Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ̀mí Àti Ìyàwó Ń Bá A Nìṣó Ní Sísọ Pé: ‘Máa Bọ̀!’”

“Ẹ̀mí Àti Ìyàwó Ń Bá A Nìṣó Ní Sísọ Pé: ‘Máa Bọ̀!’”

“Ẹ̀mí Àti Ìyàwó Ń Bá A Nìṣó Ní Sísọ Pé: ‘Máa Bọ̀!’”

“Ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ . . . Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—ÌṢÍ. 22:17.

1, 2. Ipò wo ló yẹ kí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run wà ní ìgbésí ayé wa, kì nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

 IPÒ wo ló yẹ kí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run wà nígbèésí ayé wa? Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́,’ ó sì mú kó dá wọn lójú pé bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa fún wọn ni àwọn ohun tí wọ́n bá nílò. (Mát. 6:25-33) Ó fi Ìjọba Ọlọ́run wé, péálì àtàtà, tó jẹ́ pé nígbà tí olówò arìnrìn-àjò kan rí i, ńṣe ló “ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́, ó sì rà á.” (Mát. 13:45, 46) Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà fọwọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

2 Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ méjì tó ṣáájú, bá a ṣe ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa. Ẹ̀mí Ọlọ́run tún ń kó ipa pàtàkì nínú bá a ṣe ń ṣe déédéé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Jẹ́ ká wo bó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Gbogbo Èèyàn Ni Ìkésíni Náà Wà Fún!

3. Irú omi wo la ké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n “máa bọ̀” wá mu?

3 Gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run pè nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ka Ìṣípayá 22:17.) Ìkésíni náà ni pé kí gbogbo èèyàn “máa bọ̀” láti wá pòùngbẹ nípasẹ̀ omi àrà ọ̀tọ̀ kan. Omi yìí kì í ṣe omi lásán o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé omi ṣe pàtàkì láti gbé ẹ̀mí wa ró, irú omi míì ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ fún obìnrin ará Samáríà tó bá pàdé létí kànga pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ láé, ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” (Jòh. 4:14) Ìyè àìnípẹ̀kun ni omi àrà ọ̀tọ̀ tá a ké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá mu yìí ń fúnni.

4. Báwo làwa èèyàn ṣe dẹni tó nílò omi ìyè, kí sì ni omi náà dúró fún?

4 Ìgbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, dara pọ̀ mọ́ Éfà aya rẹ̀ láti ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn Jèhófà Ọlọ́run, làwa èèyàn dẹni tó nílò irú omi àrà ọ̀tọ̀ yìí. (Jẹ́n. 2:16, 17; 3:1-6) Ọlọ́run lé tọkọtaya àkọ́kọ́ kúrò nínú ọgbà tó fi ṣe ilé wọn, “kí [Ádámù] má bàa na ọwọ́ rẹ̀ jáde, kí ó sì tún mú èso ní ti tòótọ́, láti ara igi ìyè, kí ó sì jẹ kí ó sì wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Jẹ́n. 3:22) Bó ṣe di pé Ádámù, tó jẹ́ baba gbogbo aráyé, mú ikú wọ inú ọ̀rọ̀ ìran èèyàn nìyẹn o. (Róòmù 5:12) Ohun tí omi ìyè dúró fún ni gbogbo ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe láti ra aráyé onígbọràn pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kó sì fún wọn ní ìwàláàyè pípé tí kò lópin nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ lára ìpèsè náà ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.—Mát. 20:28; Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:9, 10.

5. Ọ̀dọ̀ ta ni ìkésíni láti wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́” ti wá? Ṣàlàyé.

5 Ta ló ké sí wa pé ká wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”? Nígbà tí gbogbo ìpèsè fún ìwàláàyè bá dèyí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípasẹ̀ Jésù, nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, Bíbélì sọ pé ṣe ló máa dà bí “odò omi ìyè . . . tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì.” A rí i tí odò náà ń “ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣí. 22:1) Torí náà, Jèhófà Olùfúnni-ní-ìyè ni Orísun omi tó ní àwọn ohun tó ń fúnni ní ìyè náà. (Sm. 36:9) Òun ni Ẹni tó pèsè omi náà nípasẹ̀ “Ọ̀dọ́ Àgùntàn” náà Jésù Kristi. (Jòh. 1:29) Odò ìṣàpẹẹrẹ yìí ni Jèhófà máa lò láti mú gbogbo aburú tí Ádámù ti fà bá aráyé nípasẹ̀ àìgbọràn rẹ̀ kúrò. Ó ṣe kedere pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹni tó ké sí gbogbo èèyàn pé kí wọ́n “máa bọ̀.”

6. Ìgbà wo ni “odò omi ìyè” bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn?

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà Ẹgbẹ̀rún ọdún Ìṣàkóso Kristi ni “odò omi ìyè” náà máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn ní kíkún, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti “ọjọ́ Olúwa” èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tá a gbé “Ọ̀dọ́ Àgùntàn” náà gorí ìtẹ́ lọ́run lọ́dún 1914. (Ìṣí. 1:10) Ìdí nìyẹn táwọn ìpèsè tó lè mú ká ní ìwàláàyè fi wà lárọ̀ọ́wọ́tó lẹ́yìn náà. Lára wọn ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí a pe àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní “omi.” (Éfé. 5:26) Gbogbo èèyàn ni ìkésíni láti “gba omi ìyè” nípasẹ̀ gbígbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti dídáhùn sí ìkésíni náà wà fún. Àmọ́, ta ló ń ké sí àwọn èèyàn gan-an lọ́jọ́ Olúwa?

Ìyàwó” Ń Sọ Pé, “Máa Bọ̀!”

7. Ní “ọjọ́ Olúwa,” àwọn wo ló kọ́kọ́ ké síni pé “máa bọ̀,” àwọn wo ni wọ́n sì ń ké sí?

7 Ọ̀dọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ́ ìyàwó, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ní ìkésíni náà ti kọ́kọ́ jáde pé, “máa bọ̀.” Àwọn wo ni wọ́n ń ké sí? Kì í ṣe ara wọn ni wọ́n ń ké sí pé, “Máa bọ̀!” Àwọn tó nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” ni wọ́n ń ké sí.—Ka Ìṣípayá 16:14, 16.

8. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé láti ọdún 1918 wá làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ń mú ìkésíni Jèhófà tọ àwọn èèyàn lọ?

8 Láti ọdún 1918 làwọn ẹni àmì òróró ọmọ ẹ̀yìn Kristi ti ń ké sí àwọn èèyàn. Lọ́dún yẹn, wọ́n sọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Lè Máà Kú Láé.” Àsọyé yìí fúnni ní ìrètí pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa jèrè ìyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì. Ọ̀kan lára àwọn àsọyé tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1922, rọ àwọn tó pé jọ pé kí wọ́n ‘fọn rere ọba náà àti ìjọba rẹ̀.’ Èyí mú kí àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ìyàwó mú ìkésíni náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i. Ilé Ìṣọ́ March 15, 1929 (Gẹ̀ẹ́sì), ní àpilẹ̀kọ kan tó sọ pé “Ìkésíni Olóore-Ọ̀fẹ́,” tá a gbé ka Ìṣípayá 22:17. Díẹ̀ lára àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Àwọn olóòótọ́ àṣẹ́kù lára ẹgbẹ́ ẹni àmì òróró dara pọ̀ pẹ̀lú [Ẹni Gíga Jù Lọ náà] nínú ìkésíni olóore-ọ̀fẹ́, wọ́n sì sọ pé, ‘Máa bọ̀.’ A gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere yìí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti òtítọ́. A gbọ́dọ̀ ṣe é nísinsìnyí.” Títí di báyìí, ẹgbẹ́ ìyàwó náà ṣì ń bá a lọ láti máa ké sí àwọn èèyàn.

“Kí Ẹnikẹ́ni Tí Ń Gbọ́ sì Wí Pé: ‘Máa Bọ̀!’”

9, 10. Báwo la ṣe ń ké sí àwọn tó ń gbọ́ ìkésíni náà pé káwọn náà máa sọ pé, “Máa bọ̀!”?

9 Àwọn tó wá gbọ́ ìkésíni náà pé “máa bọ̀” ńkọ́? A rọ àwọn náà láti máa ké sí àwọn míì pé, “Máa bọ̀!” Bí àpẹẹrẹ, Ilé Ìṣọ́ August 1, 1932, ojú ìwé 232 (Gẹ̀ẹ́sì), sọ pé: “Kí àwọn ẹni àmì òróró rọ gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti lọ́wọ́ nínú sísọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró Olúwa kí wọ́n tó lè kéde ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìtùnú ńlá gbáà ló jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti mọ̀ pé àwọn láǹfààní láti gbé omi ìyè lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n la Amágẹ́dọ́nì já, kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.”

10 Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ August 15, 1934 (Gẹ̀ẹ́sì), ń sọ̀rọ̀ nípa ojúṣe àwọn olùgbọ́ láti sọ pé, “Máa bọ̀!” ó sọ lójú ìwé 249 pé: “Àwọn ẹgbẹ́ Jónádábù gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ipasẹ̀ ẹgbẹ́ Jéhù tòde òní, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró, kí wọ́n sì máa kéde ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, kódà bí wọn ò tiẹ̀ jẹ́ ẹni àmì òróró Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Lọ́dún 1935, a túbọ̀ dá “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Ìṣípayá 7:9-17 mọ̀ kedere. Èyí sì ti mú kí iṣẹ́ mímú ìkésíni Ọlọ́run tọ àwọn èèyàn lọ máa tẹ̀ síwájú lọ́nà tó gadabú. Látìgbà yẹn wá, ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà, tí iye wọn sì ń pọ̀ sí i, ti tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, wọ́n sì ti lé ní mílíọ̀nù méje báyìí. Torí pé wọ́n mọrírì ohun tí wọ́n gbọ́, wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n ṣe ìrìbọmi, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìyàwó láti máa ké sí àwọn míì pé kí wọ́n ‘wá mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.’

“Ẹ̀mí” Sọ Pé, “Máa Bọ̀!”

11. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?

11 Nígbà tí Jésù ń wàásù nínú sínágọ́gù kan ní ìlú Násárétì, ó ṣí àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà, ó sì kà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀, láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” Lẹ́yìn náà Jésù wá mú ọ̀rọ̀ náà bá ara rẹ̀ mu, ó sọ pé: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.” (Lúùkù 4:17-21) Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ní ọ̀rúndún kìíní, ẹ̀mí mímọ́ kó ipa tó gbàfiyèsí nínú iṣẹ́ ìwàásù náà.

12. Ipa wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń kó nínú kíké sí àwọn èèyàn lóde òní?

12 Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń kó nínú kíké sí àwọn èèyàn lóde òní? Jèhófà ló ni ẹ̀mí mímọ́. Ó máa ń lò ó láti ṣí ọkàn àti èrò inú ẹgbẹ́ ìyàwó náà payá láti lóye Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ ń sún wọn láti máa ké sí àwọn tó nírètí ìwàláàyè títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé, wọ́n sì tún ń ṣàlàyé àwọn òtítọ́ Bíbélì fún wọn. Àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, tí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, tí wọ́n sì tún ń ké sí àwọn míì ńkọ́? Ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn náà. Torí pé a ti batisí wọn ní ‘orúkọ ẹ̀mí mímọ́,’ wọ́n ń jẹ́ kó darí àwọn, wọ́n sì fọkàn tán an. (Mát. 28:19) Tún ronú nípa ohun tí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń pọ̀ sí i ń wàásù rẹ̀. Inú Bíbélì tí wọ́n kọ lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run ló ti wá. Nípa bẹ́ẹ̀, ipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ni ìkésíni náà ti ń wá. Ká sòótọ́, ẹ̀mí yìí ló ń darí wa. Ipa wo ló yẹ kí ìyẹn ní lórí bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìkésíni náà?

Wọ́n Ń “Bá A Nìṣó ní Sísọ Pé: ‘Máa Bọ̀!’”

13. Kí ni gbólóhùn náà “ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’” túmọ̀ sí?

13 “Ẹ̀mí àti ìyàwó” ò kàn wulẹ̀ sọ pé, “Máa bọ̀!” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí kéèyàn máa ṣe nǹkan nìṣó láìjáwọ́. Èyí ló mú kí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kà pé: “Ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’” Èyí fi hàn pé à ń bá a nìṣó láti máa mú ìkésíni Ọlọ́run tọ àwọn èèyàn lọ láìjáwọ́. Àwọn tó wá gbọ́ ìkésíni náà tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á ńkọ́? Àwọn náà ń sọ pé, “Máa bọ̀!” Bíbélì sọ nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá olùjọsìn Jèhófà pé “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìṣí. 7:9, 15) Ọ̀nà wo ni wọ́n ń gbà ṣe “iṣẹ́ ìsìn tọ̀sán-tòru”? (Ka Lúùkù 2:36, 37; Ìṣe 20:31; 2 Tẹsalóníkà 3:8.) Àpẹẹrẹ Ánà arúgbó, tó jẹ́ wòlíì obìnrin àti àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé “iṣẹ́ ìsìn tọ̀sán-tòru” túmọ̀ sí kéèyàn máa fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìtara.

14, 15. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ṣe déédéé nínú ìjọsìn wa?

14 Wòlíì Dáníẹ́lì náà jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ṣe déédéé nínú ìjọsìn wa. (Ka Dáníẹ́lì 6:4-10, 16.) Kò yí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ń ṣe nígbà gbogbo pa dà kódà fún oṣù kan, ìyẹn gbígbàdúrà sí Ọlọ́run ní “ìgbà mẹ́ta lójúmọ́, . . . gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé,” bó tílẹ̀ jẹ́ pé ó lè yọrí sí pé kí wọ́n jù ú sínú ihò kìnnìún. Ohun tí Dáníẹ́lì ṣe yìí jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn èèyàn tó ń wò ó pé kò sí ohun tó ṣe pàtàkì ju kéèyàn máa ṣe ìjọsìn Jèhófà déédéé.—Mát. 5:16.

15 Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ti lo òru ọjọ́ kan nínú ihò kìnnìún, ọba fúnra rẹ̀ lọ síbẹ̀ ó sì kígbe pé: “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀ ha lè gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún bí?” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Dáníẹ́lì dáhùn pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà, wọn kò sì run mí, níwọ̀n bí a ti rí mi ní ọlọ́wọ́ mímọ́ níwájú rẹ̀; àti níwájú rẹ pẹ̀lú, ọba, èmi kò gbé ìgbésẹ̀ aṣenilọ́ṣẹ́ kankan.” Jèhófà bù kún Dáníẹ́lì torí pé ó ń sìn ín “láìyẹsẹ̀.”—Dán. 6:19-22.

16. Ìbéèrè wo ni àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì yẹ kó sún wa láti béèrè lọ́wọ́ ara wa nípa bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?

16 Dáníẹ́lì múra tán láti kú dípò kó pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ń ṣe nígbà gbogbo tì. Àwa ńkọ́? Àwọn nǹkan wo là ń yááfì tàbí tá a múra tán láti yááfì ká bàa lè máa polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìyẹsẹ̀? Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kí oṣù kan kọjá lọ láìsọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn ẹlòmíì, ǹjẹ́ kò tún yẹ ká máa sapá láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tó bá ṣeé ṣe? Kódà tí àìlera ò bá jẹ́ ká lè ṣe púpọ̀, àmọ́ tá a wàásù fún nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lóṣù kan, ó yẹ ká ròyìn rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé a fẹ́ láti dara pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti ìyàwó láti máa bá a nìṣó ní sísọ pé, “Máa bọ̀!” Dájúdájú, a fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣe déédéé.

17. Àwọn àǹfààní wo láti mú ìkésíni Jèhófà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ni kò yẹ ká pàdánù?

17 A gbọ́dọ̀ máa mú ìkésíni Jèhófà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ, kó má ṣe jẹ́ ìgbà tá a ti yà sọ́tọ̀ láti jáde òde ẹ̀rí nìkan. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti ké sí àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ láti ‘wá mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́’ láwọn àkókò míì, irú bí ìgbà tá a bá lọ rajà, tá a bá ń rìnrìn àjò, nígbà ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ tàbí tá a ba ń lọ síléèwé. Kódà táwọn aláṣẹ bá fòfin de iṣẹ́ wa, a ó máa bá a lọ ní fífi ọgbọ́n wàásù. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a lè ṣe ilé kan lọ́wọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ká tún lọ sọ́wọ́ ìparí ká tún ṣe òmíràn títí tá a fi máa parí ìpínlẹ̀ yẹn tàbí ká tẹra mọ́ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà.

Máa Bá A Nìṣó ní Sísọ Pé, “Máa Bọ̀!”

18, 19. Báwo lo ṣe ń fi hàn pé o mọyì jíjẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?

18 Ó ti lé ní àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí tí ẹ̀mí àti ìyàwó ti ń sọ fún ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ omi ìyè ń gbẹ pé: “Máa bọ̀!” Ṣó o ti gbọ́ ìkésíni wọn tó ń múni láyọ̀ yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ọ́ pé kíwọ náà ké sí àwọn míì.

19 A ò mọ bó ṣe máa pẹ́ tó tí a ó fi máa mú ìkésíni onífẹ̀ẹ́ yìí tọ àwọn èèyàn lọ, àmọ́ táwa náà bá ń bá a nìṣó ní sísọ pé, “Máa bọ̀!” ìyẹn ń fi hàn pé alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá. (1 Kọ́r. 3:6, 9) Àǹfààní ńlá mà lèyí jẹ́ o! Ǹjẹ́ ká máa fi hàn pé a mọyì àǹfààní yìí, ká sì “máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo” nípa wíwàásù déédéé. (Héb. 13:15) Kí àwa tá a nírètí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé àti ẹgbẹ́ ìyàwó jọ máa bá a nìṣó ní sísọ pé, “Máa bọ̀!” Ǹjẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn sì wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́”!

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Àwọn wo la ké sí pé kí wọ́n “máa bọ̀”?

• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìkésíni náà láti “máa bọ̀” ti wá?

• Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú kíké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n “máa bọ̀”?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe déédéé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Máa Bá A Nìṣó ní Sísọ Pé, “Máa Bọ̀!”

1914

5,100 akéde

1918

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa jèrè ìyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé

1922

“Ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀”

1929

Àwọn olóòótọ́ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró sọ pé, “Máa bọ̀!”

1932

Àwọn ẹni àmì òróró nìkan kọ́ là ń ké sí pé, “Máa bọ̀!”

1934

A ké sí àwọn ẹgbẹ́ Jónádábù láti wàásù

1935

A dá “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà mọ̀

2009

7,313,173 akéde