Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Nínú Bí Ète Jèhófà Ṣe Ń Ní Ìmúṣẹ

Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Nínú Bí Ète Jèhófà Ṣe Ń Ní Ìmúṣẹ

Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Nínú Bí Ète Jèhófà Ṣe Ń Ní Ìmúṣẹ

“Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò . . . ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—AÍSÁ. 55:11.

1. Ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwéwèé àti ète.

 FOJÚ inú wo àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n fẹ́ gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rìnrìn àjò. Ẹni àkọ́kọ́ ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀nà kan ṣoṣo tó mọ̀ pé òun lè gbà débi tí òun ń lọ. Ẹnì kejì mọ ibi tó ń lọ dáadáa, ó sì tún mọ àwọn ọ̀nà míì tó lè gbà débẹ̀. Bí ọ̀nà kan ò bá ṣeé gbà mọ́, ó ti múra tán láti gba ibòmíì. A lè fi ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí gbà múra ìrìn àjò wọn ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwéwèé àti ète. A lè fi ìwéwèé ṣàpẹẹrẹ pé kéèyàn ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀nà kan ṣoṣo tó lè gbà débì kan, ète sì gba pé kéèyàn mọ ibi tó ń lọ dáadáa, kó sì tún mọ àwọn ọ̀nà míì tó lè gbà débẹ̀.

2, 3. (a) Kí ni ète Jèhófà wé mọ́, báwo sì ni Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀ràn tó wáyé nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́sẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń mú ète rẹ̀ ṣẹ?

2 Ní ti Jèhófà, tó bá dọ̀rọ̀ kó mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, kì í wéwèé nǹkan lọ́nà tí kò ṣeé yí pa dà, ńṣe ló máa ń mú ète rẹ̀ ṣẹ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. (Éfé. 3:11) Ète Jèhófà yìí wé mọ́ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé, ìyẹn ni pé kí gbogbo ayé di Párádísè, níbi tí àwọn èèyàn pípé á máa gbé ní àlàáfíà tí wọ́n á sì máa láyọ̀ títí láé. (Jẹ́n. 1:28) Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, ó sì ṣètò tó máa jẹ́ kí ète rẹ̀ ní ìmúṣẹ. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15.) Jèhófà pinnu pé obìnrin rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ á mú “irú-ọmọ” kan tàbí Ọmọkùnrin kan jáde, ẹni tó máa pa Sátánì tó dá ìwà ibi sílẹ̀ run, tó sì máa mú gbogbo láburú tí Sátánì ti fà kúrò.—Héb. 2:14; 1 Jòh. 3:8.

3 Kò sí agbára kankan lọ́run tàbí láyé tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ pé kó má ṣe mú ète rẹ̀ ṣẹ. (Aísá. 46:9-11) Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ náà kan ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ẹ̀mí mímọ́ tí kò sí ohun tó lè dá a dúró yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé ète Ọlọ́run “yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú.” (Aísá. 55:10, 11) Ó dára gan-an ká mọ bí ète Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀-lé. Ìwàláàyè wa ọjọ́ iwájú sinmi lórí ìmúṣẹ àwọn ète Ọlọ́run. Láfikún sí ìyẹn, bí Jèhófà ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí ẹ̀mí mímọ́ kó nínú bí ète Jèhófà ṣe ní ìmúṣẹ láyé àtijọ́, ipa tó ń kó lóde òní àti ipa tó máa kó lọ́jọ́ iwájú.

Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Kó Láyé Àtijọ́

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣí ète rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?

4 Ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ni Jèhófà ń ṣí ète rẹ̀ payá lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Níbẹ̀rẹ̀, kò rọrùn láti dá Irú-ọmọ tá a ṣèlérí náà mọ̀, “àṣírí ọlọ́wọ̀” ló jẹ́. (1 Kọ́r. 2:7) Ẹgbàá [2,000] ọdún ti kọjá lẹ́yìn náà kí Jèhófà tó tún mẹ́nu ba irú-ọmọ náà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 12:7; 22:15-18.) Jèhófà wá ṣèlérí tó máa ní ìmúṣẹ gbígbòòrò fún Ábúráhámù. Gbólóhùn náà, “nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ” jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Irú-ọmọ náà máa wá gẹ́gẹ́ bí èèyàn àti pé yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Ó yẹ kó dá wa lójú pé tọkàn tara ni Sátánì á fi máa wò ó bí Ọlọ́run ṣe ń ṣí àṣírí náà payá. Kò sí iyè méjì pé ohun tí Elénìní náà ń fẹ́ ni pé kó ba ìlà ìran tí Irú-ọmọ náà á ti wá jẹ́ tàbí kó dà á rú, kí ète Ọlọ́run má bàa ní ìmúṣẹ. Àmọ́, irú ẹ̀ kò lè ṣẹlẹ̀ láé torí pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́. Lọ́nà wo?

5, 6. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ẹ̀mí rẹ̀ láti dáàbò bo ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìlà ìdílé tí Irú-ọmọ náà ti wá?

5 Jèhófà lo ẹ̀mí rẹ̀ láti dáàbò bo ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìlà ìdílé tí Irú-ọmọ náà ti wá. Jèhófà sọ fún Ábúrámù (Ábúráhámù) pé: “Èmi jẹ́ apata fún ọ.” (Jẹ́n. 15:1) Èyí kì í ṣe àsọdùn lásán. Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tó wáyé ní nǹkan bí ọdún 1919 ṣáájú Sànmánì Kristẹni yẹ̀ wò, nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà di àtìpó nílẹ̀ Gérárì. Ábímélékì tó jẹ́ ọba Gérárì kò mọ̀ pé ìyàwó Ábúráhámù ni Sárà jẹ́, ló bá mú Sára láti fi ṣe aya. Ṣé Sátánì ló wà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ yìí, kó lè ṣèdíwọ́ fún Sárà kó má bàa bí irú-ọmọ náà fún Ábúráhámù? Bíbélì kò sọ fún wa. Ohun tó kàn sọ fún wa ni pé Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó kìlọ̀ fún Ábímélékì lójú àlá pé kó má ṣe fọwọ́ kan Sárà.—Jẹ́n. 20:1-18.

6 Ìgbà yìí nìkan kọ́ ni Jèhófà dáàbò bò wọ́n o. Jèhófà gba Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. (Jẹ́n. 12:14-20; 14:13-20; 26:26-29) Ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi sọ nípa Ábúráhámù àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ pé: “[Jèhófà] kò gba ẹ̀dá ènìyàn kankan láyè láti lù wọ́n ní jìbìtì, ṣùgbọ́n ó fi ìbáwí tọ́ àwọn ọba sọ́nà ní tìtorí wọn, pé: ‘Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, ẹ má sì ṣe ohun búburú kankan sí àwọn wòlíì mi.’”—Sm. 105:14, 15.

7. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà dáàbò bo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?

7 Jèhófà lo ẹ̀mí rẹ̀ láti dáàbò bo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, níbi tí wọ́n máa bí Irú-ọmọ náà sí. Jèhófà lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin, èyí ló pa ìjọsìn tòótọ́ mọ́, kò sì tún jẹ́ kí àwọn Júù di ẹlẹ́gbin nípa tẹ̀mí, ní ti ìwà híhù àti nípa tara. (Ẹ́kís. 31:18; 2 Kọ́r. 3:3) Lákòókò àwọn Onídàájọ́, ẹ̀mí Jèhófà fún àwọn ọkùnrin kan lágbára láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. (Oníd. 3:9, 10) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù, tó jẹ́ apá pàtàkì lára irú-ọmọ Ábúráhámù, ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ kó ipa pàtàkì nínú dídáàbò bo ìlú Jerúsálẹ́mù, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti tẹ́ńpìlì, gbogbo èyí ló sì máa kó ipa pàtàkì nínú mímú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù ṣẹ.

8. Kí ló fi hàn pé ìgbésí ayé Ọmọ Ọlọ́run àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kò ṣẹ̀yìn ẹ̀mí mímọ́?

8 Ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kò ṣẹ̀yìn ẹ̀mí mímọ́. Nínú ilé ọmọ Màríà wúńdíá, ẹ̀mí mímọ́ ṣe ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí tàbí tí kò tún tíì wáyé láti ìgbà náà wá. Ó mú kí Màríà tó jẹ́ èèyàn aláìpé lóyún, ó sì bí Ọmọ pípé, tí kò sí lábẹ́ ẹ̀bi ikú. (Lúùkù 1:26-31, 34, 35) Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ dáàbò bo ọmọ jòjòló náà Jésù lọ́wọ́ ikú àìtọ́jọ́. (Mát. 2:7, 8, 12, 13) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án gẹ́gẹ́ bí ajogún ìtẹ́ Dáfídì ó sì tún gbé iṣẹ́ ìwàásù lé e lọ́wọ́. (Lúùkù 1:32, 33; 4:16-21) Ẹ̀mí mímọ́ fún Jésù lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu, tó fi mọ́ wíwo àwọn aláìsàn, bíbọ́ ogunlọ́gọ̀ àti jíjí òkú dìde. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ìbùkún tí à ń retí nígbà tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso.

9, 10. (a) Kí ló mú kó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Kí ló wáyé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, tó jẹ́ ká mọ bí ète Jèhófà ṣe ń ní ìmúṣẹ?

9 Láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yan apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù, ọ̀pọ̀ lára wọn kì í sì í ṣe àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. (Róòmù 8:15-17; Gál. 3:29) Ó tún ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní, ó mú kí wọ́n lè fi ìtara wàásù, ó sì tún fún wọn lágbára láti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. (Ìṣe 1:8; 2:1-4; 1 Kọ́r. 12:7-11) Nípasẹ̀ àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu yìí, ẹ̀mí mímọ́ ṣí apá kan tó pabanbarì lára ọ̀nà tí ète Jèhófà gbà ń ní ìmúṣẹ payá. Jèhófà kò lo ìṣètò tó ń lò tẹ́lẹ̀ pé kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn òun nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù mọ́. Ó ti wá yí ojú rere rẹ̀ sí ìjọ Kristẹni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Látìgbà yẹn wá sì ni Jèhófà ti ń lo ìjọ tó fi ẹ̀mí yàn yìí láti mú ète rẹ̀ ṣẹ.

10 Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bí Jèhófà ṣe lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún wọn lágbára àti láti fi àmì òróró yàn wọ́n, jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó gbà fi hàn pé ète òun á máa bá a nìṣó títí tó fi máa ní ìmúṣẹ. Ní àkókò tí a wà yìí ńkọ́? Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti mú ète rẹ̀ ṣẹ? Ó yẹ ká mọ̀, torí pé a fẹ́ máa ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò mẹ́rin lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lóde òní.

Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Kó Lóde Òní

11. Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́, báwo lo sì ṣe lè fi hàn pé ò ń jẹ́ kó máa darí rẹ?

11 Àkọ́kọ́, ẹ̀mí mímọ́ ń mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run wà ní mímọ́. Àwọn tó bá ń sin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀, gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwà mímọ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.) Kí àwọn kan tó di Kristẹni, wọ́n ti lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà tí kò dára, irú bí àgbèrè, panṣágà, kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀. Ìfẹ́ ọkàn tó máa ń bí ẹ̀ṣẹ̀ lè fìdí rinlẹ̀ gbọin-gbọin lọ́kàn ẹni. (Ják. 1:14, 15) Síbẹ̀, a ti ‘wẹ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́,’ èyí tó fi hàn pé wọ́n ti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn kí wọ́n lè wu Ọlọ́run. Kí ló ń mú kí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kẹ́sẹ járí láti dènà ìfẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́? Ìwé 1 Kọ́ríńtì 6:11, sọ pé: “Ẹ̀mí Ọlọ́run wa” ni. Tá a bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ oníwà mímọ́, a ó máa fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí wa.

12. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, báwo ni Jèhófà ṣe ń darí ètò rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí rẹ?

12 Ìkejì, Jèhófà ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti darí ètò rẹ̀ sí ibi tó bá fẹ́ kó lọ. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, a fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run tí kò ṣeé dá dúró bó ti ń lọ láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ, ṣàpẹẹrẹ apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. Kí ló ń darí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run yìí gba apá ibì kan pàtó? Ẹ̀mí Mímọ́ ni. (Ìsík. 1:20, 21) Ẹ má ṣe gbàgbé pé apá méjì ni ètò Jèhófà pín sí, apá ti ọ̀run àti apá ti orí ilẹ̀ ayé. Bó bá jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí apá ti ọ̀run, a jẹ́ pé òun náà ló ń darí apá ti orí ilẹ̀ ayé nìyẹn. Tá a bá ń ṣègbọràn sí apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Ọlọ́run, tá a sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ń fún wa, ńṣe là ń fi hàn pé à ń bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run Jèhófà rìn, a sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí wa.—Héb. 13:17.

13, 14. (a) Àwọn wo ló para pọ̀ di “ìran yìí” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Fúnni ni àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé bí ìyípadà ṣe ń bá òye tá a ní nípa òtítọ́ Bíbélì kò ṣẹ̀yìn ẹ̀mí mímọ́. (Wo àpótí náà, “Ṣé Ò Ń Fọkàn sí Òtítọ́ Tó Túbọ̀ Ń Ṣe Kedere?”)

13 Ìkẹta, ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere sí wa. (Òwe 4:18) Ọjọ́ pẹ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ń lo ìwé ìròyìn yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà pàtàkì láti máa ṣí àwọn òtítọ́ inú Bíbélì payá. (Mát. 24:45) Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò oyè tá a ní nípa àwọn tó para pọ̀ jẹ́ “ìran yìí” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Ka Mátíù 24:32-34.) Ìran wo ni Jésù ń tọ́ka sí? Àpilẹ̀kọ náà, Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé Ọ Sí? ṣàlàyé pé kì í ṣe àwọn èèyàn burúkú ni Jésù ń tọ́ka sí, bí kò ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó máa tó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn. a Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí a fi ẹ̀mí bí, ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní, ni wọ́n máa rí àmì náà, tí wọ́n á sì tún fi òye mọ̀ pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jésù “ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.”

14 Báwo ni àlàyé yìí ṣe yé wa sí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè mọ bí “ìran yìí” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ á ṣe wà pẹ́ tó, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì ká fi àwọn nǹkan kan sọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ náà “ìran”: Ìran sábà máa ń túmọ̀ sí àwọn èèyàn kan tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, àmọ́ tí wọ́n jọ gbé ayé láàárín àkókò kan náà; àkókò yìí lè ṣaláì gùn jàn-ànràn-jan-anran, ó sì máa ń ní òpin. (Ẹ́kís. 1:6) Nígbà náà, báwo ló ṣe yẹ ká lóye ohun tí Jésù sọ nípa “ìran yìí”? Ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ẹni àmì òróró tí ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà máa ṣojú wọn ṣì máa gbé ayé lákòókò kan pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró tó rí àmì náà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Ìran yẹn ní ìbẹ̀rẹ̀, ó sì dájú pé ó máa ní òpin. Bí onírúurú apá tí àmì náà pín sí ṣe ń ní ìmúṣẹ jẹ́ ẹ̀rí pé ìpọ́njú náà ti sún mọ́lé. Tó o bá ń ṣe nǹkan lọ́nà tó fi hàn pé àkókò kánjúkánjú la wà yìí, tó o sì ń bá a nìṣó láti máa ṣọ́nà, ńṣe lò ń fi hàn pé ò ń fọkàn sí i bí ìyípadà ṣe ń bá òye tá a ní nípa òtítọ́ Bíbélì, o sì ń tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́.—Máàkù 13:37.

15. Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń fún wa lágbára láti máa polongo ìhìn rere?

15 Ìkẹrin, ẹ̀mí mímọ́ ń fún wa lágbára láti polongo ìhìn rere. (Ìṣe 1:8) Kí ló ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà jákèjádò ayé? Rò ó wò ná. Ó ṣeé ṣe kó o wà lára àwọn tí ìbẹ̀rù tàbí ìtìjú ti mú kí wọ́n sọ nígbà kan rí pé, ‘Mi ò lè wàásù láti ilé dé ilé láé!’ Àmọ́ ní báyìí, o ti wá ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ náà. b Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù, kódà lójú àtakò àti inúnibíni. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run nìkan ló lè fún wa lágbára láti borí àwọn ohun ìdènà tó lè múni rẹ̀wẹ̀sì, ká sì ṣe ohun tó kọjá agbára àwa ẹ̀dá èèyàn. (Míkà 3:8; Mát. 17:20) Tó o bá ń kópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe lò ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ yẹn.

Ipa Tí Ẹ̀mí Mímọ́ Máa Kó Lọ́jọ́ Iwájú

16. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá?

16 Lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kó lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ààbò. A ti wá rí i báyìí pé Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nígbà àtijọ́ láti dáàbò bo ẹnì kọ̀ọ̀kan àti gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀. Torí náà, ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà á tún lo ẹ̀mí rẹ̀ tó lágbára yìí láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ yìí. Kò yẹ ká máa méfò lórí bí Jèhófà ṣe máa bójú tó wa nígbà yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè ní ìgbọ́kànlé pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára, ká sì mọ̀ pé ojú Jèhófà tó gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kò sì síbi tí wọ́n wà tí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kò lè dé.—2 Kíró. 16:9; Sm. 139:7-12.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nínú ayé tuntun?

17 Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nínú ayé tuntun tó ń bọ̀? Ẹ̀mí mímọ́ yìí ló máa mú kó ṣeé ṣe láti ṣí àwọn àkájọ ìwé tuntun sílẹ̀. (Ìṣí. 20:12) Kí ló máa wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà? Ìsọfúnni kíkún nípa àwọn ohun tí Jèhófà á fẹ́ ká máa ṣe nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso náà ló máa wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ò ń fojú sọ́nà láti yẹ àwọn ohun tó wà nínú àkájọ ìwé náà wò? À ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún ayé tuntun náà. A kò tíì lè sọ bó ṣe máa ládùn tó láti máa gbé lákòókò ìbùkún yẹn, nígbà tí Jèhófà á máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú ète rẹ̀ fún ayé àtàwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀ ṣẹ.

18. Ìpinnu tó fìdí múlẹ̀ wo lo ṣe?

18 Ká má ṣe gbàgbé láé pé àwọn ohun tí Jèhófà ń ṣí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ máa ní ìmúṣẹ láìkùnà, torí pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tó lágbára jù lọ láyé àtọ̀run ló ń lò láti ṣí wọn payá. Ète Ọlọ́run ò yọ ìwọ náà sílẹ̀ o. Torí náà, ṣe ìpinnu tó fìdí múlẹ̀ láti máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà kó lè fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè nírètí láti máa gbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé bí Jèhófà ṣe pète rẹ̀ fún ìran èèyàn.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Tó o bá fẹ́ mọ ẹnì kan tó borí ìtìjú tó kọjá sísọ tó sì dí onítara lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1993, ojú ìwé 19.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì láti mú kí ète rẹ̀ máa ní ìmúṣẹ?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹ̀mí rẹ̀ lóde òní?

• Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láti mú ète rẹ̀ ṣẹ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣé Ò Ń Fọkàn sí Òtítọ́ Tó Túbọ̀ Ń Ṣe Kedere?

Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa fi òye ọ̀rọ̀ rẹ̀ yé àwọn èèyàn rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tá a ti tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́?

▪ Ẹ̀kọ́ àtàtà wo ni àkàwé Jésù nípa ìwúkàrà kọ́ wa nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? (Mát. 13:33)—July 15, 2008, ojú ìwé 19 sí 20.

▪ Ìgbà wo ni pípe àwọn Kristẹni tó nírètí àtilọ sọ́run dáwọ́ dúró?—May 1, 2007, ojú ìwé 30 sí 31.

▪ Kí ló túmọ̀ sí láti sin Jèhófà “ní ẹ̀mí”? (Jòh. 4:24)—July 15, 2002, ojú ìwé 15.

▪ Inú àgbàlá wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti ń sìn? (Ìṣí. 7:15)—May 1, 2002, ojú ìwé 30 sí 31.

▪ Ìgbà wo ni yíya àgùntàn àti ewúrẹ́ sọ́tọ̀ wáyé? (Mát. 25:31-33)—October 15, 1995, ojú ìwé 18 sí 28.