Máa Lo “Idà Ẹ̀mí” Lọ́nà Tó Jáfáfá
Máa Lo “Idà Ẹ̀mí” Lọ́nà Tó Jáfáfá
“Tẹ́wọ́ gba . . . idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—ÉFÉ. 6:17.
1, 2. Kí ló yẹ ká ṣe nípa àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó pọ̀ sí i tá a nílò?
BÍ JÉSÙ ti rí ohun tó ń jẹ àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ́kàn nípa tẹ̀mí, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” Jésù ò kàn fọ̀rọ̀ yẹn sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó ti sọ ọ̀rọ̀ yẹn tán, “ó fi ọlá àṣẹ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá” ó sì rán wọn jáde pé kí wọ́n lọ wàásù, ìyẹn ni pé kí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ “ìkórè.” (Mát. 9:35-38; 10:1, 5) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Jésù wá “yan àwọn àádọ́rin mìíràn sọ́tọ̀, ó sì rán wọn jáde ní méjìméjì,” láti lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù.—Lúùkù 10:1, 2.
2 Lóde òní, a ṣì nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2009, jẹ́ mílíọ̀nù méjìdínlógún, ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́sàn-án àti okòó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́ta [18,168,323]. Ìyẹn sì fi ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá ju iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lọ. Ẹ ò rí i pé pápá náà ti funfun fún ìkórè! (Jòh. 4:34, 35) Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rán àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ sí i jáde. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣiṣẹ́ lórí àdúrà tá à ń gbà? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká di òjíṣẹ́ tó túbọ̀ jáfáfá, bá a ti ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19, 20; Máàkù 13:10.
3. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń kó ipa pàtàkì nínú ríràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ tó jáfáfá?
3 Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí jíròrò bí jíjẹ́ ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí ṣe jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń mú ká lè máa “fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣe 4:31) Ẹ̀mí yìí tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ tó jáfáfá. Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i ni pé ká máa lo ohun èlò tó gbámúṣé tí Jèhófà Ọlọ́run pèsè fún wa, ìyẹn Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, lọ́nà rere. Ẹ̀mí mímọ́ ló darí àwọn tó kọ ọ́. (2 Tím. 3:16) Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì ní ìmísí Ọlọ́run. Torí náà, bá a bá ń ṣàlàyé àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ńṣe là ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí wa. Ká tó jíròrò bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣé lágbára tó.
‘Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára’
4. Ìyípadà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì lè mú kéèyàn ṣe?
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà kúkú lágbára o! (Héb. 4:12) Lọ́nà àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ tó ń wá látinú Bíbélì, mú ju idà èyíkéyìí téèyàn ṣe lọ, torí ó lágbára débi pé ó máa ń pín eegun àti mùdùnmúdùn inú rẹ̀ níyà. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ máa ń wọni lọ́kàn gan-an, ó máa ń fòye mọ ìrònú èèyàn, á sì fi irú ẹni téèyàn jẹ́ gan-an hàn. Òtítọ́ yìí lè lágbára lórí èèyàn débi táá fi yí onítọ̀hún pa dà. (Ka Kólósè 3:10.) Dájúdájú, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè yí ìgbésí ayé ẹni pa dà!
5. Ọ̀nà wo ni Bíbélì lè gbà darí wa, kí ló sì máa yọrí sí?
5 Síwájú sí i, Bíbélì jẹ́ ìwé tí ọgbọ́n inú rẹ̀ kò láfiwé. Ó láwọn ìsọfúnni tó lè jẹ́ kéèyàn mọ bó ṣe máa gbé ìgbé ayé rẹ̀ nínú ayé tí nǹkan ò ti rọrùn yìí. Kì í ṣe ìgbé ayé tá à ń gbé báyìí nìkan ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tànmọ́lẹ̀ sí, ó tún ń tànmọ́lẹ̀ sí ọjọ́ iwájú wa. (Sm. 119:105) Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro tàbí nígbà tá a bá ń ṣe ìpinnu tó jẹ mọ́ yíyan ọ̀rẹ́, eré ìnàjú, iṣẹ́, aṣọ àti àwọn nǹkan míì. (Sm. 37:25; Òwe 13:20; Jòh. 15:14; 1 Tím. 2:9) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á ṣeé ṣe fún wa láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. (Mát. 7:12; Fílí. 2:3, 4) Nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ ká mọ bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí, a máa ń ronú jinlẹ̀ nípa ibi tí ìpinnu tá a bá ṣe máa já sí. (1 Tím. 6:9) Ìwé Mímọ́ tún sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú, èyí sì ń jẹ́ ká gbé ìgbé ayé tó bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe mu. (Mát. 6:33; 1 Jòh. 2:17, 18) Ó dájú pé tá a bá jẹ́ kí àwọn ìlànà Ọlọ́run máa darí wa, ìgbésí ayé wa máa nítumọ̀.
6. Báwo ni Bíbélì ṣe lágbára tó nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà?
6 Tún ronú lórí bí Bíbélì ṣe jẹ́ ohun ìjà tó lágbára nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà. Pọ́ọ̀lù pe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní “idà ẹ̀mí.” (Ka Éfésù 6:12, 17.) Tá a bá gbé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí í ṣe ìdá ẹ̀mí yìí kalẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́, ó lè tú àwọn èèyàn sílẹ̀ kúrò lábẹ́ àjàgà Sátánì. Torí náà, idà tó ń gbani là ni, kì í ṣe èyí tó ń gbẹ̀mí ẹni. Ǹjẹ́ kò wá yẹ ká máa lò ó lọ́nà tó jáfáfá?
Fọwọ́ Títọ̀nà Mú Un
7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọ́ bí a ó ṣe máa lo “idà ẹ̀mí” dáadáa?
7 Ọmọ ogun kan lè lo ohun ìjà ogun rẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́, tó bá ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń lò ó tó sì ti fi í dánra wò. Ohun kan náà ló yẹ ká máa ṣe tó bá dọ̀rọ̀ lílo “idà ẹ̀mí” nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tím. 2:15.
8, 9. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Bíbélì sọ? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.
8 Kí ló máa jẹ́ ká lè máa “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ká tó lè gbin ohun tí Bíbélì sọ sọ́kàn àwọn ẹlòmíì, àwa fúnra wa gbọ́dọ̀ mọ ohun tó sọ. Èyí gba pé ká máa gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú ẹsẹ Bíbélì kan àtèyí tó wà lẹ́yìn rẹ̀ yẹ̀ wò dáadáa.
9 Ká tó lè lóye ẹsẹ Bíbélì kan bó ṣe tọ́, a ní láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká. A lè rí àpẹẹrẹ èyí nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Gálátíà 5:13. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú, òmìnira ni a pè yín fún, ẹ̀yin ará; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe fún ẹran ara, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìfẹ́, ẹ máa sìnrú fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Òmìnira wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ṣé òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ló ń sọ, àbí òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké tàbí kó jẹ́ ohun míì ló ní lọ́kàn? Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé, òmìnira tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni ‘ìtúsílẹ̀ kúrò lábẹ́ ègún Òfin.’ (Gál. 3:13, 19-24; 4:1-5) Torí náà, òmìnira táwa Kristẹni ní ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìfẹ́ máa ń mú kí gbogbo àwọn tó mọyì òmìnira yìí sìnrú fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Ṣùgbọ́n àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ máa ń sọ̀rọ̀ ara wọn lẹ́yìn, aáwọ̀ sì máa ń wà láàárín wọn.—Gál. 5:15.
10. Ká lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dáadáa, kí làwọn ohun tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò, ọ̀nà wo la sì lè gbà gbé wọn yẹ̀ wò?
10 Ká tó lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dáadáa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ àwọn nǹkan kan nípa rẹ̀, irú bí ẹni tó kọ ìwé Bíbélì yẹn, ìgbà tó kọ ọ́ àti bí nǹkan ṣe rí nígbà tó kọ ọ́. Ó tún ṣàǹfààní láti mọ ìdí tí wọ́n fi kọ ìwé Bíbélì yẹn, tó bá sì ṣeé ṣe, ó yẹ ká mọ irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn ń gbé nígbà yẹn, ìwà tí wọ́n ń hù àti ìsìn tí wọ́n ń ṣe. a
11. Kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún nígbà tá a bá ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́?
11 Fífi “ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” kọjá pé kéèyàn ṣàlàyé àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni lọ́nà tó tọ́. A tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ máa fi Bíbélì kó àwọn èèyàn láyà jẹ. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé a lè fi Bíbélì gbèjà òtítọ́, bí Jésù ti ṣe nígbà tí Èṣù dẹ ẹ́ wò, a ò ní máa lò ó láti fi na àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa lẹ́gba ọ̀rọ̀. (Diu. 6:16; 8:3; 10:20; Mát. 4:4, 7, 10) A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìṣílétí àpọ́sítélì Pétérù pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pét. 3:15.
12, 13. Àwọn ohun tó ti ‘fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in’ wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dojú rẹ̀ dé? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.
12 Kí ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣe tá a bá lò ó lọ́nà tó tọ́? (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:4, 5.) Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lè dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé,” ìyẹn ni pé, ó lè tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké, àwọn àṣà tó léwu àtàwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí èrò àwọn èèyàn aláìpé. A lè lo Bíbélì láti gbá àwọn àbá kan tí wọ́n “gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run” dà nù. A lè lo àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti mú èrò wọn bá òtítọ́ Bíbélì mu.
13 Gbé àpẹẹrẹ màmá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93] tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Íńdíà yẹ̀ wò. Láti kékeré ni wọ́n ti fi ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé kọ́ ọ. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípasẹ̀ lẹ́tà tí òun àti ọmọ rẹ̀ tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè ń kọ síra wọn, ó gba gbogbo ohun tó kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ gbọ́. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀kọ́ nípa àtúnwáyé fìdí rinlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀ débi pé, ńṣe ló fárígá nígbà tí ọmọ rẹ̀ kọ̀wé sí i nípa ipò táwọn òkú wà. Ó sọ pé: “Mi ò gbà pé òótọ́ lohun tí Ìwé Mímọ́ rẹ yìí ń sọ. Gbogbo ìsìn ló ń kọ́ni pé ohun kan wà nínú èèyàn tí kì í kú. Ohun tí mo sì gbà gbọ́ ni pé ara èèyàn máa ń kú, ohun kan tá ò lè fojú rí á sì jáde lára rẹ̀, táá sì máa tún ayé wá nínú ara míì fún nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó [8,400,000] ìgbà. Ṣé kì í ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn ni? Ṣé irọ́ lọ̀pọ̀ ìsìn ń pa ni?” Ǹjẹ́ “idà ẹ̀mí” á lè dojú ìgbàgbọ́ tó ti fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in bí irú èyí dé? Lẹ́yìn tí òun àti ọmọ rẹ̀ ti jíròrò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí kókó yìí síwájú sí i, ó kọ̀wé sí i ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà pé: “Mo ti wá bẹ̀rẹ̀ sí mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn òkú. Ayọ̀ mi kún láti mọ̀ pé nígbà àjíǹde, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti tún pa dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú. Mo fẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run tètè dé.”
Lò Ó Láti Fi Yíni Lérò Pa Dà
14. Kí ló túmọ̀ sí láti yí àwọn olùgbọ́ wa lérò pa dà?
14 Lílo Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kọjá kéèyàn kàn máa tọ́ka sí i. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ìyíniléròpadà,” àwa náà sì gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Ìṣe 19:8, 9; 28:23.) Ohun tí “ìyíniléròpadà” túmọ̀ sí ni láti “jèrè ẹni.” Ẹni tá a yí lérò pa dà “máa ní ìdánilójú débi táá fi ní ìgbọ́kànlé nínú ohun kan.” Tá a bá yí ẹnì kan lérò pa dà láti gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kẹ́ni náà fọkàn tán àwọn ẹ̀kọ́ náà. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti jẹ́ kó dá ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ lójú pé òótọ́ lohun tá à ń sọ. Àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ rèé.
15. Báwo lo ṣe lè darí àwọn èèyàn sínú Bíbélì lọ́nà tí wọ́n á fi mọyì rẹ̀?
15 Darí àwọn èèyàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tí wọ́n á fi mọyì rẹ̀. Tó o bá sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, pọkàn pọ̀ sórí bó ti ṣe pàtàkì tó láti mọ èrò Ọlọ́run lórí kókó náà. Lẹ́yìn tó o bá ti béèrè ìbéèrè, tó o sì ti gbọ́ èrò ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, o lè sọ pé, ‘Jẹ́ ká wo ojú tí Ọlọ́run fi wo ọ̀rọ̀ yìí.’ Tàbí kó o béèrè pé, ‘Kí ni Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀?’ Tó o bá ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ lọ́nà yìí, á ṣeé ṣe fún ẹ láti tẹ̀ ẹ́ mọ́ onílé rẹ lọ́kàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, wàá sì lè jẹ́ kí wọ́n máa fojú pàtàkì wò ó. Ó ṣe pàtàkì ká máa lo ọ̀nà yìí, àgàgà tá a bá ń wàásù fún ẹnì kan tó gba Ọlọ́run gbọ́ àmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni.—Sm. 19:7-10.
16. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ bó ṣe tọ́?
16 Ka Ìwé Mímọ́, kó o sì tún ṣàlàyé rẹ̀. Ó jẹ́ àṣà Pọ́ọ̀lù láti máa ṣàlàyé àwọn ohun tó ń kọ́ni ‘kó sì tún fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka.’ (Ìṣe 17:3) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan máa ń ní ju kókó kan lọ, ó sì lè pọn dandan pé kó o ṣàlàyé àwọn kókó tó bá ohun tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò mu. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa títún gbólóhùn tó o fẹ́ lò sọ, tàbí kó o béèrè ìbéèrè tó lè ran ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ láti rí kókó náà. Lẹ́yìn náà kó o wá ṣàlàyé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn túmọ̀ sí. Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó wá kàn ni pé kó o ran olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ láti rí bó ṣe lè fi ọ̀rọ̀ náà sílò.
17. Báwo lo ṣe lè fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ẹ lójú?
17 Fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ẹ lójú. Pọ́ọ̀lù pàrọwà fáwọn olùgbọ́ rẹ̀, ó sì lo ọgbọ́n láti lè fi ìdánilójú ‘fèrò-wérò pẹ̀lú wọn látinú Ìwé Mímọ́.’ (Ìṣe 17:2, 4) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́kàn. Máa lo ìbéèrè tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún láti fi ‘fa ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde.’ (Òwe 20:5) Má máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ luni. Ṣe ni kó o máa fi ọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ kalẹ̀, kó o sì jẹ́ kó ṣe kedere. Àwọn ẹ̀rí tó jóòótọ́ ni kó o sì máa fi ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn. Kó o máa rí i pé orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò ń gbé gbogbo ohun tó o bá ń sọ kà. Ó máa dára gan-an tó o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, tó o sì ṣe àlàyé àti àpèjúwe láti gbé kókó ibẹ̀ yọ, ju pé kó o kàn yára ka àwọn ẹsẹ Bíbélì méjì tàbí mẹ́ta léraléra. Tó o bá lo àwọn ẹ̀rí tó yè kooro láti fi ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn, ìyẹn náà tún lè ‘fi ìyíniléròpadà kún ètè rẹ.’ (Òwe ) Nígbà míì, ó lè gba pé kó o ṣe ìwádìí, kó o lè túbọ̀ fúnni láwọn àlàyé tó kún rẹ́rẹ́. Màmá àgbàlagbà tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fẹ́ mọ ìdí tí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọ̀kan fi gbayé kan bẹ́ẹ̀. Mímọ̀ tó mọ ibi tí ẹ̀kọ́ náà ti wá àti bó ṣe wọnú ọ̀pọ̀ ìsìn káàkiri ayé ló yí i lérò pa dà láti gba ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa rẹ̀. 16:23 b
Máa Bá A Nìṣó ní Lílò Ó Lọ́nà Tó Jáfáfá
18, 19. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó ní lílo “idà ẹ̀mí” lọ́nà tó jáfáfá?
18 Bíbélì sọ pé: “Ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” Àwọn èèyàn burúkú sì ń tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù. (1 Kọ́r. 7:31; 2 Tím. 3:13) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá a nìṣó láti dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” dé nípa lílo “idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”
19 Ohun tó ń múni láyọ̀ ló jẹ́ pé a ní Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à ń lo àwọn òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro tó wà nínú rẹ̀ láti fi fa àwọn ẹ̀kọ́ èké tu, a sì ń lò ó láti kọ́ àwọn ọlọ́kàn títọ́ lẹ́kọ̀ọ́! Kò sí ohunkóhun tó fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in tó lágbára ju ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sa gbogbo ipá wa láti máa lo “idà ẹ̀mí” lọ́nà tó jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn pípolongo Ìjọba rẹ̀.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ìwé tó lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti mọ àwọn nǹkan kan nípa ìwé Bíbélì kan ni, “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” Insight on the Scriptures àti àwọn àpilẹ̀kọ bí “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́.
b Wo ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú? ojú ìwé 5 sí 16.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó?
• Báwo la ṣe lè “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́”?
• Kí ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lè ṣe sí ‘àwọn nǹkan tó fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in’?
• Báwo lo ṣe lè fi kún ọ̀nà tó ò ń gbà yíni lérò pa dà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yíni Lérò Pa Dà
▪ Jẹ́ káwọn èèyàn mọyì Bíbélì
▪ Ṣàlàyé Ìwé Mímọ́
▪ Fèrò wérò lọ́nà táá fi wọni lọ́kàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
O gbọ́dọ̀ kọ́ bí wàá ṣe máa lo “idà ẹ̀mí” lọ́nà tó gbéṣẹ́