Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló lè mú kí ẹnì kan sọ pé òun fẹ́ tún ìrìbọmi ṣe?
Àwọn ohun kan wà tó lè mú kí ẹni tó ti ṣèrìbọmi ronú pé ìrìbọmi òun kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, òun sì fẹ́ tún un ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣèrìbọmi, ó ti lè máa gbé ní ipò kan tàbí kó máa dá àwọn àṣà kan tó jẹ́ pé bí wọ́n bá ká irú ẹ̀ mọ́ ẹni tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́. Ṣé ẹni tó bá ń gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run? Àyàfi bí onítọ̀hún bá ti jáwọ́ nínú irú ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ ló tó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Torí náà, kò burú bí ẹni tó ṣèrìbọmi nígbà tó ṣì ń hu irú ìwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀ bá ronú pé òun fẹ́ tún ìrìbọmi òun ṣe.
Bó bá wá jẹ́ pé nígbà tí ẹnì kan ṣèrìbọmi, kò tíì sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà ńkọ́, àmọ́ tó jẹ́ pé ìwà àìtọ́ tó hù lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi gba pé kí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ bójú tó ọ̀rọ̀ rẹ̀? Bó bá sọ pé òye tí kò yé òun tó nígbà tóun ṣèrìbọmi ló fà á ńkọ́, tó sì sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ìrìbọmi náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bí àwọn alàgbà bá ń bójú tó ọ̀rọ̀ oníwà-àìtọ́ kan, kì í ṣe tiwọn láti máa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó rò pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tóun ṣe lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tàbí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ó ṣe tán, ó tẹ́tí sí àsọyé ìrìbọmi tó dá lórí Ìwé Mímọ́ tó sì ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ìrìbọmi. Ó dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, wọ́n sì rì í bọmi. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti gbà gbọ́ pé ó ní òye kíkún nípa bí ìrìbọmi tó ṣe ti ṣe pàtàkì tó. Àwọn alàgbà á sì bójú tó ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ṣèrìbọmi.
Bí onítọ̀hún bá ń bá àwọn alàgbà fà á pé ìrìbọmi òun kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n lè pe àfiyèsí rẹ̀ sí Ile-Iṣọ Na June 1, 1962, ojú ìwé 191 àti 192 àti February 15, 1964 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 123 sí 126, níbi tá a ti ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀rọ̀ títún ìrìbọmi ṣe. Títún ìrìbọmi ṣe lábẹ́ àwọn ipò kan (bíi kéèyàn sọ pé òye Bíbélì tóun ní kò kún tó nígbà tóun ṣèrìbọmi) jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni.
Àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn Kristẹni gbé yẹ̀ wò lórí ọ̀ràn gbígbé pa pọ̀?
Gbogbo èèyàn ló nílò ibùgbé. Àmọ́, lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò dá ilé tara wọn ní. Ipò ìṣúnná owó, ọ̀ràn ìlera, tàbí àwọn nǹkan míì sì lè mú kó pọn dandan fún àwọn ìdílé kan, tó fi mọ́ àwọn ìbátan àtàwọn ojúlùmọ̀ mélòó kan láti máa gbé pọ̀. Láwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ìbátan lè máa pín yàrá kan ṣoṣo lò.
Kì í ṣe ojúṣe ètò Jèhófà láti ṣe òfin gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ nípa irú ibi tó yẹ káwọn ará tó wà nínú ìjọ Ọlọ́run kárí ayé máa gbé. A gba àwọn Kristẹni níyànjú láti ronú lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè pinnu bóyá bí wọ́n ṣe ń gbé pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu tàbí kò bá a mu. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìlànà wọ̀nyí?
Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láti gbé yẹ̀ wò ni ipa tí gbígbé pẹ̀lú àwọn míì máa ní lórí wa 1 Kọ́r. 15:33.
àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Irú àwọn èèyàn wo là ń bá gbé gan-an? Ṣé olùjọ́sìn Jèhófà ni wọ́n? Ṣé wọ́n ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé Jèhófà kórìíra àgbèrè àti panṣágà. (Héb. 13:4) Torí náà, Ọlọ́run kò ní tẹ́wọ́ gba àjọgbé èyíkéyìí tó bá máa mú kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò gbéra wọn níyàwó máa sùn nínú yàrá kan náà bíi pé tọkọtaya ni wọ́n. Kò yẹ kí Kristẹni máa gbé ní ibikíbi tí wọ́n bá ti gba ìṣekúṣe láyè.
Síwájú sí i, Bíbélì rọ gbogbo àwọn tó bá ń fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run pé kí wọ́n “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́r. 6:18) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn Kristẹni yẹra fún àjọgbé èyíkéyìí tó lè mú ká dẹ wọ́n wò láti ṣe ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn Kristẹni mélòó kan tí wọ́n jọ ń sùn nínú yàrá kan náà. Ṣé irú àjọgbé bẹ́ẹ̀ lè mú kí wọ́n ṣe ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu? Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ṣàdédé ku ọkùnrin àti obìnrin kan tí wọn kì í ṣe tọkọtaya sínú ilé, torí pé àwọn míì tó yẹ kó wà níbẹ̀ kò sí nílé ńkọ́? Bákan náà, ó léwu fún ọkùnrin àti obìnrin kan tí ọkàn wọn ti ń fà síra tẹ́lẹ̀ láti máa gbé nínú ilé kan náà. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kírú àjọgbé bí èyí má tilẹ̀ wáyé rárá.
Kò tún ní bójú mu fún àwọn tó ti kọra wọn sílẹ̀ láti jọ máa gbé nìṣó nínú ilé kan náà. Torí pé wọ́n ti jọ wà pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya rí, ó lè rọrùn fún wọn láti bára wọn ṣèṣekúṣe.—Òwe 22:3.
Kókó pàtàkì mìíràn tá a máa gbé yẹ̀ wò kẹ́yìn ni ojú tí àwọn ará àdúgbò fi ń wo irú àjọgbé bẹ́ẹ̀. Bí Kristẹni kan kò bá tiẹ̀ rí ohun tó burú nínú irú àjọgbé kan, bí àwọn ará àdúgbò bá ń sọ̀rọ̀ irú àjọgbé bẹ́ẹ̀ láìdáa, ó yẹ kírú Kristẹni bẹ́ẹ̀ wá nǹkan ṣe sí i. A kò ní fẹ́ kí ìwà wa tàbùkù sí orúkọ Jèhófà. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ rèé: “Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì pẹ̀lú àti fún ìjọ Ọlọ́run, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wu gbogbo ènìyàn nínú ohun gbogbo, láìmáa wá àǹfààní ti ara mi bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí a bàa lè gbà wọ́n là.”—1 Kọ́r. 10:32, 33.
Ó lè má rọrùn fáwọn tó fẹ́ máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà láti rí ilé tó dára tàbí láti rí sí i pé irú àjọgbé tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ò wáyé. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.” Ó pọn dandan kí wọ́n rí i dájú pé ohun àìtọ́ kankan ò ṣẹlẹ̀ nínú ilé àwọn. (Éfé. 5:5, 10) Èyí béèrè pé káwọn Kristẹni máa gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti yẹra fún àjọgbé tí kò yẹ àti ìwà tó ń dójú tini, kí wọ́n má sì tàbùkù sí orúkọ Jèhófà.