Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Láti Sin Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Láti Sin Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Láti Sin Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I

“Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”—ONÍW. 12:1.

1. Kí la ké sí àwọn ọmọ kéékèèké ní Ísírẹ́lì láti ṣe?

 NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn, Mósè tó jẹ́ wòlíì Jèhófà pàṣẹ fún àwọn wòlíì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké . . . , kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́, bí wọn yóò ti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n sì kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ṣe.” (Diu. 31:12) Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọ kéékèèké la ké sí láti pé jọ fún ìjọsìn? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọmọdé pàápàá wà lára àwọn tá a sọ fún pé kí wọ́n fetí sílẹ̀, kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní jẹ òun lógún?

2 Ní ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó bẹ̀rù òun jẹ òun lógún. Bí àpẹẹrẹ, ó mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fi àwọn ìtọ́ni kan tó dìídì darí sí àwọn ọ̀dọ́ kún àwọn lẹ́tà kan tó kọ sáwọn ìjọ. (Ka Éfésù 6:1; Kólósè 3:20.) Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí dẹni tó túbọ̀ mọrírì Baba wọn ọ̀run onífẹ̀ẹ́, wọ́n sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà.

3. Báwo làwọn ọ̀dọ́ lóde òní ṣe ń fi hàn pé Ọlọ́run làwọn fẹ́ sìn?

3 Ṣé a tún ń ké sí àwọn ọmọdé lóde òní láti pé jọ kí wọ́n lè jọ́sìn Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni! Torí náà, ohun ayọ̀ ló jẹ́ fún gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run láti rí i pé jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sọ́kàn pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Héb. 10:24, 25) Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ń bá àwọn òbí wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Nítorí ìfẹ́ àtọkànwá tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní fún Jèhófà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ló ń ṣe ìrìbọmi lọ́dọọdún, wọ́n sì ń gbádùn àwọn ìbùkún tó ń wá látinú jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi.—Mát. 16:24; Máàkù 10:29, 30.

Dáhùn sí Ìkésíni Náà Nísinsìnyí

4. Ìgbà wo làwọn ọ̀dọ́ lè dáhùn sí ìkésíni Ọlọ́run pé kí wọ́n máa sin òun?

4 Ìwé Oníwàásù 12:1 sọ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” Báwo lẹ̀yin ọ̀dọ́ ṣe máa dàgbà tó kẹ́ ẹ tó lè dáhùn sí ìkésíni náà láti máa jọ́sìn Jèhófà kẹ́ ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ìwé Mímọ́ kò dá ọjọ́ orí kankan. Torí náà, ẹ má ṣe rò pé ẹ ti kéré jù láti fetí sí Jèhófà kẹ́ ẹ sì máa sìn ín, kẹ́ ẹ wá torí ìyẹn fà sẹ́yìn. Láìka ọjọ́ orí yín sí, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ dáhùn sí ìkésíni náà láìjáfara.

5. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?

5 Ọ̀pọ̀ lára yín ló jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn òbí yín ló ràn yín lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì lè jẹ́ àwọn òbí yín méjèèjì. Èyí mú kí ọ̀rọ̀ yín dà bíi ti Tímótì tí ìtàn rẹ̀ wà nínú Bíbélì. Ìgbà tó ti wà ní ọmọdé jòjòló ni ìyá rẹ̀ Yùníìsì àti ìyá ìyá rẹ̀ Lọ́ìsì ti ń kọ́ ọ ní Ìwé Mímọ́. (2 Tím. 3:14, 15) Ó ṣeé ṣe káwọn òbí tìrẹ náà máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí. Wọ́n lè máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n máa gbàdúrà pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n máa mú ẹ lọ sáwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ ńlá táwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe, kí wọ́n sì máa mú ẹ lọ sóde ẹ̀rí. Ká sòótọ́, ojúṣe tó ṣe pàtàkì gan-an tí Jèhófà gbé lé àwọn òbí rẹ lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n kọ́ ẹ ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o mọrírì ìfẹ́ wọn àti bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe jẹ wọ́n lógún yìí?—Òwe 23:22.

6. (a) Bí Sáàmù 110:3 ṣe sọ, irú ìjọsìn wo ni inú Jèhófà dùn sí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?

6 Síbẹ̀, bí ẹ̀yin ọ̀dọ́ ṣe ń dàgbà sí i, Jèhófà fẹ́ kí ẹ “ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé,” bí Tímótì ti ṣe. (Róòmù 12:2) Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, kì í ṣe nítorí pé àwọn òbí yín fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe nítorí pé ó wù yín láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Inú Jèhófà máa dùn bí ẹ bá fi ẹ̀mí ìmúratán sìn ín. (Sm. 110:3) Nígbà náà, báwo lẹ ṣe lè fi hàn pé ẹ fẹ́ mú kí ìfẹ́ yín láti máa fetí sí Jèhófà, kẹ́ ẹ sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ jinlẹ̀ sí i? A máa ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta tẹ́ ẹ lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n dá lórí ìkẹ́kọ̀ọ́, àdúrà àti ìwà yín. Ẹ jẹ́ ká gbé wọn yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ẹ Mọ Jèhófà Gẹ́gẹ́ bí Ẹnì Kan

7. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló sì ràn án lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

7 Ọ̀nà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ lè gbà fi hàn pé ẹ fẹ́ mú kí ìfẹ́ yín láti sin Jèhófà jinlẹ̀ sí i ni pé kẹ́ ẹ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ẹ lè tẹ́ àìní yín nípa tẹ̀mí lọ́rùn, kẹ́ ẹ sì ní ìmọ̀ Bíbélì tẹ́ ẹ bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (Mát. 5:3) Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lórí èyí. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá, àwọn òbí rẹ rí i nínú tẹ́ńpìlì níbi tó ti “jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” (Lúùkù 2:44-46) Láti ìgbà ọmọdé ni Jésù ti nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Mímọ́, ó sì lóye rẹ̀. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kò sí iyè méjì pé ipa pàtàkì tí Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ kó ló ràn án lọ́wọ́. Ìránṣẹ́ Ọlọ́run làwọn méjèèjì, wọ́n sì kọ́ Jésù lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọwọ́.—Mát. 1:18-20; Lúùkù 2:41, 51.

8. (a) Ìgbà wo ló yẹ kí àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká mọ àǹfààní tó wà nínú kíkọ́ àwọn ọmọ láti kékeré jòjòló.

8 Bákan náà, àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run lóde òní mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti gbin ìfẹ́ fún òtítọ́ Bíbélì sọ́kàn àwọn ọmọ wọn láti ìgbà kékeré jòjòló. (Diu. 6:6-9) Ohun tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Rubi ṣe nìyẹn ní gbàrà tó bí Joseph àkọ́bí rẹ̀. Ojoojúmọ́ ló máa ń ka Ìwé Ìtàn Bíbélì fún un. Bí ọmọ náà ti ń dàgbà, ìyá rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti há ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí. Ǹjẹ́ Joseph jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí? Kò pẹ́ lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ló ti lè sọ àwọn ìtàn inú Bíbélì lọ́rọ̀ ara rẹ̀. Nígbà tó sì wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

9. Kí nìdí tí kíka Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó o kà fi ṣe pàtàkì?

9 Láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ẹ̀yin ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ sọ ọ́ di àṣà yín láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ jálẹ̀ ìgbà ọ̀dọ́ yín títí tí ẹ fi máa dàgbà. (Sm. 71:17) Kí nìdí tí Bíbélì kíkà fi máa ràn yín lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú? Kíyè sí ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀. Ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú.” (Jòh. 17:3) Ní ti gidi, bó o ti túbọ̀ ń gba ìmọ̀ Jèhófà sínú, á túbọ̀ wá ṣe kedere sí ẹ pé Ẹni gidi kan ni, wàá sì mú kí ìfẹ́ tó o ní fún un lágbára sí i. (Héb. 11:27) Torí náà, ìgbàkígbà tó o bá ti ka ibì kan nínú Bíbélì, lo àǹfààní yẹn láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ẹnì kan? Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi àti pé ọ̀rọ̀ mi jẹ ẹ́ lógún?’ Tó o bá ń ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí, á jẹ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àtohun tó ń retí látọ̀dọ̀ rẹ. (Ka Òwe 2:1-5.) Bíi ti Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́, a ó lè ‘yí ọ lérò padà láti ní ìgbàgbọ́’ nínú àwọn ohun tó o kọ́ nínú Ìwé Mímọ́, ìyẹn á sì sún ẹ láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn.—2 Tím. 3:14.

Bí Àdúrà Ṣe Lè Mú Ìfẹ́ Rẹ fún Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I

10, 11. Báwo ni àdúrà rẹ ṣe lè mú kí ìfẹ́ tó o ní láti sin Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i?

10 Ọ̀nà kejì tó o lè gbà mú kí ìfẹ́ tó o ní láti máa sin Jèhófà tọkàntọkàn jinlẹ̀ sí i ni pé kó o máa gbàdúrà. Nínú Sáàmù 65:2, a kà pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.” Kódà lákòókò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà lè gbàdúrà sí Ọlọ́run. (1 Ọba 8:41, 42) Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Ó dá àwọn tó ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ lójú pé ó máa gbọ́ tiwọn. (Òwe 15:8) Ó dájú pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ náà wà lára “àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo.”

11 O mọ̀ pé tó o bá fẹ́ kí àárín ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ gún, ẹ ní láti máa bá ara yín sọ̀rọ̀ dáadáa. Ó ṣeé ṣe kó máa wù ẹ́ láti sọ èrò rẹ, ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́. Bákan náà, tó o bá ń gbàdúrà látọkànwá, ńṣe lò ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá sọ̀rọ̀. (Fílí. 4:6, 7) Máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ bí ìgbà tó ò ń sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́. Ká sòótọ́, èrò tó o ní nípa Jèhófà máa hàn nínú bó o ṣe ń gbàdúrà sí i. Wàá rí i pé bí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà bá ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ ni àdúrà rẹ á ṣe máa nítumọ̀ tó.

12. (a) Kí nìdí tí àdúrà tó nítumọ̀ fi kọjá kéèyàn kàn máa sọ ohun kan ṣá? (b) Kí ló máa jẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà kò jìnnà sí ẹ?

12 Máa fi sọ́kàn pé, àdúrà tó nítumọ̀ kọjá pé kó o kàn máa sọ ohun kan ṣá. Ó kan èrò inú rẹ lọ́hùn-ún. Nínú àdúrà rẹ, máa fi hàn pé o ní ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti pé o fọkàn tán an. Bó o ṣe ń fòye mọ bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà rẹ, á wá túbọ̀ yé ẹ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sm. 145:18) Ó dájú pé Jèhófà á sún mọ́ ẹ, á sì fún ẹ lókun láti kọjú ìjà sí Èṣù, kó o sì ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Ka Jákọ́bù 4:7, 8.

13. (a) Báwo ni jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ṣe ran arábìnrin kan lọ́wọ́? (b) Báwo ni jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ṣe ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?

13 Wo bí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Cherie ṣe ní okun látinú àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ní pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tó wà níléèwé girama, ó gba ẹ̀bùn torí pé ó ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì tayọ nínú eré ìdárayá. Lẹ́yìn tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, èyí táá jẹ́ kó lè lọ sí ilé ìwé gíga. Cherie sọ pé: “Àdánwò ńlá ni ẹ̀bùn yìí, àwọn tó ń kọ́ wa léré ìdárayá àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi sì fúngun mọ́ mi pé kí n gbà á.” Àmọ́, ó mọ̀ pé tí òun bá ní kí òun tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ òun, ó máa gba pé kóun máa fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò òun kàwé kóun sì máa múra sílẹ̀ fún eré ìdárayá, èyí ò sì ní jẹ́ kí òun fi bẹ́ẹ̀ ní àyè fún ìjọsìn Jèhófà. Kí ló wá ṣe? Cherie sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti gbàdúrà sí Jèhófà, mo kọ ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.” Ó ti tó ọdún márùn-ún báyìí tó ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ pé: “Mi ò kábàámọ̀ kankan. Inú mi máa ń dùn torí mo mọ̀ pé ìpinnu tó dùn mọ́ Jèhófà nínú ni mo ṣe. Dájúdájú, tó o bá fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, àwọn ohun yòókù ni a ó fi kún un fún ẹ.”—Mát. 6:33.

Ìwà Rere Ń Fi Hàn Pé O Ní “Ọkàn-Àyà Tó Mọ́”

14. Kí nìdí tí ìwà rere rẹ fi ṣe pàtàkì lójú Jèhófà?

14 Ọ̀nà kẹta tó o lè gbà fi hàn pé ò ń sin Jèhófà tọkàntọkàn jẹ́ nípa ìwà rẹ. Jèhófà máa ń bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ oníwà mímọ́. (Ka Sáàmù 24:3-5.) Nígbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́dọ̀ọ́, ó kọ̀ láti fara wé ìwàkíwà àwọn ọmọ Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà. Ìwà rere Sámúẹ́lì kò sì pa mọ́ lójú Jèhófà. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.”—1 Sám. 2:26.

15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tó o fi ń hùwà tó dára?

15 Inú ayé tó kún fún àwọn èèyàn tó jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, onírera, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, òǹrorò, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, là ń gbé, èyí sì jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ìwà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (2 Tím. 3:1-5) Torí náà, ó lè ṣòro fún ẹ láti máa hùwà tó dára, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwà burúkú lò ń rí ní àyíká rẹ. Àmọ́, ní gbogbo ìgbà tó o bá ṣe ohun tó tọ́, tó o sì kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ìwà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí, ńṣe lò ń fi hàn pé Jèhófà lo fara mọ́ nínú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Job 2:3, 4) Ọkàn rẹ á tún balẹ̀ bó o ti mọ̀ pé ńṣe lò ń ṣe ohun tí Jèhófà rọ̀ wá pé ká ṣe nígbà tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Síwájú sí i, bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà tẹ́wọ́ gbà ẹ́ máa fún ẹ lókun láti mú ìpinnu rẹ ṣẹ pé wàá máa sìn ín.

16. Báwo ni arábìnrin kan ṣe mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀?

16 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Carol, máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nígbà tó wà níléèwé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, síbẹ̀ àwọn èèyàn kíyè sí ìwà rere rẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ máa ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́, torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ kì í jẹ́ kó bá wọn lọ́wọ́ sí àwọn ọdún àtàwọn ayẹyẹ míì tí wọ́n máa ń ṣe. Láwọn àkókò yẹn, ó máa ń láǹfààní láti ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Carol gba káàdì ìkíni kan látọ̀dọ̀ ẹnì kan tí wọ́n jọ lọ síléèwé, ohun tó kọ síbẹ̀ rèé: “Ó ti máa ń wù mí láti kàn sí ẹ, kí n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ. Mo máa ń kíyè sí ìwà rere rẹ àti àpẹẹrẹ rere rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni, àti bó o ṣe máa ń fìgboyà kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ tá a máa ń ṣe. Ìwọ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà àkọ́kọ́ tí mo bá pàdé.” Àpẹẹrẹ rere Carol wọ ọmọ iléèwé rẹ̀ yìí lọ́kàn débi pé nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kọ ọ́ sínú káàdì tó fi ránṣẹ́ sí Carol pé ó ti lé ní ogójì [40] ọdún báyìí tí òun ti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bíi ti Carol, ìwà rere ẹ̀yin ọ̀dọ́ tó ń fìgboyà rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì lóde òní lè mú kí àwọn èèyàn tó jẹ́ ọlọ́kàn títọ́ mọ Jèhófà.

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Yin Jèhófà

17, 18. (a) Báwo lọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ yín ṣe rí lára rẹ? (b) Àwọn ìbùkún wo làwọn ọ̀dọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú?

17 Ó máa ń mú gbogbo àwa tá a wà nínú ètò Jèhófà tó kárí ayé lórí yá láti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ onítara tó ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tòótọ́! Àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí máa ń mú kí ìfẹ́ wọn láti sin Jèhófà jinlẹ̀ sí i nípasẹ̀ kíka Bíbélì lójoojúmọ́, gbígbàdúrà àti híhùwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ìtura ńlá ni irú àwọn ọ̀dọ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún àwọn òbí wọn àti gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà.—Òwe 23:24, 25.

18 Lọ́jọ́ iwájú, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ á wà lára àwọn tó máa là á já bọ́ sínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Ìṣí. 7:9, 14) Níbẹ̀, bí ìmọrírì tí wọ́n ní fún Jèhófà bá ṣe ń pọ̀ sí i, wọ́n á máa gbádùn ìbùkún lọ́pọ̀ yanturu, á sì ṣeé ṣe fún wọn láti máa yin Jèhófà títí láé fáàbàdà.—Sm. 148:12, 13.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè máa lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tòótọ́ lóde òní?

• Kó o lè máa jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà, kí nìdí tí ṣíṣe àṣàrò fi ṣe pàtàkì?

• Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà?

• Tí Kristẹni kan bá ní ìwà rere, àǹfààní wo ló lè tibẹ̀ wá?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ṣé ó ti mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?