùbánisọ̀rọ̀ dípò kí wọ́n máa wo àwùjọ. Torí náà, kò ní pọn dandan pé káwọn arábìnrin tó ń ṣe ògbufọ̀ èdè tá a ń sọ lẹ́nu fi nǹkan bo orí.

Láfikún sí èyí, nítorí ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n ń lò báyìí nígbà tí wọ́n bá ń túmọ̀ àsọyé sí èdè àwọn adití, ipa tí ògbufọ̀ kan ń kó lè di èyí tó túbọ̀ hàn gbangba. Àwòrán rẹ̀ ló sábà máa ń yọ lójú ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ńlá tí wọ́n bá lò, wọ́n sì lè ṣàìrí arákùnrin tó ń sọ àsọyé yẹn gan-an fúnra rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti sọ yìí, á dára kí arábìnrin tó ń túmọ̀ àsọyé sí èdè àwọn adití fi nǹkan bo orí láti fi hàn pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ àsọyé, àmọ́ ńṣe lòun kàn ń túmọ̀.

Báwo ni ìtọ́ni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí pa dà yìí ṣe máa kan títúmọ̀ ọ̀rọ̀ sí èdè àwọn adití nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, nígbà àṣefihàn, nígbà táwọn ará bá ń dáhùn nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́? Ṣé arábìnrin tó ń túmọ̀ sí èdè àwọn adití láwọn àkókò yẹn ní láti fi nǹkan bo orí? Ó jọ pé kò ní pọn dandan kí arábìnrin náà bo orí ní àwọn ipò kan, níwọ̀n bí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ á ti mọ̀ pé òun kọ́ ló ń darí ìpàdé. Àpẹẹrẹ irú ipò bẹ́ẹ̀ ni ìgbà tí arábìnrin kan bá ń túmọ̀ ìdáhùn tí ẹnì kan dáhùn láàárín àwùjọ, tó bá ń túmọ̀ iṣẹ́ táwọn arábìnrin ṣe tàbí àṣefihàn. Àmọ́ o, nígbà tó bá ń túmọ̀ àwọn àsọyé tí arákùnrin sọ nínú àwọn ìpàdé yìí, tàbí tó bá ń ṣe ògbufọ̀ fún olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, tàbí ẹni tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, tàbí tó bá jẹ́ pé òun ló ń ṣáájú wọn nínú kíkọ orin ní èdè àwọn adití, ó ní láti bo orí rẹ̀. Ó lè di dandan fún arábìnrin kan láti ṣe ògbufọ̀ fún àwọn arákùnrin, arábìnrin, ọmọdé àtàwọn alàgbà nínú ìpàdé kan ṣoṣo. Nítorí ìdí yẹn, ohun táá dára jù lọ ni pé kó kúkú fi nǹkan bo orí jálẹ̀ ìpàdé náà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìgbà tó yẹ kí obìnrin Kristẹni máa bo orí àti ìdí tó fi yẹ kó máa ṣe bẹ́ẹ̀, wo ojú ìwé 209 sí 212 nínú ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’