Jẹ́ Kí Ìgbé Ayé Rẹ Ojoojúmọ́ Máa Fi Ògo Fún Ọlọ́run
Jẹ́ Kí Ìgbé Ayé Rẹ Ojoojúmọ́ Máa Fi Ògo Fún Ọlọ́run
ONÍSÁÀMÙ náà Dáfídì, sọ pé: “Mú kí n gbọ́ inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní òwúrọ̀, . . . mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn.” (Sm. 143:8) Nígbà tó o bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jí ẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà, ǹjẹ́ o máa ń bẹ Jèhófà bíi ti Dáfídì, pé kó tọ́ ẹ sọ́nà láti ṣe ìpinnu, kó o lè fọjọ́ yẹn ṣohun tó dára jù? Ó dájú pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ‘yálà a ń jẹ tàbí a ń mu tàbí a ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ó yẹ ká máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.’ (1 Kọ́r. 10:31) A mọ̀ pé ọ̀nà tá a bá ń gbà gbé ìgbé ayé wa lè bọlá fún Jèhófà tàbí kó tàbùkù sí i. A tún rántí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé Sátánì ń fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin Kristi “tọ̀sán-tòru,” tó sì dájú pé ohun tó ń ṣe nípa gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a wà lórí ilẹ̀ ayé náà nìyẹn. (Ìṣí. 12:10) Torí náà, a ti pinnu láti fi hàn pé èké làwọn ẹ̀sùn Sátánì, ká sì mú ọkàn Jèhófà yọ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Baba wa ọ̀run “tọ̀sán-tòru.”—Ìṣí. 7:15; Òwe 27:11.
Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ráńpẹ́ lórí ọ̀nà pàtàkì méjì tá a fi lè mú kí ìgbé ayé wa ojoojúmọ́ máa fi ògo fún Ọlọ́run. Àkọ́kọ́ ni pé ká mọ ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́, èkejì sì ni pé ká máa gba tàwọn èèyàn rò.
Bá A Ṣe Lè Máa Mú Ẹ̀jẹ́ Wa Ṣẹ
Bá a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe là ń sọ ìfẹ́ wa àtọkànwá fún un pé a fẹ́ láti máa sìn ín. A tún ṣèlérí fún Jèhófà pé a ó máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ “ní ọjọ́ dé ọjọ́,” pé a ó máa sìn ín títí láé. (Sm. 61:5, 8) Ọ̀nà wo wá la máa gbà mú ìlérí náà ṣẹ? Báwo la ṣe lè máa fi hàn lójoojúmọ́ pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá?
Kedere ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká rí àwọn ohun tí Jèhófà rétí pé ká máa ṣe gẹ́gẹ́ bí ojúṣe wa. (Diu. 10:12, 13) A to àwọn kan lára wọn sínú àpótí tó ní àkòrí náà “Àwọn Ojúṣe Tí Ọlọ́run Gbé Lé Wa Lọ́wọ́,” lójú ìwé 22. Ọlọ́run ló gbé àwọn ojúṣe yẹn lé wa lọ́wọ́, wọ́n sì ṣe pàtàkì gan-an ni. Àmọ́ báwo la ṣe lè mọ èyí tó yẹ ká kọ́kọ́ ṣe nínú wọn tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó yẹ ká bójú tó méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú wọn ní àkókò kan náà?
Iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wà ló yẹ kó gbapò àkọ́kọ́, ara rẹ̀ sì ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà, ìpàdé àti òde ẹ̀rí. (Mát. 6:33; Jòh. 4:34; 1 Pét. 2:9) Síbẹ̀, kò lè jẹ́ pé àwọn nǹkan tẹ̀mí nìkan la ó máa ṣe láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ilé ìwé àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ilé náà wà níbẹ̀ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀ náà, a ní láti sa gbogbo ipá wa láti rí i dájú pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, àtàwọn ìgbòkègbodò míì kò ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa, irú bíi lílọ sípàdé. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ṣètò bá a ṣe máa lo àkókò ìsinmi wa, a máa ń rí i dájú pé kò bọ́ sígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tàbí ìgbà àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè. A tún lè pa àwọn kan lára àwọn ojúṣe wa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo ìdílé lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìjọ tàbí ká lo àkókò oúnjẹ ọ̀sán láti wàásù fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí fáwọn ọmọléèwé wa. Ìgbà yòówù ká fẹ́ ṣèpinnu èyíkéyìí, yálà iṣẹ́ là ń wá tàbí ilé ẹ̀kọ́, tàbí a fẹ́ yan ọ̀rẹ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún wa nígbèésí ayé, ìyẹn ìjọsìn Jèhófà Bàbá wa onífẹ̀ẹ́, ló gbọ́dọ̀ máa darí ìpinnu wa.—Oníw. 12:13.
Máa Gba Tàwọn Ẹlòmíì Rò
Jèhófà fẹ́ ká máa gba tàwọn ẹlòmíì rò ká sì máa hùwà tó dáa sí wọn. Àmọ́, ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ni Sátánì ń gbé lárugẹ. Àwọn èèyàn tó kúnnú ayé rẹ̀ jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn,” “olùfẹ́ adùn” àtàwọn “tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara” lọ́kàn. (2 Tím. 3:1-5; Gál. 6:8) Ọ̀pọ̀ kì í ronú lórí ipa tí ìwà wọn máa ń ní lórí àwọn míì. Kò sì síbi tí a kì í ti í gbúròó “àwọn iṣẹ́ ti ara.”—Gál. 5:19-21.
Ẹ ò rí bí ìyẹn ṣe yàtọ̀ tó sí tàwọn tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń sún ṣiṣẹ́, àwọn tó jẹ́ pé nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn míì, àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, inú rere àti ìwà rere ni wọ́n fi ń ṣèwà hù! (Gál. 5:22) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé ka máa fi ọ̀ràn àwọn ẹlòmíì ṣáájú tara wa. Torí náà, ó yẹ ká máa ṣohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì, àmọ́ ká tún máa ṣọ́ra ká má lọ máa kojú bọ ọ̀ràn ọlọ́ràn. (1 Kọ́r. 10:24, 33; Fílí. 2:3, 4; 1 Pét. 4:15) À ń dìídì fi ìgbatẹnirò hàn fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Síbẹ̀, a tún máa ń ran àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Ǹjẹ́ o lè wá àǹfààní láti ṣoore fẹ́nì kan tó o bá bá pàdé lónìí?—Wo àpótí náà, “Máa Fi Ìgbatẹnirò Bá Wọn Lò,” lójú ìwé 23.
Kò yẹ kó jẹ́ àkókò pàtàkì kan tàbí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Gál. 6:2; Éfé. 5:2; 1 Tẹs. 4:9, 10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ojoojúmọ́ là ń gbìyànjú láti mọ ohun tó ń da àwọn ẹlòmíì láàmú, tá a sì ń tètè ràn wọ́n lọ́wọ́, kódà tí kò bá rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. A máa ń fẹ́ láti fi ohunkóhun tó bá wà níkàáwọ́ wa ṣe àwọn èèyàn lóore, ì báà ṣe àkókò, ohun ìní, ìrírí àti ọgbọ́n wa. Jèhófà mú kó dá wa lójú pé tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́, òun náà máa lawọ́ sí wa.—Òwe 11:25; Lúùkù 6:38.
kan pàtó la ó máa gba tàwọn ẹlòmíì rò. (Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀ “Tọ̀sán-Tòru”
Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà “tọ̀sán-tòru”? Bẹ́ẹ̀ ni, bá a ṣe lè ṣe é ni pé ká máa fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa, ká sì máa ṣe é déédéé. (Ìṣe 20:31) A lè máa fi gbogbo ìgbésí ayé wa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé àti ṣíṣe àṣàrò lórí rẹ̀, gbígbàdúrà láìdabọ̀, lílọ sí gbogbo ìpàdé àti lílo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti wàásù.—Sm. 1:2; Lúùkù 2:37; Iṣe 4:20; 1 Tẹs. 3:10; 5:17.
Ǹjẹ́ àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń ṣe irú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò máa hàn ní gbogbo ọ̀nà nínú ìgbésí ayé wa pé ìfẹ́ ọkàn wa ni láti máa ṣohun tó wu Jèhófà ká sì máa fi hàn pé èké làwọn ẹ̀sùn Sátánì. A ó máa sapá láti máa fògo fún Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe ní ipòkípò tá a bá bára wa. A ó máa jẹ́ káwọn ìlànà rẹ̀ darí ọ̀rọ̀ àti ìwà wa, kó sì máa tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. A ó máa fi hàn pé a mọrírì bó ṣe ń fìfẹ́ tọ́jú wa àti bó ṣe ń dúró tì wá nípa gbígbẹ́kẹ̀lé e pátápátá àti nípa lílo gbogbo okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. A ó tún máa gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí rẹ̀ nígbà tó bá ṣẹlẹ̀ pé torí àìpé wa, a ṣe ohun tí kò bá ìlànà rẹ̀ mu.—Sm. 32:5; 119:97; Òwe 3:25, 26; Kól. 3:17; Héb. 6:11, 12.
Torí náà, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé wa ojoojúmọ́ máa fi ògo fún Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí ìtura fún ọkàn wa, títí láé sì ni Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò máa fì ìfẹ́ tọ́jú wa nìṣó.—Mát. 11:29; Ìṣí. 7:16, 17.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn Ojúṣe Tí Ọlọ́run Gbé Lé Wa Lọ́wọ́
• Máa gbàdúrà lemọ́lemọ́.—Róòmù 12:12.
• Máa ka Bíbélì kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kó o sì máa fi ohun tó ò ń kà sílò.—Sm. 1:2; 1 Tím. 4:15.
• Máa sin Jèhófà nínú ìjọ.—Sm. 35:18; Héb. 10:24, 25.
• Máa pèsè ohun tí ìdílé rẹ nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, kó o sì máa ṣe ohun táá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.—1 Tím. 5:8.
• Máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kó o sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 24:14; 28:19, 20.
• Máa tọ́jú ara rẹ dáadáa, máa bójú tó ipò tẹ̀mí rẹ, kó o sì máa fi ara rẹ lọ́kàn balẹ̀ nípa ṣíṣètò fún eré ìtura tó gbámúṣé.—Máàkù 6:31; 2 Kọ́r. 7:1; 1 Tím. 4:8, 16.
• Máa bójú tó ojúṣe rẹ nínú ìjọ.—Ìṣe 20:28; 1 Tím. 3:1.
• Máa rí i pé ilé rẹ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tẹ̀ ẹ́ ń lò dùn-ún wò.—1 Kọ́r. 10:32.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Máa Fi Ìgbatẹnirò Bá Wọn Lò
• Arákùnrin tàbí arábìnrin tó jẹ́ àgbàlagbà.—Léf. 19:32.
• Ẹnì kan tó ní àìlera tàbí tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.—Òwe 14:21.
• Ará ìjọ yín kan tó nílò nǹkan lójú méjèèjì tó o sì lágbára láti ṣe é fún un.—Róòmù 12:13.
• Ẹnì kan tó jẹ́ ara ìdílé rẹ. —1 Tím. 5:4, 8.
• Kristẹni kan tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ ti kú.—1 Tím. 5:9.
• Alàgbà kan tó ń múra sí iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ yín.—1 Tẹs. 5:12, 13; 1 Tím. 5:17.