Ǹjẹ́ O Lè Ré Kọjá Lọ sí Makedóníà?
Ǹjẹ́ O Lè Ré Kọjá Lọ sí Makedóníà?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ rí ìran kan nígbà tó wà nílùú Tíróásì. Ìlú yìí wà ní àgbègbè Éṣíà Kékeré, ó sì jẹ́ ibùdókọ̀ òkun. Nínú ìràn náà, ọkùnrin ará Makedóníà kan bẹ̀ ẹ́ pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” Gbàrà tí Pọ́ọ̀lù rí ìran yìí, òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò dé “ìparí èrò náà pé Ọlọ́run ti fi ọlá àṣẹ [pe àwọn] láti polongo ìhìn rere” fún àwọn ará Makedóníà. Ohun tó yọrí sí ni pé ní ìlú Fílípì tó jẹ́ olú ìlú Makedóníà, obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà àtàwọn ará ilé rẹ̀ di onígbàgbọ́. Àwọn míì ní ìpínlẹ̀ Róòmù yẹn náà di onígbàgbọ́.—Ìṣe 16:9-15.
Lóde òní, à ń rí irú ìtara bẹ́ẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára wa ti fínnúfíndọ̀ lọ sáwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i, tó sì jẹ́ pé fúnra wọn ni wọ́n ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lisa fẹ́ fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀. Láti orílẹ̀-èdè Kánádà, ó gbéra ó di orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Tọkọtaya kan tí wọ́n ń jẹ́ Trevor àti Emily táwọn náà jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè Màláwì kí wọ́n lè fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Bàbá àti ìyá kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Paul àti Maggie, tí wọ́n ń gbé nílẹ̀ England rí i pé àsìkò táwọn fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ jẹ́ àsìkò táwọn ní àǹfààní tí kò ṣeé fowó rà láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà. Torí náà wọ́n gbéra ó di Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Ṣé ìwọ náà ní irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ yẹn? Ṣéwọ náà á gbé e yẹ̀ wò bóyá wàá lè lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì àti àmọ̀ràn wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe é láṣeyọrí?
Gbé Ipò Rẹ Yẹ̀ Wò
Ohun kan tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò ni ìdí tó o fi fẹ́ lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Jésù sọ pé àṣẹ títóbi jù lọ ni: “Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” Ìdí tó fi yẹ kéèyàn fẹ́ lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ láti ṣe iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn ní àṣeyọrí. Jésù fi kún un pé: “Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” Ọ̀nà téèyàn lè gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò òun ni pé kó ti ọkàn rẹ̀ wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 22:36-39; 28:19, 20) Sísìn nílẹ̀ òkèèrè sábà máa ń gba iṣẹ́ tó pọ̀ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Kì í ṣe ọ̀ràn ìrìn àjò afẹ́ o. Ìfẹ́ ló gbọ́dọ̀ sún ọ ṣe é. Tọkọtaya kan tí wọ́n ń jẹ́ Remco àti Suzanne tí wọ́n gbéra látilẹ̀ Netherlands lọ sìn ní orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “Ìfẹ́ ló jẹ́ ká lè dúró síbí.”
Alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Willie lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà sọ pé: “Àwọn tí wọ́n lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè tó sì dúró níbẹ̀ kò lọ pẹ̀lú èrò pé àwọn ará táwọn fẹ́ lọ bá níbẹ̀ yóò máa gbọ́ bùkátà àwọn. Ohun tó wà lọ́kàn wọn ni pé àwọn fẹ́ lọ máa sìn níbẹ̀, káwọn lè kún àwọn ará lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.”
Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tó o fi fẹ́ lọ, bi ara rẹ pé: ‘Ìmọ̀ wo ni mo ní tó máa wúlò níbi tí mo ti fẹ́ lọ sìn? Ṣé mo lè wàásù lọ́nà tó mọ́yán lórí? Àwọn èdè wo ni mo gbọ́? Ṣé màá fẹ́ kọ́ èdè míì?’ Rí i dájú pé ẹ jíròrò rẹ̀ dáadáa nínú ìdílé yín. Fi lọ àwọn alàgbà ìjọ rẹ. Sì rí i dájú pé o gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. Tó o bá fòótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ara rẹ lọ́nà yẹn, á jẹ́ kó o rí i bóyá “Mọ Ara Rẹ.”
lóòótọ́ ló lè lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè, á sì jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo pinnu láti lọ.—Wo àpótí náà,Ibo Lo Ti Lè Sìn?
Ojú ìran ni ọkùnrin kan ti ké sí Pọ́ọ̀lù pé kó wá sí Makedóníà. Lónìí, Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ lójú ìran láti darí wa lọ síbi tó yẹ ká lọ, àmọ́ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde wa míì, àwa èèyàn Ọlọ́run máa ń kà nípa ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ irú àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù bẹ́ẹ̀. Tó o bá rí i pé o ò ní lè kọ́ èdè míì tàbí tó ò fẹ́ pẹ́ ní ilẹ̀ òkèèrè, o lè ronú nípa sísìn ní ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè tó o gbọ́. Lẹ́yìn náà, kó o ṣèwádìí nípa àwọn ọ̀ràn bí ìwé àṣẹ ìrìnnà àti ìgbélùú, ọ̀ràn ọkọ̀ wíwọ̀, ọ̀ràn ààbò, ọ̀ràn àtijẹ àtimú àti bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí níbẹ̀. Ó lè ṣàǹfààní fún ọ tó o bá fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó ti lọ síbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i rí. Sì fi ọ̀rọ̀ náà sí àdúrà bó o ṣe ń ṣèwádìí. Rántí pé “ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà ní àgbègbè Éṣíà léèwọ̀” fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bítíníà, “ẹ̀mí Jésù kò gbà wọ́n láyè” láti lọ. Bákan náà, ó lè pẹ́ kíwọ náà tó mọ ibi tí wàá ti wúlò dáadáa.—Ìṣe 16:6-10.
Ní báyìí, ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn ibì kan tó o lè lọ. Tó o bá ń ronú nípa lílọ sìn nílẹ̀ òkèèrè, kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè tó o fẹ́ lọ. Sọ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ti ní rí àtèyí tó o ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kó o sì béèrè àwọn ìbéèrè tó o bá ní lórí àwọn ọ̀ràn bí àtijẹ àtimu, irú ilé tó o lè rí gbé, irú àwọn ilé ìwòsàn tó wà àti iṣẹ́ tó o lè rí. Kó o wá fi lẹ́tà rẹ lé Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ rẹ lọ́wọ́. Wọ́n á fi lẹ́tà rẹ àti lẹ́tà tí wọ́n fi dábàá nípa rẹ ránṣẹ́ tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè tó o fẹ́ lọ. Ìdáhùn wọn sáwọn ìbéèrè yìí lè jẹ́ kó o mọ ibi tó o ti lè sìn tí wàá sì wúlò jù lọ.
Willie, alábòójútó àyíká tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ pé: “Àwọn tó ti ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ náà ti kọ́kọ́ máa ń lọ wo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fẹ́ lọ sìn, wọ́n á sì wò ó bóyá àwọn lè rí ibi táwọn á lè máa gbé tayọ̀tayọ̀. Tọkọtaya kan rí i pé ó máa ṣòro fáwọn láti lọ máa gbé ní abúlé. Torí náà, wọ́n lọ sí ìlú kékeré kan tí wọ́n ti nílò oníwàásù, tí wọ́n á sì lè máa gbé irú ìgbésí ayé táá fún wọn láyọ̀.”
Àwọn Ìṣòro Tó O Lè Bá Pàdé
Kò ní ṣàì sí àwọn ìṣòro kan fún ẹni tó bá kó kúrò níbi tó ń gbé láti lọ sí àgbègbè tí kò tíì gbé rí. Lisa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ìṣòro ńlá ni pé kéèyàn dá nìkan wà.” Kí ló wá ràn án lọ́wọ́? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó fara mọ́ àwọn ará tó wà nínú ìjọ ibi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó lọ. Ó pinnu láti mọ orúkọ gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Bó ṣe ṣe é ni pé ó máa ń tètè dé sípàdé, kì í sì í tètè lọ tí ìpàdé bá parí, ó máa dúró kó lè bá àwọn
ará sọ̀rọ̀. Lisa máa ń bá àwọn ará ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ó máa ń pe ọ̀pọ̀ lára wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì ń sọ wọ́n dọ̀rẹ́. Ó sọ pé: “Mi ò kábàámọ̀ àwọn ohun tí mo yááfì. Jèhófà ti bù kún mi gan-an ni.”Lẹ́yìn tí bàbá àti ìyá tó ń jẹ́ Paul àti Maggie ti ṣíwọ́ ọmọ títọ́, wọ́n kúrò ní ilé wọn tí wọ́n ti ń gbé láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn. Bàbá yẹn sọ pé: “Kò ṣòro fún wa láti mójú kúrò lára àwọn dúkìá wa bá a ṣe rò pé ó máa ṣòro tó. Àmọ́ ohun tó le jù fún wa ní fífi àwọn ará ilé wa sílẹ̀, a ò mọ̀ pé bó ṣe máa le tó nìyẹn. A sunkún púpọ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú, tá ò bá ṣọ́ra ni, a fẹ́rẹ̀ẹ́ máa sọ pé, ‘Ẹ̀mí wa kò mà ní gbé ohun tá à ń ṣe yìí?’ Àmọ́, a gbára lé Jèhófà. Bá a tún ṣe wá ń láwọn ọ̀rẹ́ tuntun ń jẹ́ ká túbọ̀ pinnu láti máa bá iṣẹ́ náà lọ.”
Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Greg àti Crystal láti orílẹ̀-èdè Kánádà yàn láti lọ sí Nàmíbíà torí pé èdè Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ làwọn náà ń sọ. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n wá rí i pé ó yẹ káwọn kọ́ èdè ìbílẹ̀ ibẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Nígbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá wa. Ṣùgbọ́n, ìgbà tá a kọ́ èdè wọn la tó wá mọ àṣà ìbílẹ̀ wọn. Bá a tún ṣe sún mọ́ àwọn ará tó wà nínú ìjọ yẹn jẹ́ kára wa mọlé dáadáa.”
Irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmúratán bẹ́ẹ̀ lè nípa rere lórí àwọn ará tá a lọ ràn lọ́wọ́. Tìdùnnú-tìdùnnú ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jenny fi máa ń rántí àwọn ìdílé tó wá sìn ní ilẹ̀ Ireland, níbi tó gbé dàgbà. Ó ní: “Wọ́n kó èèyàn mọ́ra. Àwọn gan-an ló dìídì wá sìn wá, wọn ò retí pé kéèyàn sìn àwọn. Ìtara àti ayọ̀ wọn pọ̀ débi pé ó mú kémi náà fẹ́ láti lọ sìn.” Ní báyìí, Jenny àti ọkọ rẹ̀ ń sìn lórílẹ̀-èdè Gáńbíà.
Ìbùkún Jèhófà Ló Ń “Sọni Di Ọlọ́rọ̀”
Ẹ ò rí i bí ìrírí Pọ́ọ̀lù ní ìlú Makedóníà ti lárinrin tó! Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó kọ̀wé sáwọn ará Fílípì pé: “Mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín.”—Fílí. 1:3.
Trevor àti Emily tí wọ́n lọ sìn lórílẹ̀-èdè Màláwì kí wọ́n tó pè wọ́n sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì náà nírú ìrírí yẹn. Wọ́n ní: “Nígbà míì, a máa ń rò ó bóyá ohun tá à ń ṣe tọ́ tàbí kò tọ́, àmọ́ à ń láyọ̀. A túbọ̀ ń mọwọ́ ara wa sí i, a sì ń rí ìbùkún Jèhófà.” Greg àti Crystal, tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kàn sọ pé, “Kò sóhun míì tó dáa tó ohun tá a ń ṣe yìí.”
A mọ̀ pé gbogbo èèyàn kọ́ ló máa ṣeé ṣe fún láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti máa ṣe dáadáa ni ibi tí wọ́n ti nílò oníwàásù sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Àwọn míì lè fi ṣe àfojúsùn wọn láti lọ sìn ní ìjọ tí kò jìnnà sí ilé wọn. Ohun tó jà jù ni pé kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti sin Jèhófà. (Kól. 3:23) Ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run mí sí yóò tipa báyìí ṣẹ sí ọ lára, pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Mọ Ara Rẹ
Láti ṣàyẹ̀wò ara rẹ dáadáa kó o bàa lè mọ̀ bóyá wàá lè sìn nílẹ̀ òkèèrè, gbé àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò, kó o gbàdúrà nípa rẹ̀ kó o sì fòótọ́ inú wò ó bóyá wàá lè lọ sìn. Àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn Ilé Ìṣọ́ tó ti jáde kọjá lè wúlò fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
• Ṣé ẹni tẹ̀mí ni mí?—“Àwọn Ìgbésẹ̀ sí Jíjẹ́ Aláyọ̀” (October 15, 1997, ojú ìwé 6)
• Ṣé mo lè wàásù lọ́nà tó mọ́yán lórí?—“Bí A Ṣe Lè Ṣàṣeyọrsírere Ninu Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Aṣaaju-Ọna” (May 15, 1989, ojú ìwé 21)
• Ǹjẹ́ mo lè fi ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sílẹ̀?—“Kíkojú Àárò Ilé Lẹ́nu Iṣẹ́-Ìsìn Ọlọrun” (May 15, 1994, ojú ìwé 28)
• Ṣé mo lè kọ́ èdè míì?—“Ǹjẹ́ O Lè Lọ Sìn ní Ìjọ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Èdè Ilẹ̀ Òkèèrè?” (March 15, 2006, ojú ìwé 17)
• Ǹjẹ́ màá lè máa gbọ́ bùkátà ara mi?—“Ǹjẹ́ O Lè Sìn ní Ilẹ̀ Òkèèrè?” (October 15, 1999, ojú ìwé 23)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Téèyàn bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó sì lẹ́mìí pé nǹkan á dáa, ó lè nípa rere lórí àwọn ará ibi téèyàn ti ń sìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn tó máa ń kẹ́sẹ járí ni àwọn tó lẹ́mìí pé ńṣe làwọn fẹ́ sìn