Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Obìnrin, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Tẹrí Ba Fún Ipò Orí?

Ẹ̀yin Obìnrin, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Tẹrí Ba Fún Ipò Orí?

Ẹ̀yin Obìnrin, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Tẹrí Ba Fún Ipò Orí?

“Orí obìnrin ni ọkùnrin.”—1 KỌ́R. 11:3.

1, 2. (a) Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ètò tí Jèhófà ṣe nípa ipò orí àti ìtẹríba? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 JÈHÓFÀ ló fìdí ìṣètò ipò orí lélẹ̀ lọ́nà tó tẹ̀ léra, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé “orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi” àti pé “orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 11:3) Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí fi hàn pé Jésù kà á sí àǹfààní láti máa tẹrí ba fún Orí rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, èyí sì máa ń mú kó láyọ̀; lẹ́yìn náà ó tún fi hàn pé Kristi ni orí àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni. Nínú ìbálò Kristi pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó jẹ́ onínúure, ẹni pẹ̀lẹ́, aláàánú àti ẹni tí kò mọ ti ara rẹ̀ nìkan. Irú ẹni tó yẹ kí àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìjọ náà jẹ́ nìyẹn, pàápàá sí àwọn aya wọn.

2 Àmọ́, àwọn obìnrin ńkọ́? Ta ni orí wọn? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Orí obìnrin ni ọkùnrin.” Ojú wo ló yẹ kí àwọn obìnrin fi wo gbólóhùn tí Ọlọ́run mí sí yìí? Ṣé ìlànà yìí ṣì wúlò bí ọkọ bá jẹ́ aláìgbàgbọ́? Ṣé ohun tí ìtẹríba fún ipò orí túmọ̀ sí ni pé kí aya kàn máa dákẹ́, kó má lè sọ tẹnu rẹ̀ bí ìpinnu bá wà láti ṣe? Báwo ni obìnrin ṣe lè gba ìyìn fún ara rẹ̀?

“Èmi Yóò Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Kan fún Un”

3, 4. Kí nìdí tí ìṣètò ipò orí fi ṣàǹfààní nínú ìgbéyàwó?

3 Ọlọ́run ló fìdí ìṣètò ipò orí múlẹ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà Ọlọ́run ti dá Ádámù, ó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dá Éfà, inú Ádámù dùn gan-an pé òun ti ní ẹnì kejì àti olùrànlọ́wọ́ débi tó fi sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.” (Jẹ́n. 2:18-24) Ádámù àti Éfà ní ìrètí àgbàyanu láti jẹ́ bàbá àti ìyá fún àtìrandíran gbogbo ẹ̀dá èèyàn pípé, tí wọ́n yóò máa gbé títí láé nínú ayọ̀ lórí Párádísè ilẹ̀ ayé.

4 Nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ àwọn obí wa àkọ́kọ́, wọ́n pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé nínú ọgbà Édẹ́nì. (Ka Róòmù 5:12.) Àmọ́, ìyẹn ò fòpin sí ìṣètò ipò orí. Bí tọkọtaya bá tẹ̀ lé ìlànà ipò orí yìí, ó máa ṣe wọ́n láǹfààní ó sì máa mú kí wọ́n láyọ̀. Ọ̀rọ̀ tiwọn náà yóò wá rí bíi ti Jésù, ẹni tó tẹrí ba fún Jèhófà, tó jẹ́ Orí rẹ̀. Kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó máa “ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú [Jèhófà] ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Nítorí àìpé, kò ṣeé ṣe fún àwọn ọkùnrin mọ́ láti lo ipò orí wọn lọ́nà pípé, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣeé ṣe fún àwọn obìnrin náà láti tẹrí ba lọ́nà pípé. Àmọ́, bí tọkọtaya ò bá dẹ́kun láti máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe, ìṣètò náà á mú kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tó ga jù lọ, èyí tí ìgbéyàwó èyíkéyìí lè ní, lákòókò yìí.

5. Kí nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù 12:10 sọ́kàn?

5 Bí tọkọtaya bá fẹ́ kí ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó wà fún gbogbo Kristẹni yìí sọ́kàn pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Bákan náà, ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè “di onínúrere sí ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí [wọ́n] máa dárí ji ara [wọn] fàlàlà.”—Éfé. 4:32.

Bí Ọkọ Tàbí Aya Bá Jẹ́ Aláìgbàgbọ́

6, 7. Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí aya tó jẹ́ Kristẹni bá ń tẹrí ba fún ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́?

6 Bí ọkọ tàbí aya rẹ kì í bá ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà ńkọ́? Ohun kan ni pé, ọkọ ló sábà máa ń jẹ́ aláìgbàgbọ́. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe yẹ kí ìyàwó rẹ̀ máa ṣe sí i? Bíbélì dáhùn pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pét. 3:1, 2.

7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún aya pé kó máa wà ní ìtẹríba fún ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìwà rere aya lè mú kí irú ọkọ bẹ́ẹ̀ fẹ́ láti mọ ohun tó mú kí ìwà aya rẹ̀ dára gan-an. Ìyẹn sì lè mú kó ṣe àyẹ̀wò ohun tí aya rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni gbà gbọ́, kí òun fúnra rẹ̀ sì gba òtítọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

8, 9. Kí ni aya tó jẹ́ Kristẹni lè ṣe bí ìwà rere rẹ̀ kò bá mú kí ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ yíwà pa dà?

8 Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ìwà rere aya yìí kò mú kí ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ náà yí ìwà rẹ̀ pa dà ńkọ́? Bó ti wù kí ipò nǹkan burú tó, Ìwé Mímọ́ fún àwọn aya tó ní ọkọ aláìgbàgbọ́ ní ìṣírí pé kí wọ́n máa fi àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù nígbà gbogbo. Bí àpẹẹrẹ, a kà nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4 pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” Torí náà, ó dára kí aya tó jẹ́ Kristẹni náà máa bá a nìṣó láti hùwà “pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra,” kó sì máa fi ìfẹ́ fara da ipò náà. (Éfé. 4:2) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó ṣeé ṣe láti máa fi àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù, bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé nǹkan ò rọgbọ.

9 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílí. 4:13) Ẹ̀mí Ọlọ́run máa mú kó ṣeé ṣe fún aya tó jẹ́ Kristẹni láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ́ pé ì bá ṣòro láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, bí ọkọ bá ń fi ọwọ́ líle koko mú aya, ó lè máa ṣe aya bíi pé kó gbẹ̀san. Àmọ́, Bíbélì sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” (Róòmù 12:17-19) Bákan náà, ìwé 1 Tẹsalóníkà 5:15 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ rí i pé ẹnì kankan kò fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe fún ẹnikẹ́ni mìíràn, ṣùgbọ́n nígbà gbogbo ẹ máa lépa ohun rere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn.” Bí Jèhófà bá fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tì wá lẹ́yìn, ohun tí agbára wa kò gbé láti ṣe á wá di èyí tó rọrùn láti ṣe. Torí náà, ẹ wo bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé ká máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àìlera wa!

10. Kí ni Jésù ṣe nípa àwọn tó sọ̀rọ̀ tàbí tó hùwà tí kò dáa sí i?

10 Jésù fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn tó bá sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí kò dáa sí wa. Ìwé 1 Pétérù 2:23 sọ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” A gbà wá níyànjú pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí ìwà búburú táwọn míì ń hù mú ẹ bínú. A sì tún gba gbogbo Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú, kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn.”—1 Pét. 3:8, 9.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Àwọn Aya Kàn Máa Dákẹ́?

11. Àǹfààní ńláǹlà wo ni Ọlọ́run fi jíǹkí àwọn obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni?

11 Ó yẹ kí àwọn obìnrin máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ wọn. Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni kí wọ́n kàn máa dákẹ́, tí wọn ò sì ní máa dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé tàbí ọ̀rọ̀ mìíràn tó bá wáyé? Rárá o. Tọkùnrin tobìnrin ni Jèhófà fún ní ọ̀pọ̀ ojúṣe láti bójú tó. Ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe dá olúkúlùkù àwọn tó para pọ̀ di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] lọ́lá tó láti di ọba àti àlùfáà lókè ọ̀run nígbà tí Kristi bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ilẹ̀ ayé! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn obìnrin wà lára wọn. (Gál. 3:26-29) Ó dájú nígbà náà pé Jèhófà ní iṣẹ́ tó fẹ́ káwọn obìnrin máa ṣe nínú ìṣètò rẹ̀.

12, 13. Fúnni ní àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àwọn obìnrin sọ àsọtẹ́lẹ̀.

12 Bí àpẹẹrẹ, ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn obìnrin máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ìwé Jóẹ́lì 2:28, 29 tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. . . . Èmi yóò sì tú ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti sára àwọn ìránṣẹ́bìnrin pàápàá ní ọjọ́ wọnnì.”

13 Tọkùnrin tobìnrin ló wà lára àwọn ọgọ́fà [120] ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n pé jọ sínú yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù, lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. A sì tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí gbogbo wọn. Ìyẹn ni Pétérù fi fa ọ̀rọ̀ tí wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ yọ, tó sì sọ pé ọ̀rọ̀ yẹn ló ní ìmúṣẹ sí tọkùnrin tobìnrin tó wà níbẹ̀ lára. Pétérù sọ pé: “Èyí ni ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì pé, ‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,’ ni Ọlọ́run wí, ‘èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ . . . ; ṣe ni èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní ọjọ́ wọnnì, wọn yóò sì sọ tẹ́lẹ̀.’”—Ìṣe 2:16-18.

14. Ipa wo ni àwọn obìnrin kó nínú títan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní?

14 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn obìnrin kópa ribiribi nínú títan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀. Wọ́n wàásù fún àwọn ẹlòmíì nípa Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. (Lúùkù 8:1-3) Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Fébè ní “òjíṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkíríà.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì ń fi ìkíni ránṣẹ́ sí àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀, ó dárúkọ àwọn obìnrin mélòó kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, lára wọn ni “Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa.” Ó tún sọ nípa “Pésísì olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n, nítorí ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa.”—Róòmù 16:1, 12.

15. Ipa wo ni àwọn obìnrin ń kó nínú títan ẹ̀sìn Kristẹni kálẹ̀ lóde òní?

15 Lóde òní, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méje, tí wọ́n ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé ni wọ́n jẹ́ obìnrin tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra. (Mát 24:14) Ọ̀pọ̀ lára wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, míṣọ́nnárì àti ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Onísáàmù náà, Dáfídì, kọrin pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.” (Sm. 68:11) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí! Jèhófà mọyì ipa táwọn obìnrin ń kó nínú pípolongo ìhìn rere àti mímú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Torí náà, ohun tí Bíbélì sọ pé kí àwọn obìnrin wà ní ìtẹríba kò túmọ̀ sí pé kí wọ́n má máa sọ tinú wọn jáde.

Àwọn Obìnrin Méjì Tí Wọ́n Sọ Tẹnu Wọn

16, 17. Báwo ni àpẹẹrẹ Sérà ṣe fi hàn pé a kò retí pé kí àwọn aya má máa sọ tẹnu wọn?

16 Bí Jèhófà bá fún àwọn obìnrin ní àǹfààní tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, ṣé kò wá yẹ káwọn ọkọ máa fọ̀rọ̀ lọ ìyàwó wọn kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì? Ìwà ọgbọ́n ló máa jẹ́ fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ nínú èyí tí àwọn aya ti sọ̀rọ̀ tàbí tí wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkọ wọn kọ́ ló sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò.

17 Sérà, ìyàwó baba ńlá náà, Ábúráhámù, sọ léraléra fún ọkọ rẹ̀ pé kó lé ìyàwó rẹ̀ kejì àti ọmọ tó bí jáde nítorí pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún òun. “Ohun náà kò dùn mọ́ Ábúráhámù nínú rárá,” ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ojú tí Ọlọ́run fi wò ó. Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sárà ń sọ fún ọ di ohun tí kò dùn mọ́ ọ nínú nípa ọmọdékùnrin náà àti nípa ẹrúbìnrin rẹ. Fetí sí ohùn rẹ̀.” (Jẹ́n. 21:8-12) Ábúráhámù ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un, ó fetí sí Sérà, ó sì ṣe ohun tó béèrè.

18. Kí ni Ábígẹ́lì ṣe láìsọ fún ọkọ rẹ̀?

18 Tún ronú nípa Ábígẹ́lì, ìyàwó Nábálì. Nígbà tí Dáfídì sá kúrò níwájú Sọ́ọ̀lù Ọba tó jẹ́ òjòwú, ó pàgọ́ sítòsí agbo ẹran Nábálì, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Dípò tí Dáfídì ì bá fi mú lára ohun ìní rẹpẹtẹ tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ní, ńṣe ni òun àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ọkùnrin náà dáàbò bo ohun tí í ṣe tirẹ̀. Àmọ́, Nábálì “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀,” ó sì “fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí” àwọn ọkùnrin tí Dáfídì rán lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. “Ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun” ni, “ìwà òpònú sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè fún àwọn nǹkan díẹ̀ lọ́wọ́ Nábálì, ó kọ̀ láti fún wọn. Kí ni Ábígẹ́lì ṣe nígbà tó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀? Láìsọ fún Nábálì, ó “ṣe kánkán, ó sì mú igba ìṣù búrẹ́dì àti ìṣà wáìnì títóbi méjì àti àgùntàn márùn-ún tí a ti ṣètò àti òṣùwọ̀n séà márùn-ún àyangbẹ ọkà àti ọgọ́rùn-ún ìṣù èso àjàrà gbígbẹ àti igba ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́” ó sì kó wọn fún Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Ṣé ohun tó tọ́ ni Ábígẹ́lì ṣe? Bíbélì sọ pé “Jèhófà sì kọlu Nábálì, tí ó fi kú.” Lẹ́yìn náà ni Dáfídì fẹ́ Ábígẹ́lì.—1 Sám. 25:3, 14-19, 23-25, 38-42.

Obìnrin Tó Gba Ìyìn fún Ara Rẹ̀’

19, 20. Kí ló máa ń mú kí obìnrin yẹ lẹ́ni tó yẹ ká gbóríyìn fún?

19 Ìwé Mímọ́ gbóríyìn fún aya tó bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Nínú ìwé Òwe, a gbóríyìn fún “aya tí ó dáńgájíá,” torí pé, “ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn. Ọkàn-àyà olúwa rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, kò sì ṣaláìní èrè. Obìnrin náà fi ohun rere san án lẹ́san, láìjẹ́ ohun búburú, ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.” Síwájú sí i, “ó fi ọgbọ́n la ẹnu rẹ̀, òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sì ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀. Ó ń ṣọ́ àwọn ohun tí ń lọ nínú agbo ilé rẹ̀, kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́. Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní aláyọ̀; olúwa rẹ̀ dìde, ó sì yìn ín.”—Òwe 31:10-12, 26-28.

20 Kí ló máa ń mú kí obìnrin yẹ lẹ́ni tó yẹ ká gbóríyìn fún? Ìwé Òwe 31:30 sọ pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.” Ara ohun tó ń fi hàn pé èèyàn bẹ̀rù Jèhófà ni pé kó máa fínnú fíndọ̀ tẹrí ba fún ìṣètò ipò orí. “Orí obìnrin ni ọkùnrin,” gẹ́gẹ́ bí ‘Kristi ti jẹ́ orí olúkúlùkù ọkùnrin,’ tí ‘Ọlọ́run sì jẹ́ orí Kristi.’—1 Kọ́r. 11:3.

Máa Ṣọpẹ́ fún Ẹ̀bùn Ọlọ́run

21, 22. (a) Kí nìdí táwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó fi ní láti máa ṣọpẹ́ fún ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ìṣètò Jèhófà nípa ọlá àṣẹ àti ipò orí? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 17.)

21 Ọ̀pọ̀ ìdí wà fún àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni láti máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run! Wọ́n lè máa ṣe nǹkan ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, kí wọ́n sì máa láyọ̀. Ohun tó tún máa mú kí wọ́n kún fún ọpẹ́ jù lọ ni ìgbéyàwó tó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run àti àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣe ara wọn lọ́kàn, kí wọ́n sì máa bá Jèhófà rìn. (Rúùtù 1:9; Míkà 6:8) Jèhófà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ mọ ohun náà gan-an tó lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀. Ẹ máa ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó fẹ́, ‘ìdùnnú Jèhófà yóò sì máa jẹ́ odi agbára yín,’ nínú ayé onílàásìgbò tá à ń gbé yìí pàápàá.—Neh. 8:10.

22 Bí ọkọ kan tó jẹ́ Kristẹni bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀, á máa lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ agbatẹnirò. Ọkọ á ní ìfẹ́ tòótọ́ fún aya rẹ̀ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, torí pé aya rẹ̀ ń tì í lẹ́yìn, ó sì ń fi ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ hàn fún un. Ní pàtàkì jù lọ, ìgbéyàwó wọn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, á máa bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run wa tó yẹ ká máa yìn.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ètò wo ni Jèhófà ṣe nípa ipò orí àti ìtẹríba?

• Kí nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya máa bu ọlá fún ara wọn?

• Báwo ló ṣe yẹ kí aya tó jẹ́ onígbàgbọ́ máa ṣe sí ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́?

• Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn ọkọ máa fọ̀rọ̀ lọ àwọn aya wọn kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ?

Jèhófà ti fìdí ìṣètò nípa ọlá àṣẹ àti ipò orí múlẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye. Àǹfààní àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí àti àwọn ẹ̀dá èèyàn ni ìṣètò yìí wà fún. Ó ń fún wọn láǹfààní láti lo òmìnira wọn láti yan ohun tí wọ́n fẹ́, kí wọ́n sì tún máa bọlá fún Ọlọ́run nípa sísìn ín ní ìṣọ̀kan.—Sm. 133:1.

Ìjọ àwọn ẹni àmì òróró mọyì ọlá àṣẹ àti ipò orí Jésù Kristi. (Éfé. 1:22, 23) Níwọ̀n bí Kristi náà sì ti mọyì ọlá àṣẹ Ọlọ́run, bó bá yá “Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” (1 Kọ́r. 15:27, 28) Ẹ wo bó ṣe bá a mu tó nígbà náà pé kí àwọn èèyàn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò ipò orí láàárín ìjọ àti nínú ìdílé! (1 Kọ́r. 11:3; Héb. 13:17) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa ṣe ara wa láǹfààní bá a ti ń rí ìtẹ́wọ́gbà àti ìbùkún Jèhófà.—Aísá. 48:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àdúrà lè ran aya tó jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ láti máa fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jèhófà mọyì ipá tí àwọn obìnrin ń kó nínú mímú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ire Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú