Bí Bíbélì Ṣe Dé Erékùṣù Madagásíkà
Bí Bíbélì Ṣe Dé Erékùṣù Madagásíkà
ORÍLẸ̀-ÈDÈ Madagásíkà jẹ́ erékùṣù kan, ó wà ní nǹkan bí irinwó [400] kìlómítà sí etíkun ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, òun ló wà nípò kẹrin nínú àwọn erékùṣù tó tóbi jù lọ láyé. Malagásì ni wọ́n ń pe àwọn ará ibẹ̀. Ó sì ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, torí pé ó wà nínú Bíbélì èdè Malagásì tí wọ́n ti tẹ̀ láti àádọ́sàn [170] ọdún sẹ́yìn. Àwọn tó ṣe Bíbélì èdè Malagásì jáde lo ìforítì, gbogbo ọkàn wọn ni wọ́n sì fi ṣe iṣẹ́ ọ̀hún.
Erékùṣù Mauritius tó wà nítòsí erékùṣù Madagásíkà ni wọ́n ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Malagásì. Láti ọdún 1813 ni Gómìnà Robert Farquhar, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń ṣàkóso erékùṣù Mauritius ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bí wọ́n ṣe máa túmọ̀ ìwé Ìhìn Rere sí èdè Malagásì. Nígbà tó yá, ó gba Radama Kìíní tó jẹ́ ọba erékùṣù Madagásíkà níyànjú pé kó ránṣẹ́ pe àwọn olùkọ́ láti inú ẹgbẹ́ London Missionary Society wá sí Madagásíkà.
Ní August 18, ọdún 1818, míṣọ́nnárì méjì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Wales gbéra láti erékùṣù Mauritius lọ sí Madagásíkà, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí èbúté ní ìlú Toamasina. Orúkọ wọn ni David Jones àti Thomas Bevan. Wọ́n rí i pé àwọn èèyàn ibẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn gan-an. Ìjọsìn àwọn alálẹ̀ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ sì máa ń hàn nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Èdè Malagásì kún fọ́fọ́ fún ẹwà èdè, ó wà lára àwọn èdè tó jẹ yọ látinú èdè Malayo-Polynesia.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jones àti Bevan dá ilé ìwé kékeré kan sílẹ̀ tí wọ́n fi lọ mú ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn láti Mauritius wá sí Toamasina. Àmọ́, ó dunni pé àrùn ibà kọ lù gbogbo wọn, ó sì gbẹ̀mí ìyàwó Jones àti ọmọ rẹ̀ ní December ọdún 1818. Oṣù méjì lẹ́yìn náà ni àrùn náà pa Bevan àti ìdílé rẹ̀. David Jones nìkan ló ṣẹ́ kù nínú gbogbo àwọn tó wá sí Madagásíkà.
Jones kò jẹ́ kí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ náà ṣí òun lọ́wọ́. Ó pinnu láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di ohun táwọn ará Madagásíkà yóò máa rí kà. Jones pa dà sí erékùṣù Mauritius láti lọ tọ́jú ara rẹ̀, ibẹ̀ ló sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Malagásì, bó tilẹ̀ jé pé kò rọrùn láti kọ́ èdè náà. Àmọ́ láìpẹ́ sígbà yẹn, ó dáwọ́ lé títúmọ̀ ìwé Ìhìn Rere Jòhánù.
Ní October 1820, Jones pa dà sí Madagásíkà. Ó dé sí ìlú Antananarivo tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, kò sì pẹ́ tó fi dá ilé ẹ̀kọ́ tuntun kan sílẹ̀. Gbogbo nǹkan ò jọra nígbà yẹn. Kò síwèé tí wọ́n á máa fi kọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́, kò sí pátákó ìkọ̀wé, kò sì sí àga ìkọ̀wé. Àmọ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣètò ẹ̀kọ́ wọn múná dóko, ó sì ń wu àwọn ọmọ láti kẹ́kọ̀ọ́.
Lẹ́yìn oṣù méje tí Jones ti ń dá ṣiṣẹ́, míṣọ́nnárì míì tó ń jẹ́ David Griffiths wá dara pọ̀ mọ́ ọn, òun ló rọ́pò Bevan tó kú. Griffiths àti Jones gbájú mọ́ títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Malagásì, láìsinmi láìṣàárẹ̀.
Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Bíbélì Bẹ̀rẹ̀ Ní Pẹrẹu
Kété lẹ́yìn ọdún 1820, ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n ń gbà kọ èdè Malagásì sílẹ̀ ni èyí tí wọ́n ń pè ní sorabe. Bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́ ni pé wọ́n ń fi lẹ́tà èdè Lárúbáwá kọ ọ̀rọ̀ èdè Malagásì. Ìwọ̀nba péréte èèyàn ló sì lè kà á. Nítorí náà, àwọn míṣọ́nnárì wá gbé ọ̀ràn náà tọ Ọba Radama Kìíní lọ, ọba náà sì gbà wọ́n láyè láti máa fi lẹ́tà ABD kọ ọ̀rọ̀ dípò sorabe.
Ní September 10, ọdún 1823, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtúmọ̀ náà. Jones ń ṣiṣẹ́ lórí ìwé Jẹ́nẹ́sísì àti Mátíù, Griffiths sì mú ìwé Ẹ́kísódù àti Lúùkù. Àwọn méjèèjì ń ṣiṣẹ́ láìsinmi láìṣàárẹ̀. Yàtọ̀ sí pé fúnra wọn ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀, wọ́n tún ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé láàárọ̀ àti lọ́sàn-án. Wọ́n tún máa ń múra ìsìn sílẹ̀, wọ́n sì ń darí ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì fi ń ṣe ìsìn. Síbẹ̀ títúmọ̀ Bíbélì ni wọ́n gbájú mọ́ jù lọ.
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ méjìlá nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn, àwọn míṣọ́nnárì méjèèjì parí títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì àti ọ̀pọ̀ lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láàárín ọdún kan ààbọ̀ péré. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n túmọ̀ odindi Bíbélì àkọ́kọ́, àmọ́ iṣẹ́ ò tíì parí lórí rẹ̀. Ó ṣì yẹ kí wọ́n tún àwọn nǹkan kan ṣe nínú rẹ̀. Torí náà ẹgbẹ́ London Missionary Society rán David Johns àti Joseph Freeman, tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa èdè wá láti ilẹ̀ England pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́.
Bí Wọ́n Ṣe Fara Da Ohun Tó Fẹ́ Fa Ìdíwọ́
Nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́ lórí Bíbélì èdè Malagásì, ẹgbẹ́ London Missionary Society rán Charles Hovenden pé kó lọ to ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àkọ́kọ́ ní Madagásíkà. Ní November 21, ọdún 1826, Hovenden débẹ̀. Àmọ́, àrùn ibà kọ lù ú ó sì kú láàárín oṣù kan tó débẹ̀, kò sì sẹ́nì kankan tó lè parí títo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, James Cameron, ọ̀jáfáfá oníṣòwò kan wá láti ilẹ̀ Scotland. Òun ló rí ẹ̀rọ náà tò nígbà tó wo ìwé tí wọ́n ṣe mọ́ ẹ̀rọ náà tó rí nínú rẹ̀. Lẹ́yìn tí Cameron ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe, ó jàjà tẹ apá kan nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní ní December 4, ọdún 1827. a
Ohun míì tó fà wọ́n sẹ́yìn díẹ̀ ni ti ikú Ọba Radama Kìíní ní July 27, ọdún 1828. Ọba yìí ṣètìlẹ́yìn gan-an fún iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì. Ní àkókò yẹn, David Jones sọ pé: “Onínúure tó kó èèyàn mọ́ra púpọ̀ ni Radama Ọba. Ògúnnágbòǹgbò alátìlẹyìn ètò ẹ̀kọ́ ni. Lójú rẹ̀, káwọn èèyàn rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì di ọ̀làjú ṣe pàtàkì ju Wúrà àti Fàdákà lọ.” Àmọ́ ìyàwó rẹ̀ Ranavalona Kìíní ló jọba lẹ́yìn rẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi ṣe kedere pé obìnrin yẹn kò ní ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì bí ọkọ rẹ̀ ti ṣe.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ayaba yìí gorí ìtẹ́ ni àlejò kan láti ilẹ̀ England wá láti bá a sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì tó ń lọ lọ́wọ́. Ayaba yìí ò gbà kí àlejò náà rí òun. Ìgbà kan tún wà táwọn míṣọ́nnárì lọ sọ fún ayaba pé àwọn ṣì ní ohun tó pọ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn, títí kan èdè Gíríìkì àti Hébérù, ohun tó fi dá wọn lóhùn ni pé: “Kò sóhun tó kan èmi pẹ̀lú èdè Gíríìkì àti Hébérù, ohun tí mo fẹ́ mọ̀ ni bóyá ẹ máa lè kọ́ àwọn èèyàn mi ní ẹ̀kọ́ tó wúlò, irú bí ẹ̀kọ́ nípa ọṣẹ ṣíṣe.” Bí Cameron ṣe rí i báyìí pé wọ́n lè lé àwọn kúrò ní erékùṣù yẹn káwọn tó parí iṣẹ́ lórí títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Malagásì, ó sọ fún ayaba pé kó fáwọn ní ọ̀sẹ̀ kan káwọn fi ronú sí ohun tó sọ yẹn.
Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, Cameron kó ọ̀pá ọṣẹ méjì lọ fún àwọn dòǹgárì ayaba. Àwọn èròjà tí wọ́n rí ní erékùṣù yẹn ni wọ́n fi ṣe ọṣẹ náà. Ọṣẹ táwọn míṣọ́nnárì tó mọṣẹ́ ọwọ́ ṣe yìí, àtàwọn iṣẹ́ míì tí wọ́n ṣe fún ìlú mú kí ayaba gbà wọ́n láyè títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ẹ́ tẹ gbogbo ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tán.
Ohun Ìyanu Kan Ṣẹlẹ̀, àmọ́ Ìjákulẹ̀ Ló Tẹ̀ Lé E
Pẹ̀lú bí ayaba yẹn ṣe kọ́kọ́ láálí àwọn míṣọ́nnárì, ó tún wá ṣòfin kan tó yani lẹ́nu ní May ọdún 1831. Ó gbà kí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ máa batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni! Àmọ́ kò pẹ́ tó tún fi pèrò dà. Ìwé kan tó sọ ìtàn nípa Madagásíkà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ A History of Madagascar, sọ pé “bí iye àwọn tí wọ́n batisí ṣe ń pọ̀, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn kan tó wà láàfin tí kò fẹ́ kí àṣà wọn pa run, débi pé wọ́n kó sí ayaba nínú, wọ́n sọ fún un pé ohun tí ara Olúwa tí wọ́n ń gbà túmọ̀ sí ni jíjẹ́ ẹ̀jẹ́ pé tàwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì làwọn á máa ṣe.” Látàrí èyí, ní òpin ọdún 1831, ayaba fagi lé òfin tó fi fún àwọn aráàlú láyè láti máa ṣe batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ìyẹn lẹ́yìn oṣù mẹ́fà péré tó ṣòfin yẹn.
Bí àwọn míṣọ́nnárì ṣe rí i pé ọkàn ayaba ti yí pa dà àti pé agbára túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́wọ́ àwọn tó wà lẹ́yìn àṣà àti ẹ̀sìn ìṣẹ̀dálẹ̀, tí wọ́n jọ ń ṣèjọba, wọ́n jára mọ́ títẹ Bíbélì náà kí wọ́n lè tètè parí rẹ̀. Wọ́n ti tẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tán, wọ́n sì ti pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dà rẹ̀ fáwọn èèyàn. Àmọ́ ìfàsẹ́yìn míì tún ṣẹlẹ̀ ní March 1, ọdún 1835 nígbà tí Ayaba Ranavalona Kìíní kéde pé ẹ̀sìn Kristẹni kò bófin mu, tó sì pàṣẹ pé káwọn èèyàn kó gbogbo ìwé àwọn Kristẹni tó bá wà lọ́wọ́ wọn fáwọn aláṣẹ.
Àṣẹ ayaba yẹn tún túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ Madagásíkà tó ń kọ́ṣẹ́ kò lè ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tẹ Bíbélì mọ́. Torí náà, àwọn míṣọ́nnárì kéréje ló kù sẹ́nu iṣẹ́ náà, wọ́n ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru títí wọ́n fi parí títẹ odindi Bíbélì nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ní oṣù June ọdún 1835, wọ́n gbé odindi Bíbélì jáde. Bó ṣe di pé Bíbélì èdè Malagásì dóde nìyẹn o!
Nígbà tí wọ́n ṣì wà lábẹ́ ìfòfindè yẹn, wọ́n tètè ń pín Bíbélì fáwọn èèyàn, wọ́n sì tọ́jú àádọ́rin Bíbélì sábẹ́ ilẹ̀ kí àwọn tó fẹ́ run Bíbélì má bàa rí wọn bà jẹ́. Ọpẹ́lọpẹ́ ohun tí wọ́n ṣe yẹn ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa gbilẹ̀ lọ ràì ní erékùṣù náà, torí pé láàárín ọdún kan ṣoṣo, míṣọ́nnárì méjì péré ló ṣẹ́ kù sí erékùṣù Madagásíkà.
Àwọn Ará Madagásíkà Nífẹ̀ẹ́ Bíbélì
Ohun ayọ̀ ńlá mà ni o, pé àwọn èèyàn Madagásíkà yóò lè máa rí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà ní èdè wọn! Lóòótọ́, ìtumọ̀ Bíbélì náà ní àwọn ìkùdíẹ̀–káàtó kan, èdè inú rẹ̀ sì ti di ògbólógbòó báyìí. Síbẹ̀, ó ṣòro láti rí ilé kan tí wọn ò ti ní Bíbélì, ọ̀pọ̀ àwọn ará Madagásíkà ló sì máa ń kà á déédéé. Ohun kan tó gbàfiyèsí nípa Bíbélì yẹn ni bí wọ́n ṣe lo Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run nínú rẹ̀ jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Nínú ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀, orúkọ Ọlọ́run wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì náà. Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Madagásíkà ló mọ orúkọ Ọlọ́run.
Kódà nígbà tí wọ́n kó ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde, Ọ̀gbẹ́ni Baker tó jẹ́ amojú ẹ̀rọ tó tẹ Bíbélì yẹn rí bí ayọ̀ àwọn ara Madagásíkà ṣe pọ̀ tó, ó sọ tìyanutìyanu pé: “Kì í ṣe pé mò ń sàsọtẹ́lẹ̀ o, àmọ́ mi ò rò pé wọ́n á lè pa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rẹ́ lórílẹ̀-èdè yìí.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn sì já sóòótọ́. Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tó dojú kọ títẹ Bíbélì náà, tó fi mọ́ àrùn ibà, kíkọ́ èdè tó ṣòroó kọ́ àti òfin tí ayaba fi dè é, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàpà di èyí tó wà lórílẹ̀-èdè Madagásíkà.
Ìgbà ọ̀tun ti dé bá Bíbélì ní èdè Malagásì lákòókò yìí. Lọ́nà wo? Ní ọdún 2008, a tẹ odindi Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Malagásì. Ìtẹ̀síwájú ńlá ni èyí mú bá Bíbélì kíkà, torí pé èdè tó bóde òní mu tó sì rọrùn láti lóye la fi kọ ọ́. Nípa báyìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wá túbọ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ní erékùṣù Madagásíkà.—Aísá. 40:8.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Òfin Mẹ́wàá àti Àdúrà Olúwa ni apá ibi tí wọ́n kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ tẹ̀ nínú Bíbélì ní èdè Malagásì, erékùṣù Mauritius ni wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ ní nǹkan bí oṣù April sí May ọdún 1826. Àmọ́ kìkì ìdílé Radama Ọba àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba díẹ̀ ní wọ́n pín in fún.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Bíbélì “Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” ní èdè Malagásì gbé Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run ga