“Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
“Àwọn Olódodo Yóò Máa Tàn Yòò Bí Oòrùn”
“Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn yòò bí oòrùn nínú ìjọba Baba wọn.”—MÁT. 13:43.
1. Onírúurú nǹkan wo ni Jésù fi àpèjúwe ṣàlàyé nípa Ìjọba Ọlọ́run?
JÉSÙ KRISTI lo ọ̀pọ̀ àpèjúwe, tàbí àkàwé, láti ṣàlàyé onírúurú nǹkan nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó ‘lo àpèjúwe láti bá àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe.’ (Mát. 13:34) Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa fífúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó mú kó ṣe kedere pé ọkàn-àyà ẹnì kan máa ń nípa lórí gbígba ìhìn rere, ó sì tún jẹ́ ká rí ipa tí Jèhófà ń kó nínú mímú kí àwọn irúgbìn tẹ̀mí dàgbà. (Máàkù 4:3-9, 26-29) Jésù tún ṣe àpèjúwe nípa bí àwọn èèyàn tó máa gba ìhìn rere á ṣe pọ̀ jaburata, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má tètè kíyè sí i pé irú ìbísí bẹ́ẹ̀ ń wáyé. (Mát. 13:31-33) Láfikún sí ìyẹn, ó tún jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe gbogbo ẹni tó bá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló máa tóótun láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba yẹn.—Mát. 13:47-50. a
2. Nínú àpèjúwe Jésù nípa àlìkámà àti àwọn èpò, kí ni irúgbìn àtàtà náà ṣàpẹẹrẹ?
2 Àmọ́, ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe Jésù dá lórí bó ṣe máa ṣe àkójọ àwọn tó máa bá a ṣèjọba. Èyí ni àkàwé àlìkámà àti àwọn èpò, èyí tó wà nínú Mátíù orí 13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ fún wa nínú àpèjúwe mìíràn pé irúgbìn náà ni “ọ̀rọ̀ ìjọba náà,” àmọ́ nínú àpèjúwe yìí, ó sọ fún wa pé irúgbìn àtàtà náà ṣàpẹẹrẹ ohun kan tó yàtọ̀, ìyẹn ni “àwọn ọmọ ìjọba náà.” (Mát. 13:38) Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́, wọ́n jẹ́ “àwọn ọmọ,” tàbí àwọn ajogún, Ìjọba náà.—Róòmù 8:14-17; ka Gálátíà 4:6, 7.
Àpèjúwe Àlìkámà àti Àwọn Èpò
3. Ṣàlàyé ìṣòro tó dojú kọ ọkùnrin inú àpèjúwe yìí àti bó ṣe pinnu láti yanjú ìṣòro náà.
3 Àpèjúwe náà rèé: “Ìjọba ọ̀run wá dà bí ọkùnrin kan tí ó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó sì tún fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà náà, ó sì lọ. Nígbà tí ewé ọ̀gbìn náà rú jáde, tí ó sì mú èso jáde, nígbà náà ni àwọn èpò fara hàn pẹ̀lú. Nítorí náà, àwọn ẹrú baálé ilé náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Ọ̀gá, kì í ha ṣe irúgbìn àtàtà ni ìwọ fún sínú pápá rẹ? Nígbà náà, báwo ni ó ṣe wá ní àwọn èpò?’ Ó wí fún wọn pé, ‘Ọ̀tá kan, ọkùnrin kan, ni ó ṣe èyí.’ Wọ́n wí fún un pé, ‘Ìwọ ha fẹ́ kí àwa, nígbà náà, jáde lọ kí a sì kó wọn jọ?’ Ó wí pé, ‘Ó tì o; kí ó má bàa jẹ́ pé nípa èèṣì, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn èpò jọ, ẹ óò hú àlìkámà pẹ̀lú wọn. Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè; ní àsìkò ìkórè, ṣe ni èmi yóò sì sọ fún àwọn akárúgbìn pé, Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ láti sun wọ́n, lẹ́yìn náà ẹ lọ kó àlìkámà jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi.’”—Mát. 13:24-30.
4. (a) Ta ni ọkùnrin inú àpèjúwe náà? (b) Ìgbà wo ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí fún irúgbìn yìí, báwo ló sì ṣe ṣe é?
4 Ta ni ọkùnrin tó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀? Jésù sọ ẹni tí ọkùnrin náà jẹ́ nínú àlàyé tó ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó sọ àpèjúwe yìí, ó ní: “Afúnrúgbìn tí ó fún irúgbìn àtàtà náà ni Ọmọ ènìyàn.” (Mát. 13:37) Láàárín ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí Jésù, tó jẹ́ “Ọmọ ènìyàn” fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ló ṣètò pápá náà sílẹ̀ kó bàa lè ṣeé gbin irúgbìn sí. (Mát. 8:20; 25:31; 26:64) Lẹ́yìn náà, láti Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó bẹ̀rẹ̀ sí fún irúgbìn àtàtà, ìyẹn “àwọn ọmọ ìjọba náà.” Ó dájú pé fífún irúgbìn yìí wáyé nígbà tí Jésù, tó jẹ́ aṣojú Jèhófà, bẹ̀rẹ̀ sí tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀mí yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run. b (Ìṣe 2:33) Irúgbìn àtàtà náà dàgbà ó sì di àlìkámà. Nítorí náà, ìdí tí Jésù fi fún irúgbìn àtàtà náà jẹ́ láti ṣe àkójọ gbogbo àwọn tó máa di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì máa bá a ṣèjọba.
5. Ta ni ọ̀tá inú àpèjúwe náà, àwọn wo sì làwọn èpò ṣàpẹẹrẹ?
5 Ta ni ọ̀tá náà, àwọn wo sì ni àwọn èpò? Jésù sọ fún wa pé “Èṣù” ni ọ̀tá náà. Àwọn èpò sì ni “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” (Mát. 13:25, 38, 39) Ó ṣeé ṣe kí èpò tí Jésù lò nínú àpèjúwe rẹ̀ jẹ́ àwọn èpò kan báyìí tó máa ń ní irun lára. Kí irúgbìn onímájèlé yìí tó dàgbà, ó máa ń fara jọ àlìkámà gan-an ni. Ó bá a mu wẹ́kú láti fi àwọn afàwọ̀rajà tó pera wọn ní Kristẹni wé èpò yìí, àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ Ìjọba náà, àmọ́ tí wọn kò so ojúlówó èso! Dájúdájú, apá kan “irúgbìn” Sátánì Èṣù làwọn Kristẹni alágàbàgebè tó ń pera wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi yìí.—Jẹ́n. 3:15.
6. Ìgbà wo ni àwọn èpò bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn, báwo làwọn èèyàn sì ṣe “ń sùn” nígbà yẹn?
6 Ìgbà wo làwọn Kristẹni tó dà bí èpò yìí fara hàn? Jésù sọ pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn.” (Mát. 13:25) Ìgbà wo nìyẹn? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn alàgbà ìjọ Éfésù. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Ó wá gba àwọn alàgbà wọ̀nyẹn níyànjú pé kí wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “aṣèdíwọ́” fún ìpẹ̀yìndà ti bẹ̀rẹ̀ sí sùn nínú ikú, ọ̀pọ̀ Kristẹni sùn lọ nípa tẹ̀mí. (Ka 2 Tẹsalóníkà 2:3, 6-8.) Ìgbà yẹn gan-an ni ìpẹ̀yìndà ńlá bẹ̀rẹ̀.
7. Ṣé àwọn kan lára àlìkámà di èpò? Ṣàlàyé.
7 Jésù kò sọ pé àwọn àlìkámà máa di èpò, ohun tó sọ ni pé ọ̀tá fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà. Torí náà, kò lo àpèjúwe yìí láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ojúlówó Kristẹni tó kúrò nínú òtítọ́. Ńṣe ló fi ṣe àkàwé bí Sátánì á ṣe máa mọ̀ọ́mọ̀ sapá láti mú àwọn èèyàn burúkú wọlé wá, kí wọ́n lè ba ìjọ Kristẹni jẹ́. Nígbà tí Jòhánù tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì fi máa darúgbó, ìpẹ̀yìndà yìí ti fara hàn kedere.—2 Pét. 2:1-3; 1 Jòh. 2:18.
“Ẹ Jẹ́ Kí Àwọn Méjèèjì Dàgbà Pa Pọ̀ Títí Di Ìkórè”
8, 9. (a) Kí nìdí tí ìtọ́ni tí Ọ̀gá yẹn fún àwọn ẹrú rẹ̀ fi mọ́gbọ́n dání lójú àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀? (b) Nínú ìmúṣẹ àpèjúwe Jésù, báwo ni àlìkámà àti àwọn èpò ṣe dàgbà pa pọ̀?
8 Àwọn ẹrú Ọ̀gá náà sọ ohun tí wọ́n rí fún ọ̀gá wọn, wọ́n sì bi í pé: “Ìwọ ha fẹ́ kí àwa, nígbà náà, jáde lọ kí a sì kó [àwọn èpò náà] jọ?” (Mát. 13:27, 28) Ìdáhùn tó fún wọn lè dà bí ohun tó yani lẹ́nu. Ó sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí àlìkámà àti àwọn èpò náà dàgbà pa pọ̀ títí di ìgbà ìkórè. Ìdáhùn yẹn máa mọ́gbọ́n dání lójú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Torí wọ́n mọ bó ṣe máa ń ṣòro tó láti dá àlìkámà mọ̀ yàtọ̀ sí èpò. Àwọn tó lóye díẹ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ̀ pé ńṣe ni gbòǹgbò èpò máa ń lọ́ mọ́ gbòǹgbò ti àlìkámà. c Ìdí abájọ nìyẹn tí Ọ̀gá náà fi sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀!
9 Lọ́nà kan náà, láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èpò ti ń dàgbà nínú onírúurú ẹ̀ya ẹ̀sìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, bẹ̀rẹ̀ látorí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì títí dórí onírúurú àwùjọ ẹ̀sìn míì tó yapa kúrò lára wọn. Lákòókò yìí kan náà, à ń bá a nìṣó láti máa fún ìwọ̀nba ojúlówó irúgbìn àlìkámà sínú pápá náà, káàkiri ayé. Baálé ilé inú àpèjúwe náà fi sùúrù dúró jálẹ̀ àkókò gígùn tí irúgbìn fi máa ń dàgbà títí di àkókò ìkórè, tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gùn.
Ìgbà Ìkórè Tá A Ti Ń Fojú Sọ́nà fún Tipẹ́
10, 11. (a) Ìgbà wo ni àkókò ìkórè? (b) Báwo la ṣe ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà?
10 Jésù sọ fún wa pé: “Ìkórè ni ìparí ètò àwọn nǹkan, àwọn áńgẹ́lì sì ni akárúgbìn.” (Mát. 13:39) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí, iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ kan ń lọ lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ kó àwọn ọmọ Ìjọba náà jọ ká sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó dà bí èpò. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún wa nípa èyí pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run. Wàyí o, bí ó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wa, kí ni yóò jẹ́ òpin àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run?”—1 Pét. 4:17.
11 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, tàbí “ìparí ètò àwọn nǹkan” bẹ̀rẹ̀ tí ìdájọ́ fi bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ ojúlówó Kristẹni, láti lè mọ̀ bóyá “àwọn ọmọ ìjọba náà” ni wọ́n ní tòótọ́, àbí “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” ‘Lákọ̀ọ́kọ́’ Bábílónì Ńlá ṣubú, “lẹ́yìn náà” a kó àwọn ọmọ Ìjọba náà pa pọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè náà. (Mát. 13:30) Àmọ́, báwo la ṣe ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà? Àwọn tá a kórè wọ̀nyí wà nínú ìjọ Kristẹni tá a mú pa dà bọ̀ sípò, níbi tí wọ́n ti ń rí ojú rere àti ààbò Ọlọ́run, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ti gba èrè wọn ní ọ̀run.
12. Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí ìkórè náà tó parí?
12 Báwo ni ìdájọ́ náà ṣe pẹ́ tó? Jésù pe ìkórè náà ní “àsìkò,” èyí tó fi hàn pé ó ń bá a lọ fún àkókò gígùn kan. (Ìṣí. 14:15, 16) Ṣíṣe ìdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró á máa bá a nìṣó títí jálẹ̀ àkókò òpin. Ó di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì dì wọ́n, kó tó parí.—Ìṣí. 7:1-4.
13. Ọ̀nà wo ni àwọn èpò gbà ń fa ìkọ̀sẹ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe ń hùwà àìlófin?
13 Àwọn wo ni àwọn áńgẹ́lì máa kó jáde kúrò nínú Ìjọba náà, báwo ni wọ́n ṣe ń fa ìkọ̀sẹ̀ tí wọ́n sì tún ń hùwà àìlófin? (Mát. 13:41) Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn ni àwọn àlùfáà àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì, tí wọ́n dà bí èpò, ti ń ṣi ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́nà. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run, ìyẹn àwọn “ohun tí ń fa ìkọ̀sẹ̀,” irú bí ẹ̀kọ́ ìdálóró ayérayé nínú iná ọ̀run àpáàdì àti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí wọ́n pè ní àdììtú, tí wọ́n sì mú kó ṣòroó lóye. Ọ̀pọ̀ aṣáájú ẹ̀sìn ti fi àpẹẹrẹ búburú lélẹ̀ fún agbo wọn nítorí bí wọ́n ṣe ń ṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú ayé tí wọ́n sì tún ń lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe tó burú jáì láwọn ìgbà míì. (Ják. 4:4) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì túbọ̀ ń gba ìṣekúṣe láyè láàárín àwọn ọmọ ìjọ. (Ka Júúdà 4.) Pẹ̀lú gbogbo èyí, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa fi ara wọn hàn bí ẹni tó ní ìtara fún ìsìn tó sì tún ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ó tó ohun tí àwọn ọmọ Ìjọba náà ní láti máa yọ̀ sí pé a ti yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹ̀sìn tó fara jọ èpò àtàwọn ẹ̀kọ́ tó ń ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ tó sì tún ń fa ìkọ̀sẹ̀!
14. Báwo ni àwọn tó dà bí èpò ṣe ń sọkún tí wọ́n sì ń payín keke?
14 Báwo ni àwọn tó dà bí èpò ṣe ń sọkún tí wọ́n sì ń payín keke? (Mát. 13:42) “Àwọn ọmọ ẹni burúkú náà” ń joró ní ti pé “àwọn ọmọ ìjọba náà” ti tú àṣírí ẹ̀kọ́ onímájèlé táwọn tó dà bí èpò yìí fi ń kọ́ni. Wọ́n tún ń kédàárò torí pé àwọn ọmọ ìjọ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ kọ́wọ́ tì wọ́n mọ́, apá wọn ò sì ká àwọn ọmọ ìjọ.—Ka Aísáyà 65:13, 14.
15. Ọ̀nà wo la gbà sun àwọn tó dà bí èpò nínú iná?
15 Ọ̀nà wo la gbà ń kó àwọn èpò jọ tá a sì ń sun wọ́n nínú iná? (Mát. 13:40) Ńṣe lèyí ń tọ́ka sí ibi tí ọ̀rọ̀ àwọn èpò náà máa já sí. Sísọ wọn sínú ìléru oníná lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fi hàn pé ìparun ayérayé ni wọ́n forí lé. (Ìṣí. 20:14; ) Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́, tí wọ́n dà bí èpò, tí wọ́n sì tún jẹ́ afàwọ̀rajà, máa pa run yán-ányán-án nígbà “ìpọ́njú ńlá.”— 21:8Mát. 24:21.
Wọ́n “Yóò Máa Tàn Yòò bí Oòrùn”
16, 17. Kí ni Málákì sọ tẹ́lẹ̀ nípa tẹ́ńpìlì Jèhófà, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ sí nímùúṣẹ?
16 Ìgbà wo ni àwọn ẹni bí àlìkámà ń “tàn yòò bí oòrùn”? (Mát. 13:43) Málákì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí a ó ṣe fọ tẹ́ńpìlì Jèhófà mọ́, ó ní: “‘Olúwa tòótọ́ yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì Rẹ̀ lójijì, ẹni tí ẹ ń wá, àti ońṣẹ́ májẹ̀mú náà, ẹni tí ẹ ní inú dídùn sí. Wò ó! Dájúdájú, òun yóò wá,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. ‘Ṣùgbọ́n ta ni ó lè fara da ọjọ́ dídé rẹ̀, ta sì ni ẹni tí yóò dúró nígbà tí ó bá fara hàn? Nítorí òun yóò dà bí iná ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ọṣẹ ìfọṣọ alágbàfọ̀. Òun yóò sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà, tí ó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́, yóò sì fọ àwọn ọmọ Léfì mọ́; yóò sì mú wọn mọ́ kedere bí wúrà àti bí fàdákà, dájúdájú, wọn yóò di àwọn ènìyàn tí ń mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn wá fún Jèhófà nínú òdodo.’”—Mál. 3:1-3.
17 Lóde òní, ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí nímùúṣẹ lọ́dún 1918, nígbà tí Jèhófà àti “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà,” Jésù Kristi, bẹ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí wò. Málákì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí fífọ tẹ́ńpìlì mọ́ yìí parí. Ó sọ pé: “Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ tá a sọ agbára wọn dọ̀tun ṣe bọ́ sẹ́nu iṣẹ́ ní pẹrẹu nígbà yẹn fi hàn pé ìgbà yẹn gan-an ni àkókò ìkórè bẹ̀rẹ̀.
18. Kí ni Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa?
18 Wòlíì Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa pé: “Àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò sì máa tàn bí ìtànyòò òfuurufú; àwọn tí wọ́n sì ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo yóò máa tàn bí ìràwọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Dán. 12:3) Àwọn wo làwọn tó ń tàn yòò yìí? Ta ni wọn ì bá tún jẹ́ yàtọ̀ sáwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, àwọn ojúlówó àlìkámà tí Jésù sọ̀rọ̀ wọn nínú àpèjúwe àlìkámà àti àwọn èpò! Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, ẹni bí àgùntàn, tí iye wọn ń pọ̀ sí i, ti rí i kedere pé àwọn ayédèrú Kristẹni tí wọ́n dà bí èpò la ti ń ‘kó jáde kúrò.’ Torí náà, àwọn tó máa di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run wọ̀nyí dara pọ̀ mọ́ àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí, wọ́n sì ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tiwọn náà máa tàn yòò nínú ayé tó ṣókùnkùn yìí.—Sek. 8:23; Mát. 5:14-16; Fílí. 2:15.
19, 20. Kí ni “àwọn ọmọ ìjọba náà” ń fi ìháragàgà dúró dè, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Lónìí, “àwọn ọmọ ìjọba náà” ń fi ìháragàgà dúró de èrè ológo tí wọ́n ní ní ọ̀run. (Róòmù 8:18, 19; 1 Kọ́r. 15:53; Fílí. 1:21-24) Àmọ́, kó tó dìgbà yẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá ìṣòtítọ́ wọn nìṣó, kí wọ́n máa tàn yòò, kí wọ́n má sì ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà.” (Mát. 13:38; Ìṣí. 2:10) Inú gbogbo wa mà dùn o pé a láǹfààní láti rí àbájáde ‘kíkó’ àwọn èpò náà ‘jáde kúrò’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ní àkókò wa yìí!
20 Àmọ́, àjọse wo ló wà láàárín àwọn ọmọ Ìjọba náà àti ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń pọ̀ sí i, tí wọ́n nírètí láti máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn ìbéèrè yìí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa àwọn àpèjúwe yìí, wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2008, ojú ìwé 12 sí 21.
b Nínú àkàwé yìí, fífún irúgbìn kò ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, nípasẹ̀ èyí tí a ó fi mú àwọn ẹni tuntun tó máa di Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn wọlé wá. Ìdí ni pé Jésù kò sọ pé irúgbìn àtàtà tá a fún sínú pápá náà “máa di” àwọn ọmọ ìjọba náà. Ohun tó sọ ni pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ìjọba náà.” Torí náà, fífún irúgbìn yẹn dúró fún fífi ẹ̀mí yan àwọn ọmọ Ìjọba náà lórí ilẹ̀ ayé.
c Gbòǹgbò èpò tó máa ń ní irun lára yìí máa ń lọ́ mọ́ gbòǹgbò ti àlìkámà débi pé ẹni tó bá fẹ́ fà wọ́n tu ṣáájú àkókò ìkórè á wulẹ̀ fi àlìkámà ṣòfò ni.—Wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 1178.
Ǹjẹ́ O Rántí?
Nínú àpèjúwe Jésù nípa àlìkámà àti àwọn èpò, kí ni àwọn nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí?
• Irúgbìn àtàtà
• Ọkùnrin tó fún irúgbìn náà
• Fífún irúgbìn náà
• Ọ̀tá náà
• Àwọn èpò
• Àkókò ìkórè
• Ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́
• Sísọkún àti pípayínkeke
• Ìléru oníná
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ni fífún irúgbìn àtàtà náà bẹ̀rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ní báyìí, a ti ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.