Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Táá Jẹ́ Káwọn Ọ̀dọ́ Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn

Ìwé Táá Jẹ́ Káwọn Ọ̀dọ́ Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn

Ìwé Táá Jẹ́ Káwọn Ọ̀dọ́ Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn

NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn, Sólómọ́nì ọkùnrin ọlọgbọ́n sọ pé: ‘Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nísinsìnyí ní ọjọ́ èwe rẹ.’ (Oníw. 12:1, Bibeli Mimọ) Ìwé míì ti wà báyìí tó máa ran àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Sólómọ́nì sọ. Ìyẹn ni ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, èyí tá a mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kárí ayé láàárín May 2008 sí January 2009.

Lẹ́tà kan tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí kọ sáwọn ọ̀dọ́ wà nínú èèpo iwájú ìwé náà. Díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà náà kà pé: “Àdúrà wa ni pé kí ohun tó o máa kà nínú ìwé yìí ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa juwọ́ sílẹ̀ nítorí àwọn ìṣòro àti ìdẹwò táwọn ọ̀dọ́ òde òní ń dojú kọ, kó sì tún jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.”

Ó bọ́gbọ́n mu bí àwọn òbí ṣe ń fẹ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àmọ́, lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ bá ti bàlágà, wọn kì í dá ara wọn lójú mọ́, wọ́n sì máa ń wá ẹni tó máa tọ́ wọn sọ́nà. Bó o bá lọ́mọ tó ti bàlágà, báwo lo ṣe lè mú kó jàǹfààní gan-an látinú ìwé yìí? Àwọn àbá díẹ̀ rèé.

Gba ẹ̀dà kan ìwé yìí kó o sì kà á tinú tẹ̀yìn. Má fi mọ sórí kíkà nìkan ṣá o. Gbìyànjú láti lóye ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú ìwé náà. Dípò kí ìwé náà wulẹ̀ máa sọ fáwọn ọ̀dọ́ pé ṣe tibí má ṣe tọ̀hún, ńṣe ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ “agbára ìwòye wọn.” (Héb. 5:14) Ó tún pèsè àwọn àbá tó gbéṣẹ́ fún wọn nípa wọ́n ṣe lè dúró lórí ohun tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, Orí 15 (“Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Í Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Kó Ìwà Tí Ò Dáa Ràn Mí?”) jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ mọ̀ pé kò tó láti wulẹ̀ sọ pé àwọn ò ṣe ohun tí kò dára. Ó ṣàlàyé àwọn ọgbọ́n tó dá lórí Bíbélì tí wọ́n lè lò àti àwọn ìdáhùn tó gbéṣẹ́ tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè máa “fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kól. 4:6.

Lo àwọn ìbéèrè inú ìwé náà tó máa fún ìwọ àti ọmọ rẹ láǹfààní láti fọ̀rọ̀ wérọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ la ṣe apá yìí fún, ìwọ náà ò ṣe kọ ọ̀rọ̀ sí apá ibi tó bá ti yẹ kí òbí sọ èrò rẹ̀ nínú ìwé náà? a Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìbéèrè méjì wà lójú ìwé 16 tó gba kí òbí àti ọmọ sọ èrò wọn. Bó o bá ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbéèrè méjì tó dá lórí kéèyàn ní ẹni tó ń fẹ́ sọ́nà yìí, gbìyànjú láti rántí bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ nígbà tó o wà ní ọ̀dọ́. Bóyá wàá fẹ́ láti kọ ohun tí ì bá jẹ́ ìdáhùn rẹ nígbà yẹn sórí ìlà tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, o lè bi ara rẹ pé: ‘Látìgbà yẹn wá, báwo ni èrò mi lórí ọ̀ràn náà ṣe ń yí pa dà díẹ̀díẹ̀? Báwo lòye ṣe túbọ̀ yé mi sí i lórí ọ̀ràn náà látìgbà tí mo ti bàlágà, báwo ni mo sì ṣe lè sọ ọ́ fún ọmọ mi lọ́nà tó gbéṣẹ́?’

Bí ọmọ rẹ ò bá tíì fi ohun tó kọ hàn ẹ́, má ṣe wò ó. Àwọn apá tó wà fún ìfèròwérò nínú ìwé náà la ṣe lọ́nà tí wàá fi lè fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ọmọ rẹ, táá sì lè kọ ohun tó rò sílẹ̀ tàbí kó ronú lé e lórí. Àfojúsùn rẹ ni láti mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, kì í ṣe láti mọ ohun tó kọ sínú ìwé rẹ̀. Ní ojú ìwé 3, lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí,” ìwé náà rọ àwọn òbí pé: “Káwọn ọmọ ẹ bàa lè máa kọ ohun tó wà lọ́kàn wọn gan-an sínú ìwé yìí, ọwọ́ wọn ni kó o jẹ́ kí ìwé náà máa gbé. Bó bá yá, àwọn fúnra wọn lè wá fẹnu ara wọn sọ ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ fún ẹ.”

Ó Wúlò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé

Ìwé tó dáa gan-an tẹ́ ẹ lè lò nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín ni ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì. Níwọ̀n bí ìwé náà kò ti ní ìbéèrè tá a gbé karí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, báwo lẹ ṣe lè lò ó? Ẹ lè ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tẹ́ ẹ bá mọ̀ pé ó máa gbéṣẹ́ jù lọ fún àwọn ọmọ yín.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìdílé kan lè rí i pé ó rọ àwọn lọ́rùn láti máa ṣe ìfidánrawò nígbà táwọn bá ń jíròrò “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” ní ojú ìwé 132 àti 133. Ìbéèrè àkọ́kọ́ níbẹ̀ lè ran ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ obìnrin lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro fún un. Ìbéèrè kejì á jẹ́ kó mọ ibi tó ṣeé ṣe kó ti bá ìṣòro yìí pà dé. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó lè jẹ́ àbájáde gbígbà fún àwọn ojúgbà rẹ̀ tàbí kíkọ ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́, ìwé náà rọ ọmọ rẹ láti pinnu ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà, yálà kó gbà á mọ́ra, kó bomi paná rẹ̀, tàbí kó dà á sí wọn lára. Ran ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ obìnrin lọ́wọ́ láti mọ béèyàn ṣe ń ro àròjinlẹ̀ kó sì múra tán láti dá àwọn ojúgbà rẹ̀ lóhùn lọ́nà tó máa tẹ́ òun fúnra rẹ̀ lọ́rùn àti lọ́nà tó máa mú kó fìgboyà sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi hàn pé ohun tó ń sọ dá a lójú.—Sm. 119:46.

Ó Wúlò fún Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀

Ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti máa bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àpótí tó ní àkọlé náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Mọ́mì Tàbí Dádì Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀?” (ojú ìwé 63 sí 64) àti “Bá Àwọn Òbí Ẹ Sọ̀rọ̀!” (ojú ìwé 189) pèsè àwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn lórí àwọn kókó tó gbẹgẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan sọ pé: “Ìwé yìí ti jẹ́ kí n ní ìgboyà láti máa bá àwọn òbí mi sọ ohun tó wà lọ́kàn mi, títí kan àwọn ohun tí mo ti ṣe.”

Ìwé yìí tún ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wáyé láwọn ọ̀nà míì. Ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan, àpótí kan wà tá a pè ní “Kí Lèrò Ẹ?” Yàtọ̀ sí pé ó ṣeé lò fún àtúnyẹ̀wò, ẹ tún lè lò ó gẹ́gẹ́ bí ìlapa èrò fún ìjíròrò ìdílé. Àpótí míì tún wà ní apá ìparí orí kọ̀ọ̀kan, tá a pè ní “Ohun Tí Màá Ṣe!” Àpótí yìí fún àwọn ọ̀dọ́ láǹfààní láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà pàtó tí wọ́n lè gbà fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú orí náà sílò. Apá tó gbẹ̀yìn nínú àpótí “Ohun Tí Màá Ṣe!” yìí sọ pé: “Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni . . .” Èyí lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti máa wá ìmọ̀ràn tó jíire lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn.

Mọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wọn!

Gẹ́gẹ́ bí òbí àfojúsùn rẹ ni láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ. Ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká wo bí ìwé yìí ṣe ran bàbá kan lọ́wọ́ débi tóun àti ọmọbìnrin rẹ̀ fi ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó jíire.

“Ibì kan tó dáa wà tí èmi àti Rebekah máa ń ṣeré lọ, a lè rìn lọ síbẹ̀, a lè gun kẹ̀kẹ́ tàbí ká gbé mọ́tò lọ. Mo kíyè sí i pé ibi tá a máa ń ṣeré lọ yìí máa ń mú kó ṣeé ṣe fún un láti sọ tinú rẹ̀ jáde.

“Apá tá a kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò nínú ìwé yìí ni lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti ‘Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí.’ Gẹ́gẹ́ bí orí 3 nínú ìwé náà ṣe sọ, mo fẹ́ kí ọmọbìnrin mi mọ̀ pé ó lómìnira láti kọ èrò rẹ̀ sínú ìwé náà. Mi ò sì ní wo ohun tó bá kọ síbẹ̀.

“Mo jẹ́ kí Rebekah yan àwọn àkòrí tó máa fẹ́ ká jíròrò nínú ìwé náà, kó sì tò wọ́n lọ́nà tó máa fẹ́ ká gbà jíròrò wọn. Ọ̀kan lára àwọn àkòrí tó kọ́kọ́ yàn ni ‘Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?’ Ọkàn mi ò tiẹ̀ lọ síbẹ̀ rárá pé ìyẹn ló máa kọ́kọ́ mú! Àmọ́, ó ní ìdí tó fi yan àkòrí yẹn. Mélòó kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà tó jẹ́ ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀. Mi ò mọ bí ìwà ipá tó wà níbẹ̀ àti ọ̀rọ̀ rírùn tí wọ́n sọ nínú rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Àmọ́ gbogbo rẹ̀ ló jẹ yọ nígbà tá à ń jíròrò àpótí náà, “Ohun Tí Màá Ṣe!” tó wà lójú ìwé 251. Àpótí yẹn ran Rebekah lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó máa sọ bí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti mú kó ṣeré orí kọ̀ǹpútà.

“Tá a bá ti bá ìjíròrò wa débi àpótí yìí, Rebekah máa ń sọ ohun tó kọ sínú ìwé rẹ̀ fún mi. A máa ń sọ̀rọ̀ fàlàlà nígbà tá a bá ń ka ìwé náà. Èmi àti ẹ̀ jọ máa ń kàwé, ó sì máa ń fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó rí, tó fi mọ́ àwọn àwòrán àti àpótí tó wà níbẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ kí n lè sọ bí nǹkan ṣe rí fún mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé bíi tiẹ̀ fún un, òun náà á sì wá sọ bí nǹkan ṣe rí lóde òní fún mi. Ó máa ń fẹ́ sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀!”

Bó o bá jẹ́ òbí, kò sí iyè méjì pé o láyọ̀ gan-an nígbà tí wọ́n mú ìwé náà jáde. Àǹfààní ti wá ṣí sílẹ̀ fún ẹ báyìí láti lò ó lọ́nà rere. Ìgbìmọ̀ Olùdarí nírètí pé ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, máa wúlò fún ìdílé rẹ gan-an. Ǹjẹ́ kí ìwé yìí ran olúkúlùkù lọ́wọ́, pàápàá àwọn ọ̀dọ́ wa ọ̀wọ́n, láti ‘máa rìn nípa ẹ̀mí mímọ́.’—Gál. 5:16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn kan lára àwọn àpótí àṣàrò tó wà nínú ìwé náà wúlò fún tàgbà tèwe. Bí àpẹẹrẹ, àpótí náà, “Fọwọ́ Wọ́nú” (ojú ìwé 221) máa ran ìwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni apá tá a pè ní “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” (ojú ìwé 132 sí 133), “Ètò Ìnáwó Mi Lóṣooṣù” (ojú ìwé 163), àti “Àwọn Àfojúsùn Mi” (ojú ìwé 314).

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

Ohun Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Kan Ń Sọ

“Ìwé tó yẹ kéèyàn jókòó tì pẹ̀lú pẹ́ńsù lọ́wọ́ kó sì máa ṣàṣàrò lé lórí bó ṣe ń kà á ni ìwé yìí. Bí wọ́n ṣe ṣe é bí ìwé téèyàn lè máa kọ ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ sí mú kó rọrùn láti máa ronú lórí àwọn ohun tó wà níbẹ̀ kéèyàn bàa lè máa gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ.”—Nicola.

“Àwọn èèyàn, tó fi mọ́ àwọn tó ń fẹ́ mi fẹ́re, máa ń yọ mí lẹ́nu pé ó ti yẹ kí n lẹ́ni tí mò ń fẹ́. Apá àkọ́kọ́ nínú ìwé yìí, mú kó dá mi lójú pé ohun yòówù kí ẹnì kan sọ, mi ò tíì ṣe tán láti lẹ́ni tí mò ń fẹ́.”—Katrina.

“Àpótí náà, ‘Ṣó O Ti Ń Ronú Láti Ṣèrìbọmi?’ ti jẹ́ kí n túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìrìbọmi mi. Ó mú kí n ṣàgbéyẹ̀wò ọwọ́ tí mo fi mú ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àdúrà.”—Ashley.

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti kékeré làwọn òbí mi tó jẹ́ Kristẹni ti ń kọ́ mi, ìwé yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa dá ronú nípa ọ̀nà tí màá gbà lo ìgbésí ayé mi. Ó tún ti ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa sọ tinú mi fáwọn òbí mi.”—Zamira.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ẹ̀yin òbí, ẹ ka ìwé náà tinú tẹ̀yìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Fi ṣe àfojúsùn rẹ láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ