Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Àdúrà Rẹ Ń Sọ Nípa Rẹ?

Kí Ni Àdúrà Rẹ Ń Sọ Nípa Rẹ?

Kí Ni Àdúrà Rẹ Ń Sọ Nípa Rẹ?

“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.”—SM. 65:2.

1, 2. Kí nìdí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi lè máa gbàdúrà sí i pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn?

 JÈHÓFÀ kì í fi gbígbọ́ ṣe aláìgbọ́ nígbà táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń tọrọ nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀. Ọkàn wa balẹ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa. Kódà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá gbàdúrà sí i lẹ́ẹ̀kan náà, kò sẹ́ni tí Ọlọ́run kò ní rétí gbọ́ tirẹ̀ nínú wa.

2 Ó dá Dáfídì lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ òun, ìdí nìyẹn tó fi kọ ọ́ lórin nínú Sáàmù pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.” (Sm. 65:2) Ìdí tí Dáfídì fi ń rí ìdáhùn àdúrà rẹ̀ gbà ni pé adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà ni. Àwa náà ní láti bi ara wa léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi ń fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti pé ìjọsìn mímọ́ rẹ̀ jẹ mí lógún? Kí ni àdúrà mi ń sọ nípa mi?’

Fi Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Gbàdúrà sí Jèhófà

3, 4. (a) Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tí ‘ìrònú kan bá ń gbé wa lọ́kàn sókè’ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan tá a dá?

3 Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí i. (Sm. 138:6) A ní láti bẹ Jèhófà pé kó ṣàyẹ̀wò wa, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ṣe bẹ̀ ẹ́ nígbà tó sọ pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sm. 139:23, 24) Yàtọ̀ sí pé ká gbàdúrà, ó tún yẹ ká máa fàyè sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti yẹ̀ wá wò ká sì máa fara mọ́ ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jèhófà lè ṣamọ̀nà wa “ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin,” ìyẹn ni pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa tọ ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

4 Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ‘ìrònú kan ń gbé wa lọ́kàn sókè’ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan tá a dá ńkọ́? (Ka Sáàmù 32:1-5.) Tá a bá ń gbìyànjú láti pa ẹ̀rí ọkàn wa tó ń dá wa lẹ́bi lẹ́nu mọ́, ńṣe la máa di aláìlókun, bí igi tó gbẹ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì, ó pàdánù ayọ̀ rẹ̀, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìsàn kọ lù ú. Àmọ́ nígbà tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Ọlọ́run, ara mà tù ú gan-an ni o! Fojú inú wo bí ayọ̀ rẹ̀ á ṣe pọ̀ tó nígbà tó rí i pé Jèhófà ti ‘dárí ìdìtẹ̀ àti ẹ̀ṣẹ̀ òun ji òun.’ Téèyàn bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Ọlọ́run, ara lè tu onítọ̀hún, ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tún máa jẹ́ kí ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà tún pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Òwe 28:13; Ják. 5:13-16.

Máa Rawọ́ Ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run Kó O sì Máa Dúpẹ́

5. Kí ló túmọ̀ sí láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà?

5 Tí àníyàn bá gbà wá lọ́kàn torí ọ̀ràn kan, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílí. 4:6) Ohun tó túmọ̀ sí láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ ni pé “kéèyàn fi ìrẹ̀lẹ̀ pàrọwà.” Nígbà tá a bá wà nínú ewu tàbí inúnibíni, ó ṣe pàtàkì pé ká bẹ Jèhófà kí ó kó wa yọ kó sì ràn wá lọ́wọ́.

6, 7. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa dúpẹ́ fún nínú àdúrà wa?

6 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kìkì ìgbà tá a nílò nǹkan la máa ń gbàdúrà, kí nìyẹn ń sọ nípa irú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà? Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa sọ àwọn ohun tá à ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run “pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́.” Àwa náà gbọ́dọ̀ ní irú ẹ̀mí tí Dáfídì ní, tó mú kó sọ pé: “Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì; nítorí ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo. . . . Ọlọ́run wa, àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì ń yin orúkọ rẹ alẹ́wàlógo.”—1 Kíró. 29:11-13.

7 Jésù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oúnjẹ tó pèsè, ó sì tún gbàdúrà ìdúpẹ́ sórí búrẹ́dì àti wáìnì tí wọ́n lò nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. (Mát. 15:36; Máàkù 14:22, 23) Àwa náà ní láti máa fi ìmọrírì hàn fún irú ìpèsè bẹ́ẹ̀. Ó tún yẹ ká “máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà. . . . nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn,” “nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ òdodo” àti nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá à ń rí kà nínú Bíbélì báyìí.—Sm. 107:15; 119:62, 105.

Máa Gbàdúrà Fáwọn Ẹlòmíì

8, 9. Kí nìdí tá a fi ní láti máa gbàdúrà fáwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni?

8 Láìsí àní-àní, olúkúlùkù wa máa ń gbàdúrà fún ara rẹ̀, àmọ́ ó tún yẹ ká máa rántí àwọn ẹlòmíì nínú àdúrà wa, títí kan àwọn ará wa tá ò mọ orúkọ wọn pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè má mọ gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní Kólósè, síbẹ̀ ó sọ pé: “Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi nígbà gbogbo tí a bá ń gbàdúrà fún yín, níwọ̀n bí a ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ yín ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù àti ìfẹ́ tí ẹ ní fún gbogbo ẹni mímọ́.” (Kól. 1:3, 4) Pọ́ọ̀lù tún gbàdúrà fáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà. (2 Tẹs. 1:11, 12) Irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ ń sọ ohun púpọ̀ nípa wa àti ojú tá a fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa.

9 Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ńṣe là ń fi hàn pé ọ̀ràn ètò Ọlọ́run jẹ wá lógún. (Jòh. 10:16) Pọ́ọ̀lù ní káwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà máa gbàdúrà fóun, kí òun lè ‘ní agbára láti sọ̀rọ̀, kóun bàa lè sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìhìn rere di mímọ̀.’ (Éfé. 6:17-20) Ṣé àwa náà máa ń dá gbàdúrà fáwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lọ́nà yẹn?

10. Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn ẹlòmíì, àǹfààní wo ló lè ṣe fún wa?

10 Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn ẹlòmíì, ó lè jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò rere nípa wọn. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn ẹnì kan àmọ́ tá a ń gbàdúrà fún un, ṣé àá tún lè máa hu ìwà tí kò dára sí onítọ̀hún? (1 Jòh. 4:20, 21) Irú àdúrà yẹn máa ń gbéni ró, ó sì máa ń ṣàlékún ìṣọ̀kan àárín àwa Kristẹni. Ó tún máa ń fi hàn pé a ní ìfẹ́ bíi ti Kristi. (Jòh. 13:34, 35) Ìfẹ́ yìí sì wà nínú èso ẹ̀mí Ọlọ́run. Ǹjẹ́ olúkúlùkù wa máa ń dá gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ká bàa lè ní àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso rẹ̀, ìyẹn ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu? (Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa yóò fi hàn pé à ń rìn nípa ẹ̀mí a sì wà láàyè nípa tẹ̀mí.—Ka Gálátíà 5:16, 25.

11. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé ó bójú mu láti bẹ àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún wa?

11 Tá a bá rí i pé ohun kan lè fẹ́ mú káwọn ọmọ wa ṣe èrú nínú ìdánwò níléèwé, a ní láti gbàdúrà fún wọn ká sì tún fi Ìwé Mímọ́ tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n bàa lè máa ṣòótọ́ nílé ìwé, kí wọ́n má sì ṣe ohun àìtọ́ kankan. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ẹ má ṣe ohun àìtọ́ kankan.” (2 Kọ́r. 13:7) Irú àdúrà tá a gbà pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ báyìí máa ń dùn mọ́ Jèhófà nínú, ó sì máa ń sọ ohun tó dáa nípa wa. (Ka Òwe 15:8.) A lè ní káwọn míì máa gbàdúrà fún wa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣe. Ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún wa, nítorí àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Héb. 13:18.

Àwọn Nǹkan Míì Tí Àdúrà Wa Ń Sọ Nípa Wa

12. Àwọn ohun wo ló yẹ kó jẹ́ lájorí àdúrà wa?

12 Ǹjẹ́ àdúrà wa ń fi hàn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó láyọ̀ tó sì nítara ni wá? Ṣé ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa sábà máa ń dá lórí bá ó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bá ó ṣe máa wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀, ìdáláre ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti bí orúkọ Ọlọ́run yóò ṣe di mímọ́? Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló yẹ kó jẹ́ lájorí àdúrà wa, gẹ́gẹ́ bí àdúrà àwòkọ́ṣe Jésù ṣe fi hàn. Bí àdúrà Jésù yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mát. 6:9, 10.

13, 14. Kí ni àdúrà wa ń sọ nípa wa?

13 Àdúrà wa sí Ọlọ́run máa ń fi ohun tó ń mú wa ṣe nǹkan hàn, ó máa ń sọ ohun tó jẹ wá lógún àtohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Jèhófà mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Òwe 17:3 sọ pé: “Ìkòkò ìyọ́hunmọ́ wà fún fàdákà àti ìléru fún wúrà, ṣùgbọ́n Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.” Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa ni Ọlọ́run ń rí. (1 Sám. 16:7) Ó mọ èrò wa nípa àwọn ìpàdé wa, iṣẹ́ ìwàásù wa àti ojú tá a fi ń wo àwọn ará wa. Jèhófà mọ ohun tá à ń rò nípa “àwọn arákùnrin” Kristi. (Mát. 25:40) Ó mọ̀ bóyá lóòótọ́ là ń fẹ́ ohun tá à ń gbàdúrà fún àbí a kàn ń sọ àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ kan ṣá. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.”—Mát. 6:7.

14 Ohun tá à ń sọ nínú àdúrà wa tún ń fi bá a ṣe gbára lé Ọlọ́run tó hàn. Dáfídì sọ pé: “[Jèhófà] jẹ́ ibi ìsádi fún mi, ilé gogoro lílágbára ní ojú ọ̀tá. Dájúdájú, èmi yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin; èmi yóò sá di ibi ìlùmọ́ ìyẹ́ apá rẹ.” (Sm. 61:3, 4) Nígbà tí Ọlọ́run bá ‘na àgọ́ rẹ̀ bò wá,’ ewukéwu kò ní wu wá, ọkàn wa á sì balẹ̀. (Ìṣí. 7:15) A lè sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà, pẹ̀lú ìdánilójú pé ó “ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀” wa nígbà tí ohunkóhun bá fẹ́ dán ìgbàgbọ́ wa wò. Èyí mà ń tuni nínú o!—Ka Sáàmù 118:5-9.

15, 16. Tá a bá ń fi òótọ́ inú gbàdúrà nípa àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó wù wá, kí nìyẹn yóò ṣe fún wa?

15 Tá a bá fi òótọ́ inú gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ ìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan, yóò jẹ́ ká mọ̀ ọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wù wá láti di alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run. Ṣé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ la ní tó fi ń wù wá láti ran àwọn ará lọ́wọ́, tó sì ń wù wá láti máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú? Àbí ṣé kò lè jẹ́ pé a “ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́” tàbí ká máa fẹ́ “jẹ olúwa lé” àwọn ará lórí? Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ láàárín àwa èèyàn Jèhófà. (Ka 3 Jòhánù 9, 10; Lúùkù 22:24-27.) Tó bá jẹ́ pé èrò tí kò tọ́ la ní, fífi òótọ́ inú gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run yóò jẹ́ ká mọ̀ ọ́n, ká sì mú un kúrò kó tó jọba lọ́kàn wa.

16 Ó lè máa wu àwọn aya Kristẹni pé kí ọkọ wọn di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ di alàgbà tó bá yá. Irú àwọn arábìnrin yìí lè ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tí wọ́n ń gbà nípa ọ̀ràn náà, kí wọ́n máa sapá láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà hùwà. Èyí ṣe pàtàkì, torí pé ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìwà àwọn ìdílé ọkùnrin kan máa nípa lórí ojú tí wọ́n fi ń wò ó nínú ìjọ.

Nígbà Tá A Bá Ń Ṣojú Àwùjọ Nínú Àdúrà

17. Kí nìdí tó fi dára ká máa dá wà níbì kan láti gbàdúrà?

17 Jésù sábà máa ń kúrò láàárín àwọn èrò kó lè ráyè dá gbàdúrà sí Baba rẹ̀. (Mát. 14:13; Lúùkù 5:16; 6:12) Àwa náà ní láti máa dá wà níbì kan láti gbàdúrà. Tá a bá fara balẹ̀ gbàdúrà nínú ipò tó tura, ó ṣeé ṣe ká lè ṣe àwọn ìpinnu tínú Jèhófà yóò dùn sí, yóò sì jẹ́ kí ipò tẹ̀mí wa sunwọ̀n sí i. Àmọ́, Jésù tún gbàdúrà láàárín àwọn èèyàn, ó sì yẹ káwa náà wo bá a ṣe lè gbàdúrà lọ́nà tó bójú mu láàárín àwùjọ.

18. Àwọn ohun wo ló yẹ káwọn arákùnrin fi sọ́kàn tí wọ́n bá ń ṣojú àwùjọ nínú àdúrà?

18 Láwọn ìpàdé wa, àwọn adúróṣinṣin ọkùnrin máa ń ṣojú àwùjọ nínú àdúrà. (1 Tím. 2:8) Ó yẹ kí àwọn tó wà láwùjọ lè ṣe “àmín,” tó túmọ̀ sí “bẹ́ẹ̀ ni kó rí,” níparí irú àdúrà bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kí wọ́n tó lè ṣe àmín sí àdúrà wa, wọ́n gbọ́dọ̀ fara mọ́ ohun tá a bá sọ nínú àdúrà náà. Kò sí ọ̀rọ̀ kankan tó lè tani létí tàbí tí kò mọ́gbọ́n dání nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà. (Lúùkù 11:2-4) Bákan náà, Jésù kò bẹ̀rẹ̀ sí í to ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan tó wà láwùjọ yẹn nílò tàbí ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Inú àdúrà téèyàn ń dá nìkan gbà lèèyàn ti máa ń mẹ́nu kan ọ̀ràn tó ń jẹ ẹnì kan ṣoṣo lọ́kàn, kì í ṣe inú àdúrà téèyàn ń gbà láwùjọ. Nítorí náà, tá a bá ń ṣojú àwùjọ nínú àdúrà, a ò gbọ́dọ̀ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí.

19. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe nígbà tí àdúrà bá ń lọ lọ́wọ́?

19 Ó yẹ ká “máa bẹ̀rù Ọlọ́run” ká sì bọ̀wọ̀ fún un nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣojú wa nínú àdúrà. (1 Pét. 2:17) Àwọn ohun kan wà tó lè bójú mu ní àkókò kan tàbí ní ibì kan, àmọ́ tí kò ní bójú mu tá a bá ṣe wọ́n nípàdé ìjọ. (Oníw. 3:1) Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè fẹ́ kí àwọn mélòó kan di ọwọ́ ara àwọn mú nígbà tí àdúrà bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí lè bí àwọn kan nínú tàbí kó pín ọkàn wọn níyà, kódà àwọn àlejò tí kì í ṣe Kristẹni bíi tiwa. Àwọn tọkọtaya kan lè fọgbọ́n di ara wọn lọ́wọ́ mú nígbà tí ẹnì kan bá ń ṣojú fún ìjọ nínú àdúrà, àmọ́ tí wọ́n bá dì mọ́ra wọn lákòókò àdúrà náà, wọ́n lè mú àwọn tó ṣèèṣì rí wọn kọsẹ̀. Wọ́n lè máa rò pé ìfẹ́ lọ́kọláya tó wà láàárín tọkọtaya náà ló ṣe pàtàkì lójú wọn ju ọ̀wọ̀ fún Jèhófà lọ. Nítorí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tá a ní fún Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo” rẹ̀ ká sì yàgò fún àwọn ìwà tó lè fa ìpínyà ọkàn, kàyéfì tàbí ìkọ̀sẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.—1 Kọ́r. 10:31, 32; 2 Kọ́r. 6:3.

Kí Ló Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Fún?

20. Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé Róòmù 8:26, 27?

20 Ìgbà míì wà tí a kì í mọ ohun tó yẹ ká sọ nínú àdúrà tá à ń dá gbà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìṣòro ohun tí àwa ì bá máa gbàdúrà fún bí ó ti yẹ kí a ṣe ni àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí [mímọ́] tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde. Síbẹ̀síbẹ̀, [Ọlọ́run,] ẹni tí ń wá inú ọkàn-àyà mọ ohun tí ẹ̀mí túmọ̀ sí.” (Róòmù 8:26, 27) Jèhófà mú kí ọ̀pọ̀ àdúrà wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ló mí sí àwọn tó kọ wọ́n sílẹ̀, tá a bá fi ọ̀rọ̀ inú wọn tọrọ nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ yóò gbọ́ àdúrà wa. Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa, ó sì mọ ìtumọ̀ ohun tó jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ gbẹnu àwọn tó kọ Bíbélì sọ. Nígbà tí ẹ̀mí bá ń bá wa “jírẹ̀ẹ́bẹ̀,” ìyẹn ni pé tó ń bá wa tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Jèhófà, Jèhófà máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. Àmọ́ bá a bá ṣe ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síwájú sí i, àwọn ohun tá a fẹ́ gbàdúrà fún yóò máa tètè sọ sí wa lọ́kàn.

21. Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Bá a ti ṣe rí i, àdúrà wa máa ń sọ púpọ̀ nípa wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè fi bá a ṣe sún mọ́ Jèhófà tó àti bá a ṣe lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó hàn. (Ják. 4:8) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn àdúrà, àtàwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà mélòó kan tó wà nínú Bíbélì. Ipa wo ló ṣeé ṣe kí irú àyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ bẹ́ẹ̀ ní lórí bá a ṣe ń gbàdúrà sí Ọlọ́run?

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

• Ọ̀nà wo ni àdúrà ń gbà fi ohun tó ń mú wa ṣe nǹkan hàn?

• Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe nígbà tí àdúrà bá ń lọ lọ́wọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ǹjẹ́ o máa ń fi ìyìn àti ọpẹ́ fún Jèhófà déédéé?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ohun tá à ń ṣe nígbà tí àdúrà bá ń lọ lọ́wọ́ gbọ́dọ̀ máa bọlá fún Jèhófà