Ǹjẹ́ O Ka Jèhófà sí Bàbá Rẹ?
Ǹjẹ́ O Ka Jèhófà sí Bàbá Rẹ?
NÍGBÀ tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ fún un pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà,” ó dá a lóhùn pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, ‘Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Lúùkù 11:1, 2) Jésù ì bá ti pe Jèhófà ní àwọn orúkọ oyè bí “Olódùmarè,” ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá,’ “Ẹlẹ́dàá,” “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” àti “Ọba ayérayé.” (Jẹ́n. 49:25; Aísá. 30:20; 40:28; Dán. 7:9; 1 Tím. 1:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù pè é ní “Baba.” Kí nìdí tó fi pè é bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó fẹ́ káwa náà máa bá Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àtọ̀run yìí sọ̀rọ̀ bí ọmọdé kan ṣe ń bá baba tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀.
Àmọ́ ṣá o, àwọn kan wà tó ṣòro fún láti ka Ọlọ́run sí Bàbá wọn. Kristẹni kan tó ń jẹ́ Atsuko a sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí mo ti ṣèrìbọmi, ó ṣòro fún mi láti sún mọ́ Jèhófà kí n sì gbàdúrà sí i gẹ́gẹ́ bíi Bàbá.” Nígbà tó ń sọ ọ̀kan lára ìṣòro rẹ̀, ó ní, “Bàbá tó bí mi lọ́mọ ò fìfẹ́ hàn sí mi rí.”
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko yìí, “ìfẹ́ni àdánidá” tó yẹ kí baba máa fi hàn sọ́mọ ò fi bẹ́ẹ̀ sí mọ́. (2 Tím. 3:1, 3) Torí náà, kì í ṣe ohun àjèjì láti rí àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn rí bíi ti Atsuko. Àmọ́, ó bà ni kò tíì bà jẹ́, torí pé a ní ìdí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ka Jèhófà sí Bàbá wa onífẹ̀ẹ́.
Jèhófà Ń Fìfẹ́ Pèsè Ohun Tá A Nílò
Ká tó lè ka Jèhófà sí Bàbá wa, a gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dunjú. Jésù sọ pé: “Kò sì sí ẹnì kankan tí ó mọ Ọmọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Baba, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò mọ Baba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ fẹ́ láti ṣí i payá fún.” (Mát. 11:27) Ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà mọ irú Baba tí Jèhófà jẹ́ ni pé ká máa ronú lórí àwọn nǹkan tí Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run òtítọ́. Bọ́rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ni Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa Baba?
Nígbà tí Jésù ń fi hàn pé Jèhófà ni orísun ìwàláàyè òun, ó sọ pé: “Mo sì wà láàyè nítorí Baba.” (Jòh. 6:57) Baba ni orísun ìwàláàyè tiwa náà. (Sm. 36:9; Ìṣe 17:28) Kí ló mú kí Jèhófà fún àwọn míì ní ìwàláàyè? Ìfẹ́ ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ káwa náà nífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run nítorí ẹ̀bùn tó fún wa yìí.
Ọ̀nà gíga jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ tó ní fún aráyé hàn ni pé ó fi ọmọ rẹ̀ rúbọ kó lè rà wọ́n pa dà. Ìràpadà yìí mú kó ṣeé ṣe fún àwa ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nípasẹ̀ àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. (Róòmù 5:12; 1 Jòh. 4:9, 10) Torí pé Baba wa ọrún jẹ́ Ẹni tó máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó dá wa lójú pé gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i máa gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
Baba wa ọ̀run tún máa “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí” wa lójoojúmọ́. (Mát. 5:45) Kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ kéèyàn máa gbàdúrà pé kí oòrùn yọ. Síbẹ̀, a nílò ìtànṣán oòrùn a sì ń gbádùn bó ṣe máa ń ta síni lára! Àti pé Baba wa jẹ́ Olùpèsè tí kò lẹ́gbẹ́, tó mọ àwọn ohun tá a ṣaláìní ká tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Torí náà, ṣé kò wá yẹ kí ìmọrírì tá a ní fún Baba wa ọ̀run yìí mú ká máa kíyè sí bó ṣe ń bójú tó àwọn ohun tó dá ká sì máa ṣàṣàrò lórí wọn?—Mát. 6:8, 26.
Baba Wa Tí Ń ‘Fìfẹ́ Dáàbò Boni’
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mú kó dá àwọn èèyàn Ọlọ́run ìgbàanì lójú pé: “‘A lè ṣí àwọn òkè ńláńlá Aísá. 54:10) Àdúrà tí Jésù gbà lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé òótọ́ ni Jèhófà máa ń ‘fìfẹ́ dáàbò boni.’ Jésù gbàdúrà nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọ́n wà ní ayé, èmi sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn ní tìtorí orúkọ rẹ.” (Jòh. 17:11, 14) Jèhófà ti fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ó sì ti dáàbò bò wọ́n.
pàápàá kúrò, àní àwọn òkè kéékèèké sì lè ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, ṣùgbọ́n inú rere mi onífẹ̀ẹ́ ni a kì yóò mú kúrò lọ́dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àlàáfíà mi kì yóò ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,’ ni Jèhófà, Ẹni tí ó ṣàánú fún [“fìfẹ́ dáàbò bò,”The Bible in Living English] ọ, wí.” (Ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń gbà dáàbò bò wá lọ́wọ́ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì ni pé ó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45) Ó ṣe pàtàkì pé ká máa jẹ oúnjẹ tó ń fúnni lókun yẹn ká bàa lè “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.” Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò “apata ńlá ti ìgbàgbọ́,” tá a ó fi lè máa “paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfé. 6:11, 16) Tá a bá ní ìgbàgbọ́, ó máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sì tún máa fi hàn pé a gbà pé Jèhófà lè dáàbò bò wá.
Bá a bá fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ohun tí Ọmọ Ọlọ́run gbé ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, a máa túbọ̀ lóye pé agbatẹnirò ni Baba wa ọ̀run. Kíyè sí àkọsílẹ̀ inú Máàkù 10:13-16. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Máàkù fa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yọ, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi.” Bí àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyẹn ti pé jọ yí ká Jésù, ó fìfẹ́ gbá wọn mọ́ra ó sì súre fún wọn. Inú àwọn ọmọ náà á mà dùn gan-an ni o! Níwọ̀n bí Jésù sì ti sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú,” a mọ̀ pé Ọlọ́run òtítọ́ náà á fẹ́ ká wá sọ́dọ̀ òun.—Jòh. 14:9.
Jèhófà Ọlọ́run ni Orísun ìfẹ́ tí kò lópin. Òun sì ni Olùpèsè tí kò lẹ́gbẹ́ àti Olùdáàbòboni tí kò láfijọ, tó ń fẹ́ ká sún mọ́ òun. (Ják. 4:8) Torí náà, kò tún sí Baba tó dà bíi Jèhófà!
Àǹfààní Ńlá Ló Máa Jẹ́ Tiwa!
Àǹfààní ńláǹlà ló máa jẹ́ tiwa tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà pé òun ni Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì ń gba tiwa rò. (Òwe 3:5, 6) Jésù jàǹfààní látinú bó ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Baba rẹ̀, ó sì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi kò wà ní èmi nìkan, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi wà pẹ̀lú mi.” (Jòh. 8:16) Ó máa ń dá Jésù lójú nígbà gbogbo pé Jèhófà á máa ti òun lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ìrìbọmi rẹ̀, Baba rẹ̀ mú kó dáa lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mát. 3:15-17) Àti pé ṣáájú kí Jésù tó kú, ó ké pe Baba rẹ̀ pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” (Lúùkù 23:46) Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Jésù ní nínú Baba rẹ̀ ṣì fìdí múlẹ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá.
Bíi ti Jésù, àwa náà lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Bí Jèhófà bá sì wà ní ìhà ọ̀dọ̀ wa, kí nìdí tá a ó fi máa bẹ̀rù? (Sm. 118:6) Ó ti mọ́ Atsuko, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, lára láti máa gbẹ́kẹ̀ lé agbára tara rẹ̀ nígbà tó bá wà nínú ìṣòro. Àmọ́, nígbà tó ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì pọkàn pọ̀ sórí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àti Baba rẹ̀ ọ̀run. Kí ni àbájáde rẹ̀? Atsuko sọ pé: “Mo wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní Baba kan kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Mo sì ní ojúlówó àlàáfíà àti ayọ̀. Ó dájú pé kò sídìí tá a fi ní láti máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun.”
Báwo la ṣe lè máa jàǹfààní síwájú sí i tá a bá ka Jèhófà sí Baba wa? Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ràn àwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Ìfẹ́ tí Ọmọ Ọlọ́run ní fún Baba rẹ̀ máa ń mú kó ṣe ‘ohun tó wù ú nígbà gbogbo.’ (Jòh. 8:29) Bákan náà, ìfẹ́ tá a ní fún Baba wa ọ̀run lè mú ká máa fọgbọ́n hùwà ká sì máa “yìn [ín] ní gbangba.”—Mát. 11:25; Jòh. 5:19.
Baba Wa Ń ‘Di Ọwọ́ Ọ̀tún Wa Mú’
Baba wa ọ̀run tún pèsè “olùrànlọ́wọ́,” ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wa. Jésù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ yìí máa “ṣamọ̀nà [wa] sínú òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 14:15-17; 16:12, 13) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ Baba wa ọ̀run. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé,” ìyẹn àwọn èrò òdì, àwọn èrò tí kò tọ́, tàbí àwọn ohun tó ń dorí òtítọ́ kodò, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ “mú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́r. 10:4, 5) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní “olùrànlọ́wọ́” tó ṣèlérí, ká sì ní ìgbọ́kànlé pé “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Kò sì burú tá a bá gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Ọkàn ọmọdé máa ń balẹ̀, ará máa ń tù ú, kì í sì í bẹ̀rù bí òun àti bàbá rẹ̀ bá jọ ń lọ síbì kan. Bó bá jẹ́ pé òótọ́ lo ka Jèhófà sí Bàbá rẹ, ó dájú pé àkọsílẹ̀ yìí á mú ẹ lọ́kàn le, ó kà pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” (Aísá. 41:13) Ìwọ náà lè ní àǹfààní àgbàyanu láti máa ‘bá Ọlọ́run rìn’ títí láé. (Míkà 6:8) Máa bá a nìṣó láti ṣe ohun tó fẹ́, wàá sì ní ìfẹ́, ìdùnnú àti ìfọ̀kànbalẹ̀ téèyàn máa ń ní tó bá ka Jèhófà sí Bàbá rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyí.