Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífúnni Ní Nǹkan Látọkàn Wá

Fífúnni Ní Nǹkan Látọkàn Wá

Fífúnni Ní Nǹkan Látọkàn Wá

NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa fífúnni, ó kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọr. 9:7) Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. Ó máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní láti fi ìfọkànsìn wọn hàn nípa fífún òun ní nǹkan tìdùnnú-tìdùnnú látọkàn wọn wá. Látìgbà láéláé làwọn èèyàn rẹ̀ ti máa ń mú ọrẹ wá fún un tìdùnnú-tìdùnnú. Wo àpẹẹrẹ mẹ́ta wọ̀nyí.

Lẹ́yìn tí Jèhófà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn. Wọ́n nílò àwọn ohun tí wọ́n máa fi kọ́ ọ, torí náà Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọrẹ wá. Kí ni wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀ sí, ńṣe ni “olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́” bẹ̀rẹ̀ sí í mú wúrà àti fàdákà, ohun ọ̀ṣọ́ ara, àtàwọn ohun èlò míì wá. Àwọn èèyàn fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣe ọrẹ débi pé wọ́n ní láti kéde pé kí wọ́n ṣíwọ́ mímú ọrẹ wá.—Ẹ́kís. 35:5, 21; 36:6, 7.

Bákan náà, nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run fẹ́ kọ́ tẹ́ńpìlì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n tún láǹfààní láti fi hàn pé àwọn ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. Dáfídì Ọba fúnra rẹ̀ fi ohun tó pọ̀ ṣe ọrẹ fún iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì yẹn, ó sì rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé káwọn náà mú ọrẹ wá. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ṣe ìtìlẹ́yìn náà. Àní, iye wúrà àti fàdákà tí wọ́n dá jọ nìkan á ju èyí tá a máa rà ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là ní iye owó ti àkókò yìí! Àwọn èèyàn náà yọ̀ nítorí bí wọ́n ṣe ń fún Jèhófà ní ọrẹ àtinúwá.—1 Kíró. 29:3-9; 2 Kíró. 5:1.

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ti ọ̀rúndún kìíní náà fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ọrẹ. Ní ọjọ́ àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn ló ṣe batisí, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn kì í sì í gbé Jerúsálẹ́mù. Kí wọ́n lè rí nǹkan bójú tó àwọn aláìní tó dúró sí ìlú náà láti kọ́ ẹ̀kọ́ sí i nípa ẹ̀sìn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà, àwọn Kristẹni dá owó jọ fúngbà díẹ̀. Wọ́n ta àwọn ohun ìní wọn, wọ́n sì kó owó tí wọ́n rí níbẹ̀ wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, pé kí wọ́n fi bójú tó àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà yóò dùn gan-an láti rí báwọn èèyàn ṣe ń fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́!—Ìṣe 2:41-47.

Lóde òní, àwọn Kristẹni máa ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́ nípa yíyọ̀ǹda àkókò, okun àti owó wọn tayọ̀tayọ̀. Àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ ọ̀nà tó o lè gbà ṣe irú ìtìlẹ́yìn yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ

Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn. O sì lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. (O tún lè fi ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn nísàlẹ̀ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.) Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, “Watch Tower” ni kó o kọ sórí rẹ̀ pé kí wọ́n san án fún. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣeyebíye tàbí dúkìá mìíràn ṣètọrẹ. Kí o sì kọ lẹ́tà ṣókí mọ́ ohun tó o fẹ́ fi ránṣẹ́ láti fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́.

ỌRẸ TÉÈYÀN WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣàǹfààní fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì ẹni lẹ́nu iṣẹ́, síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí wọ́n san owó náà fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni, níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.

Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debenture Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ. A sì lè ní kí ẹ̀tọ́ náà di ti Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni.

Ilẹ̀ àti Ilé: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbénú rẹ̀, olùtọrẹ náà lè fi tọrẹ àmọ́ kó sọ pé òun á ṣì máa gbénú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tóun bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ tàbí ilé èyíkéyìí di èyí tó o fi ta wá lọ́rẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Téèyàn Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká ṣe ìwé pé Watch Tower ni ẹni tí yóò ni ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu bà wọ̀nyí lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “ọrẹ téèyàn wéwèé” gba pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà fara balẹ̀ wéwèé wọn kó tó ṣe irú ìtọrẹ bẹ́ẹ̀.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o fi nọ́ńbà tẹlifóònù tó wà níbi àdírẹ́sì náà pè wá, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Jehovah’s Witnesses

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Tẹlifóònù wa ni: 07080662020