Ìṣàkóso Sátánì Máa Forí Ṣánpọ́n
Ìṣàkóso Sátánì Máa Forí Ṣánpọ́n
“Kì yóò dára rárá fún ẹni burúkú.”—ONÍW. 8:13.
1. Kí nìdí tó fi jẹ́ ohun ìtùnú pé àwọn ẹni ibi ṣì ń bọ̀ wá jìyà iṣẹ́ ọwọ́ wọn?
BÓ PẸ́ bó yá, àwọn ẹni ibi ṣì ń bọ̀ wá jìyà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ẹ̀san gbogbo iṣẹ́ ibi wọn máa ké lórí wọn dandan. (Òwe 5:22; Oníw. 8:12, 13) Ìtùnú ńlá lèyí jẹ́, pàápàá jù lọ fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo, táwọn ẹni ibi ń rẹ́ jẹ tí wọ́n sì ń fojú wọn gbolẹ̀. Ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn aṣebi tí wọ́n máa jìyà iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni Sátánì Èṣù tó jẹ́ òléwájú nínú ìwà ọ̀daràn.—Jòh. 8:44.
2. Kí nìdí tó fi máa gba àkókò kí ọ̀ràn tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì tó yanjú?
2 Nínú ọgbà Édẹ́nì, ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú mú kí Sátánì ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n sì kọ ìṣàkóso Jèhófà. Èyí ló fà á táwọn òbí wa àkọ́kọ́ fi dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti máa sọ pé kò tọ́ bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọba Aláṣẹ, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀ lójú Rẹ̀. (Róòmù 5:12-14) Lóòótọ́ o, Jèhófà mọ ibi tí ìwà àrífín àti ọ̀tẹ̀ wọn máa bá wọn dé. Àmọ́, ó yẹ kí gbogbo èèyàn àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rí i kedere pé ibi tọ́ràn náà máa já sí nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi ní láti gba àkókò kí ọ̀ràn yẹn tó yanjú kí gbogbo ẹni tọ́ràn kàn lè rí i pé irọ́ làwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn pa.
3. Kí ni èrò wa nípa àwọn ìjọba èèyàn?
3 Níwọ̀n bí àwọn èèyàn ò ti fẹ́ kí Jèhófà máa darí àwọn, ó wá di pé kí wọ́n gbé ìjọba tara wọn kalẹ̀. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ nílùú Róòmù, ó pe ìjọba táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ní “àwọn aláṣẹ onípò gíga.” Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwọn aláṣẹ onípò gíga yìí ni ìjọba Róòmù lábẹ́ Olú Ọba Nérò tó ṣàkóso láàárín ọdún 54 sí 68 Sànmánì Kristẹni. Pọ́ọ̀lù sọ pé irú àwọn aláṣẹ onípò gíga bẹ́ẹ̀ “ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Ka Róòmù 13:1, 2.) Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé ìṣàkóso èèyàn ga ju ìṣàkóso Ọlọ́run lọ? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé, bí Jèhófà bá ṣì ń gba ìṣàkóso èèyàn láyè, àwọn Kristẹni ní láti máa bọ̀wọ̀ fún “ìṣètò Ọlọ́run” yìí, kí wọ́n má sì ta kò ó.
Ó Forí Lé Ọ̀nà Tó Ti Máa Kàgbákò
4. Ṣàlàyé ìdí tó fi di dandan pé kí ìṣàkóso èèyàn forí ṣánpọ́n.
4 Ó dájú pé ìṣàkóso èèyàn tí Sátánì ń darí máa forí ṣánpọ́n. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé kì í ṣe ọgbọ́n Ọlọ́run ni wọ́n fi ń ṣàkóso. Jèhófà nìkan ló ní ọgbọ́n tí kò kù síbì kan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òun nìkan ló lè tọ́ wa sọ́nà lórí ọ̀ràn ìṣàkóso tó máa yọrí sí rere. (Jer. 8:9; Róòmù 16:27) Jèhófà ò dà bí àwa èèyàn tó jẹ́ pé àṣìṣe ló máa ń kọ́ wa lọ́gbọ́n, gbogbo ìgbà ló máa ń mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbé nǹkan gbà. Torí náà, kò sí bí ìṣàkóso èèyàn èyíkéyìí ṣe lè rọ́wọ́ mú tá ò bá gbé e karí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ìyẹn nìkan ti tó láti mú ká gbà pé dandan ni kí ìṣàkóso àwọn èèyàn tí Sátánì ń lò láti ṣàkóso ayé forí ṣánpọ́n. Ó ṣe tán, èrò búburú ló ní lọ́kàn tó fi gbé ìṣàkóso èèyàn kalẹ̀.
5, 6. Kí ló sún Sátánì débi tó fi ń ta ko Jèhófà?
5 Kò sẹ́ni tí orí rẹ̀ pé táá dáwọ́ lé ohun kan tó máa forí ṣánpọ́n. Ó mọ̀ pé bí òun bá sọ pé tinú òun lòun máa ṣe, òun máa jẹ̀ka àbámọ̀ gbẹ̀yìn ni. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé ti fi hàn léraléra pé ẹni bá ń ta ko Ẹlẹ́dàá wa olódùmarè kàn ń fàkókò rẹ̀ ṣòfò ni. (Ka Òwe 21:30.) Àmọ́, ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú àti ìgbéraga mú kí Sátánì kẹ̀yìn sí Jèhófà. Torí náà, ńṣe ni Èṣù fi ìkùgbù yàn láti tọ ọ̀nà tó ti máa kàgbákò.
6 Nígbà tó ṣe, ọba Bábílónì kan hu irú ìwà ìkùgbù tí Sátánì hù yìí, ó sì fọ́nnu pé: “Ọ̀run ni èmi yóò gòkè lọ. Òkè àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run ni èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sí, èmi yóò sì jókòó sórí òkè ńlá ìpàdé, ní àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ ní àríwá. Èmi yóò gòkè lọ sí àwọn ibi gíga àwọsánmà; èmi yóò mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Aísá. 14:13-15) Pàbó ni gbogbo ohun tí ọba yìí fọ́nnu pé òun fẹ́ dà pàpà já sí, ẹ̀tẹ́ ló sì máa ń gbẹ̀yìn ìṣàkóso àwọn ọba tó jẹ ní Bábílónì. Bó ṣe máa rí fún Sátánì àti ayé rẹ̀ náà nìyẹn, ìparun yán-ányán ló máa gbẹ̀yìn wọn.
Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Fàyè Gbà Á?
7, 8. Àwọn àǹfààní wo ló ti wá látinú bí Jèhófà ṣe fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀?
7 Ó lè máa ṣe àwọn kan ní kàyéfì bí Jèhófà ò ṣe dá àwọn èèyàn lẹ́kun pé kí wọ́n má fara mọ́ Sátánì, tí kò sì dá wọn lẹ́kun pé kí wọn má ṣe gbé ìṣàkóso míì tó dájú pé ó máa forí ṣánpọ́n kalẹ̀. Ó dájú pé Ọlọ́run Olódùmarè lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, bó bá fẹ́. (Ẹ́kís. 6:3) Àmọ́, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tó máa ṣàǹfààní jù lọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni pé kóun ṣì yọ̀ọ̀da fáwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn yẹn ná láti pitú ọwọ́ wọn. Bó bá yá, gbogbo ẹ̀dá á wá mọ̀ pé Jèhófà ni Alákòóso onífẹ̀ẹ́ àti olódodo, àwọn olóòótọ́ èèyàn á sì jàǹfààní látinú ìpinnu tí Ọlọ́run ṣe.
8 Ká ní àwọn èèyàn kọ ohun tí Sátánì fi lọ̀ wọ́n ni, tí wọn ò sì wá òmìnira kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, kò ní sí ìdààmú kankan fún aráyé. Síbẹ̀, bí Jèhófà ṣe fàyè gba àwọn èèyàn láti máa ṣàkóso ara wọn ṣì ní àǹfààní tiẹ̀. Ó ti jẹ́ káwọn ọlọ́kàn rere rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn máa fetí sí Ọlọ́run kó sì fọkàn tán an. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn ti dán oríṣiríṣi ìṣàkóso wò, àmọ́ kò sí èyí tó sàn nínú wọn. Èyí ti túbọ̀ mú kó dá àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run lójú kedere pé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso ló dára jù lọ. Lóòótọ́ o, bí Jèhófà ṣe fàyè gba ìṣàkóso burúkú Sátánì ti mú kójú àwọn èèyàn rí màbo, tó fi mọ́ àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. Síbẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìwà ibi fúngbà díẹ̀ ti mú àwọn àǹfààní kan wá fáwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn.
Ìdìtẹ̀ Tó Ń Mú Ká Yin Jèhófà Lógo
9, 10. Ṣàlàyé bí ìṣàkóso Sátánì ṣe ń mú ká yin Jèhófà lógo.
9 Bí Jèhófà ṣe gbà kí Sátánì máa nípa lórí àwọn èèyàn tó sì gbà káwọn èèyàn máa ṣàkóso ara wọn, kò bu ìṣàkóso Ọlọ́run kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá a rí nínú ìtàn fi hàn pé òkodoro òótọ́ lohun tí Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti sọ, pé kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti ṣàkóso ara wa. (Ka Jeremáyà 10:23.) Bákan náà, ọ̀tẹ̀ Sátánì ti jẹ́ kí Jèhófà fi àwọn ànímọ́ rere rẹ̀ hàn lọ́nà tó túbọ̀ ṣe kedere. Lọ́nà wo?
10 Bí ìṣàkóso Sátánì ṣe kún fún làásìgbò yìí ti mú káwọn ànímọ́ pípé Jèhófà túbọ̀ fara hàn kedere ju bí ì bá ṣe rí ká ní ọ̀ràn ò rí bó ṣe rí yìí. Lọ́nà yìí, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ti wá rí i bó ṣe tóbi lọ́ba tó. Bó tilẹ̀ dà bí ohun tó ṣòroó gbà gbọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìṣàkóso Sátánì ń mú ká yin Ọlọ́run lógo. Ó jẹ́ ká rí ọ̀nà dídára jù lọ tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ tí wọ́n pè níjà. Kí ọ̀rọ̀ yìí lè yé wa, ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà ní ṣókí, ká sì wo bí ìṣàkóso búburú Sátánì yìí ṣe ń mú kí Jèhófà lo àwọn ànímọ́ yìí ní onírúurú ọ̀nà.
11. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo ìfẹ́ rẹ̀?
11 Ìfẹ́. Ìwé Mímọ́ sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Dídá tí Ọlọ́run dá èèyàn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀nà àgbàyanu tó jọni lójú tí Jèhófà gbà dá wa jẹ́rìí sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní yìí. Ìfẹ́ tún mú kí Jèhófà pèsè ibùgbé tó lẹ́wà fáwọn èèyàn, ó sì fi gbogbo nǹkan tá máa mú kí wọ́n láyọ̀ síbẹ̀. (Jẹ́n. 1:29-31; 2:8, 9; Sm. 139:14-16) Àmọ́, ìgbà tí ìwà ibi bẹ̀rẹ̀ láàárín àwa èèyàn ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn láwọn ọ̀nà míì. Báwo? Jésù sọ̀rọ̀ kan tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ sílẹ̀, pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Ǹjẹ́ ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ míì wà tí Ọlọ́run lè gbà lo ìfẹ́ rẹ̀ ju bó ṣe rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé láti wá ra àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà? (Jòh. 15:13) Ọ̀nà pàtàkì tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn yìí tún jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwa èèyàn, ó fún wa láǹfààní láti lo ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ lójoojúmọ́ ayé wa, bí Jésù ti ṣe.—Jòh. 17:25, 26.
12. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi agbára rẹ̀ hàn?
12 Agbára. “Ọlọ́run, Olódùmarè,” nìkan ló ní agbára láti dá àwọn ohun alààyè. (Ìṣí. 11:17; Sm. 36:9) Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí èèyàn kan, ńṣe ló máa ń dà bí abala bébà kan tí wọn ò tíì kọ nǹkan kan sí. Nígbà tónítọ̀hún bá fi máa kú, abala bébà yìí á ti kún fún àwọn ìpinnu tó ṣe, ìhùwàsí rẹ̀ àti àwọn ìrírí tó ní jálẹ̀ ìgbésí ayé, èyí tó mú kó jẹ́ irú ẹni tó jẹ́. Jèhófà lágbára láti rántí gbogbo ohun tó wà nínú bébà náà. Nígbà tó bá wá yá, Jèhófà lè jí ẹni náà dìde, táá sì ní gbogbo ànímọ́ tó ní kó tó kú. (Jòh. 5:28, 29) Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò dá àwa ẹ̀dá pé ká máa kú, bá a ṣe ń kú ti mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti fi hàn pé òun lágbára lórí ikú. Dájúdájú, Jèhófà ni “Ọlọ́run, Olódùmarè.”
13. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tó pé pérépéré nínú ọ̀ràn ìrúbọ Jésù?
13 Ìdájọ́ òdodo. Jèhófà kì í parọ́; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣègbè. (Diu. 32:4; Títù 1:2) Kì í yẹsẹ̀ lórí ìlànà òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀, èyí tí kò ṣeé fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, kódà bó bá máa ná an ní ohunkóhun. (Róòmù 8:32) Ẹ wo bó ṣe máa dun Jèhófà tó nígbà tó ń wo Ọmọ rẹ̀ àyànfẹ́ tó kú lórí òpó igi oró bí ẹni pé asọ̀rọ̀ òdì ni! Síbẹ̀, torí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn aláìpé, ó fínnú-fíndọ̀ gbà kí ìṣẹ̀lẹ̀ tó dùn ún yìí wáyé kó lè tẹ̀ lé ìlànà òdodo rẹ̀ tó pé pérépéré. (Ka Róòmù 5:18-21.) Bí ìwà ìrẹ́jẹ ṣe pọ̀ tó láyé yìí fún Jèhófà láǹfààní láti fi hàn pé ìdájọ́ òdodo tirẹ̀ ló ga jù.
14, 15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà lo ọgbọ́n àti sùúrù rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́?
14 Ọgbọ́n. Gbàrà tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀ ni Jèhófà ti fi ọ̀nà tó máa gbà mú gbogbo oró ńlá tí ọ̀tẹ̀ wọn dá kúrò. (Jẹ́n. 3:15) Ìgbésẹ̀ ojú ẹsẹ̀ tí Jèhófà gbé yìí àti bó ṣe ń ṣí àwọn ohun tó ní lọ́kàn payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tún jẹ́ ká túbọ̀ rí ọgbọ́n Jèhófà. (Róòmù 11:33) Kò sí ohun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ tí kò fi ní bójú tó àwọn nǹkan bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nínú ayé tó kún fún ìṣekúṣe, ogun, àìfòyebánilò, àìgbọràn, àìláàánú, ojúsàájú àti àgàbàgebè yìí, Jèhófà ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti fohun tó ń jẹ́ ọgbọ́n tòótọ́ han àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.”—Ják. 3:17.
15 Sùúrù àti Ìpamọ́ra. Ká ní kò di dandan pé kí Jèhófà máa fara da àìpé, ẹ̀ṣẹ̀ àti ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn èèyàn ni, a lè má mọ̀ pé ó ní sùúrù àti ìpamọ́ra tó pọ̀ gan-an. Pé Jèhófà ń bá irú àwọn èèyàn báyìí lò láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá fi hàn pé ó ní àwọn àgbàyanu ànímọ́ méjèèjì yìí lọ́nà tó pé pérépéré, ó sì yẹ ká máa dúpẹ́ fún ìyẹn. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù sọ, pé ká máa “ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.”—2 Pét. 3:9, 15.
16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa láyọ̀ pé Jèhófà múra tán láti dárí jì wá?
16 Ó Múra Tán Láti Dárí Jini. Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, a sì máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. (Ják. 3:2; 1 Jòh. 1:8, 9) Ẹ ò rí i pé ṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà múra tán láti darí jini “lọ́nà títóbi”! (Aísá. 55:7) Tún gba èyí yẹ̀ wò: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n bí wa gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀, a máa ń láyọ̀ látọkànwá nígbàkigbà tí Ọlọ́run bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Sm. 51:5, 9, 17) Bí Jèhófà ṣe ń lo ànímọ́ rẹ̀ tó ń mọ́kàn yọ̀ yìí láti dárí ji olúkúlùkù wa, ńṣe ló ń mú kí ìfẹ́ tá a ní fún un túbọ̀ lágbára, èyí sì ń mú ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú bá a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì lò.—Ka Kólósè 3:13.
Ìdí Tí Ayé Ò Fi Fara Rọ
17, 18. Àwọn ọ̀nà wo ni ìṣàkóso Sátánì ti gbà forí ṣánpọ́n?
17 Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ni gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ayé Sátánì pátá, ìyẹn àwọn ètò tó gbé kalẹ̀ láyé láti máa fi ṣàkóso, ti ń kùnà, títí di báyìí. Lọ́dún 1991, ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ The European sọ pé: “Ṣé òótọ́ ni pé ayé ò fara rọ? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́, . . . kì í ṣe àmúwá Ọlọ́run, àwọn èèyàn tó ń gbé inú rẹ̀ ló fà á tí kò fi fara rọ.” Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí! Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ gbọ́ ti Sátánì, wọ́n yan ìṣàkóso èèyàn dípò ìṣàkóso Jèhófà. Wọ́n sì tipa báyìí gbé ìṣàkóso tó dájú pé ó máa forí ṣánpọ́n kalẹ̀. Ìrora àti ìpọ́njú tójú àwọn èèyàn jákèjádò ayé ń rí báyìí fi hàn pé nǹkan ò fara rọ fún ìṣàkóso èèyàn.
18 Ìmọtara-ẹni-nìkan ló wà lẹ́yìn ìṣàkóso Sátánì. Àmọ́ orí ìfẹ́ ni ìṣàkóso Jèhófà dá lé, ìmọtara-ẹni-nìkan ò sì lè borí ìfẹ́ yìí láéláé. Ìṣàkóso Sátánì ti kùnà láti mú ayọ̀ àti ààbò wá, kò sì mú káwọn nǹkan fara rọ. Ó ti wá ṣe kedere pé Ìjọba Jèhófà ló máa mókè! Ǹjẹ́ a rí ẹ̀rí èyí lóde òní bí? Bẹ́ẹ̀ ni. A óò jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Kí Làwọn Ẹsẹ Bíbélì Yìí Kọ́ Wa Nípa Ìṣàkóso?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìṣàkóso Sátánì kò ṣàǹfààní kankan fún aráyé rí
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò U.S. Army
Fọ́tò tí P. Almasy yà fún àjọ WHO
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kódà Jèhófà lágbára lórí ikú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo Jèhófà hàn nínú bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ rúbọ