Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Kí nìdí tí Mèsáyà fi ní láti kú?

Ikú Jésù fi hàn pé ẹ̀dá pípé lè máa gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu bó tilẹ̀ ń fojú winá ìdánwò gbígbóná janjan. Bákan náà, ó san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ táwa ọmọ Ádámù jogún, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣí àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀.—12/15, ojú ìwé 22 sí 23.

• Kí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti máa lo ọtí bó ṣe yẹ?

Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè ṣèrànwọ́. Ìkóra-ẹni-níjàánu, dídúró lórí ìpinnu téèyàn bá ṣe àti yíyan àwọn ọ̀rẹ́ rere tún ṣe pàtàkì. Ẹni tó bá yàn láti máa mutí gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu pàtó, kó sì mọ bá a ṣe ń sọ pé mi ò fẹ́.—1/1, ojú ìwé 7 sí 9.

• Kí ló ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ gbádùn mọ́ àwọn ọmọdé?

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kọjá kéèyàn wulẹ̀ máa bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀, ó gba pé kéèyàn máa bi wọ́n ní ìbéèrè kó sì máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìdáhùn wọn. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé àwọn máa ń láǹfààní láti jọ sọ àwọn nǹkan tó lè wúlò fún àwọn ní àkókò oúnjẹ.—1/15, ojú ìwé 18 sí 19.

• Báwo ni Jèhófà tó jẹ́ ẹni pípé ṣe lè kẹ́dùn?

Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń yí ìwà tó ń hù sáwọn èèyàn pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ fi Jèhófà sílẹ̀ tí wọ́n sì tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn. Torí náà, Jèhófà fa ọwọ́ ààbò rẹ̀ sẹ́yìn lọ́dọ̀ wọn. Àmọ́, nígbà tí àwọn èèyàn náà kábàámọ̀ ohun tí wọ́n ṣe, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó yí ọkàn pa dà, ìyẹn ni pé ó “kẹ́dùn.” (Oníd. 2:18)—2/1, ojú ìwé 21.

• Kí ló lè mú kí ẹnì kan sọ pé òun fẹ́ tún ìrìbọmi ṣe?

Ẹnì kan lè sọ pé òun fẹ́ tún ìrìbọmi ṣe bó bá jẹ́ pé nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣèrìbọmi, ó ti ń gbé ní ipò kan tàbí kó máa dá àwọn àṣà kan tó jẹ́ pé bí wọ́n bá ká irú ẹ̀ mọ́ ẹni tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́ ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́.—2/15, ojú ìwé 22.

• Ohun mẹ́ta wo làwọn kan sábà máa ń fi àṣìṣe sọ pé ó fà á táwọn fi hùwà àìṣòótọ́?

Àwọn kan máa ń dá olè tí wọ́n jà láre torí pé wọ́n jẹ́ aláìní. Àwọn míì máa ń dá olè jíjà láre nípa sísọ pé, “Gbogbo èèyàn ló ń ṣe é.” Àwọn míì máa ń ronú pé, “ẹní rí nǹkan he ìfà tiẹ̀ ni.” Bíbélì ò gbà pé a lè torí ohun mẹ́ta yìí dá olè jíjà láre.—3/1, ojú ìwé 12 sí 14.

• Nínú àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti àwọn èpò, kí ni fífún tàbí gbígbin irúgbìn àtàtà ṣàpẹẹrẹ?

Nígbà tí Jésù tó jẹ́ Ọmọ ènìyàn wà lórí ilẹ̀ ayé ló ṣètò pápá náà sílẹ̀. Láti Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, fífún irúgbìn àtàtà náà wáyé nígbà tí Jésù fi ẹ̀mí yan àwọn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ọmọ Ìjọba náà.—3/15, ojú ìwé 20.

• Báwo la ṣe ń kó àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ inú àkàwé Jésù wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà? (Mát. 13:30)

Àkàwé yìí ní ìmúṣẹ jálẹ̀ àkókò gígùn nígbà ìparí ètò àwọn nǹkan. Àwọn ọmọ Ìjọba náà tá a fẹ̀mí yàn, ìyẹn àwọn àlìkámà ìṣàpẹẹrẹ, là ń kó sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ Jèhófà nígbà tá a bá gbà wọ́n sínú ìjọ Ọlọ́run tá a mú pa dà bọ̀ sípò tàbí nígbà tí wọ́n bá gba èrè wọn ní ọ̀run.—3/15, ojú ìwé 22.

Àwọn wo ló ṣàkójọ àwọn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pé wọ́n ní ìmísí Ọlọ́run?

Kì í ṣe àwọn ìgbìmọ̀ kan nínú Ṣọ́ọ̀ṣì tàbí àwọn olórí ìsìn ló ṣàkójọ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló darí àwọn Kristẹni tòótọ́ láti dá àwọn ìwé náà mọ̀ pé Ọlọ́run ló mí sí wọn ní tòótọ́. Èyí sì bá a mu torí pé láàárín ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀, ọ̀kan lára ẹ̀bùn ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún ìjọ Kristẹni lọ́nà ìyanu ni “fífi òye mọ àwọn àsọjáde onímìísí.” (1 Kọ́r. 12:4, 10)—4/1, ojú ìwé 28.