Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Dènà Ìpolongo Èké Sátánì

Máa Dènà Ìpolongo Èké Sátánì

Máa Dènà Ìpolongo Èké Sátánì

‘Ẹ MÁ ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ọlọ́run yín kò lè gbà yín. Ẹ jẹ́ túúbá, kẹ́ ẹ má bàa jìyà!’ Èyí ni díẹ̀ lára iṣẹ́ tí Rábúṣákè, tó jẹ́ aṣojú Senakéríbù Ọba Ásíríà, wá jẹ́ fáwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọmọ ogun tí ọba rán wá ti dó ti ilẹ̀ Júdà. Àwọn ọ̀rọ̀ aṣojú ọba yìí ni wọ́n fẹ́ lò láti kó àwọn ará Jerúsálẹ́mù láyà jẹ, kí ẹ̀rù lè bà wọ́n kí wọ́n sì túúbá.—2 Ọba 18:28-35.

Òǹrorò làwọn ọmọ ogun Ásíríà, wọ́n sì níkà. Wọ́n máa ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn ọ̀tá wọn nípa fífi ìròyìn ohun tí wọ́n ń fojú àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn rí mú wọn láyà pami. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Philip Taylor ṣe sọ: “Ó ti dàṣà wọn láti máa fi ìpolongo èké pá àwọn tí wọ́n bá kó nígbèkùn láyà kí wọ́n lè kápá wọn. Wọ́n tún máa ń lo àwòrán ara ògiri láti kó jìnnìjìnnì bá àwọn tó ṣeé ṣe kó fẹ́ bá wọn jagun. Àwọn àwòrán ara ògiri yìí ló ń ṣàfihàn bí wọ́n ṣe máa ń hùwà òǹrorò sáwọn tí wọ́n bá ṣẹ́gun. Ọṣẹ́ tí ìpolongo èké ń ṣe kò kéré rárá. Ọ̀gbẹ́ni Taylor tiẹ̀ sọ pé, ó máa “ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni.”

Àwọn Kristẹni tòótọ́ “ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí . . . àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú,” ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Éfé. 6:12) Sátánì Èṣù sì ni aṣáájú wọn. Bíi ti àwọn ọmọ ogun Ásíríà, òun náà máa ń lo ìpolongo èké tàbí èrò òdì láti múni láyà pami.

Sátánì sọ pé òun lè ba ìwà títọ́ olúkúlùkù wa jẹ́. Nígbà ayé Jóòbù olùṣòtítọ́, ó sọ fún Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” Lọ́nà míì, ohun tó ń sọ ni pé, tó bá pẹ́ tọ́wọ́ ìyà ti ń ba ẹnì kan, ó máa jáwọ́ nínú sísin Ọlọ́run. (Jóòbù 2:4) Àmọ́, ṣóòótọ́ ni Èṣù ń sọ? Tó bá dọ̀ràn pípa ìwà títọ́ mọ́, ṣé ó ní ibi tá a lè fara dà á dé ká tó gbàgbé ìlànà tá à ń tẹ̀ lé ká sì máa wá bá a ṣe lè dáàbò bo ẹ̀mí wa? Irú èrò tí Sátánì máa fẹ́ ká ní nìyẹn. Ìyẹn ló ń mú kó dọ́gbọ́n gbin èrò òdì sí wa lọ́kàn. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, ká sì wá wo bá a ṣe lè dènà rẹ̀.

“Àwọn tí Ìpìlẹ̀ Wọn Wà Nínú Ekuru”

Sátánì lo Élífásì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta tó wá bẹ̀ ẹ́ wò láti sọ pé ẹ̀mí àwa èèyàn ò gbé e láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àwa èèyàn ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Jóòbù pé: “Àwọn tí ń gbé ilé amọ̀, àwọn tí ìpìlẹ̀ wọn wà nínú ekuru! A ń tètè tẹ̀ wọ́n rẹ́ ju òólá. A ń fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ láti òwúrọ̀ di alẹ́; wọ́n ń ṣègbé títí láé láìsí ẹnikẹ́ni tí ó fi í sí ọkàn-àyà.”—Jóòbù 4:19, 20.

Níbòmíì nínú Ìwé Mímọ́, a fi àwa èèyàn wé “àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe,” ìyẹn àwọn ìkòkò amọ̀ tó jẹ́ ẹlẹgẹ́. (2 Kọ́r. 4:7) Ìdí tá ò fi lágbára sì ni pé a ti jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) A kò lè dá kojú Sátánì, bó bá gbéjà kò wá. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ní olùgbèjà. Bá a tilẹ̀ jẹ́ aláìlera, a ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. (Aísá. 43:4) Síwájú sí i, Jèhófà máa ń fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tá a bá béèrè fún un. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí rẹ̀ yìí lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” táá mú ká lè fara da ohun yòówù kí Sátánì máa fi pọ́n wa lójú. (2 Kọ́r. 4:7; Fílí. 4:13) Tá a bá mú ìdúró wa lòdì sí Èṣù, “ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́,” Ọlọ́run á mẹ́sẹ̀ wa dúró, á sì fún wa lókun. (1 Pét. 5:8-10) Torí náà, kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù Sátánì Èṣù.

“Ènìyàn Ń Mu Àìṣòdodo”

Élífásì béèrè pé: “Kí ni ẹni kíkú ti jẹ́ tí yóò fi mọ́, tàbí tí ẹnikẹ́ni tí obìnrin bí yóò fi jàre?” Lẹ́yìn náà, ó wá dáhùn pé: “Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ti gidi ní ojú rẹ̀. Áńbọ̀sìbọ́sí ìgbà tí ènìyàn jẹ́ ẹni ìṣe-họ́ọ̀-sí àti ẹni ìbàjẹ́, ènìyàn tí ń mu àìṣòdodo bí ẹni mu omi!” (Jóòbù 15:14-16) Ohun tí Élífásì ń sọ fún Jóòbù ni pé Jèhófà kò ka ẹnikẹ́ni sí olódodo. Èṣù náà máa ń gbin èrò òdì síni lọ́kàn. Ó máa ń fẹ́ ká máa ro àròkàn nípa àwọn àṣìṣe wa, ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá, ká sì máa rò pé kò sí àtúnṣe kankan fún wa mọ́. Ó tún máa ń fẹ́ ká rò pé a kò lè dójú ìlà ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa, ká sì máa rò pé kò ní àánú wa lójú, kò lè dárí jì wá àti pé kò ní tì wá lẹ́yìn.

Àmọ́ ṣá o, gbogbo èèyàn ló ti “ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀dá aláìpé kan tó lè dójú ìlà àwọn ohun tí ìlànà pípé Jèhófà ń béèrè. (Róòmù 3:23; 7:21-23) Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé a kò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Jèhófà mọ̀ pé “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì,” ló ń lo ipò àìpé wa láti mú ká ro ara wa pin. (Ìṣí. 12:9, 10) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti mọ̀ pé “ekuru ni wá,” kì í fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa bi wá, kì í sì í ‘wá àléébù wa nígbà gbogbo.’—Sm. 103:8, 9, 14.

Tá a bá kọ ìwà ibi sílẹ̀, tá a tọ Jèhófà wá pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ ọkàn àti ẹ̀mí ìrònúpìwàdà, ‘yóò dárí jì wá lọ́nà títóbi.’ (Aísá. 55:7; Sm. 51:17) Bíbélì tiẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa “tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.” (Aísá. 1:18) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi ṣe ìpinnu wa pé a kò ní juwọ́ sílẹ̀ láé bá a ti ń sapá láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

Ipò àìpé wa ò lè jẹ́ ká ní ìdúró òdodo níwájú Ọlọ́run. Ádámù àti Éfà pàdánù ìyè ayérayé àti ìwàláàyè pípé, wọ́n sì mú káwa náà pàdánù rẹ̀. (Róòmù 6:23) Àmọ́, nítorí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà ní sí ìran èèyàn, ó pèsè ọ̀nà tá a lè gbá rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ, Jésù Kristi. (Mát. 20:28; Jòh. 3:16) Ọ̀nà àgbàyanu mà ni Ọlọ́run gbà fi “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” rẹ̀ hàn sí wa yìí o! (Títù 2:11) Ọ̀rọ̀ wa ò kọjá àtúnṣe! Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣó wá yẹ ká gba Sátánì láyè láti mú ká máa rò pé ọ̀rọ̀ wa ti kọjá àtúnṣe?

“Na Ọwọ́ Rẹ, Kí O sì fi Kan Egungun Rẹ̀ àti Ẹran Ara Rẹ̀”

Sátánì sọ pé Jóòbù máa bọ́hùn bí òun bá fi àìsàn kọ lù ú. Ó wá pe Jèhófà níjà nípa sísọ pé: “Na ọwọ́ rẹ, kí o sì fi kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 2:5) Ó dájú pé inú Ọ̀tá Ọlọ́run yìí máa dùn tó bá mú ká gbà pé a kò já mọ́ nǹkan nítorí àwọn àìlera wa.

Àmọ́ Jèhófà kì í ta wá nù tá ò bá lè ṣe tó bá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ká sọ pé wọ́n gbéjà ko ọ̀rẹ́ wa kan tó sì fara pa. Ṣé a máa torí ìyẹn tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ bí kò bá lè ṣe tó bó ti ń ṣe fún wa tẹ́lẹ̀ mọ́? Ó dájú pé a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! A ṣì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ a ó sì máa tọ́jú rẹ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé torí tiwa ni wọ́n fi gbéjà kò ó. Ṣó yẹ ká retí pé Jèhófà máa ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn? Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Héb. 6:10.

Ìwé Mímọ́ sọ nípa “opó aláìní kan” tó ṣeé ṣe kó ti pẹ́ tó ti máa ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ṣàkíyèsí bó ṣe ń sọ “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” sínú àpótí ìṣúra tó wà nínú tẹ́ńpìlì, ṣó fojú tẹ́ńbẹ́lú opó náà àti ọrẹ táṣẹ́rẹ́ tó mú wá? Rárá o! Ńṣe ló gbóríyìn fún un nítorí pé ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti lè ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́.—Lúùkù 21:1-4.

Tá a bá pa ìwà títọ́ wa mọ́, ó yẹ kó dá wa lójú pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ò ní bà jẹ́, láìka ohun yòówù tí àìpé lè fà bá wa, títí kan ọjọ́ ogbó tàbí àìlera. Ọlọ́run ò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀ kìkì nítorí pé àwọn ohun tó ń bá wọn fínra ti mú kí ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ dín kù.—Sm. 71:9, 17, 18.

Gba Àṣíborí Ìgbàlà”

Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí èrò òdì tí Sátánì ń tàn kálẹ̀ nípa lórí wa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀. Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” Ọ̀kan lára àwọn ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí yẹn ni “àṣíborí ìgbàlà.” (Éfé. 6:10, 11, 17) Ká bàa lè yẹra fún èrò òdì tí Sátánì ń tàn kálẹ̀, a gbọ́dọ̀ rí i pé a gba àṣíborí yìí, a sì ń dé e. Bí àṣíborí sójà kan ṣe ń dáàbò bo orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni “ìrètí [wa] fún ìgbàlà” ìyẹn ìdánilójú tá a ní pé ìlérí Ọlọ́run nípa ayé tuntun ológo máa nímùúṣẹ, á ṣe máa dáàbò bo ọkàn-àyà wa ká má bàa gba èrò òdì Sátánì láyè. (1 Tẹs. 5:8) A gbọ́dọ̀ máa fún ìrètí wa lókun nípa fífi taratara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Jóòbù fara dà á nígbà tí Sátánì gbéjà kò ó lọ́nà rírorò. Àmọ́, ìgbàgbọ́ tí Jóòbù ní nínú àjíǹde lágbára débi pé kò bẹ̀rù ikú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:15) Kódà, bí Jóòbù bá tilẹ̀ kú torí pé ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó ní ìgbàgbọ́ pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ máa sún un láti jí wọn dìde.

Ǹjẹ́ káwa náà ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run tòótọ́. Jèhófà lè gbà wá lọ́wọ́ ohunkóhun tí Sátánì àtàwọn aṣojú rẹ̀ bá fẹ́ ṣe sí wa. Tún rántí pé Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́r. 10:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe tọkàntọkàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Gba àṣíborí ìgbàlà, kó o sì máa dé e