Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìṣojo’

‘Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìṣojo’

‘Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìṣojo’

‘Wọ́n kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’—ÌṢE 4:31.

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

 NÍGBÀ tó ku ọjọ́ mẹ́ta kí Jésù kú, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Kí Jésù tó gòkè re ọ̀run lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí òun ti pa láṣẹ fún wọn mọ́.’ Ó ṣèlérí fún wọn pé òun á wà pẹ̀lú wọn “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 24:14; 26:1, 2; 28:19, 20.

2 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ kan tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Kò sí iṣẹ́ míì tó ṣe pàtàkì bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn, èyí tó jẹ́ iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí ẹ̀mí mímọ́ tó ń darí wa lẹ́nu iṣẹ́ náà ṣe ń jẹ́ ká máa sọ̀rọ̀ láìṣojo. Àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e, á jẹ́ ká mọ bí ẹ̀mí Jèhófà, ṣé ń darí wa láti kọ́ni lọ́nà tó já fáfá ká sì tún máa wàásù láìdáwọ́ dúró.

A Gbọ́dọ̀ Máa Wàásù Láìṣojo

3. Kí nìdí tí ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run fi gba pé ká jẹ́ aláìṣojo?

3 Kò sóhun tá a lè fi wé àǹfààní tá a ní láti máa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká máa polongo Ìjọba rẹ̀. Àmọ́, iṣẹ́ náà máa ń ṣòro nígbà míì. Àwọn kan máa ń gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe bí àwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà. Jésù sọ pé: “Wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Mát. 24:38, 39) Àwọn míì sì wà tí wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí wọ́n ń ta kò wá. (2 Pét. 3:3) Àtakò lè wá látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ, àwọn ọmọléèwé wa tàbí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, tàbí látọ̀dọ̀ àwọn ìbátan wa tímọ́tímọ́ pàápàá. Ohun míì tó tún ń fa ìṣòro ni kùdìẹ̀-kudiẹ tàwa fúnra wa, irú bí ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè máà fẹ́ gbọ́rọ̀ wa. Ọ̀pọ̀ nǹkan míì ló lè mú kó ṣòro fún wa láti lo “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ,” ká sì máa sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “láìṣojo.” (Éfé. 6:19, 20) Ó gba àìṣojo kéèyàn tó lè máa bá a nìṣó láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ló lè mú ká jẹ́ ẹni tí kì í ṣojo?

4. (a) Kí ni àìṣojo? (b) Kí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máyàle láti sọ̀rọ̀ láìṣojo fún àwọn ará ìlú Tẹsalóníkà?

4 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “aláìṣojo” tún túmọ̀ sí “àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀, àìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, kọ́rọ̀ ṣe kedere.” Ọ̀rọ̀ náà tún wé mọ́ “ìgboyà, ìdánilójú, . . . àìfòyà.” Àìṣojo kò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ luni tàbí kéèyàn jẹ́ ọ̀yájú o. (Kól. 4:6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti jẹ́ aláìṣojo, a tún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn. (Róòmù 12:18) Síwájú sí i, bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa lo ọgbọ́n ká má bàa máa ṣẹ àwọn èèyàn, torí pé a fẹ́ jẹ́ aláìṣojo. Ká sòótọ́, jíjẹ́ aláìṣojo gba pé ká sapá láti ní àwọn ànímọ́ kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. A ò sì lè ní irú àìṣojo bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ agbára tiwa fúnra wa. Kí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò “máyàle” láti bá àwọn ará ìlú Tẹsalóníkà sọ̀rọ̀, lẹ́yìn tí wọ́n ti ‘hùwà sí wọn lọ́nà àfojúdi ní ìlú Fílípì’? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ Ọlọ́run wa.” (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:2.) Jèhófà Ọlọ́run lè mú ìbẹ̀rù tiwa náà kúrò, kó sì mú ká jẹ́ aláìṣojo bíi tiwọn.

5. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí Pétérù, Jòhánù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn míì di aláìṣojo?

5 Nígbà tí “àwọn olùṣàkóso [àwọn ènìyàn] . . . àti àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn akọ̀wé òfin,” gbéjà ko àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù, wọ́n sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ òdodo lójú Ọlọ́run láti fetí sí yín dípò Ọlọ́run, ẹ fúnra yín ṣèdájọ́. Ṣùgbọ́n ní tiwa, àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” Dípò kí wọ́n gbàdúrà pé kí Ọlọ́run bá àwọn dáwọ́ inúnibíni náà dúró, àwọn àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé: “Jèhófà, fiyè sí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọn, kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” (Ìṣe 4:5, 19, 20, 29) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wọn? (Ka Ìṣe 4:31.) Jèhófà fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè di aláìṣojo. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè ran àwa náà lọ́wọ́ lọ́nà yẹn. Báwo wá ni a ṣe lè rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà, kó sì máa darí wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Aláìṣojo

6, 7. Ọ̀nà wo ló ṣe tààràtà jù lọ láti rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.

6 Bá a bá fẹ́ rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà, ọ̀nà tó ṣe tààràtà jù lọ ni pé ká béèrè fún un. Jésù sọ fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Láìsí àní-àní, ó yẹ ká máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ nígbà gbogbo. Tí ẹ̀rù bá ń bà wá láti wàásù láwọn ọ̀nà kan, irú bí, ìjẹ́rìí òpópónà, ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, wíwàásù níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó sì ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìṣojo.—1 Tẹs. 5:17.

7 Ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rosa ṣe nìyẹn. a Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Rosa wà níbi iṣẹ́ rẹ̀, olùkọ́ kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ń ka ìròyìn kan tó wá láti iléèwé míì nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ọmọdé ní ìṣekúṣe. Ohun tí olùkọ́ náà kà kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, débi tó fi sọ pé: “Kí layé yìí tiẹ̀ wá dà báyìí gan-an?” Rosa kò fẹ́ kí àǹfààní tó ní láti wàásù yẹn lọ bẹ́ẹ̀. Kí ló ṣe kó lè ní ìgboyà láti sọ̀rọ̀? Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.” Ó wàásù fún olùkọ́ náà, ó sì ṣètò láti máa bá ìjíròrò náà lọ. Tún gbé ọ̀ràn ti ọmọbìnrin ọmọ ọdún márùn-ún kan tó ń jẹ́ Milane, tó ń gbé ìlú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, yẹ̀ wò. Milane sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni èmi àti mọ́mì mi máa ń gbàdúrà sí Jèhófà kí n tó lọ síléèwé.” Kí ni wọ́n máa ń gbàdúrà nípa rẹ̀? Ìgboyà ni! Ìgboyà táá jẹ́ kí Milane lè dúró lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀, kó sì lè sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run rẹ̀. Mọ́mì Milane sọ pé: “Ohun tó ran Milane lọ́wọ́ nìyẹn, tó jẹ́ kó lè sọ ìdí tí kì í fi í ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àtàwọn ọdún míì tí wọ́n ń ṣe.” Ǹjẹ́ àwọn àpẹẹrẹ yìí ò jẹ́ ká rí i pé àdúrà máa ń jẹ́ ká lè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìṣojo?

8. Kí la lè rí kọ́ lára wòlíì Jeremáyà nípa bá a ṣe lè jẹ́ aláìṣojo?

8 Tún ronú lórí ohun tó ran wòlíì Jeremáyà lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìṣojo. Nígbà tí Jèhófà yan Jeremáyà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tó sọ ni pé: “Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” (Jer. 1:4-6) Àmọ́ nígbà tó yá, Jeremáyà dẹni tó ń fìgboyà wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo débi táwọn èèyàn fi ń fojú akéde àjálù wò ó. (Jer. 38:4) Ohun tó lé lọ́dún márùndínláàádọ́rin [65] ló fi polongo ìdájọ́ Jèhófà. Ó gbajúmọ̀ ní Ísírẹ́lì nítorí bó ṣe wàásù láìbẹ̀rù àti pẹ̀lú ìgboyà débi pé ní ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn kan gbà gbọ́ pé Jeremáyà ti jíǹde. (Mát. 16:13, 14) Báwo ni Jeremáyà tó kọ́kọ́ fẹ́ yẹ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an sílẹ̀ ṣe borí ìtìjú rẹ̀? Ó sọ pé: “Nínú ọkàn-àyà mi, [ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] sì wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi; pípa á mọ́ra sú mi, èmi kò sì lè fara dà á.” (Jer. 20:9) Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ Jèhófà lágbára lórí Jeremáyà, ó sì mú kó sọ̀rọ̀.

9. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi lè nípa lórí wa bó ṣe nípa lórí Jeremáyà?

9 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè nípa lórí wa bó ṣe nípa lórí Jeremáyà. Má gbàgbé pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ni Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì, kì í ṣe èrò tara wọn ni wọ́n kọ síbẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí wọn. Nínú 2 Pétérù 1:21 a kà pé: “A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” Tá a bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jíire, ọkàn wa á kún fún àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:10.) Ńṣe lọ̀rọ̀ náà máa “dà bí iná tí ń jó” nínú wa, débi pé a kò ní lè pa á mọ́ra.

10, 11. (a) Kí ló yẹ ká ṣe nípa ọ̀nà tá à ń gbà kẹ́kọ̀ọ́, tá a bá fẹ́ máa sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìṣojo? (b) Sọ ohun kan tó o lè ṣe láti mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ sunwọ̀n sí i.

10 Kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe é lọ́nà tí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì á fi wọ̀ wá lọ́kàn, táá sì nípa lórí ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mú kí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ìran kan, ó sì sọ fún un nínú ìran náà pé kó jẹ àkájọ ìwé tó ní iṣẹ́ líle kan tó máa jẹ́ fún àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìgbọràn. Iṣẹ́ tó máa jẹ́ náà gbọ́dọ̀ yé e yékéyéké kó sì fi ṣe apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí oyin ṣe máa ń dùn lẹ́nu ni iṣẹ́ tó fẹ́ jẹ́ náà á ṣe gbádùn mọ́ ọn.—Ka Ìsíkíẹ́lì 2:8–3:4, 7-9.

11 Bíi ti Ìsíkíẹ́lì ni ọ̀ràn tiwa náà ṣe rí. Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. Tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní sísọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ á fi yé wa yékéyéké. Kò yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa jẹ́ ìdákúrekú, kàkà bẹ́ẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa ṣe é déédéé. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ wa dà bíi ti onísáàmù náà tó kọ ọ́ lórin pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.” (Sm. 19:14) Dájúdájú, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣe àṣàrò lórí ohun tá à ń kà, kí ẹ̀kọ́ Bíbélì lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin! Torí náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i. b

12. Báwo làwọn ìpàdé ìjọ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti dẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí?

12 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà jàǹfààní ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni pé ká máa “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.” (Héb. 10:24, 25) Tá a bá ń sapá láti máa pésẹ̀ sí ìpàdé déédéé, tá à ń fetí sílẹ̀ dáadáa, tá a sì ń fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ọ̀nà tó dáa nìyẹn náà jẹ́ láti mú kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa. Ó ṣe tán, à ń rí ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí Jèhófà gbà nípasẹ̀ ìjọ.—Ka Ìṣípayá 3:6.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Aláìṣojo

13. Kí la lè rí kọ́ lára ohun táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

13 Ẹ̀mí mímọ́ ni ipá tó lágbára jù lọ lọ́run àtayé, ó sì lè fún àwa èèyàn lágbára láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ẹ̀mí mímọ́ ran àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lọ́wọ́ láti gbé ohun tó pọ̀ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n wàásù ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Tá a bá tún fojú ti pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ‘kò mọ̀wé, tí wọ́n sì tún jẹ́ gbáàtúù’ wò ó, á ṣe kedere sí wa pé ipá kan tó lágbára gan-an ló tì wọ́n lẹ́yìn.—Ìṣe 4:13.

14. Kí ló lè mú kí “iná ẹ̀mí” máa jó nínú wa?

14 Tá a bá ń gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí ẹ̀mí mímọ́ á fi máa darí wa, ìyẹn náà á mú ká lè máa fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àǹfààní púpọ̀ la máa rí gbà tá a bá ń gbàdúrà déédéé fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tá à ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jíire, tá à ń fara balẹ̀ ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń pésẹ̀ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé, torí pé èyí á mú kí “iná ẹ̀mí máa jó nínú” wa. (Róòmù 12:11) Bíbélì sọ nípa “Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àpólò, ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà, ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan,” pé nígbà tó ‘dé sí Éfésù, iná ẹ̀mí ń jó nínú rẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń fi àwọn nǹkan nípa Jésù kọ́ni pẹ̀lú ìpérẹ́gí.’ (Ìṣe 18:24, 25) Tí “iná ẹ̀mí” bá ń jó nínú wa, a ó lè máa fi àìṣojo tó pọ̀ sí i ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé àti ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà.—Róòmù 12:11.

15. Àǹfààní wo ló wà nínú pé ká túbọ̀ jẹ́ aláìṣojo?

15 Tá a bá ń fi àìṣojo ṣe iṣẹ́ ìwàásù, ó máa ń so èso rere. Ojú tá a fi ń wo iṣẹ́ náà á yí pa dà, torí pé a óò túbọ̀ mọ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ náà àti àǹfààní tó wà níbẹ̀. Ìtara wa máa pọ̀ sí i, torí pé ayọ̀ wa máa kún tá a bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́nà tó túbọ̀ jáfáfá. Ohun tó sì máa jẹ́ kí ìtara wa pọ̀ sí i ni pé, a óò túbọ̀ mọ bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó.

16. Kí ló yẹ ká ṣe bí ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ti lọ sílẹ̀?

16 Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ fi ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà mọ́ ńkọ́ tàbí kí ìfẹ́ tá a ní fún iṣẹ́ náà ti dín kù? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fi àìṣẹ̀tàn ṣàyẹ̀wò ohun tó fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́r. 13:5) Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé iná ẹ̀mí ṣì ń jó nínú mi? Ṣé mo máa ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà? Ǹjẹ́ àwọn àdúrà mi ń fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé e láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ṣé àwọn àdúrà mi máa ń fi hàn pé mo mọrírì iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́? Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ mi ṣe rí? Báwo ni àkókò tí mò ń lò láti fi ṣàṣàrò lórí ohun tí mo kà àtohun tí mo gbọ́ ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ mo máa ń kópa nínú àwọn ìpàdé ìjọ?’ Tó o bá ń ronú lórí irú àwọn ìbéèrè báyìí, á jẹ́ kó o mọ ibi tó o kù sí àti bí wàá ṣe ṣàtúnṣe.

Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Sọ Ẹ́ Di Aláìṣojo

17, 18. (a) Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lónìí ṣe gbòòrò tó? (b) Báwo la ṣe lè máa fi “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà” polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

17 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) À ń ṣe iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn lọ́nà tó gbòòrò gan-an lóde òní. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méje àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀ tó lé ní ọgbọ̀nlérúgba [230], tá a sì ń lo nǹkan bíi bílíọ̀nù kan ààbọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lọ́dọọdún. Inú wa mà dùn gan-an o pé a wà lára àwọn tó ń fìtara ṣe iṣẹ́ tá ò ní pa dà ṣe mọ́ yìí!

18 Bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wa bá a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí kárí ayé. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run, a ó máa fi “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà” ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Ìṣe 28:31) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti gba ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ bá a ti ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

b Tó o bá túbọ̀ fẹ́ máa jàǹfààní látinú kíka Bíbélì àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ, wo àwọn àkòrí náà, “Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà” àti “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè” nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 21 sí 32.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àìṣojo sọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

• Kí ló jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ọ̀rúndún kìíní máa sọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìṣojo?

• Báwo la ṣe lè jẹ́ aláìṣojo?

• Àǹfààní wo là ń rí nínú jíjẹ́ aláìṣojo?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìṣojo?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àdúrà ṣókí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìṣojo lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́