Fi Hàn Pé Ojúlówó Ọmọlẹ́yìn Kristi Ni Ẹ́
Fi Hàn Pé Ojúlówó Ọmọlẹ́yìn Kristi Ni Ẹ́
“Gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde.”—MÁT. 7:17.
1, 2. Báwo làwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi ṣe yàtọ̀ sáwọn èké ọmọlẹ́yìn, pàápàá lákòókò òpin yìí?
JÉSÙ sọ pé ohun tó máa fìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń fẹnu lásán sọ pé àwọn ń sin òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ ni èso tí kálukú wọn bá ń so, ìyẹn ẹ̀kọ́ wọn àti ìwà wọn. (Mát. 7:15-17, 20) Ó dájú pé ohun táwọn èèyàn bá ń kà, ohun tí wọ́n ń wò tàbí ohun tí wọ́n ń gbọ́ sétí máa ń nípa lórí ìwà àti ìṣe wọn. (Mát. 15:18, 19) “Èso tí kò ní láárí” làwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ máa ń so, ‘èso àtàtà’ sì làwọn tí wọ́n bá fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ máa ń so.
2 À ń rí báwọn èèyàn ṣe ń so irú èso méjèèjì yìí ní àkókò òpin yìí. (Ka Dáníẹ́lì 12:3, 10.) Èrò tí kò tọ́ ni àwọn èké Kristẹni ní nípa Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń díbọ́n pé àwọn ní ìfọkànsin Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí ń sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòh. 4:24; 2 Tím. 3:1-5) Wọ́n máa ń sapá láti fàwọn ànímọ́ Kristi ṣèwà hù. Àmọ́, àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn àmì márùn-ún tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ tá a fẹ́ jíròrò yìí, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ìwà mi àti ẹ̀kọ́ tí mo fi ń kọ́ni bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu? Ǹjẹ́ mò ń ṣe ẹ̀kọ́ òtítọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ lójú àwọn tó ń wá òtítọ́?’
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Rẹ
3. Kí ni Jèhófà ń fẹ́, kí lèyí sì ń béèrè pé káwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe?
3 Jésù sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” (Mát. 7:21) Torí náà, kì í ṣe kéèyàn máa fẹnu sọ pé Kristẹni lòun ni Jèhófà ń fẹ́ bí kò ṣe kéèyàn máa hu ìwà tó fi hàn pé ó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Ohun tá a sọ yìí máa ń hàn nínú bí àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn, tó fi mọ́ ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú ọ̀ràn owó, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, eré ìnàjú, àwọn àṣà àti ayẹyẹ ayé, ìgbéyàwó àti àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn. Àmọ́ àwọn èké Kristẹni máa ń fara mọ́ èrò àti ìṣe ayé, èyí tó túbọ̀ ń burú sí i ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Sm. 92:7.
4, 5. Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Málákì 3:18 gbà kan ìgbésí ayé wa?
4 Ọ̀rọ̀ yìí bá ohun tí wòlíì Málákì sọ mu, pé: “Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Bó o ṣe ń ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ọwọ́ tèmi náà ti wọ ọwọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé, àbí tèmi yàtọ̀? Ṣé gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbìyànjú láti ṣe ohun táwọn tá a jọ jẹ́ òṣìṣẹ́ tàbí ọmọléèwé ń ṣe, àbí ìlànà Bíbélì ni mo máa ń rọ̀ mọ́, tí mo sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó bá yẹ?’ (Ka Pétérù 3:16.) Kì í ṣe pé ká jẹ́ olódodo lójú ara wa là ń sọ, àmọ́ a ní láti dá yàtọ̀ gédégbé sáwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọn kì í sì í sìn ín.
5 Bó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àtúnṣe èyíkéyìí, o ò ṣe gbàdúrà nípa rẹ̀, kó o sì wá okun tẹ̀mí nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà àti lílọ sípàdé déédéé? Bó o bá ṣe ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó, ni wàá ṣe máa so ‘èso àtàtà’ tó. Lára èso yìí si ni “èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ” Ọlọ́run.—Héb. 13:15.
Máa Polongo Ìjọba Ọlọ́run
6, 7. Ní ti ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àtàwọn èké Kristẹni?
6 Jésù sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Kí nìdí tí Jésù fi fi Ìjọba Ọlọ́run ṣe lájorí ìwàásù rẹ̀? Ìdí ni pé Jésù mọ̀ pé òun gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba yẹn àti àwọn arákùnrin òun tá a fẹ̀mí bí tí wọ́n sì ti jíǹde, máa tó mú ìparun bá ohun tó fa ìṣòro tó ń kojú aráyé báyìí, ìyẹn ni ẹ̀ṣẹ̀ àti Èṣù. (Róòmù 5:12; Ìṣí. 20:10) Torí náà, ó pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa polongo Ìjọba yẹn títí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí fi máa dé. (Mát. 24:14) Àwọn tó kàn ń fẹnu lásán pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi kì í ṣe iṣẹ́ yìí, wọn ò tiẹ̀ lè ṣe é ni. Kí ló fà á tí wọn ò fi lè ṣe é? Ó kéré tán ohun mẹ́ta ló fà á: Àkọ́kọ́, kò sí bí wọ́n ṣe lè wàásù ohun tí kò yé wọn. Èkejì, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ò ní ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà tó máa ń mú kéèyàn lè fara da yẹ̀yẹ́ àti àtakò tó lè wáyé béèyàn bá ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fáwọn aládùúgbò ẹni. (Mát. 24:9; 1 Pét. 2:23) Ẹ̀kẹta sì ni pé, àwọn èké Kristẹni yìí kò ní ẹ̀mí Ọlọ́run.—Jòh. 14:16, 17.
7 Àmọ́ àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, wọ́n sì mọ ohun tó máa gbé ṣe. Bákan náà, ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n fi ṣe àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn, wọ́n ń kéde rẹ̀ jákèjádò ayé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà. (Sek. 4:6) Ǹjẹ́ ò ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí déédéé? Ṣé ò ń gbìyànjú láti tẹ̀ síwájú sí i gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba Ọlọ́run, bóyá nípa fífi kún àkókò tó ò ń lò lóde ẹ̀rí tàbí nípa jíjáfáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ náà? Ohun táwọn kan ṣe láti mú kí ìwàásù wọn túbọ̀ mọ́yán lórí ni pé wọ́n ń lo Bíbélì lọ́nà tó múná dóko. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ti sọ ọ́ di àṣà láti máa bá àwọn èèyàn fèrò wérò nínú Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Héb. 4:12; Ìṣe 17:2, 3.
8, 9. (a) Àwọn ìrírí wo ló fi hàn bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa lo Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (b) Báwo la ṣe lè dẹni tó túbọ̀ jáfáfá nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
8 Nígbà tí arákùnrin kan wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ó ka Dáníẹ́lì 2:44 sétígbọ̀ọ́ ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ó sì ṣàlàyé bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ wá. Ọkùnrin yẹn fèsì pé: “Ó dùn mọ́ mi bó o ṣe ṣí Bíbélì rẹ tó o sì fi ohun tó sọ hàn mí dípò kó o wulẹ̀ sọ ohun tó wà nínú rẹ̀ fún mi.” Nígbà tí arákùnrin kan ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún obìnrin kan tó ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìsì, obìnrin yẹn béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè pàtàkì lọ́wọ́ rẹ̀. Bíbélì náà ni arákùnrin yìí pẹ̀lú ìyàwó rẹ fi dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Nígbà tó yá, obìnrin yẹn sọ pé: “Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á tó fi wù mí láti bá ẹ sọ̀rọ̀? Ohun tó fà á ni pé o mú Bíbélì tọ̀ mí wá, o sì kà á jáde.”
9 Lóòótọ́, a ò lè kóyán àwọn ìwé wa kéré, ó sì yẹ ká máa lò wọ́n lóde ẹ̀rí. Àmọ́ Bíbélì gan-an ni irin iṣẹ́ wa tó ṣe pàtàkì jù lọ. Torí náà, bí kò bá mọ́ ẹ lára láti máa lo Bíbélì déédéé lóde ẹ̀rí, o ò ṣe gbìyànjú láti fi ṣe àfojúsùn rẹ láti máa lò ó? Bóyá o lè yan àwọn ẹsẹ mélòó kan tó ṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti bó ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro kan tó ń kọ àwọn èèyàn tó wà ládùúgbò rẹ lóminú. Kó o sì múra sílẹ̀ láti kà á bó o ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé.
Má Ṣe Tijú Láti Jẹ́ Orúkọ Mọ́ Ọlọ́run
10, 11. Ní ti lílo orúkọ Ọlọ́run, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Jésù àtàwọn tó ń fẹnu lásán sọ pé àwọn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
10 “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi sì ni Ọlọ́run.’” (Aísá. 43:12) Jésù Kristi tó jẹ́ òléwájú lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà á sí àǹfààní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run àti láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀. (Ka Ẹ́kísódù 3:15; Jòhánù 17:6; Hébérù 2:12.) Kódà, Ìwé Mímọ́ pe Jésù ní “Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé,” torí pé ó kéde orúkọ Bàbá rẹ̀.—Ìṣí. 1:5; Mát. 6:9.
11 Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ làwọn ń ṣojú fún ti hùwà àìdáa sí orúkọ Ọlọ́run ní ti pé wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú àwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ làwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe nígbà tí wọ́n sọ fáwọn bíṣọ́ọ̀bù lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé wọn “kò gbọ́dọ̀ lo lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn YHWH, tàbí kí wọ́n pè é” bí ìjọsìn bá ń lọ lọ́wọ́. a Ẹ ò rí i pé ìwà àbùkù gbáà nìyẹn!
12. Báwo ló ṣe di pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà túbọ̀ dẹni tá a mọ̀ mọ Jèhófà lọ́dún 1931?
12 Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò tijú láti máa lo orúkọ Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi àti ti “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” tí wọ́n ti gbáyé ṣáájú Kristi. (Héb. 12:1) Nígbà tó sì di ọdún 1931, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ dẹni tá a mọ̀ mọ Jèhófà nígbà tí wọ́n gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Ka Aísáyà 43:10-12.) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi ní pàtàkì jù lọ ni “àwọn ènìyàn tí a fi orúkọ [Ọlọ́run] pè.”—Ìṣe 15:14, 17.
13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń ṣe ohun tó yẹ ẹni tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run?
13 Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè fi hàn pé à ń ṣe ohun tó yẹ ẹni tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run? Ọ̀nà kan ni pé ká máa fi tọkàntọkàn jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là. Àmọ́ ṣá o, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe wàásù láìjẹ́ pé a rán wọn jáde?” (Róòmù 10:13-15) Bákan náà, a tún gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké, irú bí ọ̀run àpáàdì, tó ń kọ́ni pé Ọlọ́run ìfẹ́ ní àwọn ànímọ́ ìkà, tó jẹ́ ti Èṣù.—Jer. 7:31; 1 Jòh. 4:8; fi wé Máàkù 9:17-27.
14. Kí làwọn kan ṣe nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ mọ orúkọ Ọlọ́run?
14 Ṣé ojú kì í tì ẹ́ láti máa jẹ́ orúkọ Bàbá rẹ ọ̀run? Ṣé o máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti mọ orúkọ mímọ́ yẹn? Obìnrin kan nílùú Paris lórílẹ̀-èdè Faransé gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ orúkọ Ọlọ́run, torí náà ó bi Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ pàdé lẹ́yìn náà pé kó fi orúkọ Ọlọ́run han òun nínú Bíbélì. Nígbà tó ka Sáàmù 83:18, ohun tó rí níbẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní báyìí òun náà ti di arábìnrin wa tó ń sìn lórílẹ̀-èdè míì. Nígbà tí obìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nílẹ̀ Ọsirélíà kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì, ó sun ẹkún ayọ̀. Láti ọ̀pọ̀ ọdún títí di báyìí ló ti wà lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan lórílẹ̀-èdè Jàmáíkà fi orúkọ Ọlọ́run han obìnrin kan nínú Bíbélì tiẹ̀ fúnra rẹ̀, omijé ayọ̀ dà lójú òun náà. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó tì ẹ́ lójú láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa sísọ orúkọ náà di mímọ̀ fún gbogbo èèyàn.
“Ẹ Má Ṣe Máa Nífẹ̀ẹ́ . . . Ayé”
15, 16. Ojú wo làwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń wo ayé, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
15 “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.” (1 Jòh. 2:15) Ńṣe ni ayé àti ẹ̀mí ayé ń ta ko Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ kò fi fẹ́ láti jẹ́ apá kan ayé. Kì í wá ṣe ìyẹn nìkan ṣá o, wọ́n tún kọ ayé lákọ̀tán, torí pé wọ́n mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe sọ: “Ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Ják. 4:4.
16 Ó lè fẹ́ ṣòro láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jákọ́bù yẹn nínú ayé tó kún fún onírúurú ìdẹwò yìí. (2 Tím. 4:10) Ìyẹn ló mú kí Jésù gbàdúrà nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 17:15, 16) Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mò ń sapá láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ ohun tí mo gbà gbọ́ nípa àwọn ayẹyẹ àtàwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu títí kan àwọn tó lè ṣàì wá látọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà, àmọ́ tó ṣe kedere pé ẹ̀mí ayé ni wọ́n ń gbé lárugẹ?’—2 Kọ́r. 6:17; 1 Pét. 4:3, 4.
17. Kí ló lè mú káwọn olóòótọ́-ọkàn fara mọ́ Jèhófà?
17 Ó dájú pé bá a ṣe ń tẹ̀ lé Bíbélì yìí kò ní jẹ́ ká rójú rere ayé yìí, àmọ́ ó lè mú káwọn olóòótọ́-ọkàn fẹ́ láti mọ̀ sí i. Kódà nígbà tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìwé Mímọ́ àti pé òun la fi ń ṣèwà hù, wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ wa, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ fáwọn ẹni àmì òróró pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—Sek. 8:23.
Máa Fi Ìfẹ́ Kristẹni Tòótọ́ Hàn
18. Kí ló túmọ̀ sí láti fi ìfẹ́ hàn sí Jèhófà àti aládùúgbò wa?
18 Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ,” ó fi kún un pé, “kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mát. 22:37, 39) Ìfẹ́ yẹn (tó jẹ́ a·gaʹpe lédè Gíríìkì) jẹ́ ìfẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ojúṣe ẹni, ìlànà àti ṣíṣe ohun tó tọ́, àmọ́ ó tún kan bọ́rọ̀ àwọn ẹlòmíì ṣe máa ń rí lára ẹni. Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni, ó sì máa ń ti inú ọkàn-àyà wá. (1 Pét. 1:22) Ìfẹ́ yìí jẹ́ òdì kejì ìmọtara-ẹni-nìkan torí pé ó máa ń mú kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe èèyàn fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹni lógún.—Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-7.
19, 20. Sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé ojúlówó ìfẹ́ làwa Kristẹni ní.
19 Torí pé ìfẹ́ jẹ́ apá kan èso ẹ̀mí Ọlọ́run, ó máa ń ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti ṣe ohun táwọn míì ò lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó ti mú ká borí ìyapa tó máa ń wáyé bí ẹ̀yà àti àṣà ìbílẹ̀ àwọn èèyàn bá yàtọ̀ síra, tí wọn ò sì sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà. (Ka Jòhánù 13:34, 35; Gál. 5:22) Ìfẹ́ yìí máa ń wú àwọn ẹni bí àgùntàn lórí gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọkùnrin kan tó jẹ́ Júù tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kọ́kọ́ lọ sípàdé wa, ẹnu yà á bó ṣe rí àwọn Júù àtàwọn Lárúbáwá tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà láìjà láìta. Ohun tó rí yìí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé déédéé tó sì gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣé ìwọ náà ń fi irú ìfẹ́ àtọkànwá bẹ́ẹ̀ hàn sáwọn ará? Ṣé o máa ń sapá láti kí àwọn ẹni tuntun káàbọ̀ tí wọ́n bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba yín, láìka ti orílẹ̀-èdè wọn, àwọ̀ wọn, tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ sí?
20 Gbogbo èèyàn pátá làwa Kristẹni tòótọ́ ń sapá láti fìfẹ́ hàn sí. Lórílẹ̀-èdè El Salvador, akéde kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ màmá arúgbó kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87], tí kò lè ṣe kó má lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Lọ́jọ́ kan, màmá yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn. Àìsàn náà sì le débi pé wọ́n gbé e lọ sílé ìwòsàn. Nígbà tí ìyá náà tilé ìwòsàn dé, àwọn ará máa ń lọ gbé oúnjẹ fún un nílé, ó sì tó oṣù kan tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Kò sẹ́nì kankan láti ṣọ́ọ̀ṣì màmá náà tó lọ bẹ̀ ẹ́ wò. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ó kó gbogbo ère rẹ̀ dà nù, ó kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó. Láìsí àní-àní, ojúlówó ìfẹ́ làwa Kristẹni ní! Ìfẹ́ yìí lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ.
21. Kí la lè ṣe tí mìmì kan ò fi ní mi ọjọ́ iwájú wa?
21 Láìpẹ́, Jésù máa sọ fáwọn tó ń fẹnu lásán sọ pé àwọn ń sìn ín pé: “Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mát. 7:23) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa so èso táá máa bọlá fún Bàbá àti Ọmọ. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” (Mát. 7:24) Lóòótọ́ ni, tá a bá jẹ́ ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi, a óò rojú rere Ọlọ́run, mìmì kan ò sì ní mi ọjọ́ iwájú wa, bí ilé téèyàn kọ́ sórí àpáta!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ìwé kan táwọn Kátólíìkì ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tó fi mọ́ Bíbélì The Jerusalem Bible túmọ̀ lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run sí “Yahweh.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo làwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi ṣe yàtọ̀ sáwọn èké Kristẹni?
• Sọ díẹ̀ lára àwọn “èso” tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀.
• Àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn rẹ tó bá dọ̀ràn síso èso tó yẹ Kristẹni?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ṣó mọ́ ẹ lára láti máa lo Bíbélì déédéé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa àwọn ayẹyẹ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu?