Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!

Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!

Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!

ÀWA èèyàn Ọlọ́run òde òní jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tó wà nínú agboolé ńlá kan. A sì ń jọ́sìn Ọlọ́run lónìí bíi tàwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ ìgbàanì. Lára wọn ni Sámúẹ́lì, Dáfídì, Sámúsìnì, Ráhábù, Mósè, Ábúráhámù, Sárà, Nóà àti Ébẹ́lì. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ adití wà lára àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, adití ni tọkọtaya tí wọ́n kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mòǹgólíà. Bákan náà, torí ìṣòtítọ́ àwọn ará wa tó jẹ́ adití lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe dá wa láre.

Lóde òní, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè àwọn ìtẹ̀jáde ní èdè àwọn adití, ó ti dá àwọn ìjọ elédè àwọn adití sílẹ̀, ó sì ti ṣètò àwọn àpéjọ lédè àwọn adití. (Mát. 24:45) Èyí ti ṣe àwọn adití láǹfààní gan-an. a Àmọ́ ǹjẹ́ o ti ronú nípa bó ṣe máa ń rí fáwọn adití láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kí wọ́n sì máa tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́ láìsì àwọn ohun tá a sọ yìí? Ṣé o ti ronú nípa ohun tó o lè ṣe láti ran àwọn adití tó wà ní àgbègbè rẹ lọ́wọ́?

Bí Nǹkan Ṣe Rí fún Wọn Tẹ́lẹ̀

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó o máa gbọ́ tó o bá bi àwọn adití tó jẹ́ àgbàlagbà nípa bí nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run? Wọ́n lè sọ fún ẹ bó ṣe rí lára wọn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ. Wọ́n á sọ bí òtítọ́ kan ṣoṣo yẹn ṣe yí ìgbésí ayé àwọn pa dà, tó sì ń gbé àwọn ró fún ọ̀pọ̀ ọdún, ká tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn fídíò àti àwo DVD lédè àwọn adití. Ìgbà yẹn ni wọ́n tó wá ń lóye òtítọ́ tó jinlẹ̀. Wọ́n lè ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn, tí wọn kì í ṣe ìpàdé lédè àwọn adití, tí wọn kì í sì í túmọ̀ ìpàdé sí èdè àwọn adití. Bó ṣe máa ń rí nígbà yẹn ni pé ẹnì kan á jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, á sì máa kọ ohun tí wọ́n ń sọ sínú ìwé kan kí wọ́n lè lóye rẹ̀. Bí arákùnrin adití kan ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọdún méje nìyẹn, kó tó di pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rẹ́ni táá máa túmọ̀ sí èdè àwọn adití fún un nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Àwọn àgbàlagbà Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ adití máa ń rántí bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn, tó jẹ́ pé wọ́n máa ń bá ìjọ jáde láti lọ wàásù fáwọn tí kì í ṣe adití. Wọ́n á fọwọ́ kan mú ìwé pélébé kan tí wọ́n kọ ìwàásù ṣókí sí. Wọ́n á sì mú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde sí ọwọ́ kejì. Iṣẹ́ ńlá tó nira gan-an ni láti máa kọ́ adití bíi tiwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé tí ohun tó wà níbẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn méjèèjì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rántí bó ṣe máa ń dun àwọn tó nígbà tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ táwọn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kò bá yé ẹni táwọn ń bá sọ̀rọ̀. Tó sì wá di pé àwọn ò lè máa bá ọ̀rọ̀ náà lọ mọ́. Ohun míì tó tún máa ń dùn wọ́n ni pé wọ́n ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà, àmọ́ wọn kò lè ṣe ohun tó fi ìfẹ́ náà hàn pẹ̀lú ìdánilójú. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò dá wọn lójú bóyá àwọn lóye ọ̀ràn náà bó ti tọ́.

Pẹ̀lú gbogbo ìdíwọ́ yìí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ adití ṣì ń di ìwà títọ́ wọn mú ṣinṣin. (Jóòbù 2:3) Wọ́n ti ń fi ìrètí dúró de Jèhófà. (Sm. 37:7) Ó sì ti wá ń bù kún wọn báyìí kọjá ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn rokàn rẹ̀ dé.

Ṣàgbéyẹ̀wò ìsapá arákùnrin kan tó jẹ́ adití tó sì láya nílé tó tún lọ́mọ lọ́ọ̀dẹ̀. Kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe fídíò èdè àwọn adití, ó máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ̀. Ọmọkùnrin rẹ̀ sọ pé: “Ó máa ń ṣòro gan-an fún bàbá mi láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, torí pé inú ìwé ni gbogbo ohun tó fẹ́ fi kọ́ wa wà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í lóye ohun tó wà nínú ìwé náà. Ńṣe làwa ọmọ gan-an tún máa ń dá kún ìṣòro rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la ti máa jẹ́ kó mọ̀ pé àlàyé tó ń ṣe yẹn kò tọ̀nà. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ó máa ń rí i pé à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé. Ó gbà pé ká rí ohun kan kọ́ nípa Jèhófà ṣe pàtàkì ju ìtìjú tó máa ń bá òun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì.”

Tún wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Richard, tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún, tó fọ́jú tó sì tún dití, tó ń gbé ní ìlú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ará mọ Richard sẹ́ni tí kì í pa ìpàdé jẹ. Tó bá fẹ́ lọ sípàdé, fúnra rẹ̀ ló máa ń wọkọ̀ ojú irin tó ń gba abẹ́ ilẹ̀, á wá máa ka iye ibi tí ọkọ̀ náà ti dúró kó bàa lè mọ̀ tó bá dé ibi tó ń lọ. Ní ìgbà òtútù kan báyìí, yìnyín ń wọ̀, ó lágbára débi pé wọ́n fagi lé ìpàdé ọjọ́ yẹn. Wọ́n sọ fún gbogbo àwọn ará ìjọ, àmọ́ lọ́nà kan ṣá, wọn ò sọ fún Richard. Nígbà táwọn ará gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá a kiri. Iwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dúró sí ni wọ́n ti rí i, ó ń retí pé kí wọ́n wá ṣílẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n bi í léèrè ìdí tó fi jáde nígbà tí yìnyín tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ń wọ̀, ó ní, “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.”

Kí Lo Lè Ṣe?

Ṣé àwọn adití kan ń gbé lágbègbè rẹ? Ǹjẹ́ o lè gbìyànjú kí ìwọ náà gbọ́ èdè àwọn adití díẹ̀ kó o bàa lè máa bá wọn sọ̀rọ̀? Àwọn adití jẹ́ èèyàn tó yááyì, wọ́n máa ń ní sùúrù nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ èèyàn ní èdè wọn. O lè pàdé adití nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí tàbí níbòmíì. Kí lo lè ṣe? Gbìyànjú láti bá a sọ̀rọ̀. Fi ara ṣàpèjúwe fún un, kọ ọ̀rọ̀ síwèé fún un, ya nǹkan sínú ìwé fún un, lo àwòrán tàbí kó o lo àwọn ohun tá a sọ yìí pa pọ̀ láti fi bá a sọ̀rọ̀. Ká tiẹ̀ ní adití yẹn sọ pé òun ò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ adití tàbí ẹni tó gbọ́ èdè àwọn adití. Ó lè wu ẹni tó jẹ́ adití láti fẹ́ gbọ́ ìwàásù tí wọ́n bá fi èdè àwọn adití bá a sọ̀rọ̀.

Bóyá ìwọ tiẹ̀ ń kọ́ èdè àwọn adití tó o sì wà ní ìjọ elédè àwọn adití. Báwo lo ṣe lè gbọ́ èdè náà dáadáa kó o sì túbọ̀ mọ̀ ọ́n fi sọ̀rọ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akéde tó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wà ní ìjọ yín, kí ló dé tí o kò máa fi èdè àwọn adití bá wọn sọ̀rọ̀ dípò èdè tá à ń sọ lẹ́nu? Èyí a jẹ́ kó o lè máa ronú lọ́nà táwọn adití gbà ń ronú. Nígbà míì, o lè wò ó pé kó o kúkú fẹnu sọ ohun tó o fẹ́ sọ torí pé kò rọrùn fún ọ láti fi èdè àwọn adití sọ ọ́. Àmọ́, bí ìgbà téèyàn ń kọ́ èdè èyíkéyìí míì náà ni, ṣe lo máa ní láti rọ́jú kó o tó lè mọ̀ ọ́n sọ dáadáa.

Tó o bá sapá láti gbọ́ èdè àwọn adití dáadáa, ó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tó jẹ́ adití, ó sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Tiẹ̀ wo bó ṣe máa ń dun àwọn adití tó, pé wọn ò lè lóye ohun táwọn èèyàn ń sọ níbi iṣẹ́ tàbí nílé ìwé lójoojúmọ́. Arákùnrin kan tó jẹ́ adití sọ pé: “Gbogbo àwọn tí mo sábà máa ń rí lójoojúmọ́ ló lè sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe mí bíi pé ṣe ni mo dá nìkan wà táwọn èèyàn sì pa mí tì, èyí máa ń jẹ́ kí agara dá mi, kódà ó máa ń mú inú bí mi. Mi ò tiẹ̀ mọ bí ǹ bá ṣe ṣàlàyé bó ṣe máa ń rí lára mi nígbà míì.” Àmọ́, ibi ìtura táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó jẹ́ adití ti lè rí oúnjẹ tẹ̀mí ló yẹ kí ìpàdé wa máa jẹ́, kó jẹ́ ibi tí wọ́n ti lè rẹ́ni bá sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì bá kẹ́gbẹ́.—Jòh. 13:34, 35.

Àwọn tá ò gbọ́dọ̀ fojú pa rẹ́ ni àwọn adití mélòó kan tí wọ́n wà nínú ìjọ tí wọ́n ti ń fi èdè tá à ń sọ lẹ́nu ṣèpàdé. Ńṣe ni wọ́n máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ní ìpàdé sí èdè àwọn adití fún wọn. Láti lè lóye ohun tá à ń sọ nípàdé dáadáa, wọ́n máa ń jókòó sọ́wọ́ iwájú nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Èyí a jẹ́ kí wọ́n lè rí ògbufọ̀ àti olùbánisọ̀rọ̀ lẹ́gbẹ́ ara wọn láìsí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yí ọrùn kiri, tí ohunkóhun kò sì ní dí wọn lójú. Ẹ̀rí ti fi hàn pé ó tètè máa ń mọ́ àwọn yòókù nínú ìjọ lára láti máa rí èyí, kì í sì í fa ìpínyà ọkàn. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láwọn àpéjọ tí wọ́n ti ń túmọ̀ sí èdè àwọn adití náà nìyẹn. Ẹni tó yẹ ká máa kí, ká máa yìn ni àwọn ará tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí èdè àwọn adití lọ́nà tó yéni tó sì bá bí àwọn adití ṣe ń sọ̀rọ̀ mu.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìjọ tó ní àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití lo wà, tàbí kó jẹ́ ìjọ tí wọ́n ní àwọn adití mélòó kan tí wọ́n ń túmọ̀ àwọn ìpàdé fún ní èdè àwọn adití. Kí lo lè ṣe láti fi hàn pé ọ̀ràn wọn jẹ ọ́ lógún? O lè ní kí wọ́n wá sí ilé rẹ. Tó bá ṣeé ṣe, kọ́ bó o ṣe lè fi èdè àwọn adití sọ ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan. Má mikàn pé o kò ní lè bá wọn sọ̀rọ̀. Lọ́nà kan ṣá, wàá rí ọgbọ́n tí wàá fi lè bá wọn sọ̀rọ̀, fífi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí wọn yóò fún ọ ní ayọ̀ tó ò ní gbàgbé. (1 Jòh. 4:8) Àwọn adití tí wọ́n jẹ́ ará wa yìí ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ rere. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni wọ́n tí wọ́n bá rí ọlọ́rọ̀ wọn, amòye èèyàn ni wọ́n, wọ́n sì máa ń ṣàwàdà gan-an. Arákùnrin kan táwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ adití sọ pé: “Àárín àwọn adití ni mo ti ń lo gbogbo ìgbésí ayé mi, ohun tí mo ti jèrè lára wọn pọ̀ kọjá ohun tí mo lè san pa dà láéláé. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ látara àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ adití.”

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ olóòótọ́ gan-an ni, tó fi mọ́ àwọn adití. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ àti ìfaradà wọn ń fi kún ẹwà ètò Jèhófà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣìkẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ adití!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2009.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ó lè wu ẹni tó jẹ́ adití láti fẹ́ gbọ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n bá fi èdè àwọn adití bá a sọ̀rọ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ibi ìtura táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó jẹ́ adití ti lè rí ìṣírí tẹ̀mí gbà ló yẹ kí ìpàdé wa jẹ́