Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mọyì Ojúṣe Rẹ Nínú Ìjọ

Mọyì Ojúṣe Rẹ Nínú Ìjọ

Mọyì Ojúṣe Rẹ Nínú Ìjọ

“Ọlọ́run ti gbé àwọn ẹ̀yà ara kalẹ̀ sínú ara, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú.”—1 KỌ́R. 12:18.

1, 2. (a) Kí ló fi hàn pé olúkúlùkù ẹni tó wà nínú ìjọ ló lè ní ojúṣe tó yẹ kó mọrírì? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 LÁTÌGBÀ ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà ti ń lo ìjọ láti bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti láti fún wọn ní ìtọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará ìlú Áì tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, Jóṣúà “ka gbogbo ọ̀rọ̀ òfin, ìbùkún àti ìfiré náà sókè, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé òfin náà . . . ní iwájú gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì.”—Jóṣ. 8:34, 35.

2 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì tó jẹ́ alàgbà pé ìjọ Kristẹni ni “agbo ilé Ọlọ́run,” ó tún pè é ní “ọwọ̀n àti ìtìlẹ́yìn òtítọ́.” (1 Tím. 3:15) Ohun tó jẹ́ “agbo ilé Ọlọ́run” lónìí ni ìjọ àwa Kristẹni tòótọ́ tá a jẹ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Ní orí kejìlá lẹ́tà kìíní tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó fi ìjọ wé ara èèyàn. Ó ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ní iṣẹ́ tó ń ṣe, gbogbo wọn pátá la nílò. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run ti gbé àwọn ẹ̀yà ara kalẹ̀ sínú ara, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú.” Ó tiẹ̀ tún sọ pé “àwọn apá kan ara tí a rò pé ó rẹlẹ̀ ní ọlá, ìwọ̀nyí ni a fi ọlá tí ó pọ̀ jù lọ yí ká.” (1 Kọ́r. 12:18, 23) Torí náà, ipa tí ẹnì kan tó dúró déédéé nínú ìjọ ń kó nínú agbo ilé Ọlọ́run kò lọ́lá ju ti Kristẹni míì tóun náà jẹ́ olóòótọ́ lọ, kò sì rẹlẹ̀ jù ú lọ. Ó kàn yàtọ̀ síra ni. Nígbà náà, báwo la ṣe lè mọ ojúṣe wa nínú ìṣètò Ọlọ́run, ká sì mọyì rẹ̀? Àwọn ohun wo ló máa pinnu irú àǹfààní tá a máa ní nínú ìjọ? Báwo la sì ṣe lè jẹ́ ‘kí ìlọsíwájú wa fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn’?—1 Tím. 4:15.

Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Mọyì Ojúṣe Wa?

3. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà mọ ojúṣe wa nínú ìjọ ká sì fi hàn pé a mọyì rẹ̀?

3 Ọ̀nà kan tá a lè gbà mọ ojúṣe wa nínú ìjọ ká sì fi hàn pé a mọyì rẹ̀ ni pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pátápátá pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú fún un. (Ka Mátíù 24:45-47.) Ó yẹ ká ronú lórí ọwọ́ tá a fi ń mú ìtọ́ni tá à ń rì gbà látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú náà. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí ẹrú náà ti ń fún wa nítọ̀ọ́ni tó ṣe ṣàkó lórí ọ̀ràn ìmúra àti ìwọṣọ, eré ìnàjú àti ewu tó yẹ ká ṣọ́ra fún lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ṣé a máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere yìí ní gbogbo ìgbà ká bàa lè wà lábẹ́ ààbò Ọlọ́run? Ojú wo la fi ń wo ìmọ̀ràn náà pé ká ní àkókò kan tá ó máa fi ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé? Ṣé à ń fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn, tá a sì tìtorí rẹ̀ ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìjọsìn ìdílé? Tá a bá jẹ́ àpọ́n, ṣé a ti ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Jèhófà yóò bù kún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹgbẹ́ ẹrú náà.

4. Kí ló yẹ ká ronú lé lórí nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀ràn ara ẹni?

4 Àwọn kan lè rò pé kò sóhun tó kan ẹnikẹ́ni nínú eré ìnàjú táwọn ń ṣe, aṣọ táwọn ń wọ̀, báwọn ṣe ń múra àtàwọn ọ̀ràn míì bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tí Kristẹni kan tó ti ṣèyàsímímọ́, tó sì mọyì àǹfààní tó ní nínú ìjọ bá fẹ́ ṣèpinnu, kò yẹ kó jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti wù ú nìkan láá máa rò. Ohun tó yẹ kó ronú lé lórí jù lọ ni ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn náà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun tó wà nínú Bíbélì ló yẹ kó jẹ́ ‘fìtílà fún ẹsẹ̀ wa, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa.’ (Sm. 119:105) Bákan náà, tá a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a óò máa ronú lórí bí ìpinnu wa ṣe máa nípa lórí iṣẹ́ ìwàásù wa, àwọn ará wa àtàwọn ẹlòmíì.—Ka 2 Kọ́ríńtì 6:3, 4.

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ra fún ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe?

5 “Ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn” ti gbòde kan débi pé ṣe ló dà bí afẹ́fẹ́ tí à ń mí símú. (Éfé. 2:2) Ẹ̀mí yẹn lè mú ká máa rò pé a ò nílò ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bíi Dìótíréfè, ẹni tí ‘kì í fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù.’ (3 Jòh. 9, 10) A ní láti máa ṣọ́ra fún ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe. Láé, a ò gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa tàbí ìṣe wa ta ko ohun tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tí Jèhófà ń lò láti bá wa sọ̀rọ̀ lónìí. (Núm. 16:1-3) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọrírì àǹfààní tá a ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ẹrú náà. Ó sì tún yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ wa ká sì jẹ́ onítẹríba.—Ka Hébérù 13:7, 17.

6. Kí nìdí tó fi yẹ kí olúkúlùkù wa ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀?

6 Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ojúṣe wa nínú ìjọ ni pé kí olúkúlùkù wa ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀ dáadáa, ká rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ‘ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lógo,’ ká sì mú ìyìn wá fún Jèhófà. (Róòmù 11:13) Àwọn kan nínú wa láǹfààní láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àwọn míì sì láǹfààní àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún bíi míṣọ́nnárì, alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà kárí ayé. Ọ̀pọ̀ ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń bá wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwa èèyàn Jèhófà ló ń sa gbogbo ipá wọn láti máa bójú tó ipò tẹ̀mí ìdílé wọn tí wọ́n sì ń kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Ka Kólósè 3:23, 24.) Ó yẹ ká fọkàn balẹ̀ pé tá a bá yọ̀ǹda ara wa tinútinú nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sìn ín tọkàntọkàn, àyè yóò máa wà fún wa nínú ètò rẹ̀.

Àwọn Ohun Tó Máa Pinnu Àǹfààní Tá A Máa Ní Nínú Ìjọ

7. Ṣàlàyé bí àǹfààní tá a máa ní nínú ìjọ ṣe sinmi lórí ipò ìgbésí ayé wa.

7 Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣàyẹ̀wò ipò ìgbésí ayé rẹ̀ dáadáa, torí pé lọ́pọ̀ ìgbà, àǹfààní tá a máa ní nínú ìjọ sinmi lórí ohun tá a bá lágbára láti ṣe tàbí ohun tí àyè gbà wá láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọ̀nà kan, àǹfààní táwọn arákùnrin máa ń ní nínú ìjọ yàtọ̀ sí èyí táwọn arábìnrin máa ń ní. Ọjọ́ orí wa, ìlera wa àtàwọn nǹkan míì tún máa ń pinnu ohun tá a máa lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Òwe 20:29 sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn, ọlá ńlá àwọn arúgbó sì ni orí ewú wọn.” Àwọn ọ̀dọ́ inú ìjọ lè ṣiṣẹ́ tó gba agbára nítorí pé eegun ọ̀dọ́ ṣì wà lára wọn, àmọ́ àǹfààní ńlá ni ìjọ ń jẹ látinú ọgbọ́n àti ìrírí àwọn àgbààgbà inú ìjọ. Ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé ohunkóhun tá a bá láǹfààní láti ṣe nínú ètò Jèhófà, ọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ni.—Ìṣe 14:26; Róòmù 12:6-8.

8. Ipa wo ni ìfẹ́ ọkàn ẹni máa ní lórí àǹfààní tá a ní nínú ìjọ?

8 Jẹ́ ká fi àpẹẹrẹ àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá ṣe àkàwé ohun míì tó máa pinnu àǹfààní tá a máa ní nínú ìjọ. Àwọn méjèèjì jáde nílé ìwé. Bákan náà ni ipò ìgbésí ayé wọn ṣe rí. Àwọn òbí wọn ti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà déédéé tí wọ́n bá ti jáde ilé ìwé. Nígbà tí wọ́n jáde, ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, èkejì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó gba gbogbo àkókò rẹ̀. Kí ló mú kí wọ́n ṣe ohun tó yàtọ̀ síra? Ìfẹ́ ọkàn wọn ni. Ohun tó wu olúkúlùkù wọn ni wọ́n pàpà ṣe. Ṣé kì í ṣe bí ọ̀ràn ọ̀pọ̀ nínú wa náà ṣe rí nìyẹn? Ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí olúkúlùkù wa máa fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ a lè fi kún ohun tá à ń ṣe, kódà tó bá tiẹ̀ gba pé ká yí àwọn nǹkan kan pa dà nínú ipò ìgbésí ayé wa?—2 Kọ́r. 9:7.

9, 10. Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé kì í wù wá ká ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

9 Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé kì í kàn-án wù wá ká ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ńkọ́, tá a ṣáà wà nínú ìjọ ṣá? Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Fílípì, ó sọ pé: “Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” Ó dájú pé Jèhófà lè sún ọkàn wa ṣiṣẹ́, kó sì mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ máa wù wá ṣe.—Fílí. 2:13; 4:13.

10 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó máa wù wá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ohun tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe nìyẹn. Ó gbàdúrà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi. Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 25:4, 5) Àwa náà lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè máa ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú. Tá a bá ronú lórí ojú tí Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ fi ń wo iṣẹ́ tá à ń ṣe fún wọn, á mú kí ọkàn wa kún fún ìmoore. (Mát. 26:6-10; Lúùkù 21:1-4) Irú ẹ̀mí ìmoore bẹ́ẹ̀ lè mú ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó máa wù wá láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Wòlíì Aísáyà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lórí irú ẹ̀mí tó yẹ ká ní. Nígbà tó gbọ́ tí Jèhófà béèrè pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Wòlíì náà dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”—Aísá. 6:8.

Báwo La Ṣe Lè Máa Tẹ̀ Síwájú?

11. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn arákùnrin máa sapá láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run? (b) Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè máa sapá láti ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn?

11 Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2008, iye àwọn tó ṣèrìbọmi jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá, ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarùn-ún àti ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta ó dín méjì [289,678]. Ìyẹn fi hàn kedere pé a nílò àwọn arákùnrin púpọ̀ táá máa mú ipò iwájú nínú ìjọ. Kí ló yẹ kí arákùnrin kan ṣe sí ọ̀ràn yìí? Ní kúkúrú, ohun tó yẹ kó ṣe ni pé kó sapá láti dójú ìlà àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fáwọn tó bá fẹ́ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. (1 Tím. 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè sapá láti dojú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀? Ohun tó máa ṣe ni pé, á máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé, á máa múra sí iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún un nínú ìjọ, á máa sapá láti mú kí ìdáhùn rẹ̀ nípàdé sunwọ̀n sí i, á sì tún máa fi hàn pé ọ̀ràn àwọn ará ìjọ jẹ òun lógún. Tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ńṣe ló ń fi hàn pé òun mọyì àǹfààní tóun ní nínú ìjọ.

12. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè fi hàn pé àwọn nítara fún òtítọ́?

12 Kí làwọn ọ̀dọ́kùnrin, pàápàá àwọn tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, lè ṣe láti máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọ? Wọ́n lè sapá láti túbọ̀ máa kún fún ‘ọgbọ́n àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí,’ nípa gbígba ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ sínú. (Kól. 1:9) Kíkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti kíkópa déédéé nínú ìpàdé yóò mú kí ìyẹn ṣeé ṣe. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tún lè sapá kí wọ́n lè dẹni tó láǹfààní láti gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” wọlé, ìyẹn ni pé kí wọ́n láǹfààní láti wọnú èyíkéyìí lára iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. (1 Kọ́r. 16:9) Téèyàn bá fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe àfojúsùn rẹ̀, pé ìyẹn lòun máa fi ìgbésí ayé òun ṣe, ìgbésí ayé rẹ̀ yóò ní adùn àti ọ̀pọ̀ ìbùkún.—Ka Oníwàásù 12:1.

13, 14. Àwọn ọ̀nà wo làwọn arábìnrin lè gbà fi hàn pé àwọn mọyì ojúṣe àwọn nínú ìjọ?

13 Olúkúlùkù àwọn arábìnrin pẹ̀lú lè fi hàn pé àwọn mọyì àǹfààní táwọn ní, ìyẹn àǹfààní kíkópa nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 68:11 ṣẹ. A kà á níbẹ̀ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.” Ọ̀nà kan tó ṣe kedere táwọn arábìnrin lè gbà fi hàn pé àwọn mọyì àǹfààní táwọn ní nínú ìjọ ni pé kí wọ́n máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Táwọn arábìnrin bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ tí wọ́n sì ń fi tinútinú yááfì nǹkan nítorí iṣẹ́ náà, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn mọyì ipa táwọn ń kó nínú ìjọ.

14 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Títù, ó sọ pé: “Kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ onífọkànsìn nínú ìhùwàsí, . . . kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere; kí wọ́n lè pe orí àwọn ọ̀dọ́bìnrin wálé láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, oníwà mímọ́, òṣìṣẹ́ ní ilé, ẹni rere, tí ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn, kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.” (Títù 2:3-5) Ẹ ò rí i pé oore ńlá làwọn arábìnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí lè ṣe fún ìjọ tí wọ́n bá wà! Tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání lórí àwọn ọ̀ràn bí ìwọṣọ, ìmúra àti eré ìnàjú, ńṣe ni wọ́n ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn mọrírì ojúṣe àwọn nínú ìjọ.

15. Kí ni arábìnrin tí kò lọ́kọ lè ṣe tó bá ń nímọ̀lára pé òun dá nìkan wà?

15 Nígbà míì, ó lè ṣòro fún arábìnrin kan tí kò lọ́kọ láti mọ àǹfààní tó ní nínú ìjọ. Arábìnrin kan tí irú rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí rí sọ pé: “Téèyàn ò bá lọ́kọ, èèyàn máa ń mọ̀ ọ́n lára pé òun dá nìkan wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” Nígbà tá a bí i pé báwo ló ṣe ń fara da ipò yẹn, ó sọ pé: “Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ràn mí lọ́wọ́ láti tún pa dà mọ àǹfààní tí mo ní nínú ìjọ. Mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wò mí. Mo sì ń gbìyànjú láti máa ran àwọn ará nínú ìjọ lọ́wọ́. Èyí ni ò jẹ́ kí n máa ronú púpọ̀ jù nípa ara mi mọ́.” Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sáàmù 32:8, Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Ó dájú pé Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣeré, títí kan àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ, yóò sì ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti mọ ojúṣe wa nínú ìjọ.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àǹfààní Tó O Ní Bọ́ Mọ́ Ẹ Lọ́wọ́!

16, 17. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé jíjẹ́ tá a jẹ́ ìpè Jèhófà pé ká wá sínú ètò rẹ̀ ni ìpinnu tó dára jù lọ tá a tíì ṣe nígbèésí ayé wa? (b) Kí la lè ṣe tí àǹfààní tá a ní nínú ètò Jèhófà kò fi ní bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́?

16 Olúkúlùkù àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ni ó fìfẹ́ pè láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòh. 6:44) Láàárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ èèyàn tó wà láyé, àwa ni Jèhófà pè wá sínú ìjọ rẹ̀ lónìí. Ìpinnu tó dára jù lọ tá a tíì ṣe láyé wa ni bá a ṣe jẹ́ ìpè Jèhófà. Èyí sì tí jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. Ayọ̀ wa mà pọ̀ o, ọkàn wa mà balẹ̀ o, pé gbogbo wa la ní àyè tiwa nínú ìjọ!

17 Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ibùgbé ilé rẹ.” Ó fi kún un pé: “Dájúdájú, ẹsẹ̀ mi yóò dúró lórí ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ; inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.” (Sm. 26:8, 12) Gbogbo wa pátápátá ni Ọlọ́run tòótọ́ ní àyè fún nínú ètò rẹ̀. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni ètò Ọlọ́run nìṣó tá a sì ń jẹ́ kí ọwọ́ wa máa dí nínú iṣẹ́ rẹ̀, àǹfààní iyebíye tá a ní nínú ètò Jèhófà kò ní bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti sọ pé gbogbo àwa Kristẹni la ní ojúṣe tiwa nínú ìjọ?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní nínú ètò Ọlọ́run?

• Àwọn nǹkan wo ló lè pinnu àǹfààní tá a máa ní nínú ìjọ?

• Báwo làwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn àgbàlagbà ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì ojúṣe àwọn nínú ètò Ọlọ́run?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Báwo làwọn arákùnrin ṣe lè sapá láti dẹni tó láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Báwo làwọn arábìnrin ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì àǹfààní táwọn ní nínú ìjọ?