“Ẹ̀tọ́ Àwọn Ọmọdé Láti Mọ Ọlọ́run”
“Ẹ̀tọ́ Àwọn Ọmọdé Láti Mọ Ọlọ́run”
NÍ December 9, 2008, àjọ kan tó ń rí sí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé lórílẹ̀-èdè Sweden, ìyẹn Swedish Academy for the Rights of the Child, ṣe àkànṣe àpérò tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ̀tọ́ Àwọn Ọmọdé Láti Mọ Ọlọ́run.” Onírúurú èrò làwọn aṣojú Ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Sweden, àwọn míì tó jẹ́ oníṣọ́ọ̀ṣì, àwọn Mùsùlùmí àtàwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó sọ̀rọ̀ níbi àpérò náà gbé kalẹ̀.
Lára àwọn tó sọ̀rọ̀ níbẹ̀ ni àlùfáà kan tó sọ pé: “Bá a bá ní ká sọ̀rọ̀ nípa báwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn ọmọdé láti mọ Ọlọ́run, agbára káká la fi lè ṣàlàyé náà dójú àmì.” Báwo làwọn ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ṣe lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run?
Àlùfáà náà sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì àtàwọn ìtàn inú rẹ̀ jẹ́ ohun táwọn ọmọdé lè ronú lé lórí kí wọ́n sì ṣàṣàrò nípa rẹ̀.” Ó mẹ́nu kan “ìtàn Ádámù àti Éfà, Kéènì àti Ébẹ́lì, Dáfídì àti Gòláyátì, ìbí Jésù, Sákéù agbowó orí, àkàwé ọmọ onínàákúnàá àti ìtàn aláàánú ará Samáríà.” Ó sì fi hàn pé wọ́n jẹ́ “díẹ̀ lára àwọn ìtàn inú Bíbélì tó lè jẹ́ kí [ọmọdé kan] mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe lórí àwọn ọ̀ràn tó gbẹgẹ́ nígbèésí ayé, irú bí àdàkàdekè, ìdáríjì, ètùtù, ìkórìíra, ìwà ìbàjẹ́, ìlàjà, ìfẹ́ ará àti ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan.” Ó fi kún un pé: “Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí jẹ́ ká rí àwọn àpẹẹrẹ téèyàn lè tẹ̀ lé, tá máa darí ìgbésí ayé èèyàn, táá sì jẹ́ ohun àwòkọ́ṣe.”
Ohun kan ni pé ó dáa kéèyàn fún àwọn ọmọdé níṣìírí láti máa ka Bíbélì. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni pé ó ṣeé ṣe fáwọn ọmọdé láti máa ‘ronú kí wọ́n sì máa ṣàṣàrò’ lórí ohun tí wọ́n ń kà nínú Ìwé Mímọ́ kí wọ́n sì ní èrò tó yẹ?
Àwọn àgbà pàápàá nílò àlàyé lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa nípa ọkùnrin kan tí ‘ríronú àti ṣíṣe àṣàrò’ lórí Ìwé Mímọ́ kò tó fún un láti mọ Ọlọ́run. Ìjòyè ará Etiópíà ni ọkùnrin náà. Ó ń ka ìwé wòlíì Aísáyà àmọ́ ohun tó ń kà kò yé e. Níwọ̀n bó ti fẹ́ lóye ohun tí wòlíì náà ń sọ, ó gbà kí ọmọ ẹ̀yìn náà, Fílípì, ṣàlàyé rẹ̀ fún òun. (Ìṣe 8:26-40) Irú èèyàn bíi ti ará Etiópíà yẹn pọ̀ gan-an ni. Gbogbo wa, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdé, la nílò àlàyé lórí Ìwé Mímọ́.
Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” (Òwe 22:15) Àwọn ọmọdé nílò ìdarí àti ìtọ́sọ́nà, ojúṣe àwọn òbí wọn sì ni láti fi Bíbélì àtàwọn ohun tí wọ́n ń gbọ́ láwọn ìpàdé ìjọ kọ́ wọn ní irú ìwà tó yẹ kí wọ́n máa hù àti bí wọ́n ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ni láti gba irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Láti kékeré ló ti yẹ kẹ́ ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run kí wọ́n lè di “àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú . . . tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Héb. 5:14.